ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 7/8 ojú ìwé 20-21
  • Ewé Pákí—Oúnjẹ Òòjọ́ Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Ènìyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ewé Pákí—Oúnjẹ Òòjọ́ Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Ènìyàn
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Tọ́ Ngunza Díẹ̀ Wò
  • Ngukassa Tàbí Kanda Díẹ̀ Ńkọ́?
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Ẹ̀pà Lílọ̀—Bí Wọ́n Ṣe Ń ṣe é Ní Áfíríkà
    Jí!—1999
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1998
  • Jẹ́ Ká Lọ sí Ọjà Kan Nílẹ̀ Áfíríkà
    Jí!—2010
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 7/8 ojú ìwé 20-21

Ewé Pákí—Oúnjẹ Òòjọ́ Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Ènìyàn

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ CENTRAL AFRICAN REPUBLIC

GBOGBO rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 1600, nígbà tí àwọn ará Portugal mú pákí, tàbí manioc, wọ Áfíríkà láti Gúúsù America. Brazil ni a gbà gbọ́ pé pákí ti wá, nítorí pé ọ̀rọ̀ náà, “manioc,” pilẹ̀ ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀ya Tupi ti Brazil ní Àfonífojì Amazon.

Àwọn ènìyàn Áfíríkà mọyì gbòǹgbò rẹ̀ gan-an, àmọ́, ewé rẹ̀ kìjikìji ńkọ́? Àwọn kan ń lò ó gẹ́gẹ́ bí egbòogi fún egbò tàbí láti wo àrùn ilẹ̀ẹ́gbóná. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ewé náà jẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ní Central African Republic àti àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà míràn, níwọ̀n bí a ti lè fi ṣe oúnjẹ aládùn. Ní ti gidi, ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn míṣọ́nnárì Watch Tower tuntun kọ́kọ́ ń mọ̀ níhìn-ín ni ngunza. Ọbẹ̀ aládùn kan tí wọ́n fi ewé pákí sè ni, oúnjẹ tí ó sì wà káàkiri orílẹ̀-èdè Central African Republic ni—oúnjẹ tí àlejò tí ó bá lọ sí àárín gbùngbun Áfíríkà gbọ́dọ̀ tọ́ wò ṣáá ni.

Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ará Europe tí ń gbé Áfíríkà kò jẹ́ fẹnu kan oúnjẹ tí wọ́n fi ewé yìí sè, níwọ̀n bí wọ́n ti kà á sí oúnjẹ àwọn ọmọ onílẹ̀, kì í ṣe fún àwọn àjèjì. Ṣùgbọ́n, kí ni òkodoro òtítọ́ ibẹ̀? Ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Central African Republic, Sierra Leone, àti Zaire, ewé yìí jẹ́ lájorí oúnjẹ fún ọ̀pọ̀ ìdílé.

Bí o bá wà nínú ọkọ̀ òfuurufú tí ó fò gba Central African Republic kọjá tàbí ti o rìnrìn àjò gba àárín rẹ̀ kọjá, ìwọ óò rí àwọ̀ ewé títutù yọ̀yọ̀—igi, igbó, koríko, àti, láàárín wọn, àwọn oko pákí pẹ̀lú ewé wọn kìjikìji dídá yàtọ̀. Abúlé kọ̀ọ̀kan ni a gbin pákí yí ká. Àwọn ènìyàn máa ń gbìn ín sẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé wọn, kódà ní olú ìlú wọn, Bangui, ìwọ óò rí pákí lóri gbogbo ilẹ̀ kéékèèké àti lórí ilẹ̀ tóóró tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé dídá dúró gedegbe tàbí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà. Dájúdájú, oúnjẹ pàtàkì ni ó jẹ́ ní ìhà ibí yìí lórí ilẹ̀ ayé.

Tọ́ Ngunza Díẹ̀ Wò

Bí àwọn míṣọ́nnárì tuntún bá dé, àwọn ọ̀rẹ́ tètè máa ń ké sí wọn láti wá tọ́ ngunza díẹ̀ wò. Ó jẹ́ oúnjẹ kan tí a fi ewé manioc olókìkí náà sè. Àwọn obìnrin ìbílẹ̀ mọ bí a ṣe ń sè é tí yóò fi dùn. Ó jọ pé obìnrin kọ̀ọ̀kan ló ní ọ̀nà tirẹ̀ láti fi sè é. Ọ̀kan lára ohun tí àwọn ọmọdébìnrin kọ́kọ́ ń kọ́ lọ́dọ̀ àwọn ìya wọn nípa oúnjẹ sísè ni bí a ṣe ń se ngunza.

