ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 September ojú ìwé 8-13
  • Ohun Tó Yẹ Ká Ṣe Táwọn Èèyàn Bá Rẹ́ Wa Jẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Yẹ Ká Ṣe Táwọn Èèyàn Bá Rẹ́ Wa Jẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • JÈHÓFÀ ÀTI JÉSÙ KÓRÌÍRA ÌRẸ́JẸ
  • OHUN TÍ JÉSÙ ṢE NÍGBÀ TÓ RÍ ÀWỌN TÍ WỌ́N RẸ́ JẸ
  • FARA WÉ JÉSÙ TÁWỌN ÈÈYÀN BÁ RẸ́ Ẹ JẸ
  • KÍ LÓ YẸ KÁ ṢE BÁYÌÍ?
  • Bó O Ṣe Lè Fara Dà Á Tí Wọ́n Bá Rẹ́ Ẹ Jẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ṣé Ìdájọ́ Òdodo Máa Wà?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • O Lè Fara Da Àìṣẹ̀tọ́!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 September ojú ìwé 8-13

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 37

ORIN 114 “Ẹ Máa Ní Sùúrù”

Ohun Tó Yẹ Ká Ṣe Táwọn Èèyàn Bá Rẹ́ Wa Jẹ

“Ó ń retí ìdájọ́ òdodo, àmọ́ wò ó! ìrẹ́jẹ ló wà.”—ÀÌSÁ. 5:7.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa rí ohun tí Jésù ṣe nígbà tó rí àwọn èèyàn tí wọ́n rẹ́ jẹ àti bá a ṣe lè fara wé e.

1-2. Kí la máa ń ṣe lónìí tí wọ́n bá rẹ́ àwa tàbí àwọn míì jẹ, àwọn ìbéèrè wo la sì lè bi ara wa?

ÌRẸ́JẸ pọ̀ láyé lónìí. Wọ́n máa ń rẹ́ àwọn kan jẹ torí pé tálákà ni wọ́n, wọ́n máa ń rẹ́ àwọn míì jẹ torí pé ọkùnrin tàbí obìnrin ni wọ́n, wọ́n sì máa ń rẹ́ àwọn kan jẹ nítorí ìlú tí wọ́n ti wá tàbí ẹ̀yà wọn. Ìdí tí ọ̀pọ̀ fi ń jìyà ni pé àwọn olówó tó ń ṣòwò mọ tara wọn nìkan, àwọn olórí ìjọba sì máa ń hùwà ìbàjẹ́. Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé kò sẹ́nì tí wọn ò rẹ́ jẹ rí.

2 Abájọ tínú ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi dùn lónìí nítorí ìwà ìrẹ́jẹ. Gbogbo wa ló wù pé ká máa gbé níbi tọ́kàn wa ti máa balẹ̀, tí ò sì ní síwà ìrẹ́jẹ. Àwọn kan máa ń dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tó ń wá bí wọ́n ṣe máa yanjú ìṣòro àwọn èèyàn. Wọ́n máa ń wọ́de kí wọ́n lè fẹ̀hónú hàn síjọba, wọ́n sì máa ń dìbò fáwọn olóṣèlú tó ṣèlérí pé àwọn máa yanjú ìṣòro wọn. Àmọ́, àwa Kristẹni ti kẹ́kọ̀ọ́ pé a “kì í ṣe apá kan ayé” a sì gbà pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú ìwà ìrẹ́jẹ kúrò pátápátá. (Jòh. 17:16) Síbẹ̀ inú wa kì í dùn, kódà inú máa ń bí wa nígbà míì tá a bá rí àwọn tí wọ́n rẹ́ jẹ. Ìyẹn lè mú ká bi ara wa pé: ‘Kí ni kí n ṣe? Kí ni mo lè ṣe káwọn èèyàn má bàa rẹ́ àwọn ẹlòmíì jẹ mọ́?’ Ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo bí ìwà ìrẹ́jẹ ṣe máa ń rí lára Jèhófà àti Jésù.

