Àwọn Alárìnkiri àti Ìlàkàkà Wọn Láti Dòmìnira
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NETHERLANDS
NÍ July 1620, àwùjọ àwọn ọmọ ilẹ̀ England, tí wọ́n jẹ́ Aláfọ̀mọ́, tí wọ́n ti wọkọ̀ òkun láti Delfshaven, nítòsí Rotterdam, Netherlands, ṣèdásílẹ̀ ibùdó pípẹ́ títí àkọ́kọ́ ti àwọn ará Europe ní New England—Ibùdó Plymouth—ní ibi tí a mọ̀ sí ìhà ìlà oòrùn gúúsù Massachusetts nísinsìnyí. Kí ní sún àwọn ènìyàn tí ìsín jinlẹ̀ nínú wọn wọ̀nyí láti fara wewu irú ìrìn àjò gígùn, tí ó sì ṣòro bẹ́ẹ̀, la Òkun Ńlá Àtìláńtíìkì tí ó kún fún ewu já nínú ọkọ̀ òkun Mayflower kékeré náà? Kí ni wọ́n wáá ṣe ní Netherlands gan-an? Èé ṣe tí wọ́n fi kúrò níbẹ̀?
Ipò Tí Ìsín Wà ní England
Láàárín àwọn ọdún 1500, Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe gbo Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì jìgìjìgì. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì bẹ̀rẹ̀ sí í yọjú jákèjádò Europe, títí kan England. Ní ti England, ìbàjẹ́ tí ó kẹ́yìn nínú ipò àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Róòmù dé, nígbà tí póòpú kọ̀ láti fọwọ́ sí ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ Ọba Henry Kẹjọ láti tú ìgbéyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́ ká. Ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ England yapa kúrò lára Róòmù, nígbà tí ó sì di 1534, Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ England gba Henry gẹ́gẹ́ bí “Olórí Gíga Jù Lọ lórí ilẹ̀ ayé, lẹ́yìn Ọlọ́run, fún Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ England.” Ó tọ́ ọmọbìnrin rẹ̀, Elizabeth, tí ó bí ní 1533, dàgbà gẹ́gẹ́ bí Pùròtẹ́sítáǹtì, lẹ́yìn tí ìyẹ́n sì di Ọbabìnrin Elizabeth Kìíní, ó fún Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà ní àbùdá ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì lílágbára. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn àwùjọ Pùròtẹ́sítáǹtì kéékèèké kan ń bẹ tí kò fara mọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà tí ó lágbára ìdarí púpọ̀ náà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí ni a wáá mọ̀ sí àwọn Aláfọ̀mọ́, nítorí pé wọ́n fẹ́ẹ́ fọ Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà mọ́ lọ́wọ́ ohunkóhun tí ó lè jẹ́ àmì ìsìn Roman Kátólíìkì. A ka àwùjọ Aláfọ̀mọ́ kan sí aláṣerégèé ní pàtàkì, nítorí pé wọ́n yapa kúrò lára ìṣètò àkóso ẹlẹ́gbẹ́ àwọn bíṣọ́ọ̀bù àti àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì. Wọ́n ka ìjọ tiwọn sí èyí tó dá wà lómìnira, lábẹ́ ìṣàkóso àwọn alàgbà tiwọn fúnra wọn.
Ọbabìnrin Elizabeth bẹ̀rù pé òun yóò pàdánù agbára òun láti darí àwọn ènìyàn bí òun kò bá dí àwọn Aláfọ̀mọ́ lọ́wọ́. Nítorí náà, ó gbé òfin líle koko kalẹ̀ lòdì sí wọn. Láìka ìyẹn sí, onírúurú àwùjọ àwọn Aláfọ̀mọ́ ń pàdé pọ̀ nìṣó, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ní bòńkẹ́lẹ́, ní àwọn ilé àdáni. Àwọn Aláfọ̀mọ́ tún pín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ìléwọ́ kéékèèké tí ń polongo ìgbàgbọ́ wọn kiri. Àwọn Aláfọ̀mọ́ ní London yan ẹgbẹ́ àwọn alàgbà tiwọn, tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọ́n jẹ́ àwọn òjíṣẹ́ ti Áńgílíkà tí a ti yọ nípò. Wọ́n ń tọ́ka sí àwọn àwùjọ tí wọ́n jáwọ́ lára ṣíṣe àfọ̀mọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà, tí wọ́n sì yapa kúrò lára rẹ̀ bí àwọn Olùyapa.
