Ṣíṣẹ́pá Ìjákulẹ̀ Ìdíwọ́ Ìwé Kíkà
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ BRITAIN
JULIE béèrè pé: “Kí ni nọ́ḿba tẹlifóònù rẹ?” Ẹni tí ń bá a sọ̀rọ́ dáhùn. Ṣùgbọ́n nọ́ḿbà tí Julie kọ sílẹ̀ kò jọ èyí tí a sọ fún un rárá.
Vanessa kédàárò pé: ‘Olùkọ́ mi fa àwòrán tí mo yà ya,’ ní ṣíṣàfikún pé, ‘N kò tilẹ̀ lè rántí ohun tí ó sọ mọ́.’
David, tí ó ti lé ní ẹni 70 ọdún, ń tiraka láti ka àwọn ọ̀rọ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí ó ti kọ́ yanjú ní èyí tí ó lé ní ẹ̀wádún mẹ́fà sẹ́yìn.
Julie, Vanessa, àti David ní ìṣòro ẹ̀kọ́ kíkọ́ kan—ọ̀kan tí ń tánni ní sùúrù. Ìdíwọ́ ìwé kíkà ni. Kí ní ń fa ipò yìí? Báwo ni àwọn tí wọ́n ní ìdíwọ́ ìwé kíkà ṣe lè ṣẹ́pá ìjákulẹ̀ tí ó máa ń fà?
Kí Ni Ìdíwọ́ Ìwé Kíkà?
Ìwé atúmọ̀ èdè kán pe ìdíwọ́ ìwé kíkà ní “ìdíwọ́ agbára ìkàwé.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a sábà máa ń bojú wò ó gẹ́gẹ́ bí ìdabarú kan nínú ìwé kíkà, ìdíwọ́ ìwé kíkà lè ní jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú.a
Ọ̀rọ̀ náà léde Gẹ̀ẹ́sì pilẹ̀ láti inú àwọn ọ̀rọ̀ ède Gíríìkì náà, dys, tí ó túmọ̀ sí “ìṣòro pẹ̀lú,” àti lexis, “ọ̀rọ̀.” Ìdíwọ́ ìwé kíkà ní ìṣòro pẹ̀lú ẹyọ ọ̀rọ̀ tàbí èdè nínú. Ó tilẹ̀ tún kan ìṣòro títo àwọn nǹkan lọ́nà ìtòtẹ̀léra títọ́, bí àwọn ọjọ́ inú ọ̀sẹ̀ àti àwọn wóróhùn inú ọ̀rọ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀mọ̀wé H. T. Chasty, ti Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ìdíwọ́ Ìwé Kíkà ti Britain, ṣe wí, ìdíwọ́ ìwé kíkà “jẹ́ àìlèṣe ìtòtẹ̀léra tí ń ba agbára ìrántí onígbà kúkúrú, agbára ìlóye àti agbára ìfọwọ́ṣiṣẹ́ jẹ́.” Abájọ nígbà náà tí àwọn tí wọ́n ní ìdíwọ́ ìwé kíkà fi rí i bí ohun tí ń jáni kulẹ̀!
Ṣàyẹ̀wò ọ̀ran David. Báwo ni òǹkàwé onítara ọkàn tí ó sì ń já geere nígbà kan rí yìí ṣe wáá di ẹni tí ó nílò ìrànlọ́wọ́ ìyàwo rẹ̀ láti tún kọ́ bí a ti ń kàwé lẹ́ẹ̀kan sí i? Àrùn ẹ̀gbà ló ba apá tí ó so pọ̀ mọ́ ìlò èdè nínú ọpọlọ David jẹ́, èyí sì mú kí ìtẹ̀síwájú rẹ̀ nínú ìwé kíkà falẹ̀ lọ́nà tí ń roni lára. Síbẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tí ó gùn kò fún un níṣòro tó àwọn tí ó kúrú. Láìka ìdíwọ́ ìwé kíkà tí àrùn ẹ̀gbá fà yìí sí, agbára David láti jíròrò àti èrò orí rẹ̀ jíjáfáfá kò ní ìpalára. Ọpọlọ ẹ̀dá ènìyán díjú tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn olùwádìí kò fi tí ì lóye gbogbo ohun tí ó jẹ mọ́ bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìsọfúnni tí ó ń rí gbà nípa ohùn àti ìríran síbẹ̀.
