Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Ìdájọ́ Òdodo
“Èmi, Jèhófà, nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo.”—AÍSÁYÀ 61:8.
1, 2. (a) Kí ni “ìdájọ́ òdodo” àti “àìṣèdájọ́ òdodo” túmọ̀ sí? (b) Kí ni Bíbélì sọ nípa Jèhófà àti ìdájọ́ òdodo tó jẹ́ ànímọ́ rẹ̀?
ÌDÁJỌ́ ÒDODO túmọ̀ sí ‘àìṣe ojúsàájú, àìṣègbè, híhùwà ọmọlúwàbí àti ṣíṣe ohun tó dáa.’ Àìṣèdájọ́ òdodo ni àìṣẹ̀tọ́, ẹ̀tanú, ìwà ibi àti ìrẹ́nijẹ.
2 Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún báyìí tí Mósè ti kọ̀wé nípa Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run pé: “Gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Diutarónómì 32:4) Ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún méje lẹ́yìn náà, Ọlọ́run mí sí Aísáyà láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀ pé: “Èmi, Jèhófà, nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Aísáyà 61:8) Nígbà tó sì di ọ̀rúndún kìíní, léraléra ni Pọ́ọ̀lù ń tẹnu mọ́ ọn pé: “Àìṣèdájọ́ òdodo ha wà pẹ̀lú Ọlọ́run bí? Kí èyíinì má ṣe rí bẹ́ẹ̀ láé!” (Róòmù 9:14) Ní ọ̀rúndún yẹn kan náà ni Pétérù sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Dájúdájú, “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.”—Sáàmù 37:28; Málákì 3:6.
Àìṣẹ̀tọ́ Gbilẹ̀
3. Báwo ni àìṣẹ̀tọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?
3 Ìdájọ́ òdodo kì í ṣe ànímọ́ tó wọ́pọ̀ lóde òní. Kò síbi táwọn èèyàn kì í ti í ṣèrú, yálà níbi iṣẹ́, nílé ìwé, lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ, tàbí láwọn ọ̀nà míì, tó fi mọ́ àárín ẹbí àtọ̀rẹ́. Irú àìṣèdájọ́ òdodo tàbí àìṣẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ kì í ṣohun tuntun. Àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ló fà á tí aráyé fi ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀, ìdí sì ni pé wọ́n gbà kí Sátánì Èṣù, ẹni ẹ̀mí tó di ọlọ̀tẹ̀ náà, mú kí wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara wọn di aṣetinú-ẹni. Ìwà àìtọ́ gbáà ló jẹ́ fún Ádámù, Éfà àti Sátánì láti ṣi ẹ̀bùn àgbàyanu tí Jèhófà fún wọn láti yan ohun tó wù wọ́n lò. Ìwà àìtọ́ tí wọ́n hù sì yọrí sí ìjìyà ńláǹlà àti ikú fún gbogbo aráyé pátá.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; Róòmù 5:12; Hébérù 2:14.
4. Báwo ló ṣe pẹ́ tó tí àìṣẹ̀tọ́ ti wà láyé?
4 Láti nǹkan bí ẹgbàáta [6,000] ọdún tí ìwà ọ̀tẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì ni àìṣẹ̀tọ́ ti wà láwùjọ. Kò sì yẹ kí èyí yani lẹ́nu nítorí pé Sátánì ni ọlọ́run ayé yìí. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Òpùrọ́ ni, ó sì tún jẹ́ baba èké. Abanilórúkọjẹ́ ni, ó sì tún ń ta ko Jèhófà. (Jòhánù 8:44) Kò níṣẹ́ méjì ju kó máa tan ìwà àìṣòdodo kálẹ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ, mímú tí Sátánì ń mú káwọn èèyàn hùwà ibi ṣáájú Ìkún-omi ọjọ́ Nóà ló fà á tí Ọlọ́run fi kíyè sí i pé “ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:5) Bí nǹkan sì ṣe rí nìyẹn nígbà tí Jésù wà láyé. Ìyẹn ló fi sọ pé: “Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.” Búburú tí Jésù ń sọ ni àwọn ìṣòro apinnilẹ́mìí, bí àìṣẹ̀tọ́ tàbí ìrẹ́jẹ tó ń wáyé lójoojúmọ́. (Mátíù 6:34) Bí Bíbélì ṣe sọ gan-an ló rí pé: “Gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.”—Róòmù 8:22.