Ọba James Kìíní, tí ó jẹ tẹ̀ lé Ọbabìnrin Elizabeth, tẹ̀ lé ìlànà ọbabìnrin náà nípa ìsìn, pẹ̀lú ìhàlẹ̀ láti “lé [àwọn Aláfọ̀mọ́] kúrò ní ilẹ̀ náà tipátipá.” Ní àkókò kan náà, ó ṣàgbékalẹ̀ ìṣètumọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì lọ́tun—ìtumọ̀ King James Version, tí ó parí ní 1611. Ìtumọ̀ tuntun yìí sún ọ̀pọ̀ ènìyàn láti ṣàyẹ̀wò Bíbélì. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tí ó yàtọ̀ sí ti ṣọ́ọ̀ṣì Orílẹ̀-èdè náà. Kí ni ò bá ti ṣe, ká ní o wà láàyè nígbà yẹn? Ǹjẹ́ o rò pé ò bá ti ṣàtúnṣe èrò ìgbàgbọ́ ìsìn rẹ lójú inúnibíni tí a fi ń halẹ̀ mọ́ni náà? Ǹjẹ́ ò bá ti rọ̀ mọ́ èrò ìdánilójú rẹ tímọ́tímọ́, láìka ohun tí ó lè jẹ́ àbájáde rẹ̀ sí? Ọ̀pọ̀ àwọn Aláfọ̀mọ́ ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì kọ̀ láti juwọ́ sílẹ̀.
Sísá Lọ sí Holland
A rí àwùjọ àwọn Olùyapa kan tí kò juwọ́ sílẹ̀ ní ìlú kékeré Scrooby ti ilẹ̀ England. Níbẹ̀ ni wọ́n ti ń pàdé ní bòńkẹ́lẹ́, nílé akólẹ́tà kan, William Brewster, tí ó jẹ́ “Alàgbà Alákòóso” wọn. John Robinson, àlùfáà Áńgílíkà tẹ́lẹ̀ rí kan, dara pọ̀ mọ́ wọn. Ní àfikún sí ṣíṣalágbàwí ìṣàkóso ṣọ́ọ̀ṣì láti ọwọ́ àwọn alàgbà, dípò àwọn àlùfáà àti bíṣọ́ọ̀bù, àwùjọ tí ó wà ní Scrooby kọ aṣọ oyè àlùfáà àti ọ̀pọ̀ lára àwọn ayẹyẹ ìjọsìn Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òfín kan àwọn ohun wọ̀nyí nípá.
Nígbà tí àwùjọ yìí rí i pé pákáǹleke náà ń pọ̀ sí i, wọ́n pinnu láti sá lọ sí Netherlands, tí ó jẹ́ ibì kan ṣoṣo ní Europe tí a ti lè fàyè gba àwọn ojú ìwòye wọn àti àṣà wọn nígbà náà. Bí ó ti wù kì ó rí, kíkó kúrò nílùú kò bófin mu. Nítorí náà, bí ó ti ṣeé yọ́ ṣe tó, wọ́n ta àwọn ilé wọn àti ohun gbogbo mìíràn tí wọn kò lè mú dání lọ, wọ́n sì wọ ọkọ̀ òkun lọ sí Amsterdam ní 1608. Ní Netherlands ni àwọn Olùyapa ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ara wọn sí alárìnkiri.
Àwọn Alárìnkiri náà kó lọ sí Leiden lẹ́yìn ọdún kan tí wọ́n gúnlẹ̀, ọdún kan náà tí wọ́n dáwọ́ ogun tí ó ti ń lọ láàárín Sípéènì àti Netherlands dúró fúngbà díẹ̀. Ìdáwọ́ ogun dúró fúngbà díẹ̀ náà yọrí sí ipò àyíká tí ó túbọ̀ lálàáfíà fún àwọn Alárìnkiri náà. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ìsáǹsá púpọ̀ sí i ń dé láti ilẹ̀ England, àwùjọ náà sì pọ̀ sí i níye tó bí 300. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n ra ilé ńlá kan, níbi tí John Robinson àti ìdílé rẹ̀ ń gbé, tí wọ́n sì lè máa ṣe ìpàdé níbẹ̀ pẹ̀lú.
