O ha ń yán hànhàn fún Ayé Onídàájọ́ Òdodo?
ỌKỌ̀ òkun kan tí a fi igi ṣe tí ó ní òpó mẹ́ta pẹ̀lú àjà méjì ń sún mọ́ etíkun tí a ń pè ní Cape Cod, Massachusetts, U.S.A., nísinsìnyí. Ó ti rẹ àwùjọ atukọ̀ àti 101 àwọn èrò ọkọ̀ náà tí wọ́n ti wà lójú agbami òkun fún ọjọ́ 66 tẹnutẹnu. Ní wíwá ọ̀nà láti yè bọ́ lọ́wọ́ inúnibíni ìsìn àti ìnira ọrọ̀ ajé, wọ́n ti rìnrìn àjò atánnilókun láti lè kọjá Òkun Àtìláńtíìkì.
Bí àwọn èrò ọkọ̀ òkun yìí, Mayflower, ṣe tajú kán rí ilẹ̀ lọ́ọ̀ọ́kán ní November 11, ọdún 1620, inú wọn dùn jọjọ fún níní ìrètí ìbẹ̀rẹ̀ tuntun kan. Ní fífẹ́ láti fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ayé kan tí ó dára jù, ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àgbàlagbà ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ èrò inú ọkọ̀ òkun náà fọwọ́ sí Májẹ̀mú Mayflower. Nínú rẹ̀, wọ́n fohùn ṣọ̀kan láti gbé “òfin tí ó ní ìdájọ́ òdodo àti ìbánilò lọ́gbọọgba nínú” kalẹ̀ fún “ire gbogbo ilẹ̀ àkóso náà.” Àlá wọn nípa ayé tí ó kún fún ìwà rere, tí kì í sì í ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni—ayé onídàájọ́ òdodo—ha ti ṣẹ bí?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ka Májẹ̀mú tí a fọwọ́ sí nínú ọkọ̀ Mayflower sí ọ̀kan nínú ìpìlẹ̀ ètò ìṣàkóso ilẹ̀ Amẹ́ríkà, àìsídàájọ́ òdodo jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà, àní bí ó ṣe wà káàkiri ayé. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa ọkùnrin kan tí ọlọ́pàá yìnbọn lù bí ó ti ń gbìyànjú láti sá lọ lẹ́yìn tí ó fipá jalè, tí ó sì yìnbọn lu ẹni tí ó ni ilé ìtajà náà. Ó pe àjọ ọlọ́pàá àti ìlú New York lẹ́jọ́, ó sì gba ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù dọ́là gẹ́gẹ́ bí owó gbà-máà-bínú.
Gbé àpẹẹrẹ mìíràn yẹ̀ wò. Nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òfin ń ṣèdánwò tí wọn yóò fi tóótun gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò ní Pasadena, California, àìsàn kọ lu ọ̀kan nínú wọn, ó sì dá kú. Kíá ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì tí wọ́n wà nítòsí rẹ̀ lo ìlànà ìmọ́kànsọjí fún un títí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera fi dé. Wọ́n lo 40 ìṣẹ́jú láti ṣaájò ọkùnrin náà. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n béèrè fún àkókò àfidípò kí wọ́n lè parí ìdánwò wọn, àwọn òṣìṣẹ́ ẹgbẹ́ àwọn agbẹjọ́rò kọ̀ jálẹ̀.
