Wíwo Ayé
Àwọn Àrùn Tí Ń Gbèèràn Gbógun
Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) sọ pé àwọn àrùn tí ń gbèèràn ló pa ìdá mẹ́ta lára mílíọ̀nù 52 ènìyàn tí ó kú ní èṣín. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn mílíọ̀nù 17 tí a fojú bù pé wọ́n kú náà jẹ́ àwọn ọmọ kéékèèké. Gẹ́gẹ́ bí ìwé The World Health Report 1996, tí àjọ WHO gbé jáde ṣe sọ, ó kéré tán, a ti dá 30 àrùn tuntun tí ń gbèèràn mọ̀ láàárín 20 ọdún tí ó kọjá, lára wọn sì ni fáírọ́ọ̀sì Ebola àti àrùn AIDS. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè dènà àwọn àrùn tí ń wuni léwu bí ikọ́ ẹ̀gbẹ, onígbá méjì, àti ibà, tàbí kí a gbàtọ́jú wọn lówó pọ́ọ́kú, wọ́n tún ti ń padà dé, wọ́n sì túbọ̀ ń di kò gbóògùn sí i. Ìròyìn náà sọ pé, ohun tó fà á ni “lílò tí àwọn ènìyàn ń lo àwọn egbòogi agbóguntikòkòrò láìlákòóso àti láìyẹ,” pa pọ̀ mọ́ àwọn kókó mìíràn, bí ìrìn àjò láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn àti bí iye ènìyán ṣe ń pọ̀ sí i ní àwọn àgbègbè ilẹ̀ olóoru tí àwọn ẹ̀fọ́n ti gbilẹ̀.
Àwọn Ibi Ìjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Nílé Ìtàwé
Ẹgbẹ́ àwọn Kátólíìkì kan ní Ítálì ti pinnu láti ṣàgbékalẹ̀ àwọn ibi ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ní àwọn ilé ìtàwé ìsìn rẹ̀, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò ní àlùfáà tí ń gbọ́ ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Àfidánrawò náà bẹ̀rẹ̀ ní Milan. Ọ̀gá àgbà ilé ìtajà náà sọ pé, ní gbogbo Wednesday, ní ilé ìtàwé kan ní agbègbè ìṣòwò ìlú, àlùfáà kan máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún “gbogbo àwọn tó bá ń fẹ́ẹ́ rí àlùfáà—ṣùgbọ́n tí kò fẹ́ẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì—láti gba ìmọ̀ràn tẹ̀mí, tàbí láti ṣe ìjẹ́wọ́ pàápàá.” Ó fi kún un pé: “Àwọn ìyọrísí ìbẹ̀rẹ̀ gan-an dára púpọ̀ ju ìfojúsọ́na wa dídára jù lọ fún àṣeyọrí lọ.” Èrèdí lílo àtinúdá náà? Ìwé agbéròyìnjáde La Repubblica ti Ítálì sọ pé, ó jẹ́ “láti dí àlàfo ìdínkù bí májẹ̀mú ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ṣe ń dín kù.”
Ohunkóhun Kò Ṣòfò
Lẹ́yìn tí a bá ti jẹ nǹkan bí ìwọ̀n 270 kìlógíráàmù ara ẹran tán, kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí ìyókù ẹran màlúù náà? A ń fi díẹ̀ lára àwọn nǹkan inú, bí èkùrọ́ ọrùn, pancreas, ẹ̀dọ̀ fóró, ọlọ inú, ẹ̀yà ara apèsè omi ìsúnniṣe lókè kíndìnrín, ilé ẹyin, ẹṣẹ́ pituitary, àti òróòro láti inú ẹ̀dọ̀kì àti àpò òróòro, ṣe egbòogi. A ń yọ èròjà collagen láti inú egungun, pátákò ẹsẹ̀, àti awọ, fún ìlò nínú àwọn ìpara àti òróró ìṣaralóge. Àwọn kèrékèré àti ọ̀rá ni a fi ń ṣe àwọn èròjà bíi butyl stearate, PEG-150 distearate, àti glycol stearate tí a fi ń ṣe ọ̀pọ̀ èròjà ìṣaralóge àti èròjà ìṣerunlóge. Ọ̀rá ẹran la fi ń ṣe ọ̀pọ̀ jù lọ ọṣẹ. A sì ń lọ egungun àti pátákò ẹsẹ̀ pọ̀ láti fi ṣe èròjà gelatin tí a ń lò nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ohun jíjẹ, títí kan ice cream, àwọn dáyá mélòó kan, àti ọ̀pọ̀ àwọn àṣemújáde “kò lọ́ràá.” A tún ń fi àwọn ẹ̀yà ara kan ṣe àwọn ẹfun ìkùnwé, ìṣáná, amúlẹ̀dán, kápẹ́ẹ̀tì onífùlùfúlù igi, èròjà tí kì í jẹ́ kí ohun olómi tètè dì pọ̀, sìmẹ́ǹtì, oògùn apàgbẹ́, láílọ́ọ̀nù, bébà fọ́tò, àwọn ohun èèlò eré ìdárayá, àwọn ohun èèlò onítìmùtìmù, àti aṣọ. Àwọn òkúta inú àpò òróòro ló níye lórí jù—600 dọ́là (U.S.) fún ìwọ̀n gíráàmù 28! Àwọn oníṣòwò láti ìhà Ìlà Oòrùn Jíjìn ń rà wọ́n láti fi ṣe oògùn arùmọ̀lára ìbálòpọ̀ sókè.
Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ Ọmọ Bíbí
Ìwádìí kúlẹ̀kúlẹ̀ kan, tí àjọ UNICEF (Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé) ṣe, fi hàn pé nǹkan bí 585,000 obìnrin ní ń kú lọ́dọọdún nígbà tí wọ́n lóyún àtí nígbà tí wọ́n ń bímọ. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn The Progress of Nations 1996 ṣe sọ, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀ràn ìbànújẹ́ ọmọ bíbí náà ni ó ṣeé dènà. Ó sọ pé: “Ní apá púpọ̀ jù lọ, èyí kì í ṣe ikú aláìsàn, tàbí ti arúgbó kùjọ́kùjọ́, tàbí ti ọ̀dọ́, bí kò ṣe ti àwọn obìnrin onílera ní ìgbà títayọ lọ́lá jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn.” Nǹkan bí 75,000 obìnrin ní ń kú lọ́dọọdún nítorí àṣìṣe níbi ìṣẹ́yún; 40,000 ń kú nítorí ìdíwọ́ ìgbà ìrọbí; 100,000 ń kú nítorí àwọn kòkòrò àrùn tí ń gbógun ti ìṣàn ẹ̀jẹ̀; 75,000 ń kú nítorí ìbàjẹ́ tí àrùn eclampsia (àìperí àti ẹ̀jẹ̀ ríru tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí oyún bá ti gòkè) ń ṣe fún ọpọlọ àti kíndìnrín; iye tí ó lé ní 140,000 sì ń kú nítorí ẹ̀jẹ̀ dídà. Wọ́n ti sọ pé àìtó ìtọ́jú ìṣègùn nígbà ìbímọ ló jẹ́ lájorí okùnfà rẹ̀ lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè. Àwọn òṣìṣẹ́ àjọ UNICEF sọ pé ìwádìí oníṣirò náà fi hàn pé ìpíndọ́gba obìnrin 1 nínú 35 ní Gúúsù Éṣíà àti 1 nínú 13 ní ìhà gúúsù Sàhárà ilẹ̀ Áfíríkà ní ń kú nítorí àwọn ohun tí ó níí ṣe pẹ̀lú oyún níní àti ọmọ bíbí, bí a bá fi wéra pẹ̀lú obìnrin 1 nínú 7,300 ní Kánádà, 1 nínú 3,300 ní United States, àti 1 nínú 3,200 ní Europe. Iye náà fi ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún ju ìdíyelé nǹkan bí 500,000 tí ń kú lọ́dọọdún, tí ó wà tẹ́lẹ̀ lọ.
