Àǹfààní Wà Nínú Kéèyàn Fara Da Ìjìyà
“Àwọn tí wọ́n lo ìfaradà ní a ń pè ní aláyọ̀.”—JÁKỌ́BÙ 5:11.
1, 2. Kí ló fi hàn pé Jèhófà ò dá èèyàn láti máa jìyà?
KÒ SÍ onílàákàyè èèyàn tá fẹ́ kóun máa jìyà; bẹ́ẹ̀ náà sì ni kò wu Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, pé káwa èèyàn máa jìyà. A lè rí i pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyí bá a bá ṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí, tá a sì kíyè sí ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́. Ọkùnrin ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá. Bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ nìyí: “Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru ilẹ̀, ó sì fẹ́ èémí ìyè sínú ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Ara Ádámù àti ìrònú rẹ̀ jẹ́ pípé, nítorí náà kò lè ṣàìsàn bẹ́ẹ̀ sì ni kò lè kú.
2 Ibi tí Ádámù ń gbé ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run gbin ọgbà kan ní Édẹ́nì, síhà ìlà-oòrùn, ibẹ̀ ni ó sì fi ọkùnrin tí ó ti ṣẹ̀dá sí. Nípa báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mú kí olúkúlùkù igi tí ó fani mọ́ra ní wíwò, tí ó sì dára fún oúnjẹ hù láti inú ilẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:8, 9) Àgbàyanu nibi tí Ọlọ́run fi ṣe ibùgbé Ádámù. Ẹ̀gàn ni hẹ̀! Kò sí ohunkóhun tó ń jẹni níyà nínú ọgbà Édẹ́nì.
3. Àwọn ohun tó lárinrin wo ni Ọlọ́run gbé ka iwájú tọkọtaya àkọ́kọ́?
3 Jẹ́nẹ́sísì 2:18 fi tó wa létí pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: ‘Kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.’” Lẹ́yìn ìyẹn ni Jèhófà wá dá obìnrin pípé kan gẹ́gẹ́ bí aya fún Ádámù, èyí tó máa mú kí ilé wọn jẹ́ ilé aláyọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:21-23) Bíbélì sọ fún wa síwájú sí i pé: “Ọlọ́run sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.’” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Tọkọtaya tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá ní àǹfààní àgbàyanu. Àǹfààní náà sì ni pé kí wọ́n mú kí ọgbà Édẹ́nì tó jẹ́ Párádísè máa gbòòrò sí i títí táá fi tàn dé apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé, tí gbogbo ilẹ̀ ayé á sì wá di Párádísè. Wọ́n á bí àwọn ọmọ tó máa láyọ̀, tí wọn ò ní máa jìyà kankan. Bó ṣe di pé gbogbo nǹkan bẹ̀rẹ̀ lọ́nà tó lárinrin fún wọn nìyẹn o!—Jẹ́nẹ́sísì 1:31.
Ìjìyà Bẹ̀rẹ̀
4. Kí làwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ti mú kó ṣe kedere nípa aráyé?
4 Síbẹ̀, bá a bá wo ipò tí aráyé wà látìgbà yẹn wá, ó ṣe kedere pé nǹkan ti mẹ́hẹ. Ọ̀pọ̀ láburú ló ti ṣẹlẹ̀, aráyé sì ti jìyà púpọ̀. Títí dòní olónìí, gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà ló ń ṣàìsàn, wọ́n ń darúgbó, bó bá sì ṣe wọ́n á kú. Ó dájú pé ayé ò tíì di Párádísè táwọn èèyàn aláyọ̀ á máa gbé. Àní bí Róòmù 8:22 ṣe ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà gẹ́lẹ́ ló rí, ó sọ pé: “Gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.”
5. Báwo làwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣe mú kí aráyé dẹni tó ń jìyà?
5 Jèhófà kọ́ ló lẹ̀bi gbogbo ìyà ńláǹlà tó ti ń jẹ aráyé látìgbà yìí wá. (2 Sámúẹ́lì 22:31) Èyí tí aráyé jẹ̀bi ẹ̀ nínú ọ̀ràn ọ̀hún ní í jóun. Bíbélì ṣáà sọ pé: “Wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun, wọ́n ti hùwà lọ́nà ìṣe-họ́ọ̀-sí nínú ìbálò wọn.” (Sáàmù 14:1) Ọlọ́run ò fawọ́ ohun rere kankan sẹ́yìn fún Ádámù àti Éfà níbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Kìkì ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe káwọn ohun rere náà má bàa bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́ ni pé kí wọ́n jẹ́ onígbọràn, àmọ́ ṣe ni wọ́n yàn láti máa dá pinnu ohun tó bá wù wọ́n. Níwọ̀n báwọn òbí wa àkọ́kọ́ sì ti yàn láti kọ Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sọ ara wọn di aláìpé lójú Jèhófà. Ìlera wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn títí tí wọ́n fi kú. Bó sì ṣe di pé àwa náà jogún àìpé nìyẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19; Róòmù 5:12.