Ní ìdà kejì, Julie àti Vanessa, ní ìdíwọ́ ìwé kíkà ti ìdàgbàsókè, èyí tí ó wá ń hàn kedere bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Ní gbogbogbòò, àwọn olùwádìí gbà pé àwọn ọmọ tí ń fi ìlọ́gbọ́nlóye yíyẹ hàn, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń ní ìṣòro nínú kíkọ́ láti kàwé, kọ̀wé, àti láti lo àwọn wóróhùn ọ̀rọ̀, ní ọmọ ọdún méje tàbí mẹ́jọ lè ní ìdíwọ́ ìwé kíkà. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà máa ń kọ ojú wóróhùn tí wọ́n fẹ́ẹ́ dà kọ sẹ́yìn. Finú wòye ìjákulẹ̀ tí Julie àti Vanessa ní nígbà tí àwọn olùkọ́ fi àṣìṣe kà wọ́n sí dìndìnrìn, aláìníkan-ánṣe, àti òkú ọ̀lẹ!
Ní Britain, ènìyàn 1 lára 10 ní ìdíwọ́ ìwé kíkà. Ìkùnà àwọn ẹlòmíràn láti lóye àwọn ìṣòro tí àwọn wọ̀nyí ń dojú kọ wulẹ̀ ń fi kún ìjákulẹ̀ wọn ni.—Wo àpótí ní ojú ìwé 14.
Kí Ní Ń Fa Ìdíwọ́ Ìwé Kíkà?
Agbára ìríran tí kò dára máa ń fa ìṣòro ẹ̀kọ́ kíkọ́ nígbà púpọ̀. Ṣàtúnṣe àbùkù ìríran náà, ìdíwọ́ ìwé kíkà náà yóò sì pòórá. Iye kéréje kan lára àwọn tí wọ́n ní ìṣòro kíkọ́ ìwé kà rí i pé wọ́n lè túbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí ọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá gbé abala ọ̀rá fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláwọ̀ mèremère sórí ìwé náà. Èyí kò wúlò fún àwọn mìíràn.
Ní kíkíyè sí i pé ipò náà ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ nínú ìdílé, àwọn kán ṣàlàyé pé apilẹ̀ àbùdá ló ń fà á. Ní tòótọ́, láìpẹ́ yìí, ìwé ìròyin New Scientist ròyìn nípa ìwádìí “tí ń ṣàtúpalẹ̀ ìsopọ̀ tí a mọ̀ nípa àwọn apilẹ̀ àbùdá tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn àrùn tí agbára ìdènà àrùn tí ń gbógun ti ara rẹ̀ ń fà, irú bíi túúlu àti òtútù àyà, àti àwọn apilẹ̀ àbùdá tí ń fa ìdíwọ́ ìwé kíkà.” Nítorí pé ó túbọ̀ rọrùn fún àwọn tí wọ́n ní ìdíwọ́ ìwé kíkà àti àwọn ìbátan wọn láti ní àwọn àrùn tí agbára ìdènà àrùn tí ń gbógun ti ara rẹ̀ ń fà, àwọn onímọ sáyẹ́ǹsí gbà gbọ́ pé àwọn apilẹ̀ àbùdá tí ń fa ìdíwọ́ ìwé kíkà wà ní agbègbè àpò apilẹ̀ àbùdá tí ó ní àwọn apilẹ̀ àbùdá àrùn wọ̀nyí nínú. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí onímọ sáyẹ́ǹsì nípa ìhùwà ẹ̀dá láàárín àwùjọ, Robert Plomin, ṣe sọ, àwọn olùwádìí “wulẹ̀ ti ṣàwárí agbègbè kan, kì í ṣe apilẹ̀ àbùdá, fún àìlágbára ìṣe ìwé kíkà.”