5. Kí ló fà á ti àìṣẹ̀tọ́ fi wọ́pọ̀ ní àkókò tiwa ju ti ìgbàkígbà rí lọ?
5 Nítorí náà, ọjọ́ pẹ́ tí àìṣẹ̀tọ́ ti ń fa aburú. Ọ̀ràn náà tiẹ̀ ti wá gogò sí i báyìí. Kí ló fà á ná? Ohun tó fà á ni pé láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn la ti wà nínú àwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” ayé búburú yìí, tí àwọn nǹkan tó ń mú kí ọjọ́ ìkẹyìn jẹ́ “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” sì ń ṣẹlẹ̀ bí òpin ṣe ń sún mọ́lé. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àwọn èèyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, . . . aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.” (2 Tímótì 3:1-5) Irú àwọn ìwàkiwà tí Bíbélì mẹ́nu kàn wọ̀nyí ló ń fa onírúurú àìṣẹ̀tọ́.
6, 7. Àìṣẹ̀tọ́ tó kọ sísọ wo ló ń wáyé lákòókò tá à ń gbé yìí?
6 Láti ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, àìṣẹ̀tọ́ tó ń wáyé ti wá burú jáì débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà tíì sírú ẹ̀ rí. Ohun kan tó sì mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé láàárín àwọn ọdún náà logun tíì jà jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òpìtàn kan ti fojú bù ú pé nígbà Ogun Àgbáyé Kejì nìkan ṣoṣo, àwọn tó kú á tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà àádọ́ta [50,000,000] sí àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́ta [60,000,000], àwọn aráàlú lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà, tí wọn ò mọwọ́ mẹsẹ̀ ló sì pọ̀ jù lára àwọn tó kú náà. Látìgbà tí ogun ọ̀hún sì ti parí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ni wọ́n ti pa nínú onírúurú ogun, àwọn aráàlú ló sì tún forí fá èyí tó pọ̀ jù. Sátánì ń rúná sírú àìṣẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé inú ń bí i gidigidi, níwọ̀n bó ti mọ̀ pé Jèhófà máa tó ṣẹ́gun òun pátápátá. Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe kà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì rèé: “Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣípayá 12:12.
7 Kárí ayé, iye owó táwọn ológun ń ná lọ́dọọdún báyìí ti wọ nǹkan bí àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà àádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló wà tí wọn ò rí ná tí wọn ò sì rí lò. Ì bá ti dára tó ká ní orí ọ̀rọ̀ àlàáfíà ni wọ́n ń ná owó náà lé! Nǹkan bí àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ẹgbẹ̀rún èèyàn ni wọn ò róúnjẹ jẹ tó, nígbà táwọn míì sì wà tí wọ́n ń jẹ àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù. Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tiẹ̀ sọ pé ó tó nǹkan bí àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà márùn-ún àwọn ọmọdé tó ń kú lọ́dọọdún nítorí ebi. Àìṣẹ̀tọ́ gbáà mà nìyẹn o! Àwọn ọmọ tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ táwọn èèyàn ṣẹ́ oyún wọn dà nù ńkọ́? Wọ́n fojú bù ú pé, irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ń ṣẹ́ oyún wọn dà nù kárí ayé tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ogójì sí àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́ta lọ́dọọdún! Àìṣẹ̀tọ́ yìí mà ga o!
8. Ọ̀nà kan ṣoṣo wo ni àìṣẹ̀tọ́ lè gbà kásẹ̀ nílẹ̀?
8 Gbogbo báwọn alákòóso ṣe ń gbìyànjú tó láti wá ojútùú sáwọn ìṣòro ńláǹlà tó ń han aráyé léèmọ̀ yìí, ibi pẹlẹbẹ náà ni ọ̀bẹ wọn ń fi lélẹ̀; kò sì dà bíi pé ìsapá ẹ̀dá lè mú káwọn ìṣòro náà kásẹ̀ nílẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àkókò tá à ń gbé yìí “àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a ó sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.” (2 Tímótì 3:13) Bí ẹ̀wù tiẹ̀ làwọn èèyàn ṣe ń gbé àìṣẹ̀tọ́ wọ̀ báyìí, wọn kì í sì í fẹ́ bọ́ ọ sílẹ̀ mọ́. Ọlọ́run ẹ̀san nìkan ló lè bọ́ ọ kúrò lọ́rùn wọn. Òun nìkan ló lè mú Sátánì, àwọn áńgẹ́lì burúkú, àtàwọn olubi ẹ̀dá gbogbo kúrò.—Jeremáyà 10:23, 24.
