A Dá Ìfẹ́ Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Mọ́ Wa
“Àwọn ẹyẹ ń fò, àwọn ẹja ń lúwẹ̀ẹ́; ọmọ ènìyàn ń ronú ó sì ń kẹ́kọ̀ọ́.”—LÁTẸNU JOHN HOLT, TÓ JẸ́ ÒǸKỌ̀WÉ ÀTI OLÙKỌ́.
GBÀRÀ tí wọ́n bá ti bí ẹtu kalẹ̀ lá á ti wù ú láti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ́gẹ́lẹ́gẹ́, tó ń gbò yèpéyèpé tẹlẹ̀ kó bàa lè máa rìn tọ ìyá rẹ̀ lẹ́yìn. Àmọ́, tó bá jẹ́ ọmọ téèyàn bí ni, ọdún kan lè kọjá kó tó mọ̀ ọ́n rìn. Síbẹ̀, Ọlọ́run fi àgbàyanu ọpọlọ tó ju ti ẹranko èyíkéyìí lọ fíìfíì, jíǹkí àwa ẹ̀dá ènìyàn. Agbára tí èèyàn ní ju ẹranko lọ yìí ló fà á tí kì í fi í sú àwọn ọmọdé láti máa wá fìn-ín ìdí kókò kí wọ́n sì kọ́ àwọn ohun tuntun.
Ńṣe làwọn ọmọ tára wọn bá dá ṣáṣá, máa ń sọ àyíká wọn di ibi tí wọ́n ti lè ṣèwádìí, kí wọ́n sì ṣàkíyèsí àwọn nǹkan, kí wọ́n bàa lè mọ gbogbo ohun tó wù wọ́n láti mọ̀. Ìwọ fi ohun kan lé wọn lọ́wọ́, kó o sì rí bí wọ́n á ṣe tẹjú roro mọ́ ọn, wọ́n á fẹ́ mo gbogbo nǹkan nípa ẹ̀, wọ́n tiẹ̀ lè fi ahọ́n tọ́ ọ wò pàápàá! Ìwádìí tí wọ́n ń ṣe nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò mọ síbẹ̀ yẹn. Gbogbo òbí ló mọ̀ pé, bí eré bí eré, àwọn ọmọdé lè rún irú nǹkan bẹ́ẹ̀, wọ́n lè là á mọ́lẹ̀, wọ́n lè mì í jìgìjìgì, wọ́n sì lè fọ́ ọ níbi tí wọ́n ti ń wọ́nà àtilóye ohun tó jẹ́, kí wọ́n bàa lè mọ̀ nípa àyíká wọn.
Ìgbà táwọn ọmọdé bá jàjà mọ ọ̀rọ̀ sọ gan-an ni wọ́n á túbọ̀ fẹ́ láti máa fa ìmọ̀ mu bí ẹni mu omi, ohun àgbàyanu kan sì tún nìyẹn jẹ́ láyè ara ẹ̀! Ṣàdédé lá wá dà bí ẹni pé àwọn ọmọdé ò mọ nǹkan míì ju kí wọ́n máa béèrè ìbéèrè lọ. Bí ọ̀wààrà òjò ni wọ́n á máa da ìbéèrè bolẹ̀, irú bíi, ‘Kí ni tibí?’ ‘Kí ni tọ̀hún?’, tí ìyẹn á sì fẹ́rẹ̀ẹ́ dá ọ̀pọ̀ òbí lágara. Òǹkọ̀wé John Holt sọ pé: “Kì í pẹ́ táwọn ọmọdé fi máa ń lóye ohun tára wọn bá wà lọ́nà láti mọ̀.”
Lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọdé, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀, á wá bẹ̀rẹ̀ abala ìgbésí ayé mìíràn tó jẹ́ ti ẹ̀kọ́ kíkọ́ ní pẹrẹu, wọ́n á wá mọ ohun tó ń jẹ́ olùkọ́, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, tábìlì ìkàwé, àti bóyá, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọdé mìíràn bíi tiwọn. Ó bani nínú jẹ́ pé, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún nílé ẹ̀kọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni ìtara wọn fún kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà yẹn ti máa ń dín kù. Ilé ìwé á tiẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí sú àwọn míì, tàbí kí wọ́n kà á sí iṣẹ́ kan tí ò gbádùn mọ́ni. Bóyá a rí lára ohun tí wọ́n ń kọ́ wọn tí ò yé wọn tó, ó sì lè jẹ́ olùkọ́ wọn ló tutù jù. Tàbí kó jẹ́ pé àkólékàn nítorí àtigba máàkì tó dáa ló ń mú wọn ṣàníyàn tó pọ̀ jù.
Irú ìṣarasíhùwà tí ò dáa bẹ́ẹ̀ tọ́mọ kan bá ní nípa ẹ̀kọ́ kíkọ́, ṣeé ṣe kó bá ọmọ náà dàgbà, kódà, ó lè mọ́ ọn lára dọjọ́ ogbó, tá á sì mú kó máa sá fún ohunkóhun tó bá ní í ṣe pẹ̀lú àròjinlẹ̀, ẹ̀kọ́ kíkọ́, tàbí ṣíṣe ìwádìí. Láfikún sí ìyẹn, àwọn àgbà tún máa ń dojú kọ ìṣòro mìíràn tó yàtọ̀, ìyẹn èrò náà pé ńṣe lọjọ́ ogbó máa ń rani níyè, téèyàn ò sì ní lè kẹ́kọ̀ọ́ kankan mọ́. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí a ó ṣe rí i, kó sídìí fún ríronú lọ́nà yẹn.
Ṣó o fẹ́ láti mú kí agbára àti ìfẹ́ ọkàn rẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n sí i, láìka ọjọ́ orí rẹ sí? Bó o bá jẹ́ òbí, ṣó o fẹ́ káwọn ọmọ rẹ di akẹ́kọ̀ọ́ tó dáńgájíá kí wọ́n sì gbádùn ẹ̀kọ́ kíkọ́ nígbà tí wọ́n bá wà nílé ìwé àti lẹ́yìn tí wọ́n bá jáde? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, máa bá wa ká lọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 2]
Ó máa ń wu àwọn ọmọdé láti kẹ́kọ̀ọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó ń relé ẹ̀kọ́ lọkàn wọn kì í balẹ̀ tí wọ́n sì máa ń ṣàníyàn