Apá tí ń ṣàkóso ipò ìrísí ara, ìséraró, àti ìṣiṣẹ́pọ̀ àwọn ẹ̀yà ara nínú ọpọlọ ni a ń pè ní cerebellum. Àwọn onímọ sáyẹ́ǹsì kán sọ pé ó tún ń kópa nínú ìrònú àti ṣíṣàtúpalẹ̀ ède wa. Ó dùn mọ́ni nínú pé àwọn olùwádìí ní Yunifásítì Sheffield ní England ti ṣèmújáde àyẹ̀wò kan nípa ìdíwọ́ ìwé kíkà tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìséraró, àti ìṣiṣẹ́pọ̀ àwọn ẹ̀yà ara. Wọn ronú pé àìṣiṣẹ́ déédéé cerebellum ń sún àwọn apá tí ara wọ́n dá ṣáká nínú ọpọlọ láti ṣe àfidípò. Àwọn ọmọdé kì í sábà ní ìṣòro nígbà tí a bá sọ pé kí wọ́n dúró pẹ̀lú ẹsẹ̀ kan níwájú èkejì, kí wọ́n sì na apá síwájú. Ṣùgbọ́n fi nǹkan dì wọn lójú, àwọn ọmọ tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà yóò sì túbọ̀ máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, níwọ̀n bí wọ́n ti gbára lé agbára ìríran láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti séraró.
Àwọn olùṣèwádìí mìíràn sí i tún tọ́ka sí i pé ọpọlọ àwọn ọmọ tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà ń fi ìyàtọ̀ nínú ètò ìgbékalẹ̀ ara hàn. Bí ó ti yẹ, apá ẹ̀yìn ẹ̀gbẹ́ òsì nínú ọpọlọ́ máa ń tóbi díẹ̀ ju apá kan náà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún lọ, nígbà tí ó jẹ́ pé, nínú ọpọlọ ẹnì kan tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà, ó jọ pé ti ọ̀tún àti ti òsì ń rí bákan náà. Lẹ́yìn náà, àwọn kán tún sọ pé àwọ́n ti rí àìdọ́gba kan nínú ìṣètò àwọn sẹ́ẹ̀lì iṣan ní àwọn apá tí ó kan èdè nínú ọpọlọ.
Ṣùgbọ́n, láìka ohun tí ó ṣeé rí, tí ó jẹ́ okùnfà ìdíwọ́ ìwé kíkà sí, báwo ni a ṣe lè ran àwọn tí wọ́n ní ìṣòro náà lọ́wọ́ lọ́nà dídára jù lọ?