Àrùn AIDS Ń Pọ̀ Sí I
Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ròyìn pé: “Fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn AIDS ń yára kánkán gbilẹ̀ sí i ní àwọn apá gbígbòòrò lágbàáyé, ní pàtàkì, ní Éṣíà àti ìhà gúúsù Áfíríkà, iye ènìyàn tí àrùn AIDS ń ṣe sì ti yára ga sókè gan-an.” Ìsọfúnni oníṣirò tí Ètò Àjọṣe Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí H.I.V.-AIDS ṣàkójọ rẹ̀ fi hàn pé ní 1995, nǹkan bí 1.3 mílíọ̀nù ènìyàn ṣàìsàn tí ó ní àwọn àmì àrùn AIDS, ó sì fi ìbísí ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún ju ti ọdún tó ṣáájú lọ. Ní báyìí, a fojú bù ú pé mílíọ̀nù 21 àwọn àgbàlagbà kárí ayé ní fáírọ́ọ̀sì HIV, nǹkan bí ìpín 42 nínú ọgọ́rùn-ún lára wọ́n sì jẹ́ obìnrin. Àfikún 7,500 ènìyán sì ń ní in lójoojúmọ́. A tún gbọ́ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdé ní in pẹ̀lú. Ó ń gba nǹkan bí ọdún mẹ́wàá, láti ìgbà tí ẹnì kán bá kó o, kí àìsàn líle kokó tóó yọjú. Ìròyìn àjọ UN náà fojú bù ú pé 980,000 ènìyàn ni àwọn àrùn tí ó jẹ mọ́ AIDS pa ní 1995 àti pé iye yìí yóò lọ sókè sí 1,120,000 ní 1996. Fáírọ́ọ̀sì náà ti gbilẹ̀ gan-an ní gúúsù Áfíríkà àti Íńdíà láìpẹ́ yìí, a sì retí pé yóò tún ṣe bákan náà ní China àti Vietnam. Ìwọ̀n tí ó fi ń ràn ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà ti ga tó ìpín 16 sí 18 nínú ọgọ́rùn-ún. Ó ń dani lọ́kàn rú pé iye àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí àrùn náà ń ràn ń yára pọ̀ sí i lágbàáyé. Ìdámẹ́ta àwọn ọmọ tí àwọn obìnrin wọ̀nyí bá bí yóò ní fáírọ́ọ̀sì náà pẹ̀lú.
Ṣọ́ra fún Eré Àsápajúdé!
Ìwé agbéròyìnjáde The Daily Telegraph ti London ròyìn pé lọ́dọọdún, 1,000 ará Britain ní ń kú, tí 77,000 sì ń fara pa, nítorí eré àsápajúdé nígbà tí wọ́n bá ń wakọ̀. Kódà, títẹ̀ lé òòté tí a gbé ka orí eré sísá lè léwu síbẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò kan. Iye tí ó lé ní ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ìjàm̀bá ojú títì tí a ti ń sáré gan-an ni sísúnmọ́ ọkọ̀ tó wà níwájú jù ń fà. Ìwé Òfin Ìrìnnà Ilẹ̀ Britain sọ pé kí awakọ̀ fi àlàfo tí ó lè fi eré tí ó ń sá bọ̀ parí ní ìṣẹ́jú àáyá méjì sílẹ̀ láàárín òun àti ọkọ̀ tí ń bẹ níwájú, ṣùgbọ́n èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlọ́po méjì nígbà tí ó bá ń wakọ̀ lójú títì tí ó lómi, tàbí tí ó ń yọ̀, tàbí níbi tí ìríranríwájú kò bá ti dán mọ́rán. Kì í ṣe kìkì pé sísún mọ́ ọkọ̀ tí ń lọ níwájú jù léwu nìkan ni; ṣùgbọ́n ó ń mú ọkọ̀ wíwà súni, ó sì ń tánni lókun. Àwọn awakọ̀ sábà ń ṣàròyé pé, bí àwọ́n bá fi àlàfo sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, ọkọ̀ míràn ń kó wọ̀ ọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun kan ṣoṣo tí ó dára jù lọ láti ṣe bí èyí bá ṣẹlẹ̀ ni láti dẹ̀rìn kí o sì tún fi àlàfo náà sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Títẹ ìjánu ọkọ̀ lójijì lè fa ìjàm̀bá, nítorí náà, wà lójúfò sí àwọn ewu tí ó ṣeé ṣe kí ó wà látòkèèrè. Níní ìhùmọ̀ àìtìjánupa kò dín àlàfo tí ọkọ̀ kán nílò láti fi dúró kù. Paul Ripley, olùdánilẹ́kọ̀ọ́ ọkọ̀ wíwà, sọ pé: “Ìwọ̀n eré sísá tí kò léwu lábẹ́ ipò èyíkéyìí sábà máa ń kéré gan-an ju bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn awakọ̀ ṣe mọ̀ lọ.”