6. Ọ̀nà wo ni Sátánì gbà mú kí aráyé máa jìyà?
6 Lára ohun tó tún mú ìjìyà wá sórí aráyé ni ẹ̀dá ẹ̀mí tá a wá mọ̀ sí Sátánì Èṣù. Ọlọ́run fún un ní òmìnira láti pinnu ohun tó bá wù ú. Àmọ́, ó ṣi òmìnira yẹn lò nítorí pé ó ń fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn òun. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Jèhófà nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn, kì í ṣe àwọn nǹkan tó dá. Sátánì yìí ló tan Ádámù àti Éfà táwọn náà fi ń fẹ́ láti máa dá pinnu àwọn nǹkan láyè ara wọn, bíi pé wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ “dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:5.
Jèhófà Nìkan Ló Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Máa Ṣàkóso
7. Kí la rí kọ́ látinú ohun tí ìwà ọ̀tẹ̀ tí Sátánì hù sí Jèhófà yọrí sí?
7 Aburú tí ìwà ọ̀tẹ̀ tí Sátánì hù sí Jèhófà fà fi hàn pé, Jèhófà Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso àti pé àkóso rẹ̀ nìkan ṣoṣo ló jẹ́ àkóso òdodo. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tó ti kọjá ti fi hàn pé Sátánì, tó di “olùṣàkóso ayé yìí” ti fìdí ìṣàkóso kan múlẹ̀. Ìṣàkóso burúkú, aláìṣòdodo tó kún fún ìwà ipá, tí kò sì dára fún ohunkóhun ni. (Jòhánù 12:31) Àkóso tó kún fún òṣì àti àre táwọn èèyàn ti ń ṣe látọjọ́ tó ti pẹ́ lábẹ́ ìdarí Sátánì, ti wá mú kó ṣe kedere pé ẹ̀dá èèyàn ò lágbára láti ṣàkóso lọ́nà òdodo. (Jeremáyà 10:23) Nípa bẹ́ẹ̀, irú àkóso yòówù káwọn èèyàn dáwọ́ lé, yàtọ̀ sí ti Jèhófà, máa forí ṣánpọ́n gbẹ̀yìn náà ni. Ìtàn ti jẹ́ ká rí i pé òótọ́ tí ò ṣeé já ní koro nìyẹn.
8. Kí ni Jèhófà máa ṣe nípa onírúurú àkóso ẹ̀dá èèyàn, báwo ló sì ṣe máa mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ?
8 Ní báyìí tí Jèhófà ti yọ̀ǹda fún ẹ̀dá èèyàn láti fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún dá ṣàkóso ara wọn láìbá wọn lọ́wọ́ sí i, kò sí ohun tó burú níbẹ̀ bó bá palẹ̀ ọ̀kan-ò-jọ̀kan àkóso tí wọn ti dán wò mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé tó sì fi ìjọba tiẹ̀ rọ́pò. Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa èyí sọ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [àkóso ẹ̀dá èèyàn], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ [ìjọba Ọlọ́run tó wà ní ìkáwọ́ Kristi] èyí tí a kì yóò run láé. . . . Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 2:44) Àkóso àwọn ẹ̀mí èṣù àti tàwọn èèyàn á dópin, kìkì Ìjọba Ọlọ́run tí yóò máa ṣàkóso láti ọ̀run wá nìkan ló máa ṣẹ́ kù tí yóò sì máa ṣàkóso ilẹ̀ ayé. Kristi ló máa jẹ́ Ọba ìjọba náà, àwọn èèyàn olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí a mú láti orí ilẹ̀ ayé ni wọ́n máa jùmọ̀ ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀.—Ìṣípayá 14:1.
Béèyàn Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Ìjìyà
9, 10. Báwo ni Jésù ṣe jàǹfààní látinú ìyà tó jẹ?
