Bá A Ṣe Lè Dẹni Tó Nífẹ̀ẹ́ sí Ẹ̀kọ́ Kíkọ́
“Tọ́ ọmọde li ọ̀na ti yio tọ̀: nigbati o si dàgba tan, kì yio kuro ninu rẹ̀.”—ÒWE 22:6, BIBELI MIMỌ.
ṢÓ O ti gbìyànjú rí láti sọ fáwọn ọmọdé pé kí wọ́n lọ sùn, nígbà tí ohun kan tó gbádùn mọ́ wọn ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ti rẹ̀ wọ́n, kí wọ́n máa ké, tàbí kí ara máa kan wọ́n pàápàá, wọn ò ní jẹ́ sùn wọ́n á sì fẹ́ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Òǹkọ̀wé John Holt sọ pé: “Bí àwọn ọmọdé ò ṣe lè foúnjẹ ṣeré, tí ìsinmi àti oorun sì jẹ́ kòṣeémánìí fún wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni lílóye ohun tó ń lọ láyìíká wọn àti kíkópa nínú ẹ̀ ṣe jẹ wọ́n lógún. Nígbà míì sì rèé, lílóye ohun tó ń lọ láyìíká wọn yìí ló máa ń jẹ wọ́n lógún jù lọ.”
Ìṣòro tó wà níbẹ̀ ni bí ìfẹ́ táwọn ọmọdé ní sí ẹ̀kọ́ kíkọ́ yìí á ṣe máa bá a lọ jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn, tó fi mọ́ àwọn ọdún tí wọ́n bá lò nílé ẹ̀kọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ọ̀nà tá a lè fọwọ́ sọ̀yà pó dáa jù lọ láti gbé nǹkan gbà, àwọn ọ̀nà bíi mélòó kan tó ti ṣiṣẹ́ fáwọn kan wà táwọn òbí, àwọn olùkọ́, àtàwọn ọmọ lè gbé nǹkan gbà. Àmọ́ ṣá o, ohun kan wà tó ṣe pàtàkì ju ọgbọ́n èyíkéyìí tẹ́nì kan lè dá lọ, ìyẹn ni ìfẹ́.
Ìfẹ́ Lá Á Mú Kọ́mọ Lè Ṣe Dáadáa
Kò sọ́mọ tí kì í fẹ́ kí òbí fẹ́ràn òun. Ó máa ń mú kí ọkàn wọn balẹ̀, ó sì máa ń mú kí wọ́n fẹ́ láti bá òbí sọ̀rọ̀, kí wọ́n béèrè àwọn ìbéèrè, kí wọ́n sì wádìí àwọn nǹkan. Ìfẹ́ máa ń sún àwọn òbí láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ déédéé kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́. Ìwádìí fi hàn pé “ó dà bí ẹni pé yálà ọmọ kan á fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ tàbí kò ní fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́, sinmi lórí ipa táwọn òbí bá ní lórí ọmọ náà,” gẹ́gẹ́ bí ìwé Eager to Learn—Helping Children Become Motivated and Love Learning ṣe ṣàlàyé. Irú ipa tí òbí ń ní lórí ọmọ yìí á túbọ̀ jinlẹ̀ sí i bí wọ́n bá ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùkọ́. Ìwé náà tún sọ pé: “Kò sí ohun tó lágbára tó láti sọ ìfẹ́ tí ọmọ kan ní sí ẹ̀kọ́ kíkọ́ dọ̀tun bíi kí òbí àti olùkọ́ fọwọ́ sowọ́ pọ̀.”
Àwọn òbí tún máa ń nípa lórí bí ọmọ á ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ tó. Nínú ìwádìí kan táwọn olùṣèwádìí fi àkókò gígùn ṣe nípa ìdílé mẹ́tàlélógójì, tí wọ́n sì ròyìn nípa rẹ̀ nínú ìwé Inside the Brain, àwọn olùṣèwádìí “rí i pé àwọn ọmọ táwọn òbí sábà máa ń bá sọ̀rọ̀ [ní ọdún mẹ́ta àkọ́kọ́ tí wọ́n dáyé] máa ń ní làákàyè tó tayọ tàwọn ọmọ táwọn òbí wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ bá sọ̀rọ̀.” Ìwé náà fi kún un pé “ó jọ pé àwọn òbí tí wọ́n sábà máa ń bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ máa ń yin àwọn ọmọ náà bí wọ́n bá ṣe ohun kan, wọn kì í fetí palàbà ìbéèrè wọn, wọ́n máa ń fún wọn ní ìtọ́sọ́nà dípò kí wọ́n máa pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì máa ń lo ọ̀rọ̀ tó tọ́ lákòókò yíyẹ.” Bó o bá jẹ́ òbí, ṣó o máa ń bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ déédéé, ṣé ọ̀rọ̀ tó lè gbé wọn ró lo sì ń bá wọn sọ?