Lẹ́yìn tí wọ́n ti lo nǹkan bí ọdún mẹ́wàá ní Leiden, àwọn Alárìnkiri náà bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára àìbalẹ̀ ọkàn. Ìdáwọ́ ogun dúró fúngbà díẹ̀ pẹ̀lú Sípéènì ń kásẹ̀ nílẹ̀ lọ, wọ́n sì bẹ̀rù pé, bí Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ nílẹ̀ Sípéènì bá lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ní Netherlands, nǹkan yóò túbọ̀ burú fún àwọn ju ti ìgbà tí àwọ́n wà lábẹ́ Ọba James lọ. Síwájú sí i, wọn kò fohùn ṣọ̀kan ní ti ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wọn, ará Netherlands tí wọ́n tún kóni mọ́ra jù wọ́n lọ, wọ́n sì ń ṣàníyàn nípa àjọṣepọ̀ àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú àwọn èwe ará Netherlands, tí wọ́n kà sí aláìníjàánu. Kí ni kí wọ́n ṣe? Wọ́n gbèrò láti tún gbéra sọ lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ lẹ́ẹ̀kan sí i—lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n ń kó lọ sí America!
Ìrìn Àjò Nínú Ọkọ̀ Mayflower!
Ìṣòro títóbi jù lọ tí wọ́n ní ni rírí owó láti fi gbọ́ bùkátà irú ìrìn àjò gígùn bẹ́ẹ̀. Ìṣòro mìíràn tó tún gbàfiyèsí ni pé wọ́n ní láti gbàṣẹ fún irú ìjádelọ bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ ọba ilẹ̀ England—ọba kan náà tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti sá lọ fún nígbà tí wọ́n sá lọ sí Netherlands! Àwọn Alárìnkiri náà fi ìbéèrè ẹ̀bẹ̀ wọn dá Ọba James lágara, títí tí ó fi fún wọn láṣẹ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Níkẹyìn, àwùjọ àwọn oníṣòwò kan ní London gbé ẹrù ìnáwó ìdáwọ́lé náà.
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó tó àkókò láti gbéra! Àwọn ọmọ ìjọ Ṣọ́ọ̀ṣì Alárìnkiri ní Leiden, tí wọ́n pinnu láti rin ìrìn àjò náà, wọ ọkọ̀ òkun Speedwell, wọ́n sì gbéra láti Delfshaven ní July 22, 1620, lọ sí England, níbi tí àwọn mẹ́ḿbà míràn ti dara pọ̀ mọ́ wọn. Àwọn Alárìnkiri náà bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn pẹ̀lú ọkọ̀ òkun méjì, Speedwell àti Mayflower. Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí pé omí bẹ̀rẹ̀ sí í wọnú ọkọ̀ Speedwell, ó di ọ̀ràn-anyàn kí wọ́n padà sí England, níbi tí ọkọ̀ Mayflower ti kó àwọn èrò àti ohun èèlò láti inú ọkọ̀ Speedwell. Níkẹyìn, ní September 6, ọkọ̀ Mayflower kékeré, onímítà 27 náà bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Plymouth, England, ní òun nìkan, ó kó ìdílé 24—gbogbo èrò inú rẹ̀ jẹ́ 102—àwọn agbo òṣìṣẹ́ sì jẹ́ 25. Ẹ wo irú ìgboyà tí ó gbà fún àwọn arìnrìn àjò aláìnírìírí wọ̀nyẹn láti dáwọ́ lé ìrìn àjò tí ó jìnnà tó 5,000 kìlómítà lójú agbami òkun! Ọkọ̀ òkun náà ti kún jù, ó sì ní láti kojú ipò ojú ọjọ́ líléwu ti Àríwá Òkun Àtìláńtíìkì. Fojú inú wo ìmọ̀lára àwọn èrò ọkọ̀ náà, bí wọ́n ṣe fojú gán-ánní ilẹ̀, lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́sàn-án tí wọ́n ti ń rìn lójú agbami òkun!