9 Ó dáa ká ṣàyẹ̀wò báwọn tó máa ṣàkóso nínú Ìjọba ọ̀run ṣe kúnjú ọ̀ṣùwọ̀n tó. Kristi Jésù ló kọ́kọ́ fi bóun ṣe kúnjú òṣùwọ̀n tó láti jẹ́ Ọba hàn. Ó ti lo ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún lọ́dọ̀ Jèhófà, láti fi ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀, kódà òun ni “àgbà òṣìṣẹ́” rẹ̀. (Òwe 8:22-31) Nígbà tí Jèhófà ṣètò pé kí Jésù wá sórí ilẹ̀ ayé, ńṣe ló fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara ẹ̀. Nígbà tó sì dórí ilẹ̀ ayé, ó pọkàn pọ̀ sórí sísọ fáwọn ẹlòmíì nípa ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ àti nípa Ìjọba Ọlọ́run. Jésù fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ fún gbogbo èèyàn nípa títẹrí ba pátápátá fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ.—Mátíù 4:17; 6:9.
10 Wọ́n ṣenúnibíni sí Jèsù kó tó di pé wọ́n pa á. Àmọ́ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó kíyè sí i níbi gbogbo tó ń dé pé inú ipò òṣì àti àre laráyé wà. Ǹjẹ́ ohun tó fojú ara ẹ̀ rí yẹn àti ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ṣe é láǹfààní èyíkéyìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Hébérù 5:8 sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ Ọmọ [Ọlọ́run], ó kọ́ ìgbọràn láti inú àwọn ohun tí ó jìyà.” Ohun tójú Jésù rí nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé mú kó túbọ̀ lóye àwọn nǹkan tó ń ṣe aráyé kó sì tún jẹ́ aláàánú. Ó fojú ara ẹ̀ rí ìṣòro tó ń bá aráyé fínra. Ó mọ bó ṣe lè káàánú àwọn tí ìyà ń jẹ, ìyẹn á sì tún jẹ́ kó túbọ̀ mọrírì àǹfààní tó ní láti gbà wọ́n sílẹ̀. Wo bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe gbé kókó yìí yọ nínú ìwé Hébérù nígbà tó sọ pé: “Ó di dandan fún un láti dà bí ‘àwọn arákùnrin’ rẹ̀ lọ́nà gbogbo, kí ó lè di àlùfáà àgbà tí ó jẹ́ aláàánú àti olùṣòtítọ́ nínú àwọn ohun tí ó jẹmọ́ ti Ọlọ́run, kí ó bàa lè rú ẹbọ ìpẹ̀tù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn. Nítorí níwọ̀n bí òun fúnra rẹ̀ ti jìyà nígbà tí a ń dán an wò, ó lè wá ṣe àrànṣe fún àwọn tí a ń dán wò.” “Nítorí àwa ní gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, kì í ṣe ẹni tí kò lè báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa, bí kò ṣe ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.”—Hébérù 2:17, 18; 4:14-16; Mátíù 9:36; 11:28-30.
11. Báwo ni ìrírí àwọn tó máa jẹ́ ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Jésù á ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jẹ́ olùṣàkóso rere?
11 Ohun kan náà gẹ́lẹ́ la lè sọ nípa àwọn ọ̀kẹ́ méjè ó lé ẹgbàajì [144,000] tí “a rà” láti ilẹ̀ ayé pé kí wọ́n bá Kristi Jésù ṣàkóso nínú Ìjọba rẹ̀ òkè ọ̀run. (Ìṣípayá 14:4) Orí ilẹ̀ ayé ńbí la bí wọn sí, inú ayé tó kún fún ìjìyà yìí ni wọ́n dàgbà sí, àwọn fúnra wọn sì jìyà. Ọ̀pọ̀ lára wọn ni wọ́n ṣenúnibíni sí, wọ́n sì pa àwọn kan nítorí pé wọ́n ń bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti pé wọ́n ń fínnúfíndọ̀ tọ Jésù lẹ́yìn. Àmọ́ wọn ò ‘tijú ẹ̀rí nípa Olúwa wọn, wọ́n sì jìyà ibi fún ìhìn rere.’ (2 Tímótì 1:8) Ìrírí tí wọ́n ní lórí ilẹ̀ ayé gan-an ló sọ wọ́n dẹni tó tóótun láti ṣèdájọ́ gbogbo aráyé látọrùn wá. Wọ́n ti kọ́ béèyàn ṣeé jẹ́ abánikẹ́dùn, onínúure àti ẹni tó múra tán láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.—Ìṣípayá 5:10; 14:2-5; 20:6.
Ayọ̀ Táwọn Tó Máa Gbé Lórí Ilẹ̀ Ayé Á Ní
12, 13. Báwo làwọn tó ń fojú sọ́nà láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé ṣe lè jàǹfààní látinú ìyà tó bá ń jẹ wọ́n?
