ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 8/15 ojú ìwé 32
  • Ìwé Kíkọ—Ṣe Pàtàkì Gan-an ní Ísírẹ́lì Ayé Ọjọ́un

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwé Kíkọ—Ṣe Pàtàkì Gan-an ní Ísírẹ́lì Ayé Ọjọ́un
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 8/15 ojú ìwé 32

Ìwé Kíkọ—Ṣe Pàtàkì Gan-an ní Ísírẹ́lì Ayé Ọjọ́un

ǸJẸ́ o ti ka díẹ̀ lára àwọn ewì àtayébáyé méjì ti ilẹ̀ Gíríìsì àtijọ́ tó ń jẹ́ Iliad àti Odyssey? Àwọn èèyàn gbà pé àárín ọ̀rúndún kẹsàn-án tàbí ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ wọ́n. Báwo la ṣe rí àwọn ìwé ewì náà sí tá a bá fi wọ́n wéra pẹ̀lú Bíbélì tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú ìgbà tí wọ́n kọ wọ́n? Ìwé kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní The Jewish Bible and the Christian Bible sọ pé: “Ó kéré tán, ó tó ìgbà irínwó lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [429] tí Bíbélì sọ nípa ìwé kíkọ́ sílẹ̀ àti èyí tí wọ́n ti kọ parí. Ohun tó mú kí kókó yìí gba àfiyèsí ni pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré ni ewì Iliad tá à ń sọ yìí sọ nípa ìwé kíkọ́ sílẹ̀ nígbà tó sì jẹ́ pé Odyssey ò tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìwé kíkọ́ rárá.”

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Oxford Encyclopedia of Archaeology in the Near East ṣàlàyé pé: “Ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, ó jọ pé apá pàtàkì ni ìwé kíkọ jẹ́ nínú ìjọsìn wọn.” Bí àpẹẹrẹ, ńṣe ni wọ́n kọ májẹ̀mú Òfin sílẹ̀ tí wọ́n sì máa ń kà á níwájú tọkùnrin tobìnrin, tọmọdé tàgbà wọn. Bákan náà, wọ́n máa ń kà á, wọ́n sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pa pọ̀. Kálukú wọn náà sì máa ń kà á. Lẹ́yìn tí Alan Millard tó jẹ́ olùkọ́ àgbà ní Yunifásítì Liverpool tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣàyẹ̀wò àwọn apá ibì kan nínú májẹ̀mú Òfin náà, ó sọ pé: “Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì gbà pé gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pátá látinú onírúurú ipò tó yàtọ̀ síra ló mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà.”— Diutarónómì 31:9-13; Jóṣúà 1:8; Nehemáyà 8:13-15; Sáàmù 1:2.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé irú ojú tó yẹ káwọn Kristẹni máa fi wo Ìwé Mímọ́, ó sọ pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” Ǹjẹ́ ò ń fi hàn pé o mọrírì Bíbélì nípa kíkà á déédéé?— Róòmù 15:4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́