JÈHÓFÀ ÀTI JÉSÙ KÓRÌÍRA ÌRẸ́JẸ

3. Kí nìdí tínú wa kì í fi í dùn tí wọ́n bá rẹ́ àwa tàbí ẹlòmíì jẹ? (Àìsáyà 5:7)

3 Bíbélì ṣàlàyé ìdí tínú wa kì í fi í dùn tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ. Bíbélì sọ pé Jèhófà dá wa ní àwòrán ara ẹ̀, ó sì “nífẹ̀ẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.” (Sm. 33:5; Jẹ́n. 1:26) Jèhófà kì í rẹ́ àwọn èèyàn jẹ, kò sì fẹ́ káwa èèyàn máa rẹ́ ara wa jẹ. (Diu. 32:3, 4; Míkà 6:8; Sek. 7:9) Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé wòlíì Àìsáyà, Jèhófà gbọ́ “igbe ìdààmú” ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì táwọn èèyàn rẹ́ jẹ. (Ka Àìsáyà 5:7.) Torí náà, Jèhófà fìyà jẹ àwọn tó ń rú Òfin ẹ̀ léraléra, tí wọ́n sì ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ.—Àìsá. 5:5, 13.

4. Báwo ló ṣe rí lára Jésù nígbà tí wọ́n ṣe ohun tí ò dáa sí ọkùnrin kan? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 Jésù nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, ó sì kórìíra ìrẹ́jẹ bíi Jèhófà. Nígbà tí Jésù wà láyé, ìgbà kan wà tó rí ọkùnrin kan tí ọwọ́ ẹ̀ rọ. Àánú ọkùnrin náà ṣe Jésù, ó sì wò ó sàn. Àmọ́ nígbà táwọn olórí ẹ̀sìn rí i pé ó ti wo ọkùnrin náà sàn, inú bí wọn gan-an. Dípò kínú wọn máa dùn pé Jésù wo ọkùnrin náà sàn, ṣe ni wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó rú òfin Sábáàtì. Báwo ni nǹkan tí wọ́n ṣe yìí ṣe rí lára Jésù? “Ẹ̀dùn ọkàn bá a gidigidi torí pé ọkàn wọn ti yigbì.”—Máàkù 3:1-6.

Jésù wà nínú sínágọ́gù, ó ń bá àwọn olórí ẹ̀sìn Júù sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin tọ́wọ́ ẹ̀ rọ tó fẹ́ wò sàn. Àmọ́ ṣe làwọn olórí ẹ̀sìn náà ń fojú burúkú wo Jésù.

Àwọn olórí ẹ̀sìn Júù ò rí tàwọn èèyàn rò, àmọ́ Jésù máa ń ṣàánú àwọn èèyàn, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 4)


5. Kí ló yẹ ká máa rántí tínú bá ń bí wa torí pé wọ́n rẹ́ wa jẹ tàbí rẹ́ àwọn ẹlòmíì jẹ?

5 Inú Jèhófà àti Jésù kì í dùn tí wọ́n bá rẹ́ àwọn èèyàn jẹ, torí náà kò burú tó bá ń ṣe àwa náà bẹ́ẹ̀. (Wo Éfé. 4:26 àti àlàyé ọ̀rọ̀ “Be wrathful” nínú nwtsty-E) Síbẹ̀, ó yẹ ká máa rántí pé kò sí bọ́rọ̀ náà ṣe lè ká wa lára tó, a ò lè mú ìrẹ́jẹ kúrò. Kódà, tá a bá bínú jù, ó lè fa àìsàn sí wa lára tàbí kí ìdààmú bá wa. (Sm. 37:1, 8; Jém. 1:20) Torí náà, kí ló yẹ ká ṣe tí wọ́n bá rẹ́ àwa tàbí ẹlòmíì jẹ? Ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù.