Ìfẹ́ A Máa Ní Inú Rere A sì Máa Lóye
Ohun táwọn ọmọ lágbára láti ṣe àti bí wọ́n ṣe lè tètè lóye nǹkan sí yàtọ̀ síra. Àwọn òbí ò wá ní jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọ-tó bá-ṣípá-là-á-gbé sún wọn láti fẹ́ràn ọmọ kan ju ìkan lọ nítorí pé wọn ò rí bákan náà. Síbẹ̀, láyé òde òní, béèyàn bá ṣe mọ nǹkan ṣe sí làwọn èèyàn á ṣe gba tiẹ̀ sí, èyí sì lè mú káwọn ọmọ kan “máa wò ó pé ṣíṣe àṣeyọrí ní tìpá tìkúùkù lọ̀nà tí wọ́n lè gbà mú káwọn ẹlòmíì gba àwọn lọ́gàá,” gẹ́gẹ́ bí ìwé Thinking and Learning Skills ṣe sọ. Yàtọ̀ sí pé èyí á mú kí “ẹ̀rù àìfẹ́kùnà tètè máa ba” àwọn ọmọ yìí, gbígbàgbọ́ pé ṣíṣàṣeyọrí la fi í gbani lọ́gàá lè mú kí wọ́n máa ṣàníyàn kí wọ́n sì máa dààmú láìnídìí. Ìwé ìròyìn India Today sọ pé, ṣíṣàníyàn nítorí iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ àti àìsí ìtìlẹ́yìn àwọn òbí ni wọ́n sọ pé ó jẹ́ olórí ìdí tó fà á táwọn ọ̀dọ́ tó ń para wọn fi pọ̀ sí i ní ìlọ́po mẹ́ta lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sẹ́yìn nílẹ̀ Íńdíà.
A tún lè dọ́gbẹ́ sáwọn ọmọ lọ́kàn bá a bá ń pè wọ́n ní “ọ̀dẹ̀” tàbí “dọndú.” Dípò kí irú èdè àlùfààṣá bẹ́ẹ̀ mú kó wu ọmọdé láti kẹ́kọ̀ọ́, yóò máa lé e sá nídìí ẹ̀kọ́ kíkọ́ ni. Àmọ́ ṣá o, ńṣe ló yẹ kí ìfẹ́ máa sún òbí láti ní inú rere, kó sì máa ṣètìlẹ́yìn fún ọmọ tó bá dìídì fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́, ní ìwọ̀nba ibi tí agbára ọmọ náà bá mọ, kó má sì fi í ṣe ẹlẹ́yà. (1 Kọ́ríńtì 13:4) Bó bá ṣòro fún ọmọ kan láti kẹ́kọ̀ọ́, ńṣe làwọn òbí onífẹ̀ẹ́ á wá ọ̀nà àtiràn án lọ́wọ́, wọn ò ní sọ ohun tá á mú kó rò pé òpònú tàbí aláìníláárí lòun. Lóòótọ́ ni ìyẹn gba sùúrù àti ọgbọ́n tó ní àròjinlẹ̀, ṣùgbọ́n ipá tí òbí bá sà tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Báwo lèèyàn ṣe lè ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀? Fífi ojú tẹ̀mí wo nǹkan ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tó ṣe pàtàkì.
Fífojú Tẹ̀mí Wo Nǹkan A Máa Múni Wà ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì
Ipò tẹ̀mí tá a gbé karí Bíbélì ṣeyebíye gan-an fún àwọn ìdí mélòó kan. Ohun kan nípa ipò tẹ̀mí sì ni pé, ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi ẹ̀kọ́ ìwé sí àyè tó yẹ ẹ́, ó ń jẹ́ ká rí i bí ohun tó ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, ìṣirò lè wúlò lónírúurú ọ̀nà, ṣùgbọ́n kò lè sọni di oníwà rere.
Bíbélì tún fún wa níṣìírí láti má ṣe lo àkókò tó pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ fún ẹ̀kọ́ ìwé, nípa sísọ pé: “Nínú ṣíṣe ìwé púpọ̀, òpin kò sí, fífi ara ẹni fún wọn lápọ̀jù sì ń mú ẹran ara ṣàárẹ̀.” (Oníwàásù 12:12) Lóòótọ́ ló yẹ káwọn ọmọ kàwé dé ìwọ̀n àyè kan, ṣùgbọ́n kó yẹ kí ìyẹn gba gbogbo àkókò wọn. Ó tún yẹ kí wọ́n wá àkókò fún àwọn ìgbòkègbodò gbígbámúṣé mìíràn, pàápàá àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí, tó ń kọ́ èrò inú àti ọkàn àyà lẹ́kọ̀ọ́.