Dídá Ibùdó Náà Sílẹ̀
Kí àwọn Alárìnkiri náà tóó gúnlẹ̀, wọ́n ṣe àdéhùn àjùmọ̀ṣe, tàbí májẹ̀mú kan, nípa ìṣàkóso ibùdó náà lọ́jọ́ iwájú. Nípa àdéhùn yìí, tí àwọn ọkùnrin 41 nínú àwùjọ náà fọwọ́ sí, àwọn Alárìnkiri náà gbára wọn jọ di “Àgbájọ Aráàlú Lábẹ́ Ètò Ìjọba Kan Ṣoṣo,” wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ ṣíṣe àwọn òfin tí yóò máa ṣàkóso gbogbo àwọn àlámọ̀rí wọn, kí wọ́n sì pa wọ́n mọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òpìtàn kán ti pe ìwé àkọsílẹ̀ yìí ní àkọsílẹ̀ òfin ilẹ̀ America kìíní, ìwé agbédègbẹ́yọ̀ Grote Winkler Prins Encyclopedie tọ́ka sí i pé àwọn Alárìnkiri tí ó ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ “ní in lọ́kàn láti ṣàgbékalẹ̀ ọlá àṣẹ ti ìrísí onísìn kan.” Ète rẹ̀ jẹ́ láti mú kí gbogbo àwọn mẹ́ḿbà ibùdó náà wà pa pọ̀ ní ti ara àti ní ti ìsìn.
Ní December títutù nini, lẹ́yìn wíwo etíkun náà yí ká àti ṣíṣe ìwádìí ní àtàkè, àwùjọ náà dó sí ibi tí wọ́n sọ ni New Plymouth, tí wọ́n wáá pè ní Ibùdó Plymouth lẹ́yìn náà. Wọ́n bá àwọn oko tí àwọn Amerind ti ń ro níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn àrùn tí àwọn olùṣàwárí tí ó kọ́ débẹ̀ ní ọdún mélòó kan ṣáájú ní—títí kan ìgbóná àti èèyi—ti run àwọn Amerind rẹpẹtẹ tí wọ́n rí nígbà náà. Bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, àwọn Amerind ì bá ti ta ko ìsapá àwọn Alárìnkiri náà láti dá ibùdó kan sílẹ̀.
Àwọn Alárìnkiri náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kíkọ́ ilé àjùmọ̀ni kan àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ilé àdáni. Ìbẹ̀rẹ̀ náà kò rọrùn, nítorí pé ìgbà òtútù ni wọ́n dé sí, oúnjẹ tí ó sì kù láti inú èyí tí wọ́n gbé wọkọ̀ tẹ́lẹ̀ kò tó nǹkan. Láàárín ìgbà òtútù àkọ́kọ́ yẹn, àrún pa àwọn 52, tí ó ní àwọn ọkọ 13 lára àwọn 24 àti 14 lára àwọn ìyàwó 18 náà nínú. John Carver, gómìnà wọn àkọ́kọ́, wà lára àwọn tí ó kú náà. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó là á já pinnu láti máa gbé New Plymouth nìṣó. Gómìnà tí ó tẹ̀ lé e, William Bradford ọlọ́yàyà, pa àkọsílẹ̀ ìtàn ibùdó tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde náà mọ́, a sì tipa bẹ́ẹ̀ kà á sí òpìtàn ará America kìíní.