Àìṣẹ̀tọ́ Tó Ohun Téèyàn Ń Torí Ẹ̀ Ṣàníyàn
9, 10. Kí ló mú kí ọkàn Ásáfù rẹ̀wẹ̀sì?
9 Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, a tiẹ̀ rí lára àwọn tó kọ Bíbélì táwọn náà ń ṣe kàyéfì nípa ohun tó fà á tí Ọlọ́run ò fi tíì dá sí ọ̀ràn aráyé kó sì mú kí àìṣẹ̀tọ́ kásẹ̀ nílẹ̀ kí òdodo sì gbilẹ̀. Jẹ́ ká gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin kan lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì yẹ̀ wò. Ásáfù lorúkọ rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ fara hàn nínú àkọlé Sáàmù 73, ó sì ṣeé ṣe kí orúkọ náà jẹ́ ti ọmọ Léfì kan tó jẹ́ gbajúmọ̀ akọrin nígbà ìṣàkóso Dáfídì Ọba, ó sì lè jẹ́ orúkọ àwọn akọrin tó wà nínú ìdílé tí Ásáfù ti jẹ́ olórí ẹbí. Ásáfù yìí àtàwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ kọ ọ̀pọ̀ orin táwọn èèyàn máa ń lò láti fi ṣe ìjọsìn. Síbẹ̀, ó tó àkókò kan nígbà ayé Ásáfù tó kọ ìwé sáàmù yìí tóun náà bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀wẹ̀sì nítorí ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìjọsìn rẹ̀. Ó rí i bí ọrọ̀ àwọn èèyàn búburú ṣe ń pọ̀ sí i, ó sì kíyè sí i pé ó jọ pé ìgbésí ayé wọn máa ń tẹ́ wọn lọ́rùn, láìsí pé ẹ̀rù ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí wọn ń bà wọ́n.
10 Ó sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Èmi ṣe ìlara àwọn aṣògo, nígbà tí mo rí àlàáfíà àwọn ènìyàn burúkú. Nítorí tí wọn kì í ní ìroragógó ikú; ikùn bẹ̀ǹbẹ̀ wọn sì yọ. Wọn kò tilẹ̀ sí nínú ìdààmú ẹni kíkú, ìyọnu kì í sì í bá wọn bí ti àwọn ènìyàn mìíràn.” (Sáàmù 73:2-8) Nígbà tó ṣe, òǹkọ̀wé Bíbélì yẹn wá rí i pé èrò òdì gbáà lòun ní. (Sáàmù 73:15, 16) Onísáàmù náà gbìyànjú láti mú kí ìrònú ẹ̀ bá ti Ọlọ́run mu, síbẹ̀ náà kò lóye ohun tó fà á tó fi dà bíi pé àwọn ẹni ibi ń ṣe ohun tí ò dáa láṣegbé táwọn tó nífẹ̀ẹ́ àtimáa ṣe ohun tó tọ́ sì ń jìyà.
11. Kí ni onísáàmù náà Ásáfù wá lóye ẹ̀ nígbà tó yá?
11 Àmọ́ nígbà tó yá, ọkùnrin ìgbàanì tó jẹ́ olùṣòtítọ́ yẹn mọ ibi tọ́rọ̀ àwọn ẹni ibi máa já sí, ó rí i pé bó pẹ́ bó yá Jèhófà máa mú gbogbo ọ̀ràn tọ́. (Sáàmù 73:17-19) Dáfídì kọ̀wé pé: “Ní ìrètí nínú Jèhófà, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé. Nígbà tí a bá ké àwọn ẹni burúkú kúrò, ìwọ yóò rí i.”—Sáàmù 37:9, 11, 34.
12. (a) Kí ni Jèhófà máa ṣe sí ìwà ibi àti àìṣẹ̀tọ́? (b) Kí lèrò ẹ nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run máa gbà mú àìṣẹ̀tọ́ kúrò?
12 Ó dájú hán-únhán-ún pé Jèhófà máa mú gbogbo ìwà ibi àti àìṣẹ̀tọ́ tó ń bá a rìn kúrò lórí ilẹ̀ ayé bó bá tó àkókò lójú rẹ̀. Ohun kan sì tún nìyẹn táwọn Kristẹni adúróṣinṣin gbọ́dọ̀ máa rán ara wọn létí nígbà gbogbo. Jèhófà máa mú gbogbo àwọn tí kò bá ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu kúrò, ó sì máa san àwọn tó bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́ lẹ́san rere. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ojú rẹ̀ ń wò, ojú rẹ̀ títàn yanran ń ṣàyẹ̀wò àwọn ọmọ ènìyàn. Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá. Òun yóò rọ̀jò pańpẹ́, iná àti imí ọjọ́ sórí àwọn ẹni burúkú . . . Nítorí olódodo ni Jèhófà; ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ìṣe òdodo.”—Sáàmù 11:4-7.