Ohun mìíràn tí ipò tẹ̀mí tá a gbé karí Bíbélì tún fi ń kọ́ni ni ìmọ̀wọ̀n ara ẹni. (Míkà 6:8) Àwọn tó mọ̀wọ̀n ara wọn kì í gbà pé àwọn mọ gbogbo nǹkan tán, nítorí náà, wọn kì í kópa nínú mo-fẹ́-digbá-mo-fẹ́-dagbọ̀n àti fifi tìpá tìkúùkù di aṣáájú èyí tó ń ṣẹlẹ̀ káàkiri àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga. Ìwé ìròyìn India Today sọ pé àṣà jágbajàgba yìí “máa ń kódààmú ọkàn báni ni.” Yálà a jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, á sàn fún wa báa bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn onímìísí tó wà nínú Bíbélì pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di olùgbéra-ẹni-lárugẹ, ní ríru ìdíje sókè pẹ̀lú ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, ní ṣíṣe ìlara ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” “Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.”—Gálátíà 5:26; 6:4.
Báwo làwọn òbí ṣe lè fi èyí sílò ní ti ẹ̀kọ́ ìwé àwọn ọmọ wọn? Ọ̀nà kan tí wọ́n lè gbà ṣe èyí ni pé kí wọ́n fún ọmọ kọ̀ọ̀kan níṣìírí láti máa ní ohun kan tó ń lépa, kó sì máa fi àṣeyọrí tó bá ṣe wé èyí tó ti ṣe tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bí ọmọ rẹ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìdánwò ìṣirò tàbí ti sípẹ́lì ọ̀rọ̀ láìpẹ́ yìí, jẹ́ kó fi máàkì tó gbà wé èyí tó ti gbà tẹ́lẹ̀ nígbà tó ṣe irú ìdánwò kan náà. Lẹ́yìn náà ni kó o wá yìn ín tàbí kó o fún un níṣìírí. Lọ́nà yìí, wàá ràn án lọ́wọ́ láti mọ bá a ṣeé lépa ohun tọ́wọ́ ẹni lè tó, bó ṣe lè máa mọ bóun ṣe ń tẹ̀ síwájú sí, àti ohun tó lè ṣe níbi tó bá kù sí, láìsí pé ò ń fi í wé àwọn ẹlòmíì.
Àmọ́ ṣá o, àwọn ọ̀dọ́ kan tórí wọ́n yá síwèé lóde òní á kúkú yàn láti wà lẹ́gbẹ́ àwọn tí ò mọ̀wé kí wọ́n má bàa fi wọ́n ṣẹ̀sín. Ojú táwọn èwe kan fi ń wo ọ̀ràn náà ni pé, “kò sóhun tó dáa nínú kéèyàn jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rere.” Ṣé fífojú tẹ̀mí wo nǹkan lè ṣèrànwọ́ níbi tọ́rọ̀ dé yìí? Bẹ́ẹ̀ ni! Ìwọ ronú nípa ohun tó wà nínú Kólósè 3:23, èyí tó sọ pé: “Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.” (Kólósè 3:23) Àbí ìdí míì wà tó ń sún ọ ṣiṣẹ́ kára tó tayọ fífẹ́ tó o fẹ́ láti tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn? Irú ojú ìwòye tí ò lábùkù bẹ́ẹ̀ máa ń fúnni lókun láti yẹra fún ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, tí kò lóòre kan dà bí alárà tó ń ṣe fúnni.
Kọ́ Àwọn Ọmọdé Láti Nífẹ̀ẹ́ sí Ìwé Kíkà
Pàtàkì ohun tí ẹ̀kọ́ ìwé tó dáa, yálà nípa tara tàbí nípa tẹ̀mí, máa ń kọ́ni ni ìwé kíkà àti ìwé kíkọ. Àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà nípa kíkàwé sí wọn létí látìgbà ọmọ ọwọ́. Daphne obìnrin kan, tó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akàwéṣàtúnṣe, láyọ̀ pé àwọn òbí òun máa ń kàwé sí òun létí déédéé nígbà tóun wà lọ́mọdé. Ó ṣàlàyé pé: “Àwọn ni wọ́n jẹ́ kí n nífẹ̀ẹ́ sí kíkàwé. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, mó ti mọ̀wé kà kí n tó bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́. Àwọn òbí mi tún kọ́ mi báa ṣeé ṣèwádìí kí n bàa lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mi. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí ṣì ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an, títí dòní olónìí.”
