ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 5/8 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣẹ́pá Ìjákulẹ̀ Ìdíwọ́ Ìwé Kíkà
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 5/8 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Ìdíwọ́ Ìwé Kíkà Mo ń kọ̀wé láti fi ìmoore àtọkànwá mi hàn fún àpilẹ̀kọ náà, “Ṣíṣẹ́pá Ìjákulẹ̀ Ìdíwọ́ Ìwé Kíkà.” (August 8, 1996) Lẹ́yìn tí mo ka ọ̀rọ̀ inú àpótí náà, “Bí A Ṣe Ń Mọ̀ Bí Àwọn Ọmọdé Bá Ní Ìdíwọ́ Ìwé Kíkà” tán, èmi àti ọkọ mi ṣàyẹ̀wò ọmọkùnrin wa ọlọ́dún mẹ́wàá. A rí i pé ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà, a sì ti ń gbégbèésẹ̀ láti pèsè ìrànlọ́wọ́ tí ó nílò fún un, ní ilé àti ní ilé ẹ̀kọ́. Àwọn olùkọ́ rẹ̀ ti sábà máa ń wí fún wa pé, ọmọ tí ó dáńgájíà gidigidi ni, àmọ́, kò jẹ́ fọkàn sí ohun tí ń ṣe. Nítorí náà, ẹ lè finú wòye bí ọpẹ́ wa ti tó pé ẹ tẹ àpilẹ̀kọ yìí jáde.

J. S., Scotland

Gẹ́gẹ́ bí ìyá tí ó ní ọmọ méjì, tí wọ́n ní ìdíwọ́ ìwé kíkà, inú mi dùn láti ka àpilẹ̀kọ yìí. Ó ṣe iṣẹ́ àgbàyanu kan ní kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí àbùkù yí ti jẹ́ gidi tó àti bí ó ṣe ṣòro tó fún àwọn tí wọ́n ní in. Ǹjẹ́ ẹ lè finú wòye ẹni tí kò lè ka àmì òpópónà kan? Tàbí ẹnì kan tí ń gbìyànjú láti yan oúnjẹ láti inú àkọsílẹ̀ oríṣiríṣi oúnjẹ, kí ó sì béèrè fún un, nígbà tí ó jẹ́ pé kò lè ka ohun tí ó wà nínú rẹ̀? Ó dá mi lójú pé àwọn tí àrùn náà ń ṣe yóò fi ìsọfúnni náà sílò gidigidi.

M. K., United States

Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Tí A Wu Léwu Mo dúpẹ́ látọkànwá fún àwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Tí A Wu Léwu—Èrèdí Ìdàníyàn?” (August 8, 1996) A wà nínú ewu pípàdánù búrùjí kan. Àpilẹ̀kọ náà mú kí ìfẹ́ ọkàn mi láti gbé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, níbi tí àwọn ẹranko yóò ti lè gbé láìsí híhalẹ̀ àkúrun mọ́ni, wà lójúfò.

D. I., Albania

Yánpọnyánrin Wíwá Ibi Ìsádi Mo jẹ́ olùwá-ibi-ìsádi kan láti Burundi, mo sì fẹ́ láti fi ìmoore mi hàn fún àwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Ìṣòro Wíwá Ibi Ìsádi—Yóò Ha Dópin Láé Bí?” (August 22, 1996) Ó wú mi lórí gan-an láti kẹ́kọ̀ọ́ ojú ìwòye Jèhófà lórí ọ̀ràn yí àti bí ó ṣe mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ fi inú rere onífẹ̀ẹ́ bá àwọn olùwá-ibi-ìsádi lò ní ìgbà ìjímìjí. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àwọn àpilẹ̀kọ náà; wọ́n tù mí nínú ní gidi.

D. M., Kenya

Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ Bọ́ọ̀sì Nígbà tí mo ń ka àpilẹ̀kọ náà, “Ṣíṣẹ́pá Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ Pẹ̀lú Okun Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà” (August 22, 1996), mo wulẹ̀ ń sunkún ni, nítorí pé ó kàn mí gbọ̀ngbọ̀n. Èmi náà ní ìjàǹbá kan, pẹ̀lú ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ kan. Wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn náà ni ó kú, nítorí pé ó fara pa yánnayànna. Láàárín ọdún márùn-ún tí ó tẹ̀ lé e, mo kọ́ láti máa mú àwọn ìmọ̀lára ẹ̀dùn ọkàn àti ẹ̀bi lílekoko tí mo ní nítorí pé èmi là á já tí òun kò sì là á já mọ́ra. Mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò rántí ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n. Àánú àwọn tí àwọn olólùfẹ́ wọn kú nínú ọ̀ràn ìbànújẹ́ yìí ní Sípéènì ṣe mí pẹ̀lú.

J. T., United States

Kíkólòlò Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà, “Ahọ́n Àwọn Akólòlò Pàápàá Yóò Sọ̀rọ̀.” (August 22, 1996) Ìrírí Petr Kunc fún mi lókun lọ́nà gígadabú. Èmi náà ń kólòlò. Kí n tó sọ àwíyé Bíbélì kan, mo sábà máa ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti lè ṣàlàyé ọ̀rọ̀ mi ní ketekete.

M. M., Ítálì

Nígbà tí mo pé ọmọ 20 ọdún, mo rí i pé kì í rọrùn fún mi láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ àti láti orí pèpéle ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn iṣẹ́ àyànfúnni kan, òógùn yóò bò mí, yóò sì rẹ̀ mí tẹnutẹnu. Ìṣírí ńlá gbáà ni ó jẹ́ láti ka ìrírí nípa Kristẹni arákùnrin ẹlẹgbẹ́ mi kan tí ń sin Jèhófà láìka ìṣòro yìí sí. Ó ti ràn mí lọ́wọ́ láti ní ojú ìwòye títọ̀nà nípa àwọn nǹkan.

M. S., Japan

Mo ní ìsúnniṣe láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún títẹ ìrírí yìí jáde. Mo ti ní irú ìṣòro kan náà láti ìgbà ọmọdé. Bíi ti Petr, mo ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà kan nínú ìjọ, mo sì ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà fún okun láti ṣàṣeparí àwọn iṣẹ́ àyànfúnni mi. Nísinsìnyí, mo ń darí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, ní ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nínú ọ̀nà ìsọ̀rọ̀ wọn.

N. O. N., Nàìjíríà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́