Ìrànwọ́ Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Òbí
Àwọn òbí kan tí wọ́n ní ọmọ tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà ń nímọ̀lára ẹ̀bi, wọ́n sì ń dá ara wọn lẹ́bi fún ipò ìṣòro ọmọ wọn. Bí ìwọ́ bá ń nímọ̀lára lọ́nà yìí, mú ìdágùdẹ̀ náà kúrò nípa mímọ̀ pé kò sí ẹni tí ó pé nínú wa, gbogbo wá sì yàtọ̀ síra. Bẹ̀rẹ̀ nípa mímọ̀ pé ọmọ rẹ tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà nílò ìrànwọ́ láti kojú àìlera rẹ̀ lọ́nà kan náà tí ọmọ kan tí kì í mọ ìyàtọ̀ láàárín àwọ̀ fi nílò rẹ̀. Ìwọ gẹ́gẹ́ bí òbí ní ipa gúnmọ́ láti kó nínú ẹ̀kọ́ ọmọ rẹ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, a kò tí ì lè ṣèdíwọ́ fún ìdíwọ́ ìwé kíkà tàbí kí a wò ó sàn, a lè mú un fúyẹ́. Báwo? Ọ̀jọ̀gbọ́n T. R. Miles, tí ó kọ ìwé Understanding Dyslexia, gba àwọn òbí nímọ̀ràn láti kọ́kọ́ ṣàwárí ohun tí ó jẹ́ ìṣòro fún ọmọ tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà. Lẹ́yìn náà, wọn yóò lè ṣe ìdíyelé bíbọ́gbọ́n mu lórí ibi tí agbára ọmọ wọ́n mọ àti ohun tí wọ́n lè fojú sọ́nà fún. Ìwe Reading and the Dyslexic Child gbani nímọ̀ràn pé: “A gbọ́dọ̀ béèrè pé kí ọmọ náà ṣe dáradára dé ìwọ̀n tí ó bá lè ṣe, kì í sì í ṣe dáradára jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Nípa jíjẹ́ afọ̀rànrora-ẹni àti afúnni-níṣìírí, àti nípa ṣíṣètò fún ọ̀nà ìkọ́ni tí a mú bá ipò ọmọ náà mu, àwọn òbí lè sọ ipa tí ìdíwọ́ ìwé kíkà ní di bínńtín, kí wọ́n sì dín ìdààmú gíga lọ́lá tí ọmọ tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà ń nímọ̀lára rẹ̀ kù.
Ìrànwọ́ Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Olùkọ́
Rántí pé ìṣòro ẹ̀kọ́ kíkọ́ ni ìdíwọ́ ìwé kíkà. Nítorí náà, àwọn olùkọ́ ní láti lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà ní kíláàsi wọn, kí wọ́n sì sapá láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Jẹ́ kí ìjákulẹ̀ àwọn ọmọ náà mọ níwọ̀n nípa jíjẹ́ kí ohun tí o ń retí lọ́dọ wọ́n bọ́gbọ́n mu. Ó ṣe tán, ọmọ tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà lè dàgbà di àgbàlagbà tí ó ṣì ní ìṣòro láti kàwé sókè ketekete.
Má ṣe di apara-ẹni-láyò. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbóríyìn fún àwọn ọmọ náà fún ìtẹ̀síwájú èyíkéyìí tí wọ́n bá ní—àti dájúdájú, fún gbogbo ìsapá wọn. Lẹ́yìn náà pẹ̀lú, yẹra fún ìyìn tí kò mọ síbì kan. Ọ̀jọ̀gbọ́n Miles dámọ̀ràn pé nígbà tí àwọn olùkọ́ bá ṣàkíyèsí ìtẹ̀síwájú díẹ̀, kí wọ́n sọ fún ọmọ tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, mo gbà pé o ti ṣe àwọn àṣìṣe díẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ṣì ń sọ pé o ti ṣe dáradára; ó sàn ju ti ọ̀sẹ̀ tó kọjá lọ, bí a bá sì wo ti ìṣòro tí o ní mọ́ ọn, ó jẹ́ àbájáde tí ó tẹ́ni lọ́rùn kan.” Ṣùgbọ́n nígbà tí kò bá sí ìmúsunwọ̀n kankan, ó dámọ̀ran sísọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ó jọ pé èyí báyìíbáyìí ṣì ń fún ọ níṣòro; jẹ́ kí á wò ó bóyá a lè ṣàwárí ọ̀nà míràn kan láti ràn ọ́ lọ́wọ́.”
Ṣọ́ra fún sísọ àwọn ọ̀rọ kòbákùngbé nípa agbára ìkàwé ọmọ tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà. Sapá láti mú kí ìwé àti ìwé kíkà jẹ́ ohun ìgbádùn fún un. Báwo? Àwọn òbí àti olùkọ́ lápapọ̀ lè dábàá pé kí ọmọ náà fi ohun ìsàmì kan, bóyá rúlà kékeré kan, sábẹ́ ìlà ìwé tí ó ń kà, níwọ̀n bí òǹkàwé tí kò yára kán ti sábà máa ń jẹ́ kí ohun mìíràn gbà á lọ́kàn. Bí ìṣòro náà bá ń fara hàn nínú kíka àwọn wóróhùn inú ọ̀rọ̀ kan lódì, fi pẹ̀lú inú rere béèrè pé, “Èwo ni wóróhùn àkọ́kọ́?”
