ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 21
  • Ṣé Ìdájọ́ Òdodo Máa Wà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ìdájọ́ Òdodo Máa Wà?
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí ló fà á tí kò sí ìdájọ́ òdodo?
  • Ṣé Ọlọ́run ò fẹ́ kí ìdájọ́ òdodo wà ni?
  • Ṣé Ọlọ́run máa mú kí ìdájọ́ òdodo wà?
  • Báwo ni nǹkan ṣe máa rí nínú ayé tuntun?
  • Ṣé o gba ìlérí Ọlọ́run gbọ́ pé ìdájọ́ òdodo máa wà láyé?
  • Ṣé a lè jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo wà ní báyìí?
  • Ohun Tó Yẹ Ká Ṣe Táwọn Èèyàn Bá Rẹ́ Wa Jẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • O Lè Fara Da Àìṣẹ̀tọ́!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Ìdájọ́ Òdodo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 21
Obìnrin kan tó ń wo òṣùwọ̀n ìdájọ́ òdodo, tí wọ́n gbé sí ibi tó ga.

Ṣé Ìdájọ́ Òdodo Máa Wà?

Kò sí ìdájọ́ òdodo mọ́ láwùjọ. Àpẹẹrẹ àwọn méjì tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n láìtọ́ rèé:

  • Ní January ọdún 2018, adájọ́ kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní kí wọ́n dá ọkùnrin kan tó ti wà lẹ́wọ̀n fún nǹkan bí ọdún méjìdínlógójì [38] sílẹ̀. Ohun tí wọ́n rí nínú àbùdá (DNA) rẹ̀ ni wọ́n fi mọ̀ pé kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.

  • Ní September ọdún 1994, wọ́n ju àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́ta kan láti ilẹ̀ Áfíríkà sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò fàyè gbà wọ́n láti wọṣẹ́ ológun. Ní September ọdún 2020, wọ́n ti lo ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] lẹ́wọ̀n bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tíì fi ẹ̀sùn èyíkéyìí kàn wọ́n, wọn ò sì tíì fara hàn nílé ẹjọ́.

Bí wọ́n bá ti hùwà àìdáa sí ẹ rí, ó lè ṣe ẹ́ bíi ti ọkùnrin kan nínú Bíbélì tó ń jẹ́ Jóòbù, tó sọ pé: “Mò ń kígbe ṣáá pé mo nílò ìrànlọ́wọ́, àmọ́ kò sí ìdájọ́ òdodo.” (Jóòbù 19:7) Ṣùgbọ́n, bó bá tiẹ̀ dà bíi pé kò lè sí ìdájọ́ òdodo, Ọlọ́run ṣèlérí nínú Bíbélì pé ìdájọ́ òdodo ṣì máa wà. Tó o bá sì ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì sílò, áá jẹ́ kó o lè fara da àìṣòdodo ní báyìí ná.

Kí ló fà á tí kò sí ìdájọ́ òdodo?

Ohun tó fà á tí kò fi sí ìdájọ́ òdodo ni pé àwọn èèyàn ò gbà kí Ọlọ́run máa tọ́ àwọn sọ́nà. Bíbélì fi hàn pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìdájọ́ òdodo ti ń wá. (Àìsáyà 51:4) Ọ̀rọ̀ Bíbélì tá a tú sí “ìdájọ́ òdodo” àti “òdodo” lédè Yorùbá jọra gan-an ni. (Sáàmù 33:5) Ìwà òdodo, ìwà títọ́ àti ìwà tó bójú mu ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run máa ń yọrí sí ìdájọ́ òdodo. Ṣùgbọ́n, ẹ̀ṣẹ̀ ló ń fa àìṣòdodo, èyí tó túmọ̀ sí títàpá sí ìlànà òdodo Ọlọ́run. Jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò:

  • Ìmọtara-ẹni-nìkan. Ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan àti ẹ̀ṣẹ̀ jọ ń rìn pọ̀ ni. (Jémíìsì 1:​14, 15) Kí ọwọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lè tẹ ohun tí wọ́n fẹ́, wọ́n máa ń rẹ́ àwọn míì jẹ kí wọ́n lè rí tọwọ́ wọn gbà. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run fẹ́ ká máa fi iré àwọn ẹlòmíì ṣáájú tiwa.​—1 Kọ́ríńtì 10:24.

