O Lè Fara Da Àìṣẹ̀tọ́!
ǸJẸ́ a rí ẹnì kan nínú wa tí wọn ò tíì fi ẹ̀tọ́ ẹ̀ dù rí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè má fi bẹ́ẹ̀ mọ àwọn àìṣẹ̀tọ́ kan lára tàbí kó jẹ́ pé ṣe ni a kàn ń finú rò ó, síbẹ̀ ó máa ń wáyé ní ti gidi.
Kò sígbà tí àìṣẹ̀tọ́ wáyé tí kì í wọ̀ wá lákínyẹmí ara, kódà ó lè nípa tí ò dáa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó tiẹ̀ lè ṣe wá bíi pé ká tètè wá nǹkan ṣe sí àìṣẹ̀tọ́ náà. Kí nìdí? Ìdí kan ni pé Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, “ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀,” ti dá wa lọ́nà tá a ó fi máa kórìíra àìṣẹ̀tọ́. (Diutarónómì 32:4; Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Síbẹ̀, a lè bá ara wa nípò kan tá a ti máa rí i pé ẹnì kan rẹ́ wa jẹ. Ọlọgbọ́n ọkùnrin kan sọ nígbà kan rí pé: “Èmi alára sì padà, kí n lè rí gbogbo ìwà ìninilára tí a ń hù lábẹ́ oòrùn, sì wò ó! omijé àwọn tí a ń ni lára, ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú; ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára sì ni agbára wà, tí ó fi jẹ́ pé wọn kò ní olùtùnú.” (Oníwàásù 4:1) Bọ́rọ̀ ṣe wá rí yìí, báwo la ṣe lè máa fara da àìṣẹ̀tọ́?
Kí Tiẹ̀ Ni Àìṣẹ̀tọ́?
Àìṣẹ̀tọ́ ni kí wọ́n gbé ẹ̀tọ́ ẹni fún ẹlòmíì tàbí kí wọ́n rẹ́ni jẹ. Kí ló yẹ káwọn èèyàn máa fi pinnu ohun tó bá ẹ̀tọ́ mu? Láìsí àní-àní, Ẹlẹ́dàá wa tó jẹ́ olódodo tí kì í sì í yí padà nìkan ló ní àṣẹ láti fi ìlànà lélẹ̀ nípa ẹ̀tọ́ àti àìṣẹ̀tọ́. Nípa báyìí, rírìn nínú “àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ ìyè” túmọ̀ sí pé kéèyàn má ṣe lọ́wọ́ nínú “àìṣèdájọ́ òdodo.” (Ísíkíẹ́lì 33:15) Ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé nígbà tí Jèhófà dá ọkùnrin àkọ́kọ́, ó dá ẹ̀rí ọkàn mọ́ ọn, ìyẹn ohùn inú lọ́hùn-ún tó lè ràn án lọ́wọ́ láti fìyàtọ̀ sáàárín rere àti búburú. (Róòmù 2:14, 15) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ti jẹ́ ká mọ̀ nípa ẹ̀tọ́ àti àìṣẹ̀tọ́ nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Bá a bá róye pé wọ́n ti fẹ̀tọ́ wa dù wá tàbí pé wọ́n ti rẹ́ wa jẹ ńkọ́? Ó máa dáa ká yẹ ọ̀ràn náà wò láìpọ̀n sọ́nà kan ká bàa lè mọ̀ bóyá lóòótọ́ lọ̀rọ̀ rí bá a ṣe rò. Bí àpẹẹrẹ, ìwọ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jónà, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Hébérù. Jèhófà pàṣẹ fún un pé kó lọ kìlọ̀ fáwọn ará Nínéfè nípa ewu tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lé wọn lórí. Dípò tí Jónà ì bá fi ṣe ohun tí Ọlọ́run ní kó ṣe, ńṣe ló fẹsẹ̀ fẹ. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó lọ sí Nínéfè, ó sì kìlọ̀ fún wọn pé gudugbẹ̀ kan máa tó já. Nígbà táwọn èèyàn náà wá ronú pìwà dà, Jèhófà pinnu láti dá ìlú náà sí tòun tàwọn tó ń gbébẹ̀. Báwo lèyí ṣe rí lára Jónà? “Kò dùn mọ́ Jónà nínú rárá, inú rẹ̀ sì ru fún ìbínú.” (Jónà 4:1) Lójú tiẹ̀, ńṣe ni Jèhófà yí ìdájọ́ po.
Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, Jèhófà ò lẹ́bi kankan nínú ọ̀ràn yìí nítorí pé arínúróde ni, ó sì tún jẹ́ “olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.” (Sáàmù 33:5) Ohun tó kàn yẹ kí Jónà mọ̀ ni pé Jèhófà kì í ṣègbè tó bá ń dájọ́, ohun tí Jèhófà sì ṣe gan-an nìyẹn. Bó bá ṣe àwa náà bíi pé wọ́n ti fi ẹ̀tọ́ wa dù wá, a lè bi ara wa pé, ‘Àbí ọ̀tọ̀ lojú tí Jèhófà máa fi wo ọ̀ràn yìí?’