Finú wòye bí ó ti jẹ́ ohun amúnirẹ̀wẹ̀sì tó fún ọmọ tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà pé kí olùkọ́ ìṣiro rẹ̀ máa sọ fún un léraléra pé àwọn ìdáhun rẹ̀ kò tọ̀nà. Ẹ wo bí ì bá ti dára tó láti fún un ní àwọn iṣẹ́ tí ó túbọ̀ rọrùn, kí a lè fi ìtẹ́lọ́run yíyanjú wọn dáradára rọ́pò ìjákulẹ̀ tí àìyege ń fà.
Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ olùkọ́ kan sọ pé: “Kókó pàtàkì fún àwọn tí wọ́n ní ìdíwọ́ ìwé kíkà ni kíkẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ gbogbo agbára ìmọ̀lára.” Pa ìríran, ìgbọ́ràn, àti ìfọwọ́bà pọ̀ láti ran ọmọ náà lọ́wọ́ láti kàwé, àti láti pe àwọn wóróhùn ọ̀rọ̀ yanjú. Ọ̀jọ̀gbọ́n Miles ṣàlàyé pé: “Ọmọ náà ní láti fara balẹ̀ wò, kí ó fara balẹ̀ gbọ́, kí ó fiyè sí ìsúnlọsúnbọ̀ ọwọ́ rẹ̀ bí ó ṣe ń kọ̀wé, kí ó sì fiyè sí ìsúnlọsúnbọ̀ ẹnu rẹ̀ bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀.” Nípa ṣíṣe èyí, ọmọ tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà náà yóò mú ìrísí àkọsílẹ̀ wóróhùn bára dọ́gba pẹ̀lú ìró rẹ̀ àti bí ó ṣe ń sún ọwọ́ lọ bọ̀ láti kọ ọ́. Láti ran ọmọ náà lọ́wọ́ láti mọ ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín àwọn wóróhùn tí ń rú u lójú, kọ́ ọ láti bẹ̀rẹ kíkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn wóróhùn náà ní ọ̀gangan ọ̀tọ̀ọ̀tọ rẹ̀. Ìwe Reading and the Dyslexic Child dámọ̀ràn pé: “Bí ó ti yẹ, ọmọ kọ̀ọ̀kan [tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà] gbọ́dọ̀ ní wákàtí kan lóòjọ́ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́mọ kan sí olùkọ́ kan.” Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn àyíká ipò kì í sábà fàyè gba èyí. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà lè ran ara wọn lọ́wọ́.
Ríran Ara Ẹni Lọ́wọ́
Bí o bá ní ìdíwọ́ ìwé kíkà, fojú sun kíka ọ̀pọ̀ jù lọ ìwé rẹ nígbà tí ará bá tù ọ́ jù lọ. Àwọn olùwádìí ti rí i pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ní ìdíwọ́ ìwé kíkà ń ní àbájáde rere bí wọ́n bá ń bá kíka ìwé nìṣó fún nǹkan bíi wákàtí kan àti ààbọ̀, ṣùgbọ́n pé lẹ́yìn ìyẹn, iṣẹ́ wọn ń jó rẹ̀yìn. Ìwe Dyslexia at College sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí ìwọ̀n ẹ̀kọ́ mímọ níwọ̀n, ṣùgbọ́n tí a ń kọ́ déédéé túbọ̀ ṣàǹfààní ju ìsapá gbígbóná janjan ní ìdákúrekú lọ.” Lóòótọ́, yóò gbà ọ́ lákòókò tí ó túbọ̀ gùn láti kàwé kí o sì mọ àwọn wóróhùn dunjú. Ṣùgbọ́n, fàyà rán an.