Àwọn Alárìnkiri Náà àti Àwọn Amerind
Àwọn Alárìnkiri tí ó kọ́kọ́ dé New Plymouth ṣàdéhùn àlàáfíà àjùmọ̀ṣe kan pẹ̀lú Massasoit, olóyè gíga jù lọ ti ẹ̀yà Wampanoag ti Amerind, tí ó jẹ́ ìbílẹ̀. Nínú àdéhùn náà, àwọn Alárìnkiri náà àti àwọn Wampanoag ṣèlérí láti má ṣe pa ara wọn lára, wọ́n sì jẹ́jẹ̀ẹ́ ìdáàbòbò àjùmọ̀ṣe bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ogún dé pẹ̀lú àwọn mìíràn láti ìta. Láìsí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Massasoit, kò jọ pé èyíkéyìí lára àwọn Alárìnkiri náà ì bá là á já. Àwọn Amerind wọ̀nyí fún àwọn abulẹ̀dó náà ní àgbàdo ìbílẹ̀ wọn láti jẹ àti láti gbìn, àjọṣe pẹ̀lú wọ́n sì mú kí àwọn ẹ̀yà míràn má pa àwọn Alárìnkiri náà run.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, àwọn Amerind ran àwọn abulẹ̀dó náà lọ́wọ́ gidigidi. Gẹ́gẹ́ bí Gómìnà William Bradford ṣe sọ ọ́, Amerind kan tí ń jẹ́ Tisquantum kọ́ àwọn abulẹ̀dó náà “bí ó ṣe yẹ kí wọ́n gbin àgbàdo, ibi tí wọ́n ti lè rẹ́ja pa, àti bí wọ́n ṣe lè rí àwọn ohun mìíràn tí wọ́n nílò, òun ni ó sì ń fọ̀nà hàn wọ́n ní àwọn ibi tí wọn kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ fún àǹfààní wọn.” Ìkórè àgbàdo àwọn Amerind àkọ́kọ́ dára gan-an ni, ọwọ́ àwọn Alárìnkiri náà sì dẹ ní ti ẹyẹ pípa. Wọ́n ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run, wọ́n sì pinnu láti ṣàjọyọ̀ ìkórè ọlọ́jọ́ mẹ́ta. Massasoit àti 90 akíkanjú ológun rẹ̀ wá, wọ́n sì mú ìgalà márùn-ún wá láti fi kún àsè náà.
Bíi ti ibùdó náà fúnra rẹ̀, ayẹyẹ náà ní ìtumọ̀ ti ìsìn gidi gan-an. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Alárìnkiri kò ṣe ayẹyẹ náà lọ́dún kejì nítorí irè oko tí kò fi bẹ́ẹ̀ dára, Ọjọ́ Ìdúpẹ́ wáá di họlidé ọdọọdún ti orílẹ̀-èdè àti ti ìsìn lẹ́yìn náà ní United States, Kánádà, àti àwọn orílẹ̀-èdè díẹ̀ míràn. Lónìí, Ọjọ́ Ìdúpẹ́ ní Àríwá America jẹ́ àpẹẹrẹ àṣeyẹ àsè ìdílé níbi tí a ti ń jẹ tòlótòló, ọbẹ̀ tí a fi èso cranberry sè, àti pie tí a fi elégédé ṣe—ṣùgbọ́n ní ti ìpìlẹ̀, ó jẹ́ “àkókò fún ìrònújinlẹ̀ tọkàntọkàn nípa ìsìn, ayẹyẹ ìsìn ní ṣọ́ọ̀ṣì, àti àdúrà.”—The World Book Encyclopedia, 1994.a
Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Ẹ̀yìn Ìgbà Náà
Ní 1622, àwọn Alárìnkiri púpọ̀ sí i dé láti Leiden àti England. Lẹ́yìn náà, àwọn ọkọ̀ òkún tí ó kó àwọn onígbàgbọ́ kan náà wá láti Europe tún dé láfikún. Ní 1630, àwùjọ àwọn Alárìnkiri tí ó kẹ́yìn dé sí ibùdó náà láti Leiden, tí ó mú kí iye wọ́n tó nǹkan bí 300. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ibùdó náà dà pọ̀ mọ́ Ibùdó Ìyawọlẹ̀ Omi Òkun Ti Massachusetts, tí ó tóbi púpọ̀ gan-an jù ú lọ, tí kò jìnnà síhà àríwá. Àwọn abulẹ̀dó wọ̀nyí ní ìgbàgbọ́ Aláfọ̀mọ́ bákan náà. Bí ó ti wù kí ó rí, àìfararọ ń pọ̀ sí i láàárín àwọn abulẹ̀dó náà àti àwọn Amerind, aládùúgbò wọn, nígbà kan náà. Àwọn Aláfọ̀mọ́, tí wọ́n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ni ó ti kádàrá àwọn láti jọba lé ilẹ̀ tuntun náà, túbọ̀ ní ẹ̀mí ìjọra ẹni lójú sí i. Nígbà tí àwọn Amerind rí èyí, wọ́n túbọ̀ kórìíra wọn sí i. Ó bani nínú jẹ́ pé, ní ọdún 55 péré lẹ́yìn àdéhùn tí wọ́n bá àwọn Wampanoag ṣe, ibùdó tí ó wà ní Plymouth, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ibùdó àwọn ará England mẹ́ta mìíràn àti àwọn Amerind míràn, lọ gbógun ti ọmọkùnrin Massasoit. Wọ́n pa òun àti nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún àwọn Amerind lọ́kùnrin, lóbìnrin, àti lọ́mọdé, àwọn Aláfọ̀mọ́ náà sì ta àìlóǹkà àwọn mìíràn sóko ẹrú. Àwọn Wampanoag wáá kú run.