12 Ǹjẹ́ àǹfààní èyíkéyìí tiẹ̀ lè jẹ yọ látinú ìyà tó ń jẹ àwọn tó ń fojú sọ́nà láti gbé títí láé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé níbi tí kò ti ní sí àìsàn, ìrora àti ikú mọ́? Ó dájú pé ìrora tí ìjìyà máa ń fà àti ìbànújẹ́ ńláǹlà tó máa ń kóni sí kì í ṣe nǹkan tó dáa lára. Ṣùgbọ́n tá a bá fara da irú ìjìyà bẹ́ẹ̀, ó lè mú káwọn ànímọ́ wa sunwọ̀n sí i ká sì tún ní àníkún ayọ̀.
13 Ìwọ ronú lórí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí sọ nípa irú ìjìyà àti ayọ̀ bẹ́ẹ̀: “Àní bí ẹ bá ní láti jìyà nítorí òdodo pàápàá, ẹ̀yin jẹ́ aláyọ̀.” “Bí a bá ń gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹ̀yin jẹ́ aláyọ̀.” (1 Pétérù 3:14; 4:14) “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi. Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:11, 12) “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífarada àdánwò, nítorí nígbà tí ó bá di ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, yóò gba adé ìyè.”—Jákọ́bù 1:12.
14. Kí lohun tó wá nínú ìjìyà tó ń mú káwọn tó ń sin Jèhófà máa láyọ̀?
14 Kì í ṣe ìyà tó ń jẹ wá gan-an ló ń mú wa láyọ̀. Ohun tó ń mú ká láyọ̀ ká sì tún ní ìtẹ́lọ́rùn ni mímọ̀ tá a mọ̀ pé ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà àti títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù ló fà á tá a fi ń jìyà. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n ju àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì sẹ́wọ̀n, lẹ́yìn náà ni wọ́n mú wọn wá sí ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù tí wọ́n sì dẹ́bi fún wọn ní gbangba nítorí pé wọ́n ń wàásù nípa Jésù Kristi. Ẹ̀yìn tí wọ́n nà wọ́n lẹ́gba ni wọ́n tó dá wọn sílẹ̀. Kí ni wọ́n ṣe? Àkọsílẹ̀ inú Bíbélì sọ pé wọ́n “kúrò níwájú Sànhẹ́dírìn, wọ́n ń yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nítorí orúkọ rẹ̀.” (Ìṣe 5:17-41) Kì í ṣe nínà tí wọ́n nà wọ́n àti ìrora tó fà ló mú wọn láyọ̀ o. Ohun tó mú wọn láyọ̀ ni mímọ̀ tí wọ́n mọ̀ pé ìfẹ́ Jèhófà táwọn ń ṣe láìyẹsẹ̀ àti ipasẹ̀ Jésù táwọn ń tọ̀ ló fà á tí wọ́n fi na àwọn.—Ìṣe 16:25; 2 Kọ́ríńtì 12:10; 1 Pétérù 4:13.
15. Bá a bá ń fara da ìjìyà nísinsìnyí, báwo ló ṣe lè ṣe wá láǹfààní lọ́jọ́ iwájú?
15 Bá a bá ní èrò tó tọ́ nígbà tá a bá ń fara da àtakò àti inúnibíni, ó lè mú ká dẹni tó ní ìfaradà. Èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti forí ti àwọn ìjìyà ọjọ́ iwájú. Ìyẹn ni Bíbélì fi sọ pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ìdùnnú, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ ní tòótọ́ pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín yìí tí a ti dán wò ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà.” (Jákọ́bù 1:2, 3) Bákan náà, Róòmù 5:3-5 sọ fún wa pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nígbà tí a bá wà nínú ìpọ́njú, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé ìpọ́njú ń mú ìfaradà wá; ìfaradà, ní tirẹ̀, ipò ìtẹ́wọ́gbà; ipò ìtẹ́wọ́gbà, ní tirẹ̀, ìrètí, ìrètí náà kì í sì í ṣamọ̀nà sí ìjákulẹ̀.” Nítorí náà, bá a bá ṣe ń fara da àdánwò tó nísinsìnyí nítorí ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe rọrùn fún wa tó láti fara da àwọn àdánwò míì tó bá tún bá wa nínú ayé búburú yìí.