Ẹ̀wẹ̀, Holt, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, wá kìlọ̀ pé kíkàwé sáwọn ọmọdé létí “kì í ṣe oògùn ajẹ́bíidán o.” Ó fi kún un pé: “Bí ìwé kíkà náà ò bá gbádùn mọ́ àtọmọ àtòbí, búburú tá a tìdí ẹ̀ jáde á pọ̀ ju rere lọ. . . . Kódà, àwọn ọmọ tó fẹ́ràn káwọn òbí máa kàwé ketekete sáwọn létí . . . kì í nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà síni létí báwọn òbí wọn ò bá fẹ́ràn àtimáa kà á sí wọn létí.” Nítorí náà, Holt dámọ̀ràn pé káwọn òbí yan àwọn ìwé táwọn alára gbádùn, kí wọ́n sì ní in lọ́kàn pé àwọn ọmọ lè fẹ́ kí wọ́n ka àwọn ìwé náà fáwọn ní àkàtúnkà! Ìwé méjì tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn òbí kárí ayé gbádùn láti máa kà sáwọn ògo wẹẹrẹ wọn létí ni Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà àti Iwe Itan Bibeli Mi, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la sì tẹ àwọn ìwé méjèèjì jáde. Níwọ̀n bí a ti ṣe àwọn ìwé náà nítorí àwọn ọmọdé, àwòrán pọ̀ nínú wọn, wọ́n á ran wọ́n lọ́wọ́ láti ronú, wọ́n á sì kọ́ wọn ní àwọn ìlànà Ọlọ́run.
Tímótì, tó jẹ́ Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní, jọlá ìyá rẹ̀ àti ìyá ìyá rẹ̀ tí wọ́n fọwọ́ dan-in dan-in mú ẹ̀kọ́ rẹ̀, pàápàá ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa tẹ̀mí. (2 Tímótì 1:5; 3:15) Tímótì dàgbà di ẹni títayọ tó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ tó sì ṣeé gbára lé. Kò sí bí ẹ̀kọ́ nípa tara nìkan ṣe lè mú kéèyàn ní àwọn ànímọ́ bí irú èyí. (Fílípì 2:19, 20; 1 Tímótì 4:12-15) Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n dáńgájíá bíi Tímótì ṣì wà nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́ríì Jèhófà kárí ayé, nítorí pé wọ́n ní àwọn òbí onífẹ̀ẹ́, tí nǹkan tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.
Fi Ìtara Kọ́ni!
Bí olùkọ́ kan bá fẹ́ káwọn míì nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ kíkọ́, “o gbọ́dọ̀ lo ìtara,” gẹ́gẹ́ bí ìwé Eager to Learn ṣe sọ. “Bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bá ti fojú kan olùkọ́ tó ní ìtara báyìí, wọ́n á ti mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ń kọ́ àwọn, ìtara rẹ̀ á sì máa hàn nínú ọ̀nà tó ń gbà kọ́ wọn.”
Àmọ́ o, ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kì í ṣe gbogbo òbí tàbí olùkọ́ ló ní ìtara. Ìdí nìyẹn táwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá gbọ́n fi máa ń lo ìdánúṣe tiwọn, wọ́n máa ń wo ẹ̀kọ́ kíkọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹrù iṣẹ́ tara wọn. Ìwé tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lókè yẹn tiẹ̀ sọ pé ó ṣe tán, “kò sẹ́ni tá á máa jókòó ti àwọn ọmọ wa jálẹ̀ ìyókù ìgbésí ayé wọn tá á sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́, láti ṣe iṣẹ́ tó pójú owó, láti ronú, kí wọ́n sì ṣe àfikún ìsapá tó máa ń mú kéèyàn ní ànímọ́ títayọ.”
Lẹ́ẹ̀kan sí i, èyí fi hàn pé kékeré ni ti ilé ẹ̀kọ́ mọ nínú ọ̀rọ̀ náà, inú ilé tí ọmọ kan ti jáde wá àti ìlànà ìwà rere tí wọ́n fi kọ́ ọ ló ṣe pàtàkì jù. Ẹ̀yin òbí, ǹjẹ́ ẹ ní ìtara fún ẹ̀kọ́ kíkọ́? Ǹjẹ́ ọ̀nà tẹ́ ẹ gbà ṣètò ilé yín mú kó rọrùn láti kẹ́kọ̀ọ́, ṣé ibi tí ẹ ti fọwọ́ dan-in dan-in mú àwọn ìlànà ìwà rere tẹ̀mí ni? (Éfésù 6:4) Ẹ rántí o, àpẹẹrẹ tẹ́ ẹ bá fi lélẹ̀ àti ẹ̀kọ́ tẹ́ ẹ bá fi ń kọ́ àwọn ọmọ yín á nípa lórí wọn fún àkókò gígùn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti jáde ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n sì fi ilé sílẹ̀.—Wo àpótí náà, “Àwọn Ìdílé Tí Ẹ̀kọ́ Kíkọ́ Gbádùn Mọ́,” tó wà lójú ìwé 7.
