ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 11/22 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 11/22 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Àìríṣẹ́ṣe Ẹ ṣeun púpọ̀ fún ọ̀wọ́ “Àìríṣẹ́ṣe—Ojútùú Kan Wà.” (March 8, 1996) Ó dé sí àkókò tí mo ń wá iṣẹ́, ṣùgbọ́n tí n kò ríṣẹ́ kankan. Mo gbìyànjú láti dá iṣẹ́ sílẹ̀ nílé bí ẹ ṣe sọ ní ojú ìwé 11, ó sì gbéṣẹ́ fún mi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún yín!

J. M., French Guiana

Àwọn àpilẹ̀kọ náà ṣàpèjúwe ipò tí mo bá ara mi láìpẹ́ yìí. Fún oṣù mélòó kan, mo ní láti mú ara mi bá ipò ṣíṣe “gbogbo onírúurú iṣẹ́” mu, gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ kán ṣe pè é. Síbẹ̀, n kò rẹ̀wẹ̀sì. Mo gbìyànjú láti ní ojú ìwòye nǹkan yóò dára, mo sì rí iṣẹ́ tí ó dúró déédéé kan níkẹyìn. Láàárín sáà yẹn, ìyàwó mi ràn mí lọ́wọ́ gan-an, ní ti pé ó máa ń ṣúnwó ná nígbà tí ó bá ń rajà. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ ṣeun fún àwọn ìsọfúnni tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti lo àwọn ìlànà Bíbélì nínú àwọn ipò tí ó ṣòro.

U. C., Ítálì

Ní pàtàkì, mo gbádùn àpótí yín, “Dídá Iṣẹ́ Sílẹ̀ Nílé.” Mo jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé, ajíhìnrere alákòókò kíkún, mo sì ní ibùdó àbójútó àwọn ọmọ de òbí lójúmọmọ fún ọdún méjì pẹ̀lú ìwé àṣẹ. Mo máa ń bójú tó àwọn ọmọ ṣáájú ilé ẹ̀kọ́ àti lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́, owó tó ń wọlé fún mi sì jọjú. Ó ń jẹ́ kí n lè máa wàásù ní apá ìdajì ọjọ́, mo sì ń ṣiṣẹ́ fún wákàtí mẹ́rin lóòjọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn òbí mọrírì rẹ̀ nítorí pé kò rọrùn láti rí àbójútó dáradára. Mo retí pé àwọn mìíràn pẹ̀lú lè rí iṣẹ́ tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà.

T. K. L., United States

Ẹ dámọ̀ràn pé àwọn aláìríṣẹ́ṣe lè dáwọ́ lé ṣíṣe àwọn ohun ìjókòó onítìmùtìmù, gígẹ irun, iṣẹ́ àtúnṣe àyíká ilé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ tún sọ pé lábẹ́ àwọn ipò kan, wọ́n lè polówó iṣẹ́ wọn lọ́fẹ̀ẹ́ tàbí lówó pọ́ọ́kú. Ǹjẹ́ èyí kò níí tẹ òfin lójú ní Germany?

R. T., Germany

Àwọn òfin ń yàtọ̀ láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè, bóyá àwọn ìdámọ̀ràn wọ̀nyí lè ṣàìbófinmu ní àwọn ilẹ̀ kan. Ìdí nìyẹn tí a fi tọ́ka sí i ní ojú ìwé 9 pé ó pọn dandan láti mọ̀, kí a sì bọ̀wọ̀ fún àwọn òfin ètò ìlú àti owó orí, ṣáájú bíbẹ̀rẹ̀ irú ìdáwọ́lé bẹ́ẹ̀. Àwọn Kristẹni wà lábẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti ṣègbọràn sí àwọn òfin orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá ń gbé. (Róòmù 13:1)—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.

Ọgbà Ẹranko Mo gbádùn àpilẹ̀kọ náà, “Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì—Nínú Ọgbà Ẹranko!” (March 8, 1996) Mo fẹ́ràn àwọn ìsọfúnni nípa àwọn ẹranko tí a mẹ́nu kàn nínú Bíbélì. N kò fìgbà kankan mọ̀ pé a mẹ́nu kan kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà nínú Bíbélì. Mo tún fẹ́ràn ìpínrọ̀ tí ó sọ nípa àwọn èèrùn. Àpilẹ̀kọ náà ti fún mi níṣìírí láti máa wádìí oríṣi ẹranko ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kan lóṣooṣù.

M. F., United States

Ọ̀rẹ́ Mi Ọ̀wọ́n Mo fẹ́ẹ́ fi ìmọrírì àtọkànwá mi hàn fún àpilẹ̀kọ dídùnmọ́ni náà, “Ọ̀rẹ́ Mi Ọ̀wọ́n.” (February 22, 1996) Ó mú inú ẹni dùn láti kà pé irú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ alárinrin bẹ́ẹ̀ wà láìka irú ìyàtọ̀ ọjọ́ orí bẹ́ẹ̀ sí. Ó fi hàn pé kì í ṣe dandan fún àwọn èwe láti ní kìkì àwọn ojúgbà wọn bí ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́ jù lọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbàlagbà ń bẹ tí wọ́n ní ohun púpọ̀ láti fi fúnni ní ti ìrírí, ọgbọ́n, àti ànímọ́ ìdẹ́rìn-ín pani.

S. T., England

Àpilẹ̀kọ náà fi ẹ̀rí hàn pé tèwetàgbà lè jùmọ̀ ṣe pọ̀, àti pé, àwọn ọ̀dọ́ lè jàǹfààní láti inú ìrírí ọlọ́ràá tí àwọn àgbàlagbà ti ní. Èmi tìkáraàmi ti lo ọ̀pọ̀ wákàtí alárinrin, tí ó dùn mọ́ni, pẹ̀lú ọ̀rẹ́ kan tí ó dàgbà jù mí lọ. Ó ti ṣèrànwọ́ púpọ̀ fún mi láti kojú àwọn ìṣòro bí ìkìmọ́lẹ̀ ojúgbà.

W. S., Austria

Títí di báyìí, n kò ì fìgbà kankan gbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn tó jù mí lọ. Ọpẹ́ ni fún àpilẹ̀kọ yìí, mo wáá lóye irú ohun tí mo lè kọ́ lọ́dọ̀ irú àwọn àgbàlagbà bẹ́ẹ̀. Mo ń dàníyàn gan-an láti di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà mélòó kan tí wọ́n ní ọgbọ́n gidigidi.

R. K., Japan

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́