Jẹ́ Ká Lọ sí Ọjà Kan Nílẹ̀ Áfíríkà
Ọ̀KAN lára àwọn ọ̀nà téèyàn lè gbà mọ àṣà àti oríṣi oúnjẹ tó wà lórílẹ̀-èdè kan ni pé kéèyàn lọ sí ọjà wọn. Ibẹ̀ ni èèyàn á ti rí bí àwọn ará ìlú náà ṣe ń ṣe, èèyàn á lè jẹ oúnjẹ wọn, á sì lè ra oríṣiríṣi nǹkan. Wàá tún rí àwọn oníṣòwò tí wọ́n ń fi ọ̀yàyà ṣe ọrọ̀ ajé, tí wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti polówó ọjà wọn fún ẹ láìka èdè tó ò ń sọ sí.
Ṣàṣà ni ibi téèyàn ti lè rí àwọn ọjà míì tó fani mọ́ra bíi ti ilẹ̀ Áfíríkà. Oríṣiríṣi èèyàn làwọn ọlọ́jà Áfíríkà máa ń bá dòwò pọ̀, onírúurú ọjà ni wọ́n sì máa ń tà. Téèyàn bá débẹ̀, èèyàn á mọ ohun tó ń lọ nílẹ̀ Áfíríkà. Ó yá ká jọ lọ sí ọjà kan tó wà nílùú Douala lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù.
Bí Wọ́n Ṣe Máa Ń Lọ Sọ́jà
Ní ọ̀pọ̀ àwọn ìlú ńláńlá tó wà nílẹ̀ Áfíríkà, alùpùpù làwọn èèyàn sábà máa ń gùn lọ sọ́jà, òun ló yá jù lọ, owó rẹ̀ sì mọ níwọ̀n. Ṣàṣà ni ibi téèyàn ò ti lè rí àwọn tó ń fi alùpùpù gbé àwọn èèyàn lọ gbé wọn bọ̀ láàárín ìlú. Tó bá jẹ́ pé o kì í bẹ̀rù, o lè ní kí wọ́n gbé ẹ. Lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù, alùpùpù làwọn èèyàn sábà máa ń gùn torí ó yá ju àwọn ohun ìrìnnà míì lọ, owó tí wọ́n ń gbà sì mọ níwọ̀n.
Fún àwọn tí kì í fẹ́ ṣe wàhálà púpọ̀ àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n fi ń gbé àwọn èèyàn tún wà lóríṣiríṣi. Àwọn bíi mélòó kan máa ń wọ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan náà, kí wọ́n lè jọ pín owó rẹ̀ san.
Àwọn Ilé Ìtajà Lóríṣiríṣi
Béèyàn bá dé ọjà yìí fúngbà àkọ́kọ́, ó lè má mọ ibi tóun ti máa bẹ̀rẹ̀ torí bí èrò ṣe pọ̀ táwọn ìsọ̀ tó wà níbẹ̀ kò sì lóǹkà. O máa rí ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan àwọn ọmọdé, tó ń kiri ọjà. Tó o bá wo àwọn apẹ̀rẹ̀ tí wọ́n gbé sórí dáadáa, wàá rí àwọn adìyẹ, ọsàn tí wọ́n ti hó, oògùn lóríṣiríṣi àtàwọn nǹkan míì.
Wọ́n tún fi ọ̀pọ̀ àwọn káńtà onígi pàtẹ ẹ̀fọ́ àti èso lóríṣiríṣi, irú bí cabbage, kárọ́ọ̀tì, apálá, ìgbá, gbọ̀rọ̀, ẹ̀wà ilẹ̀ Faransé, ọ̀dùnkún, tòmátì, iṣu àti oríṣiríṣi ewébẹ̀ lettuce. Ẹni tó bá jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ Áfíríkà lè má mọ gbogbo nǹkan tí wọ́n ń tà yìí torí pé àwọn kan lára àwọn ọjà yìí kò sí láwọn ilẹ̀ míì. Ìsọ̀ àwọn tó ń ta ata tó pọ́n dáadáa àtèyí tó láwọ̀ ìyeyè máa ń fani lójú mọ́ra gan-an, ìrísí àwọn ata náà máa ń fani mọ́ra nígbà tí oòrùn bá ń yọ lọ́wọ́ àárọ̀. Àwọn kan máa ń pàtẹ píà, ọ̀gẹ̀dẹ̀, jàgbure, ẹ̀gúsí, ọ̀pẹ̀yìnbó, ọsàn mímu àti ọsàn wẹ́wẹ́. Wọ́n máa ń wu èèyàn jẹ, owó rẹ̀ kì í sì í pọ̀ jù! Iṣu, ẹ̀gẹ́ àti ìrẹsì náà kì í gbẹ́yìn láwọn ọjà yìí, torí àwọn ló máa ń pọ̀ jù lọ nínú àwọn irúgbìn ilẹ̀ náà. Wọ́n tún máa ń ta àwọn àlùbọ́sà àti aáyù tí wọ́n kó wọ̀lú láti òkè òkun.