Máa lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kékeré alágbèéká tàbí, èyí tí ó túbọ̀ sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà ìtẹ̀wé tí ó ní ìṣètò tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò àwọn wóróhùn ọ̀rọ̀ tí o bá tẹ̀. Fi ẹ̀kọ́ nípa bí a ṣe ń to ìsọfúnni àti bí a ṣe ń fi ìjáfáfá ṣàmúlò ìsọfúnni kún èyí.—Wo àpótí ojú ìwé 13.
Gbádùn àwọn ìwé nípa títẹ́tí sí àwọn tí a gba sóri kásẹ́ẹ̀tì. Dájúdájú, ìwé ìròyìn yìí àti ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Ilé Ìṣọ́, ń wà lóri kásẹ́ẹ̀tì déédéé nísinsìnyí ní ọ̀pọ̀ èdè, bí odindi Bíbélì ti wà.
Bí o bá gbà gbọ́ pé o ní ìdíwọ́ ìwé kíkà lẹ́yìn tí o ti ka àwọn ohun tí a kọ sínú àpótí náà, má ṣe fi ìṣòro náà pa mọ́. Tẹ́wọ́ gbà á, kí o sì fi í sọ́kàn. Fún àpẹẹrẹ, o lè máa gbara dì fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún iṣẹ́. Bíi ti ọ̀pọ̀ ènìyàn, o lè rí i pé pákáǹleke ipò náà mú kí ó ṣòro fún ọ láti ṣàlàyé ara rẹ kí ó yéni kí ó sì ṣe ṣàkó. O kò ṣe gbìyànjú ìfidánrawò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò mélòó kan ṣáájú àkókò?
Àwọn ìṣòro tí ìdíwọ́ ìwé kíkà ń fà kò rọrùn láti tún ṣe. Ṣùgbọ́n bí ọpọlọ́ ti jẹ́ ohun àgbàyanu, ó máa ń san àfidípò fún ìṣòro náà. Nítorí náà, kò jọ pé àìláyọ̀ títí gbére lè ṣẹlẹ̀. Julie, Vanessa, àti David ti ṣiṣẹ́ kára láti ṣẹ́pá ìjákulẹ̀ wọn. O lè ṣe bákan náà. Mọ̀ pé ìṣòro rẹ ní pàtó kò fi dandan ní láti dá ọ dúró lẹ́nu kíkẹ́kọ̀ọ́. Fi àyà rán an ní gbígbìyànjú láti kàwé, kọ̀wé, kí o sì kọ wóróhùn bí ó ti yẹ. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣẹ́pá ìjákulẹ̀ ìdíwọ́ ìwé kíkà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn aláṣẹ kán lo èdè ọ̀rọ̀ náà, “dysgraphia” láti júwe ìṣòro ẹ̀kọ́ kíkọ́ tí ó jẹ mọ́ ìwé kíkọ àti “dyscalculia” fún àwọn tí ó jẹ mọ́ ìṣirò.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
Àwọn Àbá fún Ìṣètò Ara Ẹni
Lo àwọn nǹkan wọ̀nyí:
• pátákó àfiyèsí ti ara ẹni
• kàlẹ́ńdà ohun tí a fẹ́ẹ́ ṣe
• àpótí kan tí a fi ń kó àwọn iṣẹ́ tí ó wà lọ́wọ́ láti ṣe sí
• fáìlì ara ẹni kan
• ìwé àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ kan
• ìwé àdírẹ́sì kan
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]
Bí A Ṣe Ń Mọ̀ Bí Àwọn Ọmọdé Bá Ní Ìdíwọ́ Ìwé Kíkà
Bí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sí mẹ́ta tàbí mẹ́rin lára àwọn ìbéèrè ìsàlẹ̀ wọ̀nyí lábẹ́ ìsọ̀rí ọjọ́ orí kọ̀ọ̀kan, ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ tí ọ̀rán kan ní ìdíwọ́ ìwé kíkà dé ìwọ̀n kan.