Ọ̀ràn ìfìyàjẹni fún ìwà ọ̀daràn pẹ̀lú kò gbẹ́yìn. Aṣèfọ́síwẹ́wẹ́ ètò ọrọ̀ ajé Ed Rubenstein sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ ìwà ọ̀daràn ni kì í yọrí sí ìfàṣẹ-ọba-múni. Ọ̀pọ̀ àwọn tí a fàṣẹ ọba mú ni a kì í mú lọ sí ilé ẹjọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tí a dá lẹ́bi ni a ń tú sílẹ̀. Ìyà tí ó yẹ kí a fi jẹ ọ̀daràn kan jẹ́ ọ̀ran bóyá, kì í ṣe ohun tí ó dájú.” Ní lílo àkójọ ìsọfúnni ti ìwà fọ́léfọ́lé, ó parí èrò pé, fọ́léfọ́lé kan “kì yóò lọ sẹ́wọ̀n fún èyí tí ó lé ní ìpín 98 nínú ọgọ́rùn-ún ìgbà tí a bá fi ẹ̀sùn kàn án.” Ìfìyàjẹni tí ó túbọ̀ ń lọ sílẹ̀ ń mú kí ìwà ọ̀daràn àti àwọn tí a ń hù ú sí pọ̀ sí i.—Oníwàásù 8:11.
Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ ni ó túbọ̀ ń lọ́rọ̀ sí i nígbà tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn òtòṣì sì ń dojú kọ àìsídàájọ́ òdodo ní ti ọrọ̀ ajé. Irú àìsídàájọ́ òdodo bẹ́ẹ̀ ń gbilẹ̀ nígbà tí àwọn ènìyàn kò bá ní àǹfààní láti mú ipò wọn sunwọ̀n sí i tàbí láti lè gbọ́ bùkátà ara wọn nítorí àwọ̀ wọn, ẹ̀yà tí wọ́n ti wá, èdè tí wọ́n ń sọ, jíjẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, tàbí nítorí ìsìn tí wọ́n ń ṣe. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ti sọ, fún àpẹẹrẹ, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́rin bílíọ̀nù kan ènìyàn tí ń gbé Gúúsù Éṣíà tí ẹ̀sìn Híńdù ti gbilẹ̀—ọ̀pọ̀ jù lọ wọn wà ní Íńdíà àti Nepal—ni a bí gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò ṣeé fọwọ́ kàn, tí wọ́n sì kú bẹ́ẹ̀.” Ìyọrísí rẹ̀ ni pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ni òṣì, ebi, àti àrùn pọ́n lójú. A kò fi ìdájọ́ òdodo bá wọn lò jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn láti ìgbà ọmọdé títí tí wọn fi lọ sínú sàréè.
Àìsídàájọ́ òdodo tí ó dà bí èyí tí ó kọjá agbára ẹ̀dá ènìyàn ńkọ́? Ronú nípa àwọn ọmọ ọwọ́ tí a bí ní alábùkù ara—tí wọ́n fọ́jú, tí wọ́n rán, tàbí tí wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara? Obìnrin kò ha ní rò pé a kò fi ìdájọ́ òdodo bá òun lò bí ó bá bí ọmọ rẹ̀ ní arọ tàbí tí ó bí i lókùú, nígbà tí àwọn obìnrin tí ń bẹ nítòsí rẹ̀ sì ń gbé ọmọ tiwọn tí ara wọn le koko mọ́ra?
Ó bani nínú jẹ́ pé, àìsídàájọ́ òdodo ń peléke sí i, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn àbájáde rẹ̀—ìjìyà kíkàmàmà àti àìsí àlàáfíà, ayọ̀, àti ìtẹ́lọ́rùn. Nítorí tí àìsídàájọ́ òdodo tí wọ́n ń rí tàbí tí ń ṣẹlẹ̀ sí wọn ń bí wọn nínú, ọ̀pọ̀ ti yíjú sí ìwà ipá, kìkì láti fi kún ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn. Ọ̀pọ̀ jù lọ ogun ti bẹ́ sílẹ̀ nítorí mímọ̀ pé àìsídàájọ́ òdodo ń bẹ.
Èé ṣe tí ènìyàn fi kùnà láti mú ayé onídàájọ́ òdodo wá? Irú ayé bẹ́ẹ̀ ha jẹ́ àlá lásán bí?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Corbis-Bettmann
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Fífọwọ́sí Májẹ̀mú Mayflower
[Credit Line]
Corbis-Bettmann