OHUN TÍ JÉSÙ ṢE NÍGBÀ TÓ RÍ ÀWỌN TÍ WỌ́N RẸ́ JẸ

6. Báwo ni wọ́n ṣe rẹ́ àwọn èèyàn jẹ nígbà ayé Jésù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

6 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó rí ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n rẹ́ jẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó rí bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣe ń fayé ni àwọn èèyàn lára. (Mát. 23:2-4) Ó tún rí bí ìjọba Róòmù ṣe ń fojú àwọn èèyàn gbolẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló fẹ́ gbòmìnira lọ́wọ́ ìjọba Róòmù. Kódà, àwọn Júù kan tó jẹ́ alátakò dá ẹgbẹ́ sílẹ̀, wọ́n sì máa ń jà kí wọ́n lè gbòmìnira lọ́wọ́ ìjọba Róòmù. Síbẹ̀, Jésù ò dara pọ̀ mọ́ wọn, kò sì dá ẹgbẹ́ èyíkéyìí sílẹ̀. Kódà, nígbà tí Jésù gbọ́ pé wọ́n fẹ́ fi òun jọba, ó kúrò níbẹ̀.—Jòh. 6:15.

Jésù ń rìn lórí òkè. Àwọn èèyàn rẹpẹtẹ wà nísàlẹ̀ òkè náà.

Nígbà táwọn èèyàn fẹ́ fi Jésù jọba, ó kúrò lọ́dọ̀ wọn (Wo ìpínrọ̀ 6)


7-8. Kí nìdí tí Jésù ò fi mú ìrẹ́jẹ kúrò nígbà tó wà láyé? (Jòhánù 18:36)

7 Nígbà tí Jésù wà láyé, kò dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kankan kó lè mú ìrẹ́jẹ tó ń ṣẹlẹ̀ kúrò. Kí nìdí tí ò fi ṣe bẹ́ẹ̀? Torí ó mọ̀ pé àwa èèyàn ò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ara wa, a ò sì lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Sm. 146:3; Jer. 10:23) Yàtọ̀ síyẹn, àwa èèyàn ò lè mú ohun tó ń fa ìrẹ́jẹ kúrò. Sátánì Èṣù àti àìpé wa ló sì ń fa ìrẹ́jẹ. Sátánì ló ń darí ayé, ẹni burúkú ni, ó sì máa ń mú káwọn èèyàn rẹ́ àwọn míì jẹ. (Jòh. 8:44; Éfé. 2:2) Bákan náà, torí pé aláìpé ni wá, kì í rọrùn fún wa láti ṣe ohun tó tọ́ ní gbogbo ìgbà.—Oníw. 7:20.

8 Jésù mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú ohun tó ń fa ìrẹ́jẹ kúrò. Ìdí nìyẹn tó fi lo gbogbo okun àti àkókò ẹ̀ láti “wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 8:1) Ó mú kó dá “àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ” lójú pé ìrẹ́jẹ àti ìwà ìbàjẹ́ máa tó dópin. (Wo Mát. 5:6 àti àlàyé ẹsẹ Bíbélì yìí nínú nwtsty-E; Lúùkù 18:7, 8) Àwọn ẹgbẹ́ tó ń wá bí wọ́n ṣe máa yanjú ìṣòro àwa èèyàn ò lè ṣe é torí ó kọjá agbára wọn. Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè ṣe é torí kì í “ṣe apá kan ayé yìí.”—Ka Jòhánù 18:36.