Má Ṣe Gbàgbé Pé Onírúurú Ọ̀nà Làwọn Èèyàn Ń Gbà Kẹ́kọ̀ọ́
Bákan náà là á gbọ́rọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló máa ń yéni sí. Ohun tó sì wúlò fún ẹnì kan lè máà fi bẹ́ẹ̀ wúlò fún ẹlòmíì. Nítorí èyí, Dókítà Mel Levine, sọ nínú ìwé rẹ̀ A Mind at a Time, pé: “Bá a bá fẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ rí bákan náà, bí ìgbà tá a fẹ́ fáwọn kan fún ìyà jẹ ni. Ìrànlọ́wọ́ tọ́mọ kọ̀ọ̀kan ń fẹ́ nípa ẹ̀kọ́ kíkọ́ yàtọ̀ síra; wọ́n sì lẹ́tọ̀ láti rí ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n bá nílò gbà.”
Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan tètè máa ń lóye ọ̀rọ̀ wọ́n sì máa ń rántí rẹ̀ dáadáa nígbà tí wọ́n bá rí àwòrán tàbí ohun kan tá a yà láti ṣàkàwé ohun tá à ń sọ. Ohun táwọn míì sì fẹ́ ni pé ká kọ nǹkan sílẹ̀ tàbí ká sọ ọ́ lọ́rọ̀, tábì ká ṣe méjèèjì pọ̀. Levine sọ pé: “Ọ̀nà tó dára jù lọ láti rántí ohun kan ni pé ká yí i padà, ká tún ọ̀rọ̀ náà sọ nírú ọ̀nà èyíkéyìí mìíràn. Bó bá jẹ́ àwòrán ni, sọ ọ́ lọ́rọ̀, bó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu ni, ya àwòrán láti fi ṣàlàyé ẹ̀.” Kì í ṣe pé gbígbé nǹkan gba ọ̀nà yìí á mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ṣàǹfààní nìkan ni, ṣùgbọ́n á tún mú kó gbádùn mọ́ni.
Àmọ́ ṣá o, àfi kó o dán onírúurú ọ̀nà wò kó o tó lè mọ èyí tó dára jù lọ fún ọ. Hans, Kristẹni òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan, ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú George, bàbá àgbàlagbà kan tí kò kàwé púpọ̀. Ó ṣòro fún bàbá náà láti lóye àwọn ohun tó ń kọ́ kó sì rántí wọn. Nítorí náà, Hans máa ń ṣàkàwé àwọn kókó ẹ̀kọ́ náà fún un nípa fífọwọ́ ya àwọn kókó pàtàkì nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sórí ìwé. Hans sọ pé: “Kíá ni nǹkan yí padà fún bàbá yìí. Kódà, àwọn nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí yé e, ó sì ń rántí wọn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ ìyàlẹ́nu fún òun alára! Gbàrà tí mo ti wá lóye ọ̀nà tí nǹkan máa ń gbà yé e, èmi fúnra mi wá rí i pé ó tété máa ń lóye nǹkan ju bí mo ṣe rò tẹ́lẹ̀ lọ. Kò pẹ́ tó fi dẹni tó nígboyà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fojú sọ́nà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ju ti ìgbàkígbà rí lọ.”
O Ò Dàgbà Jù Láti Kẹ́kọ̀ọ́
Ìwé Inside the Brain sọ pé: “Ohun tí ọpọlọ lè ṣe sinmi lórí yálà a lò ó tàbí a kò lò ó. Lò ó tàbí kó o pàdánù agbára rẹ̀ lọ̀rọ̀ ti ọpọlọ, ó sì ṣe tán láti kọ́ àwọn nǹkan tuntun.” Ìwé náà tún sọ pé: “Bí eré ìdárayá ṣe máa ń mú kí ara àwọn èèyàn mókun látẹni àádọ́rin ọdún títí wọ nǹkan bí ẹni àádọ́rùn-ún ọdún, àwọn olùṣèwádìí ń jẹ́ kó di mímọ̀ pé lílo ọpọlọ láti ṣe àwọn nǹkan lè ṣiṣẹ́ ìmúlókun kan náà fún ọpọlọ ẹni tó ti ń darúgbó. Tipẹ́ làwọn èèyàn ti máa ń rò pé bọ́jọ́ ogbó bá ti dé báyìí ńṣe lọpọlọ á bẹ̀rẹ̀ sí jò. Ṣùgbọ́n ìwádìí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe náà fi hàn pé nítorí pé àwọn èèyàn ń ronú lọ́nà yẹn ló fi dà bí ẹni pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, àmọ́ àìlo ọpọlọ ló sàbá máa ń fà á tọ́ràn fi ń rí bẹ́ẹ̀. Síwájú sí i, àwọn èèyàn kì í pàdánù apá tó pọ̀ nínú àwọn sẹ́ẹ̀lì ọpọlọ wọn lójoojúmọ́ bí wọ́n ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe rò pé ọ̀rọ̀ rí.” Bí ọpọlọ ò bá ṣiṣẹ́ dáadáa tó bó ṣe yẹ, a jẹ́ pé àrùn ti ń ṣe é nìyẹn o, lára irú àrùn bẹ́ẹ̀ sì ni èyí tó jẹ mọ́ ọkàn àti òpójẹ̀.