Jèhófà Máa Dí I Fáwọn Tó Bá Pàdánù Nítorí Ìjìyà
16. Kí ni Jèhófà máa ṣe fáwọn tó máa jẹ́ ọba àti àlùfáà tó máa dí ìyà tó ti jẹ wọ́n?
16 Kódà bá a bá pàdánù ohun ìní wa nítorí àtakò tàbí inúnibíni tí wọ́n ṣe sí wa nítorí pé à ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ńṣe ni ká fọkàn balẹ̀ nítorí a mọ̀ pé Jèhófà máa san wá lẹ́san rere ní kíkún. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn kan tí wọ́n ń fojú sọ́nà fún lílọ sí ọ̀run pé: “Ẹ fi . . . ìdùnnú gba pípiyẹ́ àwọn nǹkan ìní yín, ní mímọ̀ pé ẹ̀yin fúnra yín ní ohun ìní dídárajù” gẹ́gẹ́ bí alákòóso nínú Ìjọba Ọlọ́run. (Hébérù 10:34) Ẹ sì wá wo bí ayọ̀ wọn ṣe máa kún tó nígbà tí Kristi àti Jèhófà bá ń darí wọn láti máa rọ̀jò àgbàyanu ìbùkún sórí àwọn olùgbé ayé nínú ayé tuntun. A lè wá rí i pé òótọ́ gbáà lọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ pé: “Mo ṣírò rẹ̀ pé àwọn ìjìyà àsìkò ìsinsìnyí kò jámọ́ ohunkóhun ní ìfiwéra pẹ̀lú ògo tí a óò ṣí payá nínú wa.”—Róòmù 8:18.
17. Kí ni Jèhófà máa ṣe fáwọn tó ń fojú sọ́nà láti gbé lórí ilẹ̀ ayé, àmọ́ tí wọ́n ń sìn ín láìyẹsẹ̀ nísinsìnyí?
17 Bákan náà, ohun yòówù káwọn tó ń fojú sọ́nà láti jogún ayé pàdánù nísinsìnyí tàbí èyí tí wọ́n fínnúfíndọ̀ lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó máa fí ohun tó fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú san èrè tabua fún wọn. Ó máa fi ìwàláàyè pípé tí kò lópin jíǹkí wọn nínú Párádísè ilẹ̀ ayé. Nínú ayé tuntun yẹn, Jèhófà “yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:4) Ìlérí àgbàyanu mà lèyí o! Kò sí ohun tá a mọ̀ọ́mọ̀ yọ̀ǹda nítorí iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run tàbí ohun tí ìṣòro tàbí inúnibíni gbà lọ́wọ́ wa nítorí pé à ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà tó máa tó nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìgbésí ayé àgbàyanu tó ń dúró dè wá, èyí tí Ọlọ́run máa fi jíǹkí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tí wọ́n bá fara da ìjìyà.
18. Ìlérí tó ń tuni nínú wo ni Jèhófà ṣe fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀?
18 Bí ìjìyà èyíkéyìí bá tiẹ̀ wà tá a ṣì ní láti fara dà, ó dájú pé kò ní ní ká má gbádùn ìyè ayérayé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ń mú bọ̀ wá. Gbogbo ìyà wọ̀nyẹn ò ní já mọ́ nǹkan mọ́ tá a bá fi wé àwọn nǹkan àgbàyanu tá a máa gbádùn nínú ayé tuntun. Aísáyà 65:17, 18 sọ fún wa pé: “Àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà. Ṣùgbọ́n ẹ yọ ayọ̀ ńláǹlà, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá.” Ìyẹn ló fi bá a mu gan-an bí Jákọ́bù, iyèkan Jésù ṣe sọ lásọtúnsọ pé: “Àwọn tí wọ́n lo ìfaradà ní a ń pè ní aláyọ̀.” (Jákọ́bù 5:11) Ó dájú pé bá a bá fara da ìjìyà ìsinsìnyí láìráhùn, a ó lè jàǹfààní nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ló fà á táráyé fi ń jìyà?
• Àwọn àǹfààní wo ni ìjìyà lè ṣe fáwọn tó máa ṣàkóso ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú àtàwọn tá máa gbé lórí ilẹ̀ ayé?
• Kí nìdí tá a fi lè máa láyọ̀ nísinsìnyí bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń jìyà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ohun àgbàyanu ni Ọlọ́run ní lọkàn láti ṣe fáwọn òbí wa àkọ́kọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Bí Jésù ṣe fojú ara ẹ̀ rí àwọn tó ń jìyà ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ Ọba àti Àlùfáà Àgbà rere
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn àpọ́sítélì ‘ń yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí’ nítorí ìgbàgbọ́ wọn