Ayé Tuntun Òdodo
13, 14. Kí nìdí tí òdodo àti ẹ̀tọ́ á fi gbilẹ̀ nínú ayé tuntun?
13 Tí Jèhófà bá pa ayé tí àìṣẹ̀tọ́ ti gbilẹ̀, tó wà níkàáwọ́ Sátánì yìí run tán, yóò mú ayé tuntun ológo wá. Ìjọba Ọlọ́run lókè ọ̀run, èyí tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ láti máa gbàdúrà fún, lá máa ṣàkóso ayé tuntun náà. Ìwà ibi àti àìṣẹ̀tọ́ á kógbá sílé, òdodo àti ẹ̀tọ́ á sì gbilẹ̀, nítorí pé Ọlọ́run á ti dáhùn àdúrà wa ní kíkún pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:10.
14 Bíbélì jẹ́ ká mọ irú àkóso tó yẹ ká máa retí, ó jẹ́ irú àkóso tí gbogbo èèyàn ọlọ́kàn títọ́ ti ń wọ̀nà fún tipẹ́tipẹ́. Nígbà náà ni Sáàmù 145:16 á wá ní ìmúṣẹ rẹ̀ kíkún pé: “Ìwọ [Jèhófà Ọlọ́run] ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” Síwájú sí i, Aísáyà 32:1 sọ pé: “Wò ó! Ọba kan [Jésù Kristi lókè ọ̀run] yóò jẹ fún òdodo; àti ní ti àwọn ọmọ aládé [àwọn aṣojú Kristi lórí ilẹ̀ ayé], wọn yóò ṣàkóso bí ọmọ aládé fún ìdájọ́ òdodo.” Aísáyà 9:7 wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù Kristi tó máa jẹ́ Ọba ìjọba náà pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin, lórí ìtẹ́ Dáfídì àti lórí ìjọba rẹ̀ láti lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in àti láti gbé e ró nípasẹ̀ ìdájọ́ òdodo àti nípasẹ̀ òdodo, láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin. Àní ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe èyí.” Ǹjẹ́ o lè fojú inú rí ara rẹ pé ò ń gbé lábẹ́ àkóso tí ẹ̀tọ́ á ti gbilẹ̀ yẹn?
15. Kí ni Jèhófà máa ṣe fún aráyé nínú ayé tuntun?
15 Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, a ò tún ní máa sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Oníwàásù 4:1 mọ́, pé: “Èmi alára sì padà, kí n lè rí gbogbo ìwà ìninilára tí a ń hù lábẹ́ oòrùn, sì wò ó! omijé àwọn tí a ń ni lára, ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú; ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára sì ni agbára wà, tí ó fi jẹ́ pé wọn kò ní olùtùnú.” Nítorí pé aláìpé ni wá, a ò lè fọkàn yàwòrán kúlẹ̀kúlẹ̀ bí ayé tuntun tí òdodo á máa gbénú ẹ̀ yẹn ṣe máa jẹ́ àgbàyanu tó. Ìwà búburú á ti kásẹ̀ nílẹ̀, ire la ó sì máa rí bí ojúmọ́ kọ̀ọ̀kan bá ṣe ń mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà á tún gbogbo ohun tí kò bá tọ̀nà ṣe, á sì ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó máa dára ju bá a ti lè rò lọ. Ó bá a mu wẹ́kú nígbà náà pé Jèhófà Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pétérù láti kọ̀wé pé: “Ọrun tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé”!—2 Pétérù 3:13.
16. Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà fìdí “ọ̀run tuntun” múlẹ̀, ọ̀nà wo sì ni ó gbà ń fi ìpìlẹ̀ “ayé tuntun” lélẹ̀ lónìí?