Wọ́n máa ń yangàn láti ṣàlàyé ohun tí ó jẹ́ àti bí wọ́n ṣe ń sè é. Inú àwọn obìnrin máa ń dùn bí o bá fi ọkàn ìfẹ́ hàn sí oúnjẹ ìbílẹ̀ yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, wọn óò sọ fún ọ pé ewé pákí kò wọ́nwó, ó sì pọ̀ àti pé o lè rí i nígbà òjò àti nígbà ẹ̀ẹ̀rùn. Ní àwọn àkókò tí gbogbo bùkátà ìdílé àti ìfòsókè owó ọjà bá ń ṣẹlẹ̀, ewé pákí ń kó ipa pàtàkì nínú bíbọ́ ìdílé. Jọ̀wọ́ rántí pé àwọn ìdílé Áfíríkà sábà máa ń tóbi. Ẹnú pọ̀ láti bọ́, àwọn tí yóò sì jẹún pọ̀. Ó máa ń gba wákàtí bíi mélòó kan láti se ngunza. A gbọ́dọ̀ yọ gbogbo ìkorò ara ewé náà dà nù kí a tóó jẹ ẹ́. A ń lo ọ̀nà ìbílẹ̀ láti mú oje ara rẹ̀ kúrò, èyí sì ní lílọ̀ àti sísè é lemọ́lemọ́ nínú.

Epo pupa ni àwọn obìnrin Áfíríkà fẹ́ràn jù lọ láti máa fi se ngunza. Kòṣeémánìí ni epo pupa ìbílẹ̀. Ngunza pẹ̀lú ẹ̀pà lílọ̀ díẹ̀ àti bóyá àlùbọ́sà díẹ̀ àti àlùbọ́sà eléwé ni oúnjẹ òòjọ́ ìdílé kan. Àmọ́ bí o bá ń retí àlejò ńkọ́? Nígbà náà, ngunza gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun pàtàkì, ohun tí wọn óò máa rántí. Nítorí náà, obìnrin tí ó gbà wọ́n lálejò yóò fi èròjà tí ó fẹ́ràn jù lọ sí i—ẹja yíyan tàbí ègé ẹran yíyan—pẹ̀lú àlùbọ́sà eléwé àti àlùbọ́sà pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ẹ̀pà tí wọ́n fọwọ́ lọ̀ nílé. Inú ìṣasùn ńlá kan ni wọn óò da gbogbo èyí sí. Sùúrù àti sísè é fún àkókò gígùn ni ìyókù gbà.

Lónìí, obìnrin tí ó gbà wá lálejò yóò fún wa ní ngunza pẹ̀lú ìrẹsì jẹ. Ìrẹsì tí a bù sílẹ̀ pẹ̀lú ṣíbí ngunza gbígbóná kan tàbí méjì tí a dà sórí rẹ̀ jẹ́ oúnjẹ aládùn fún àwọn ará Áfíríkà àti ọ̀pọ̀ àwọn àjèjì pẹ̀lú. Fi ata díẹ̀ sí i, nígbà yìí ni ìwọ óò mọ ohun tí ngunza jẹ́. Bí o bá fi ife wáìnì pupa kan tẹ oúnjẹ náà, ìwọ yóò gbádùn ìtọ́wò rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.

Ngukassa Tàbí Kanda Díẹ̀ Ńkọ́?

Tí o bá ń rìnrìn àjò láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè náà, ìwọ yóò rí i pé oríṣiríṣi ọ̀nà ni àwọn ènìyàn ń gba se ngunza. Ngukassa ńkọ́? Ní ọjọ́ tí òjò bá mú kí àyíká tutù, ngukassa, ọbẹ̀ tí a fi onírúurú àwọn ohun ọ̀gbìn inú ọgbà tàbí oko sè, lè jẹ́ ohun tí ó yẹ ọ́. Epo pupa, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà, ẹ̀pà, ọ̀dùnkún, ọkà (àgbàdo), àti pàápàá ewé pákí díẹ̀ ni a sè pa pọ̀, àmọ́, wọn kò fi iyọ̀ sí i—hóró iyọ̀ kan kò sí níbẹ̀. Àṣírí ibẹ̀ nìyẹn! Adùnyùngbà àti aṣaralóore ni ọbẹ̀ náà. Bí o bá sì ń lọ ìrìn àjò gígùn kan, mú kanda díẹ̀ dání. Ewé pákí pẹ̀lú ẹja tàbí ẹran yíyan tí wọ́n lọ̀ pọ̀ ni wọ́n fi se eléyìí. Wọ́n máa ń se kanda nípa fífi ewé pákí wé e, tí wọn óò sì yan án lórí iná fún ọ̀pọ wákàtí títí tí yóò fi le, tí yóò sì gbẹ. Ó ṣeé gbé pa mọ́ fún ọjọ́ púpọ̀, a sì lè jẹ ẹ́ pẹ̀lú búrẹ́dì. Ó dára dọ́ba fún àwọn arìnrìn àjò.

Ìgbàkigbà tí o bá ṣèbẹ̀wò sí Áfíríkà, èé ṣe tí o kò béèrè fún pákí? Dán an wò, kí o sì dara pọ̀ mọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tí ń gbádùn rẹ̀!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́