Àwọn ọmọ ọlọ́dún 8 tàbí tí kò tó bẹ́ẹ̀:
Wọ́n ha pẹ́ kí wọ́n tóó kọ́ ọ̀rọ̀ sọ bí?
Wọ́n ha ṣì ní ìṣòro gan-an pẹ̀lú ìwé kíkà tàbí pípe wóróhùn bí? Èyí ha ń yà ọ́ lẹ́nu bí?
O ha ní èrò pé nínú àwọn ọ̀ràn tí kò bá ìwé kíkà àti pípe wóróhùn tan, wọ́n jí pépé, wọ́n sì já fáfá bí?
Wọ́n ha ń kọ wóróhùn tàbí nọ́ḿbà ní òdì òdì bí?
Nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìṣirò, wọ́n ha ń nílò ìrànwọ́ ohun gidi fún kíkà, ìka ọwọ́, tàbí àwọn àmì orí ìwé fún àkókò gígùn ju àwọn ojúgbà wọn lọ bí? Wọ́n ha ń ní ìṣòro tí kò wọ́pọ̀ láti rántí àwọn òǹkà ìsọdipúpọ̀ bí?
Wọ́n ha ń ní ìṣòro mímọ ọ̀tún yàtọ̀ sí òsì bí?
Wọ́n ha jẹ́ aláìlóye iṣẹ́ lọ́nà àràmàǹdà bí? (Kì í ṣe gbogbo ọmọdé tí ó ní ìdíwọ́ ìwé kíkà ní ń jẹ́ aláìlóye iṣẹ́.)
Àwọn ọmọdé ọlọ́dún 8 sí 12:
Wọ́n ha máa ń ṣe àṣìṣe nínú pípe wóróhùn lọ́nà tí kò wọ́pọ̀ bí? Wọ́n ha máa ń fo wóróhùn nínú ọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n ṣi wóróhùn tò nínú ọ̀rọ̀ bí?
Wọ́n ha máa ń ṣe àṣìṣe àìfara balẹ̀ tí ó hàn gbangba nínú ìwé kíkà bí?
Ǹjẹ́ ó jọ pé lílóye ìwé kíkà wọ́n falẹ̀ ju bí ó ti yẹ fún àwọn ọmọdé ọlọ́jọ́ orí wọn bí?
Wọ́n ha ń ní ìṣòro ṣíṣe àdàkọ láti ara pátákó ìkọ̀wé nílé ẹ̀kọ́ bí?
Nígbà tí wọ́n bá ń kàwé sókè, wọ́n ha máa ń fo ọ̀rọ̀ tàbí odindi ìlà, tàbí wọ́n máa ń tún ìlà kan ṣoṣo kà lẹ́ẹ̀mejì bí? Wọ́n ha kórìíra kíka ìwé sókè ketekete bí?
Wọ́n ha ṣì ń ní ìṣòro láti rántí àwọn òǹkà ìsọdipúpọ̀ bí?
Wọ́n ha ń ní agbára ìmòye ìhà tí nǹkán wà, tí wọ́n ń ṣi ọ̀tún mú fún òsì bí?
Wọ́n ha ṣàìní ìdára-ẹni-lójú, tí ọ̀wọ̀ ara ẹni wọ́n sì kéré bí?
[Credit Line]
—Awareness Information, tí Ẹgbẹ́ Ìdíwọ́ Ìwé Kíkà ní Britain tẹ̀ jáde, àti Dyslexia, tí Ilé Iṣẹ́ Ìtìlẹ́yìn Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, Ìkànnì Kẹrin Tẹlifíṣọ̀n, London, England, mú jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀, fi ohun ìsàmì kan sábẹ́ ìlà tí o fẹ́ẹ́ kà