Ogún Tí Àwọn Alárìnkirí Fi Sílẹ̀
Ní Netherlands, o ṣì lè ṣèbẹ̀wò sí àdúgbò tí àwọn Alárìnkiri náà gbé ní Leiden, kí o sì dé Delfshaven, èbúté tí wọ́n ti gbéra lọ sí America. Ní ìlú Plymouth, Massachusetts, ti ìsinsìnyí, o lè rí Oko Ọ̀gbìn Ńlá Plymouth, àtúnkọ́ abúlé ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà tí àwọn Alárìnkirí kọ́, pẹ̀lú ilé àkójọ óhun ìṣẹ̀m̀báyé àwọn Alárìnkiri àti aláfarajọ ọkọ̀ òkun Mayflower kan. Ní abúlé náà, àwọn òṣèré máa ń ṣe bí àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ gbé ibẹ̀. Wọn yóò sọ fún ọ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run àti pé “ṣọ́ọ̀ṣì” kì í ṣe ilé olókùúta kan, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ló para pọ̀ ń jẹ́ bẹ́ẹ̀. Bí o bá bi wọ́n pé, “Àwọn alàgbà mélòó ló wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì yín?” wọn á dáhùn pé: “Iyekíye tí ó bá ti dójú ìlà ohun tí Bíbélì là sílẹ̀ ni.”
Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Puritan Heritage—America’s Roots in the Bible ṣe sọ, àwọn Alárìnkiri náà gbìyànjú láti gbé àwùjọ wọn kalẹ̀ lọ́nà tí yóò fi “jọ ti àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá lábẹ́ Mósè, bí ó ti lè ṣeé ṣe tó.” Síbẹ̀síbẹ̀, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn Aláfọ̀mọ́ náà ń lọ jìnnà jù. Bí àpẹẹrẹ, òkìkí tí wọ́n ní gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́kára jẹ yọ títí dé ìwọ̀n kan, láti inú ìgbàgbọ́ wọn pé ìníláárí ní ti ohun ìní jẹ́ àfihàn ojú rere Ọlọ́run. Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fẹ́ràn àwọn ọmọ wọn tinútinú, ọ̀pọ̀ àwọn Aláfọ̀mọ́ ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ́ gbà gbọ́ pé àwọ́n gbọ́dọ̀ “fi ìfẹ́ni rírékọjá ààlà . . . tí àwọ́n ní pa mọ́.” Nípa bẹ́ẹ̀, “jíjẹ́ aláfọ̀mọ́” ti wáá ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìrísí ìkanjúko àti àìlọ́yàyà, ìlekoko, àti ìmógìírí ju bó ti yẹ lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, láìka jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ aláìpé sí, àwọn Alárìnkiri ní agbára ìhùwà rere dé ìwọ̀n kan, wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn, wọ́n sì sapá láti gbé ìgbésí ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì. Ó ṣe kedere pé àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ni ó so àwọn Alárìnkiri náà pọ̀ ṣọ̀kan, tí ó sì mú wọn la ọ̀pọ̀ lára àwọn ìdánwò tí wọ́n dojú kọ já.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Kristẹni tòótọ́ kò nílò ọjọ́ pàtó kan láti fọpẹ́ fún Ọlọ́run. Fún àfikún ìsọfúnni, jọ̀wọ́ wo ìtẹ̀jáde Jí!, November 22, 1976 (Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 9 sí 13.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn Amerind ti ẹ̀yà Wampanoag ran àwọn Alárìnkiri lọ́wọ́
[Credit Line]
Harper’s Encyclopædia of United States History
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Lókè: Model van de Mayflower