16 Kódà, bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí pàápàá, Ọlọ́run ti fìdí “ọ̀run tuntun” yẹn, ìyẹn ìjọba Ọlọ́run lókè ọ̀run tí Kristi á máa ṣàkóso lé lórí, múlẹ̀. Kódà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, ó ń ṣe àkójọ àwọn èèyàn tí wọ́n máa pilẹ̀ “ayé tuntun,” ìyẹn àwùjọ èèyàn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n máa wà nínú ayé tuntun. Wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà méje báyìí, a sì lè rí wọn ní nǹkan bí òjìlénígba ó dín márùn-ún [235] ilẹ̀ àti láwọn ìjọ tó tó ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000]. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn yìí ti ń kọ́ láti máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà tó jẹ́ ọ̀nà òdodo àti ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ìyẹn ló sì fà á tó fi jẹ́ pé ní gbogbo ibi tí wọ́n wà láyé, ìfẹ́ Kristẹni so gbogbo wọn pọ̀ ṣọ̀kan. Àárín wọn ni ìṣọ̀kan ti gbilẹ̀ jù lọ, ọjọ́ sì ti pẹ́ tírú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ ti wà láàárín wọn. Ìṣọ̀kan ọ̀hún sì ta yọ ohunkóhun yòówù tá a lè rí láàárín àwọn tí Sátánì ń ṣàkóso lé lórí. Irú ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn nǹkan tá a máa gbádùn nínú ayé tuntun Ọlọ́run tó ń bọ̀ lọ́nà, níbi tí Jèhófà á ti máa fi òdodo àti ẹ̀tọ́ darí ohun gbogbo.—Aísáyà 2:2-4; Jòhánù 13:34, 35; Kólósè 3:14.
Pàbó Ni Àtakò Sátánì Máa Já Sí
17. Kí ló mú kó dájú pé pàbó ni àtakò tí Sátánì máa fẹ́ fi pa àwọn èèyàn Jèhófà run máa já sí?
17 Láìpẹ́, Sátánì àtàwọn tó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn á gbéjà ko àwọn olùjọsìn Jèhófà kí wọ́n bàa lè pa wọ́n run pátápátá. (Ìsíkíẹ́lì 38:14-23) Ìyẹn á wà lára ohun tí Jésù pè ní “ìpọ́njú ńlá . . . irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mátíù 24:21) Ṣé àtakò Sátánì á kẹ́sẹ járí? Rárá o. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kó dá wa lójú pé: “Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà, òun kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀. Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni a óò máa ṣọ́ wọn dájúdájú; ṣùgbọ́n ní ti ọmọ àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò ní tòótọ́. Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:28, 29.
18. (a) Kí ni Ọlọ́run máa ṣe tí Sátánì bá gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run? (b) Àwọn àǹfààní wo lo ti rí nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀tọ́ ló máa lékè?
18 Àtakò tí Sátánì àti agbo àwọn áńgẹ́lì burúkú tó kó sòdí máa gbé ko àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ni ìwọ̀sí tí Jèhófà máa gbà kó fi lọ òun kẹ́yìn. Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì Sekaráyà pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” (Sekaráyà 2:8) Ṣe ló máa dà bí ìgbà tó ti ìka rẹ̀ bọ ẹyinjú Jèhófà. Kò ní gbà yẹn rárá, lọ́gán ló máa pa àwọn ọ̀dàlẹ̀ náà run. Kò sẹ́ni tó dà bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé yìí, àwọn ni wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn jù lọ, àwọn ni wọ́n wà ní ìṣọ̀kan jù lọ, àwọn ló jẹ́ ẹni àlàáfíà jù lọ, àwọn ló sì ń pa òfin mọ́ jù lọ. Kí wá lẹnì kan fẹ́ sọ pé òun ń tìtorí ẹ̀ ṣàtakò sí wọn bí kì í bá ṣe pé onítọ̀hún fẹ́ ṣe ohun tí kò bá ẹ̀tọ́ mu? Jèhófà tó jẹ́ “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo” ò ní gba irú ẹ̀ láyè rárá. Á gbèjà wọn nípa pípa àwọn ọ̀tá wọn run ráúráú, débi pé ẹ̀tọ́ á lékè, ìgbàlà á sì jẹ́ tàwọn tó ń sin Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo náà. Ohun àgbàyanu tí ń mọ́kàn yọ̀ làwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú yìí á mà jẹ́ fún wa o!—Òwe 2:21, 22.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ló fà á tí àìṣẹ̀tọ́ fi gbilẹ̀ gan-an?
• Báwo ni Jèhófà ṣe máa fòpin sí àìṣẹ̀tọ́ lórí ilẹ̀ ayé?
• Kí lohun tó wọ̀ ẹ́ lọ́kàn jù nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí nípa bí ẹ̀tọ́ ṣe máa lékè?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìwà búburú gbilẹ̀ gan-an ṣáájú Ìkún-omi, bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe ń gbilẹ̀ láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” yìí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, ẹ̀tọ́ àti òdodo ló máa wà dípò ìwà ibi