Ohun Tó O Lè Ṣe Nípa Àìṣẹ̀tọ́
Bíbélì mẹ́nu ba ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n fi ẹ̀tọ́ wọn dù tàbí tí wọ́n rẹ́ jẹ. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ nípa ṣíṣe àyẹ̀wò bí wọ́n ṣe kojú ìṣòro náà. Ṣó o rántí Jósẹ́fù táwọn òjòwú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tà lẹ́rú fáwọn ará Íjíbítì. Nígbà tó dé Íjíbítì, aya ọ̀gá rẹ̀ ní kó bá òun ṣèṣekúṣe, ìgbà tó sì lóun ò gbà, aya ọ̀gá rẹ̀ purọ́ mọ́ ọn pé ó fẹ́ bá òun ṣe. Ká tó wí ká tó fọ̀, Jósẹ́fù ti bára rẹ̀ látìmọ́lé. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣì lágbára gan-an. Kò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run yingin bí wọ́n tilẹ̀ rẹ́ ẹ jẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbà kí ìyẹn dín ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú Jèhófà kù.—Jẹ́nẹ́sísì 37:18-28; 39:4-20; Sáàmù 105:17-19.
Ẹlòmíì tí wọ́n tún rẹ́ jẹ ni Nábótì. Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ̀, ṣe ni Jésíbẹ́lì aya Áhábù ọba Ísírẹ́lì fi irọ́ bo òtítọ́ mọ́lẹ̀. Ilẹ̀ kan tó wà nítòsí ààfin tó jẹ́ ogún tó kan Nábótì ni ọba lóun fẹ́. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé èèwọ̀ ni ní Ísírẹ́lì pé kí ẹnikẹ́ni ta ogún rẹ̀, Nábótì kọ̀ láti ta ilẹ̀ náà fún ọba yìí. (Léfítíkù 25:23) Nítorí ìwà ìkà tó wà lọ́kàn ìyàwó Áhábù, ó kó àwọn ẹlẹ́rìí èké jọ, wọ́n sì fẹ̀sùn kan Nábótì pé ó ń bú Ọlọ́run àti ọba. Àbájáde rẹ̀ ni pé, wọ́n pa Nábótì àtàwọn ọmọ rẹ̀. Fọkàn ro bí ọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣe máa rí lára Nábótì báwọn èèyàn ṣe ń bẹ̀rẹ̀ he òkúta tí wọ́n máa fi pa á!—1 Àwọn Ọba 21:1-14; 2 Àwọn Ọba 9:26.
Síbẹ̀, àwọn àpẹẹrẹ tá a mẹ́nu kàn yìí ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìrẹ́jẹ tó wáyé nínú ọ̀rọ̀ Kristi Jésù. Ẹ̀rí èké ni wọ́n kó jọ láti fi bá a ṣẹjọ́ tí wọ́n sì dájọ́ ikú fún un. Ará Róòmù tó jẹ́ gómìnà tó wà lórí àga ìdájọ́ ò nígboyà láti ṣèdájọ́ òdodo. (Jòhánù 18:38-40) Ẹ ò rí i pé bá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àìṣẹ̀tọ́ tó tíì burú jù lọ láyé yìí, Kristi Jésù ni Sátánì ṣe é sí!
Ǹjẹ́ àwọn àpẹẹrẹ tá a mẹ́nu bà wọ̀nyí fi hàn pé Jèhófà ò ka fífi táwọn èèyàn ń fi ẹ̀tọ́ ẹni duni tí wọ́n sì ń rẹ́ni jẹ sí? Ó tì o! Ojú tí ẹ̀dá fi ń wo nǹkan kọ́ ni Jèhófà fi wo àwọn àpẹẹrẹ tá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé yẹ̀ wò tán yìí. (Aísáyà 55:8, 9) Títà tí wọ́n ta Jósẹ́fù lẹ́rú lọ́jọ́sí ló mú kó lè gba ìdílé rẹ̀ là. Òun ló di alábòójútó oúnjẹ nílẹ̀ Íjíbítì kí ìyàn ńlá tó febi pa ìdílé rẹ̀ tó mú. Rò ó wò ná, ká ní Jèhófà ò fàyè gba àìṣẹ̀tọ́ yẹn ni, Jósẹ́fù ì bá má dèrò ẹ̀wọ̀n. Ọgbà ẹ̀wọ̀n níbẹ̀ ló ti sọ ìtumọ̀ àlá táwọn ẹlẹ́wọ̀n bíi tiẹ̀ méjì lá. Nígbà tó yá, ọ̀kan nínú wọn wá sọ fún Fáráò nípa Jósẹ́fù, kò sì pẹ́ tí Jósẹ́fù fi di alábòójútó oúnjẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 40:1; 41:9-14; 45:4-8.