Lóòótọ́ ni pé agbára ọpọlọ lè ṣe bí ẹní dín kù ráńpẹ́ béèyàn ṣe ń dàgbà sí i, ṣùgbọ́n kò ní jẹ́ lọ́nà kan tó ṣe bàbàrà tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn olùṣèwádìí sọ pé, ọpọlọ ẹni tó bá já fáfá, kì í gbó bọ̀rọ̀, pàápàá jù lọ bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá ní ètò tó dáa fún ṣíṣe eré ìdárayá. Ìwé Elderlearning—New Frontier in an Aging Society sọ pé: “Béèyàn bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i tó, bẹ́ẹ̀ náà ni agbára téèyàn ní láti kẹ́kọ̀ọ́ á máa pọ̀ sí i tó. Ńṣe ni ẹ̀kọ́ kíkọ́ túbọ̀ máa ń dùn mọ́ àwọn tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé.”
Nínú ìwádìí kan tí wọ́n fogún ọdún ṣe nílẹ̀ Ọsirélíà, nípa àwọn èèyàn tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọgọ́ta ọdún sí ọdún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún, ni wọ́n ti fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀. Nígbà tí wọ́n ṣèdánwò fún wọn láti mọ bí ọpọlọ wọn ṣe ń ṣiṣẹ́ tó, ohun tí máàkì èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn fi lọ sílẹ̀ ju ìdá kan lórí ọgọ́rùn-ún lọ lọ́dún. Àmọ́, ìròyìn náà sọ pé “àwọn kan wà, tó fi mọ́ àwọn tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé àádọ́rùn-ún ọdún, tí máàkì wọn ò lọ sílẹ̀ rárá. Àwọn wọ̀nyí sábà máa ń jẹ́ àwọn èèyàn tó ti kópa rí nínú ẹ̀kọ́ kíkọ́ tó gba ìfarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ bíi kíkọ́ èdè àjèjì tàbí lílo ohun èlò orin tàbí kí wọ́n kọ́ méjèèjì papọ̀.”
George, tá a ti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ tẹ́lẹ̀, ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni Virginia, tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún báyìí, àti ọkọ rẹ̀ olóògbé, Robert; àgbà ara làwọn méjèèjì fi bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Virginia sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú Robert ti ń ṣe bàìbàì, ó máa ń sọ àwọn àsọyé Bíbélì ṣókí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìlapa èrò tó ti há sórí ló sì máa ń lò. Ní tèmi, mi ò fìgbà kan rí fẹ́ràn ìwé kíkà, ṣùgbọ́n mo ti fẹ́ràn ẹ̀ báyìí. Kódà, ní kùtùkùtù òwúrọ̀ yìí, mo ti ka odidi ìtẹ̀jáde Jí! kan tán.”
Àpẹẹrẹ àwọn èèyàn mẹ́ta péré ni ti George, Robert, àti Virginia jẹ́ lára ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà tí wọn ò fetí sí ohun táwọn èèyàn ń sọ tí wọ́n sì lo ọpọlọ wọn dáadáa. Ìwádìí fi hàn pé bí ẹni tó fi ìdérí ìgò bu omi sínú àgbá ńlá ló rí béèyàn bá lo àádọ́rin tàbí ọgọ́rin ọdún láti kó ẹ̀kọ́ ságbárí, kò lè tu irun kankan lára ọpọlọ. Kí ló fà á tí agbára tí ọpọlọ wa ní fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Ṣé Íńtánẹ́ẹ̀tì àti Tẹlifíṣọ̀n Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Ni àbí Wọ́n Ń Kó Bá Wa?
Ìwé náà, A Mind at a Time, sọ pé: “Bí Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe wúlò tó náà ló ṣe lè ṣàkóbá tó.” Kíkọ́ bá a ṣeé wá ìsọfúnni rí máa ń ranni lọ́wọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n ìwé náà ṣàlàyé pé ńṣe làwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan wulẹ̀ máa ń “ta ìsọfúnni látaré látorí íńtánẹ́ẹ̀tì sínú kọ̀ǹpútà tiwọn, láìlóye ìsọfúnni náà tàbí ọ̀nà tó gbà bá ohun tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ mu. Nítorí náà, ewu tó wà níbẹ̀ ni pé ó ṣeé ṣe kí Íńtánẹ́ẹ̀tì náà di oríṣi ọ̀nà mìíràn táwọn èèyàn á fi di ọ̀lẹ nídìí ìwé kíkà tàbí kí wọ́n di ẹni tó ń pọ̀n sẹ́yìn èrò elérò bí ẹni pé òye tiwọn ni wọ́n ń lò.”