FARA WÉ JÉSÙ TÁWỌN ÈÈYÀN BÁ RẸ́ Ẹ JẸ

9. Kí ló mú kó o gbà pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú ìrẹ́jẹ kúrò pátápátá?

9 Ìwà ìrẹ́jẹ pọ̀ gan-an lóde òní ju ti ìgbà ayé Jésù lọ. Sátánì àtàwọn èèyàn aláìpé tó ń hùwà bíi tiẹ̀ ló ṣì ń fa ìrẹ́jẹ láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” yìí. (2 Tím. 3:1-5, 13; Ìfi. 12:12) Bíi Jésù, a mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú ohun tó ń fa ìrẹ́jẹ kúrò pátápátá. Ìdí nìyẹn tí a kì í fi dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń wọ́de, àwọn tó ń fi ẹ̀hónú hàn àtàwọn ẹgbẹ́ tó ń wá bí wọ́n ṣe máa mú ìrẹ́jẹ kúrò. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Stacy.a Kó tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó máa ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ tó ń wá bí wọ́n ṣe máa mú ìrẹ́jẹ kúrò. Àmọ́ nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì nípa ohun tó ń ṣe. Ó sọ pé: “Tá a bá ń wọ́de, mo máa ń bi ara mi pé ṣé ohun tí mò ń ṣe yìí lè yanjú ìṣòro yìí ṣá? Àmọ́ mo ti wá mọ̀ báyìí pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè ṣe é. Ó dá mi lójú pé Jèhófà máa gbèjà gbogbo àwọn tí wọ́n rẹ́ jẹ, ohun témi ò sì lágbára láti ṣe nìyẹn.”—Sm. 72:1, 4.

10. Kí ni Jésù sọ nínú Mátíù 5:43-48 tó jẹ́ ká mọ̀ pé kò yẹ ká dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tó ń wá bí wọ́n ṣe máa yanjú ìṣòro àwọn èèyàn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

10 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ tó ń ta ko ìjọba. Inú máa ń bí wọn, wọ́n máa ń rúfin, kódà wọ́n máa ń ṣe àwọn èèyàn léṣe. Ìyẹn sì yàtọ̀ pátápátá sóhun tí Jésù kọ́ wa. (Éfé. 4:31) Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Jeffrey sọ pé: “Mo mọ̀ pé táwọn èèyàn bá ń wọ́de, nǹkan lè yí pa dà lójijì kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ba nǹkan jẹ́, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í jalè, kódà wọ́n lè ṣe àwọn èèyàn léṣe.” Àmọ́, ohun tí Jésù kọ́ wa yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Ó ní ká máa fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn títí kan àwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa àtàwọn tó ń ta kò wá. (Ka Mátíù 5:43-48.) Torí náà, àwa Kristẹni kì í ṣe ohun tó yàtọ̀ sóhun tí Jésù sọ fún wa, a sì máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fara wé e.

Arábìnrin kan rọra ń kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn tínú ń bí, tí wọ́n sì ń wọ́de.

A gbọ́dọ̀ nígboyà tá ò bá fẹ́ dá sọ́rọ̀ òṣèlú, ká má sì ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn tó ń wá bí wọ́n ṣe máa mú ìrẹ́jẹ kúrò (Wo ìpínrọ̀ 10)


11. Kí ló lè mú kó máa ṣe wá bíi pé ká dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tó ń wá bí wọ́n ṣe máa yanjú ìṣòro àwa èèyàn?

11 Lóòótọ́, a mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú gbogbo ìrẹ́jẹ kúrò, àmọ́ ó lè ṣòro fún wa nígbà míì láti fara wé Jésù tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ. Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Janiya, wọ́n kórìíra ẹ̀ nítorí àwọ̀ ẹ̀. Ó sọ pé: “Inú bí mi gan-an. Ó dùn mí débi pé mo fẹ́ gbẹ̀san ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Mo wá ronú pé kí n dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tó ń ta ko àwọn tó ń hùwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, torí mo rò pé ìyẹn máa jẹ́ kí n fi hàn pé inú ń bí mi.” Nígbà tó yá, Janiya rí i pé ó yẹ kóun ṣàtúnṣe. Ó tún sọ pé: “Mo ti ń jẹ́ káwọn èèyàn kó sí mi lórí. Wọ́n ti ń jẹ́ kí n máa rò pé àwọn èèyàn lè yanjú ìṣòro wa dípò Jèhófà. Bí mo ṣe pinnu pé mi ò ní dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ yẹn mọ́ nìyẹn.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú máa ń bí wa tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ, ó yẹ ká ṣọ́ra ká má lọ bẹ̀rẹ̀ sí í dá sọ́rọ̀ òṣèlú tàbí ká dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tó ń wá bí wọ́n ṣe máa yanjú ìṣòro àwa èèyàn.—Jòh. 15:19.

12. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣọ́ ohun tá à ń kà, tá a sì ń gbọ́?

12 Kí ni ò ní jẹ́ ká bínú jù tí wọ́n bá rẹ́ àwa tàbí àwọn míì jẹ? Ohun tó ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ ni pé wọ́n máa ń ṣọ́ ohun tí wọ́n ń kà, ìròyìn tí wọ́n ń gbọ́ àtohun tí wọ́n ń wò. Ìdí sì ni pé àwọn kan máa ń kọ àwọn ìròyìn kan sórí ìkànnì àjọlò kínú lè bí àwọn èèyàn, kí wọ́n sì máa ta ko ìjọba. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn kì í sọ bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an. Tí ìròyìn wọn bá tiẹ̀ jóòótọ́, ṣé a lè yanjú ìṣòro náà tá a bá lọ ń wá fìn-ín ìdí kókò nípa ọ̀rọ̀ náà? Tá a bá ń lo àkókò tó pọ̀ nídìí irú ìròyìn bẹ́ẹ̀, ó lè mú kí nǹkan sú wa tàbí ká ní ẹ̀dùn ọkàn. (Òwe 24:10) Èyí tó burú jù níbẹ̀ ni pé ó lè mú ká gbọ́kàn kúrò nínú Ìjọba Ọlọ́run tó máa mú gbogbo ìrẹ́jẹ kúrò.

13. Tá a bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, báwo ló ṣe máa jẹ́ ká mọ ohun tá a máa ṣe tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ?

13 Tá a bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, tá a sì ń ronú nípa ohun tá a kà, àá mọ ohun tó yẹ ká ṣe tí wọ́n bá rẹ́ àwa tàbí àwọn míì jẹ. Inú máa ń bí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Alia tó bá rí àwọn tí wọ́n rẹ́ jẹ ládùúgbò ẹ̀. Ó jọ pé àwọn tó ń hùwà burúkú náà máa ń lọ láìjìyà. Ó ní: “Mo bi ara mi pé ṣé mo gbà lóòótọ́ pé Jèhófà nìkan ló lè yanjú àwọn ìṣòro yìí? Ni mo bá ka Jóòbù 34:22-29. Àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn rán mi létí pé Jèhófà ń rí gbogbo àwọn tó ń hùwà burúkú. Òun nìkan lonídàájọ́ òdodo, òun nìkan ló sì lè yanjú gbogbo ìṣòro yìí.” Àmọ́ kí Ìjọba Ọlọ́run tó dé, àá ṣì máa fara da ìrẹ́jẹ. Torí náà, kí la lè ṣe?

KÍ LÓ YẸ KÁ ṢE BÁYÌÍ?

14. Kí ni ò ní jẹ́ ká máa rẹ́ àwọn èèyàn jẹ? (Kólósè 3:10, 11)

14 A ò lè pinnu báwọn èèyàn ṣe máa hùwà sáwọn míì, àmọ́ a lè pinnu pé àá máa hùwà tó dáa sí gbogbo èèyàn. Bá a ṣe sọ níṣàájú, tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, Jésù là ń fara wé yẹn. Ìfẹ́ á jẹ́ ká máa hùwà tó dáa sí gbogbo èèyàn títí kan àwọn tó ń rẹ́ àwọn míì jẹ. (Mát. 7:12; Róòmù 12:17) Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ń hùwà tó dáa sáwọn èèyàn, tá ò sì ṣojúsàájú.—Ka Kólósè 3:10, 11.