Ẹ̀yin Oníṣẹ́ Abẹ, Ẹ Ṣọ́ Ẹnu Yín
Àwọn olùṣèwádìí láti Yunifásítì Erasmus ní Netherlands ti ṣàwárí pé, ó ṣeé ṣe fún àwọn olùgbàtọ́jú tí a ń ṣe iṣẹ́ abẹ fún láti “gbọ́ròó,” kódà bí a bá tilẹ̀ lo oògùn apàmọ̀lára fún wọn pàápàá. Lẹ́yìn tí wọ́n parí iṣẹ́ abẹ fún 240 olùgbàtọ́jú, wọ́n sọ sílébù àkọ́kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ti sọ jáde nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ abẹ náà fún wọn, wọ́n sì sọ pé kí wọ́n parí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí ó kọ́kọ́ wá sí wọn lọ́kàn. Kódà, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùgbàtọ́jú lè rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ní wákàtí 24 lẹ́yìn tí a sọ ọ́. Àwọn olùṣèwádìí náà sọ pé, èyí fi hàn pé àwọn olùgbàtọ́jú tí a lo oògùn apàmọ̀lára fún lè “fetí kọ́ ọ̀rọ̀” nígbà tí a ń ṣiṣẹ́ abẹ fún wọn lọ́wọ́, kí àwọn ọ̀rọ̀ òdì tàbí èébú tí a sọ́ sì nípa lórí wọn. Lẹ́tà ìròyìn Research Reports From the Netherlands, tí Àjọ Ìwádìí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ilẹ̀ Netherlands tẹ̀ jáde, parí ọ̀rọ̀ pé: “Nítorí náà, àwọn òṣìṣẹ́ ìṣègùn ní láti máa kíyè sí àwọn ìjíròrò wọn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ abẹ lọ́wọ́.”
“Àrùn Dìgbòlugi Màlúù”
◼ “Àrùn dìgbòlugi màlúù” tó bẹ́ sílẹ̀ ní Britain ti pe kókó àtọjọ́mọ́jọ́ kan nípa ẹran sísìn wá sí àfiyèsí. A ti yí àwọn ẹranko padà kúrò ní jewéjewé sí jẹranjẹran nípa fífi àwọn ẹ̀yà ara àwọn ẹranko mìíràn bọ́ wọn. Ẹ̀jẹ̀ gbígbẹ, egungun lílọ̀, àti oúnjẹ ẹlẹ́ran, tàbí oúnjẹ ẹranko, tí ó ní ìfun, okùn ògooro ẹ̀yìn, ọpọlọ, àti àwọn nǹkan inú mìíràn, bíi pancreas, kòmóòkun, àti kíndìnrín nínú, ni a ń fún wọn jẹ déédéé kí a lè dín ìnáwó kù, kí a fi kún èrè jíjẹ, kí a sì ṣàlékún ìdàgbà ẹranko. Dókítà Harash Narang, ọ̀kan lára àwọn ògbóǹkangí tí ó kọ́kọ́ ṣèkìlọ̀ nípa àrùn náà sọ pé nígbà tí ọmọ màlúù kan bá fi pé oṣù mẹ́fà, a ti fi nǹkan bí kìlógíráàmù 12 oúnjẹ tí a fi ìyókù ẹ̀yà ara àwọn ẹranko mìíràn ṣe, bọ́ ọ. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ìbẹ̀wò kan tí ó ṣe sí ibùpẹran kan, ó ní: “Ẹ̀rú bà mí. A wulẹ̀ ń ṣàyídà màlúù sí màlúù ní ti gidi ni. Lójú mi, ó jẹ́ àṣà àwọn ẹranko tí ń jẹ ẹranko ẹlẹgbẹ́ wọn.”
◼ Ní ìhà dídùnmọ́ni kan, àgbẹ̀ ẹlẹ́ran ọ̀sìn ará Britain kan ti ṣàwárí ọ̀nà kan láti lo àwọn màlúù rẹ̀ tí kò lè rí tà jèrè nítorí ìbẹ̀rù “àrùn dìgbòlugi màlúù” náà. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ròyìn rẹ̀ nínú ìwé ìròyìn Newsweek, ó ń lò wọ́n bíi pátákó ìpolówó. Ó ń gbé àwọn ìpolówó sí ara àwọn màlúù rẹ̀ tí ń jẹko lẹ́bàá òpópónà tí ọkọ̀ ti ń lọ, tí ó sì ń bọ̀, ó sì ń pa nǹkan bí 40 dọ́là lórí màlúù kọ̀ọ̀kan lọ́sẹ̀. Àgbẹ̀ náà sọ pé: “A ní láti wá àwọn ọ̀nà míràn tí owó yóò fi máa wọlé. Ó jọ pé ọ̀nà tí ó dára fún àwọn màlúù náà nìyẹn láti fi pa owó ìgbọ́bùkátà lórí wọn.”