Nábótì wá ńkọ́ o? Tún gbìyànjú láti wo ọ̀ràn náà bí Jehófà ṣe wò ó. Òótọ́ ni pé Nábótì kú, àmọ́ nígbà tí òkú rẹ̀ tiẹ̀ ṣì wà nílẹ̀ẹ́lẹ̀ pàápàá, bí ẹni pé kò kú ni lójú Jèhófà, ẹni tó lè jí òkú dìde. (1 Àwọn Ọba 21:19; Lúùkù 20:37, 38) Kìkì pé Nábótì kàn ní láti dúró dìgbà tí Jèhófà máa jí i dìde ni, ó ṣe tán, bí ìgbà téèyàn kàn pajú pẹ́ ló máa rí fún Nábótì, torí pé òkú ò mọ nǹkan kan. (Oníwàásù 9:5) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà gbẹ̀san Nábótì lára Áhábù àtàwọn ìdílé rẹ̀.—2 Àwọn Ọba 9:21, 24, 26, 35, 36; 10:1-11; Jòhánù 5:28, 29.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kú, síbẹ̀, Ọlọ́run jí i dìde, ó sì gbé e sípò tó ga “fíofío ré kọjá gbogbo ìjọba àti ọlá àṣẹ àti agbára àti ipò olúwa àti gbogbo orúkọ tí a ń dá.” (Éfésù 1:20, 21) Lóòótọ́ ni Sátánì mú kí wọ́n rẹ́ Kristi Jésù jẹ, àmọ́ ìyẹn ò lè dá Jèhófà dúró láti san Ọmọ rẹ̀ lẹ́san rere. Ó dá Jésù lójú gbangba pé bí Jèhófà bá fẹ́, kò ná an ní ohunkóhun láti jẹ́ kí wọ́n yí ìdájọ́ èké tí wọ́n ṣe yẹn padà. Ṣùgbọ́n Kristi fúnra rẹ̀ mọ̀ pé Jèhófà ní àkókò kan pàtó tó máa mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ ṣẹ tó sì máa fòpin sí gbogbo ìrẹ́jẹ.
Òótọ́ ni pé Sátánì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ máa ń fi ẹ̀tọ́ àwọn olódodo dù wọ́n, àmọ́ Jèhófà máa ń san ẹ̀tọ́ wọn padà fún wọn. Ó ṣe tán, ó máa tó fòpin sí gbogbo ìrẹ́jẹ títí láé fáàbàdà. Nítorí náà, bí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ, ńṣe ni ká ní sùúrù dìgbà tí Ọlọ́run máa fòpin sí i.—Diutarónómì 25:16; Róòmù 12:17-19.
Kí Nìdí Tí Jèhófà Fi Lè Gba Àìṣẹ̀tọ́ Láyè?
Bí Jèhófà bá fàyè gba àwọn nǹkan kan, ó ní láti nídìí tó fi fàyè gbà á. Ó lè yọ̀ǹda pé kí wọ́n fi ẹ̀tọ́ wa dù wá láti lè fi kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. Ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Ọlọ́run ‘kì í fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán ẹnikẹ́ni wò.’ (Jákọ́bù 1:13) Síbẹ̀, ó lè gba àwọn nǹkan kan tí kò bára dé láyè pé kó ṣẹlẹ̀ sí wa, ó sì lè ran àwọn tí wọ́n bá fara da irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà fún ìgbà díẹ̀, Ọlọ́run inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo . . . yóò fúnra rẹ̀ parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yín, yóò fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, yóò sì sọ yín di alágbára.”—1 Pétérù 5:10.
Síwájú sí i, gbìgbà tí Jèhófà bá gba ìrẹ́jẹ kan láyè lè mú kí arẹ́nijẹ náà ní àkókò láti ronú pìwà dà. Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn táwọn Júù pa Jésù, Pétérù wàásù fáwọn kan lára wọn, ìwàásù náà sì “gún wọn dé ọkàn-àyà.” Wọ́n tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọkàntọkàn, wọ́n sì ṣe batisí.—Ìṣe 2:36-42.
Ohun kan tó dájú ni pé, kì í ṣe gbogbo ẹní bá ń ṣàìtọ́ ló máa ronú pìwà dà. Àwọn kan tiẹ̀ lè ti pinnu láti máa rẹ́ni jẹ lọ láìwẹ̀yìn. Síbẹ̀ Òwe 29:1 sọ pé: “Ènìyàn tí a fi ìbáwí tọ́ sọ́nà léraléra, ṣùgbọ́n tí ó mú ọrùn rẹ̀ le, yóò ṣẹ́ lójijì, kì yóò sì ṣeé mú lára dá.” Bẹ́ẹ̀ ni, kò sígbà tí Jèhófà ò ní pa gbogbo àwọn tó ń ṣe ohun tí ò dáa láìronúpìwàdà run.—Oníwàásù 8:11-13.
Bó ṣe wù kó pẹ́ tó ká tó bọ́ lọ́wọ́ àìṣẹ̀tọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà mọ bó ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti rí ẹ̀tọ́ wa gbà. Ó sì dájú pé ó máa mú gbogbo ìpalára yòówù kí àìṣẹ̀tọ́ ti fà nínú ayé búburú yìí kúrò. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Jèhófà ti ṣèlérí kan fún wa, ìyẹn ni, ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun nínú èyí tí “òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:13.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Báwo ló ṣe máa rí lára Nábótì nígbà tí wọ́n ń hùwà àìtọ́ tó burú jáì sí i?