Àwọn olùṣèwádìí tún sọ pé lílo àkókò tó pọ̀ jù nídìí tẹlifísọ̀n lè mú kí agbára tí ẹnì kan ní láti yanjú àwọn ìṣòro àti láti fetí sílẹ̀ jó rẹ̀yìn, kì í jẹ́ kéèyàn lè ronú kó sì wòye àwọn nǹkan, kì í sì í sọni di ọmọlúwàbí. Ìwé Eager to Learn sọ pé: “Ṣe ló yẹ kí irú ìsọfúnni tí wọ́n ń lẹ̀ mọ́ ara páálí sìgá láti ṣèkìlọ̀ pé ó léwu fún ìlera, máa wà lára tẹlifíṣọ̀n náà.”
Ìwé míì tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ dámọ̀ràn pé ohun táwọn ọmọdé nílò jù lọ ni kí wọ́n “là wọ́n lójú sí èdè kíkọ́ (kíkà àti sísọ), kí wọ́n fìfẹ́ hàn sí wọn, kí wọ́n sì máa gbá wọn mọ́ra tọ̀yàyàtọ̀yàyà.”
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ìdílé Tí Ẹ̀kọ́ Kíkọ́ Gbádùn Mọ́
Ṣíṣe àwọn ohun tá a tò sísàlẹ̀ yìí tàbí níní èyíkéyìí lára àwọn ànímọ́ tá a júwe síbẹ̀ lè mú kí ẹ̀kọ́ kíkọ́ gbádùn mọ́ ìdílé rẹ:
◼ Fífi tìfẹ́tìfẹ́ jíròrò déédéé pẹ̀lú àwọn ọmọ, jíjẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o fẹ́ kí wọ́n máa ṣe dáadáa, kí wọ́n sì máa hùwà tí ò lábùkù
◼ Wíwo iṣẹ́ àṣekára gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà téèyàn lè gbà ṣàṣeyọrí
◼ Kéèyàn jẹ́ òṣìṣẹ́ dípò kéèyàn máa jókòó tẹtẹrẹ
◼ Kí àwọn ọmọ máa lo ọ̀pọ̀ wákàtí láti kẹ́kọ̀ọ́ nílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kí wọ́n sì máa kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́, ìwé àkàgbádùn, eré ìgbà-ọwọ́-dilẹ̀, ohun tí ìdílé jùmọ̀ ṣe, ẹ̀kọ́ ilé àti iṣẹ́ ilé
◼ Kí àwọn ọmọ rí ìdílé gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ti lè rí àtìlẹ́yìn àti ibi tí wọ́n ti lè rí alábàárò bí ìṣòro bá dé
◼ Kí àwọn ọmọ ní òye tó ṣe kedere nípa àwọn ìlànà tẹ́ ẹ bá gbé kalẹ̀ nínú ìdílé, kẹ́ ẹ sì rí i pé wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà
◼ Kí òbí má ṣe jìnnà sáwọn olùkọ́
◼ Kí àwọn ọmọ mọ̀ pé lílóye àwọn nǹkan tẹ̀mí ló ṣe pàtàkì jù
[Àwòrán]
Ẹ̀yin òbí, ǹjẹ́ ẹ̀ ń kọ́ àwọn ọmọ yín láti gbádùn ìwé kíkà?
[Credit Line]
Látinú ìwé Eager to Learn —Helping Children Become Motivated and Love Learning.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Àwọn Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Mú Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Sunwọ̀n sí I Kó sì Túbọ̀ Gbádùn Mọ́ni
Nífẹ̀ẹ́ sí Ohun Tó Ò Ń Kọ́ Bó o bá fọkàn sí ohun kan, wà á rí i pé kò ní pẹ́ tá á fi yé ọ. Ìwé Motivated Minds—Raising Children to Love Learning ṣe àkíyèsí tó tẹ̀ lé e yìí: “Àwọn olùṣèwádìí sọ ọ́ di mímọ̀ ní kedere pé nígbà táwọn ọmọ bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nítorí pé ó ń gbádùn mọ́ wọn, òye tí wọ́n máa ní á túbọ̀ jinlẹ̀, á gbámúṣé, á sì wà pẹ́ títí. Wọn kì í jáwọ́ bọ̀rọ̀ nínú kíkẹ́kọ̀ọ́, wọ́n máa ń lè ṣe nǹkan tuntun, ó sì máa ń yá wọn lára láti ṣe iṣẹ́ tó gbàrònú jinlẹ̀.”