15. Kí ni ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́ àwọn èèyàn máa ń jẹ́ kí wọ́n ṣe?

15 Ohun tó dáa jù tá a lè ṣe fáwọn èèyàn ni pé ká kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe táwọn èèyàn bá rẹ́ wọn jẹ. Ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé “ìmọ̀ Jèhófà” máa ń yí àwọn èèyàn pa dà. Kódà, àwọn tó máa ń bínú gan-an àtàwọn oníwà ipá ti yí pa dà di èèyàn jẹ́jẹ́, wọ́n sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. (Àìsá. 11:6, 7, 9) Kí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jemal tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan tó ń dìtẹ̀ síjọba torí ó gbà pé ìjọba yẹn ń ni àwọn èèyàn lára. Nígbà tó yá, ó sọ pé: “Ẹ ò lè fipá yí àwọn èèyàn pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kankan ò fipá mú mi pé kí n yí pa dà, ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo kọ́ ló yí ìwà mi pa dà.” Ohun tí Jemal kọ́ ló jẹ́ kó pinnu pé òun ò ní jà mọ́. Bí àwọn tí Bíbélì ń yí ìgbésí ayé wọn pa dà ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ làwọn tó ń rẹ́ èèyàn jẹ á máa dín kù.

16. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn?

16 Bíi Jésù, à ń wàásù fáwọn èèyàn pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú ìrẹ́jẹ kúrò pátápátá. Ohun tí Bíbélì sọ yìí máa ń fi àwọn tí wọ́n rẹ́ jẹ lọ́kàn balẹ̀. (Jer. 29:11) Stacy tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo kọ́ ló jẹ́ kí n lè fara dà á nígbà tí wọ́n rẹ́ èmi àtàwọn ẹlòmíì jẹ. Ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí ni Jèhófà fi tù mí nínú.” A gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ ká tó lè sọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn pé ìrẹ́jẹ máa tó dópin. Tó o bá túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìrẹ́jẹ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí tó sì dá ẹ lójú, á rọrùn fún ẹ láti sọ ọ́ fáwọn míì tí wọ́n bá dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀ níléèwé tàbí níbiiṣẹ́.b

17. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ báyìí ká lè fara da ìrẹ́jẹ?

17 Tí Sátánì bá ṣì jẹ́ “alákòóso ayé yìí,” ìrẹ́jẹ ò lè dópin. Àmọ́ ọkàn wa balẹ̀ torí Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa ràn wá lọ́wọ́ kó tó dìgbà tó máa ‘lé Sátánì jáde.’ (Jòh. 12:31) Bí àpẹẹrẹ nínú Bíbélì, Jèhófà jẹ́ ká mọ ìdí táwọn èèyàn fi ń hùwà ìrẹ́jẹ. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́, ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé inú òun ò dùn sí ìyà tó ń jẹ wá torí ìwà burúkú táwọn èèyàn ń hù. (Sm. 34:17-19) Nípasẹ̀ Jésù, Jèhófà jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe táwọn èèyàn bá rẹ́ wa jẹ, ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú gbogbo ìrẹ́jẹ kúrò pátápátá. (2 Pét. 3:13) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ká sì máa retí ìgbà tí “ìdájọ́ tí ó tọ́ àti òdodo” máa gbilẹ̀ láyé.—Àìsá. 9:7.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí nìdí tínú wa kì í fi í dùn tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ tàbí rẹ́ àwọn ẹlòmíì jẹ?

  • Kí nìdí tá ò kì í dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ tó ń wá bí wọ́n ṣe máa fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ?

  • Kí ló yẹ ká ṣe táwọn èèyàn bá rẹ́ wa jẹ?

ORIN 158 “Kò Ní Pẹ́ Rárá!”

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

b Wo Àfikún A, kókó 24-27 nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn.

[Àwòrán ojú ìwé 9]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́