Ní ọ̀kan lára àwọn ọjà tó wà nílùú Douala, àwọn Haúsá àtàwọn Fúlàní ló ni ìsọ̀ tó pọ̀ jù lọ níbẹ̀. Lára ohun tó mú kí àwọn oníṣòwò yìí yàtọ̀ ni ẹ̀wù àlọ́mọ́ra aláwọ̀ búlúù, funfun tàbí aláwọ̀ ìyeyè tí wọ́n máa ń wọ̀, wọ́n máa ń pè é ní gandouras tàbí boubous. Bí wọ́n ṣe ń fọ̀yàyà kí àwọn èèyàn lédè Fulfulde tún jẹ́ kí wọ́n dá yàtọ̀. Ara sábà máa ń tu àwọn èèyàn nínú ọjà náà. Nígbà tí mo ṣèbẹ̀wò síbẹ̀, Ibrahim, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń tajà níbẹ̀ fún mi ní àlùbọ́sà ńláńlá mẹ́ta. Ó wá sọ pé: “Sọ fún ìyàwó ẹ pé kó fi se ìrẹsì aládùn fún ẹ, kó má ṣe jẹ́ kí iná pọ̀ jù.”
Bí mo ṣe rìn síwájú díẹ̀, mo kan ìsọ̀ àwọn ẹlẹ́ran níbi tí wọ́n ti ń ta àwọn ẹran màlúù àti ti ewúrẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa. Àwọn gìrìpá ọkùnrin máa ń gbé àwọn ẹran tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa yìí sí èjìká wá sí ìsọ̀, wọ́n á sì gbé wọn sórí tábìlì. Àwọn ẹlẹ́ran máa ń fi ọ̀bẹ gígùn wọn dárà bí wọ́n ṣe ń pe àwọn oníbàárà pé kí wọ́n nawọ́ sí èyí tí wọ́n bá fẹ́. Òòyẹ̀ ewúrẹ́, adìyẹ àti ẹlẹ́dẹ̀ wà níbẹ̀ fún àwọn oníbàárà tó bá fẹ́ lọ pa á fúnra wọn.
Ó Yá Ká Lọ Jẹun
Kò sí bí ọjà ṣe máa wà tí kò ní sí ibi téèyàn ti lè jẹun. Lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù, àwọn ìsọ̀ tí wọ́n ti ń ta oúnjẹ máa ń wà láwọn ọjà wọn. Àwọn kan máa ń yí orin sókè láti pàfiyèsí oníbàárà, síbẹ̀ àwọn ilé oúnjẹ tí kò sáriwo téèyàn ti lè jẹ àwọn oúnjẹ ilẹ̀ Áfíríkà kéèyàn sì rí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà tún wà. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n kọ àwọn oúnjẹ tó wà fún títà sára pátákó kan, ẹni tí kò bá sì lóye ohun tí wọ́n kọ síbẹ̀ lè wá ẹni tó máa túmọ̀ rẹ̀ fún un.
Oúnjẹ méjì tí wọ́n sábà máa ń tà ni ìrẹsì àti fùfú. Iyán pákí, ti ọ̀gẹ̀dẹ̀ tàbí ti iṣu ni wọ́n ń pè ní fùfú lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù. Wọ́n tún máa ń ta ẹja àti ẹran yíyan, ẹran adìyẹ pẹ̀lú ọbẹ̀ ilá, ọbẹ̀ ẹ̀pà lílọ̀ tàbí ọbẹ̀ tòmátì. Wọn kì í sábà kánjú jẹun làwọn ilé oúnjẹ yìí, ìyẹn sì máa ń jẹ́ káwọn èèyàn lè bára wọn sọ̀rọ̀ fún àkókò gígùn níbẹ̀.
Nígbà tá a wọ ilé oúnjẹ kan, àwọn obìnrin méjì ló wá fún wa lóúnjẹ. Ọ̀kan nínú wọn fi abọ́ pẹrẹsẹ gbé ìrẹsì tó ń gbóná fẹlifẹli, ẹ̀wà àti fùfú wá. Wọ́n sì tún gbé ọbẹ̀ ilá, ẹran àti ẹja yíyan wá pẹ̀lú. Ata gígún tún wà nínú ike kékeré kan fún àwọn tó bá fẹ́ kí oúnjẹ wọn ta lẹ́nu. Obìnrin kejì fi bàsíà gbé omi ìṣanwọ́ wá, ó sì tún mú tówẹ́ẹ̀lì ìnuwọ́ wá. Ó di dandan pé ká fọwọ́ wa torí pé ọwọ́ ni wọ́n fi ń jẹ àwọn oúnjẹ ìbílẹ̀ wọn. Àwọn oníbàárà sábà máa ń gbàdúrà kí wọ́n tó jẹun, àwọn ẹlòmíì tí wọ́n jọ wà nínú ilé oúnjẹ náà sì máa ń dara pọ̀ láti ṣe “Àmín” lẹ́yìn àdúrà náà.
Wíwàásù Lọ́jà
Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń ṣe nǹkan pa pọ̀ láàárín ọjà. Kì í ṣe rírà àti títà nìkan ló máa ń wáyé ní ọjà, àmọ́ wọ́n tún máa ń gbọ́ ìsọfúnni níbẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ máa ń pàdé ara wọn níbẹ̀, àwọn èèyàn sì máa ń ríṣẹ́ níbẹ̀. Bíbélì sọ pé Jésù lọ sí àwọn ibi ọjà, níbi tó ti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tó sì tún wò wọ́n sàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà fèròwérò “ní ibi ọjà pẹ̀lú àwọn tí ó wà ní àrọ́wọ́tó.” (Ìṣe 17:16, 17; Máàkù 6:56) Bákan náà lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù ti rí i pé ó dáa gan-an láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní ọjà.—Ẹnì kan ló kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn ata rírẹ̀dòdò