Mọ Bí Ohun Tó Ò Ń Kọ́ Ṣe Bá Ohun Tó Ò Ń Ṣe Mu Òǹkọ̀wé tó sì tún jẹ́ olùkọ́, Richard L. Weaver Kejì, kọ̀wé pé: “Bí akẹ́kọ̀ọ́ bá rí bí ohun tí wọ́n ń kọ́ òun ní kíláàsì ṣe bá ohun tí òun ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ mu, bí ìgbà téèyàn ṣẹ́ ògiri léèékánná tí ìmọ́lẹ̀ òye sì mọ́lẹ̀ yòò ni.”
Gbìyànjú Láti Lóye Ohun Tó Ò Ń Kọ́ Nígbà táwọn èèyàn bá gbìyànjú láti lóye ohun kan, ńṣe ni wọ́n ń mú kí agbára ìrònú àti agbára ìríran wọn pọ̀ sí i. Ẹ̀kọ́ àkọ́sórí ní àyè tiẹ̀, ṣùgbọ́n kò ṣeé fi rọ́pò lílóye ohun tá à ń kọ́. Òwe 4:7, 8, sọ pé: “Pẹ̀lú gbogbo ohun tí o sì ní, ní òye. Gbé e níyì gidigidi, yóò sì gbé ọ ga.”
Pọkàn Pọ̀ Ìwé Teaching Your Child Concentration ṣàlàyé pé: “Pípa ọkàn pọ̀ ló ń jẹ́ kéèyàn lóye ohun tó bá kọ́. [Ó] ṣe pàtàkì débi pé wọ́n ti pè é ní kòṣeémánìí bó bá dọ̀ràn níní làákàyè, wọ́n tiẹ̀ sọ pé ọ̀kan náà lòun àti làákàyè.” A lè kọ́ni láti máa pọkàn pọ̀. Ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà ṣe é ni pé ká má máa pẹ́ lórí ìkẹ́kọ̀ọ́ nígbà tá a bá bẹ̀rẹ̀, a lè wá máa fa àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gùn díẹ̀díẹ̀.
Tún Ọ̀rọ̀ Sọ Lọ́nà Mìíràn Dókítà Mel Levine sọ nínú ìwé rẹ̀ A Mind at a Time, pé: “Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó dáńgájíá jù lọ làwọn tó mọ bí wọ́n ṣe lè sọ ohun tí wọ́n kọ́ lọ́nà mìíràn.” Títún ọ̀rọ̀ sọ lọ́nà mìíràn máa ń dín ọ̀rọ̀ kù sí kékeré, níwọ̀nba ṣókí, tá á sì rọrùn láti rántí. Ìlànà yìí làwọn tó mọ bá a ti í ṣe àkọsílẹ̀ máa ń lò tí wọn kì í fi í kọ gbogbo ọ̀rọ̀ sílẹ̀.
Fi Ohun Tó O Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ń Kọ́ Wé Èyí Tó O Ti Mọ̀ Tẹ́lẹ̀ Nínu ìwé The Brain Book, Peter Russell sọ pé bí ìgbà tí akọ́rọ́ kan bá kọ́ òmíràn ni ohun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ ṣe tan mọ́ ohun tá a ti mọ̀ ságbárí tẹ́lẹ̀. Ní kúkúrú, wà á máa níran nǹkan púpọ̀ sí i bó o bá ṣe ń fi àwọn ohun tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ wé èyí tó o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Bí ohun tó ò ń fi wéra bá ṣe pọ̀ tó, ni ohun tí wà á máa níran á ṣe máa pọ̀ sí i tó.
Fojú Inú Yàwòrán Àwòrán tó ṣe kedere kì í kúrò lọ́kàn bọ̀rọ̀. Nítorí náà, fọkàn yàwòrán ohun tó ò ń kọ́ bí àǹfààní ẹ̀ bá yọ. Ọgbọ́n táwọn olùṣèwádìí nípa béèyàn ṣe lè máa rántí nǹkan máa ń dá nìyẹn, wọ́n sábà máa ń fọkàn yàwòrán tó lè pani lẹ́rìn-ín gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti gba rántí nǹkan.
Ṣàtúnyẹ̀wò Láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún a lè gbàgbé ìdá mẹ́rin nínú márùn-ún lára ohun tá a bá kọ́. Nípa ṣíṣe àtúnyẹ̀wò ráńpẹ́ lẹ́yìn tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ tán, ká tún ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ kan, lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, lẹ́yìn oṣù kan, àti lẹ́yìn oṣù mẹ́fà pàápàá, a ó lè mú agbára ìrántí wa sunwọ̀n sí i gan-an, kódà a ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máa rántí gbogbo nǹkan tá a bá kọ́.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ńṣe ló yẹ káwọn òbí àtàwọn olùkọ́ pawọ́ pọ̀ ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ọjọ́ orí ò dí ẹ̀kọ́ kíkọ́ lọ́wọ́