  • Àìmọ̀kan. Àwọn míì lè má mọ̀ pé àwọn ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ, síbẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ni Ọlọ́run ka irú ìwà bẹ́ẹ̀ sí. (Róòmù 10:3) Kódà, àìmọ̀kan ló mú káwọn èèyàn hu ọ̀kan lára ìwà àìṣòdodo tó tíì burú jù lọ, ìyẹn ni pípa tí wọ́n pa Jésù Kristi.​—Ìṣe 3:​15, 17.

  • Ètò tí kò kẹ́sẹ járí. Ṣe ló yẹ kí ètò ìṣèlú, ètò ìṣòwò àti ètò ẹ̀sìn rí sí i pé kò sí ìrẹ́jẹ àti ojúsàájú láwùjọ. Ṣùgbọ́n, àwọn ètò yìí gan-an ló sábà máa ń fa àṣìṣe, ìwà ìbàjẹ́, ẹ̀tanú, ìwọra, ìṣẹ́ àti àìnísùúrù, èyí tó lè yọrí sí àìṣòdodo. Lára àwọn tó wà nídìí ètò yìí ní èrò tó dáa. Ṣùgbọ́n, ohun téèyàn bá ṣe láì tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ò lè kẹ́sẹ járí.​—Oníwàásù 8:9; Jeremáyà 10:23.

Ṣé Ọlọ́run ò fẹ́ kí ìdájọ́ òdodo wà ni?

Rárá o, Ọlọ́run kórìíra àìṣòdodo, ìwà àti ìṣesí àwọn tó ń fà á. (Òwe 6:​16-18) Ó mí sí wòlíì Àìsáyà láti kọ̀wé pé: “Èmi Jèhófà,a nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo; mo kórìíra olè jíjà àti àìṣòdodo.”​—Àìsáyà 61:8.

Ó hàn nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ pé ó fẹ́ kí ìdájọ́ òdodo wà láàárín àwọn èèyàn òun. Ó pàṣẹ fún àwọn tó jẹ́ onídàájọ́ láàárín wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọn ò sì gbọ́dọ̀ yí ìdájọ́ po. (Diutarónómì 16:​18-20) Ó dẹ́bi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ṣàìgbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí wọ́n sì ń kó àwọn aláìní àti àwọn ẹni rírẹlẹ̀ nífà, ó kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pátápátá torí pé wọn ò tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀.​—Àìsáyà 10:​1-3.

Ṣé Ọlọ́run máa mú kí ìdájọ́ òdodo wà?

Bẹ́ẹ̀ ni. Nípasẹ̀ Jésù Kristi, Ọlọ́run máa fòpin sí ẹ̀ṣẹ̀ tó ń fa àìṣòdodo, ó sì máa sọ àwọn èèyàn di pípé. (Jòhánù 1:29; Róòmù 6:23) Ó tún ti gbé Ìjọba kan kalẹ̀ tó máa mú ayé tuntun wá tó sì máa rí sí i pé ìdájọ́ òdodo wà fún gbogbo èèyàn. (Àìsáyà 32:1; 2 Pétérù 3:13) Kó o lè mọ̀ sí i nípa Ìjọba ọ̀run yìí, wo fídíò náà Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Báwo ni nǹkan ṣe máa rí nínú ayé tuntun?

Nígbà tí ìdájọ́ òdodo bá wà jákèjádò ayé, gbogbo èèyàn á máa gbé ní àlàáfíà àti ààbò. (Àìsáyà 32:16-18) Ẹ̀mí gbogbo èèyàn jọ Ọlọ́run lójú, torí náà kò ní hùwà ìrẹ́jẹ sí ẹnikẹ́ni. Kò ní sí ìbànújẹ́, ẹkún àti ìrora tí àìṣòdodo ń fà mọ́ láé. Bí ọjọ́ sì ti ń gorí ọjọ́, àròdùn tí àìṣòdodo máa ń dá sílẹ̀ ò ní sí mọ́. (Àìsáyà 65:17; Ìfihàn 21:3, 4) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ náà, “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?”

Ṣé o gba ìlérí Ọlọ́run gbọ́ pé ìdájọ́ òdodo máa wà láyé?

Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀rí tó dájú wà nínú Bíbélì pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àti ìtàn inú rẹ̀ ṣeé gbára lé, ohun tó sọ bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu, kò sì ta kora. Gbogbo èyí fi hàn pé o lè ní ìgbọ́kànlé nínú ìlérí Ọlọ́run. O lè ka àlàyé síwájú sí i nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí:

  • Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì? (fídíò)

  • “Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ti Ṣẹ”

  • “Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Máa Ń Ṣẹ Pátápátá”

  • “Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gba Bíbélì Gbọ́”

Ṣé a lè jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo wà ní báyìí?

Àwọn èèyàn rere tó gbé láyé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n má bàa rẹ́ wọn jẹ. Bí àpẹẹrẹ, wọn fi èrú gbọ́ ẹjọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kí wọ́n lè fi ikú dẹ́rù bà á. Dípò tí ì bá fi fara mọ́ ìwà ìrẹ́jẹ náà láìjanpata, ó fi ẹsẹ̀ òfin tó wà nígbà náà tọ̀ ọ́, ó sì pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sọ́dọ̀ Késárì.​—Ìṣe 25:8-12.

Ṣùgbọ́n, bó ti wù kí àwọn èèyàn sapá tó láti mú gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ kúrò nínú ayé yìí, pàbó ló máa já sí. (Oníwàásù 1:15) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ti rí i pé bí àwọn ṣe ní ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀ nínú ìlérí Ọlọ́run pé òun máa mú ayé tuntun wa ti mú káwọn borí ìdààmú, ọkàn wọn sì balẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń rẹ́ wọn jẹ.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.​—Sáàmù 83:18.

Bíbélì mú kí wọ́n borí ìwà ìrẹ́jẹ

  • Rafika.

    Rafika dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan tó sọ pé àwọn máa fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ, ṣùgbọ́n ó fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ nígbà tó rí bí wọ́n ṣe ń fi ìwà ipá kọ́ni. Lẹ́yìn yẹn, ó wá ní ìgbọ́kànlé nínú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo máa wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Wo fídíò tó ti sọ ìtàn rẹ̀.

  • Antoine.

    Antoine dàgbà sí ìlú Lẹ́bánónì lásìkò ogun abẹ́lé, ó ti ń gbìyànjú láti fi òpin sí ìwà ìrẹ́jẹ nípa híhùwà ipá. Ṣùgbọ́n ẹsẹ Bíbélì méjì mú kó ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Ka bí Bíbélì ṣe yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.

  • Jukka.

    Jukka jà láti fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ láwùjọ ṣùgbọ́n agbára rẹ̀ ò gbé e mọ́, torí pé àṣeyọrí tó ṣe ò tó nǹkan. Ní báyìí, ó ní ìtẹ́lọ́rùn bó ṣe ń sọ fáwọn èèyàn nípa ayé tuntun tó jẹ́ ìrètí kan ṣoṣo tó ṣeé gbára lé. Ka ìtàn rẹ̀.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ nípa ìdájọ́ òdodo

Oníwàásù 3:16: “Mo tún ti rí i lábẹ́ ọ̀run pé: Ìwà burúkú ti rọ́pò ìdájọ́ òdodo.”

Ìtumọ̀: Bíbélì gbà pé òótọ́ ní kò sí ìdájọ́ òdodo nínú ayé.

Jóòbù 34:12: “Torí ó dájú pé, Ọlọ́run kì í hùwà burúkú; Olódùmarè kì í sì í yí ìdájọ́ po.”

Ìtumọ̀: Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àìṣòdodo.

Diutarónómì 32:4, 5: “Àpáta náà, pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, torí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀. Ọlọ́run olóòótọ́, tí kì í ṣe ojúsàájú; olódodo àti adúróṣinṣin ni. Àwọn ló hùwà ìbàjẹ́. Wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀, àwọn ló kan àbùkù.”

Ìtumọ̀: Àwọn èèyàn tó ń dẹ́ṣẹ̀ tí wọn ò sì tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ló ń fa àìṣòdodo, kì í ṣe Ọlọ́run.

Àìsáyà 32:1: “Ọba kan máa jẹ fún òdodo, àwọn ìjòyè sì máa ṣàkóso fún ìdájọ́ òdodo.”

Ìtumọ̀: Òdodo àti ìdájọ́ òdodo máa wà nínú Ìjọba Ọlọ́run.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́