Ayé Onídàájọ́ Òdodo Kì Í Ṣe Àlá Lásán!
ÀGBÀ òṣèlú ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Daniel Webster, ṣàkíyèsí pé: “Ìdájọ́ òdodo ni ohun pàtàkì tí ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí lórí ilẹ̀ ayé.” Bíbélì sì sọ pé: “Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.” (Orin Dáfídì 37:28, NW) Àwọn tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run, ní àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, títí kan òye ìdájọ́ òdodo.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27.
Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú sọ nípa ‘àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin tí wọ́n ń ṣe ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá.’ Nípa báyìí, wọ́n “fi ọ̀ràn òfin hàn gbangba pé a kọ ọ́ sínú ọkàn àyà wọn, nígbà tí ẹ̀rí ọkàn wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí àti, láàárín ìrònú tiwọn fúnra wọn, à ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tàbí à ń gbè wọ́n lẹ́yìn pàápàá.” (Róòmù 2:14, 15) Bẹ́ẹ̀ ni, a fi agbára ẹ̀rí ọkàn jíǹkí ẹ̀dá ènìyàn—òye inú láti mọ ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Ó ṣe kedere pé, a bí àìní fún ìdájọ́ òdodo mọ́ ènìyàn.
Ohun tí ó tún ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ìyánhànhàn tí ènìyàn ní fún ìdájọ́ òdodo ni ayọ̀, nítorí Orin Dáfídì 106:3 (NW), polongo pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa ìdájọ́ òdodo mọ́, àwọn tí ń ṣe òdodo ní gbogbo ìgbà.” Àmọ́, èé ṣe tí kò fi tí ì ṣeé ṣe fún ènìyàn láti mú ayé onídàájọ́ òdodo wá?
Èé Ṣe Tí Ènìyàn Fi Kùnà?
Ìdí pàtàkì kan tí ó wà fún kíkùnà láti mú ayé onídàájọ́ òdodo wá ni àbààwọ́n tí a ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ inú ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Ẹ̀ṣẹ̀ ni àbààwọ́n náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a dá wọn láìlábùkù, Ádámù àti Éfà pinnu láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n sì tipa báyìí sọ ara wọn di ẹlẹ́ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:1-6) Nítorí èyí, wọ́n fi ogún ẹ̀ṣẹ̀, ìtẹ̀sí láti hùwà àìtọ́, sílẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn.
Àwọn ìwà àbímọ́ni bí ìwọra àti ẹ̀tanú kò ha jẹ́ àbájáde ìtẹ̀sí láti dẹ́ṣẹ̀ bí? Àwọn ìwà wọ̀nyí kò ha sì dá kún àìṣèdájọ́ òdodo tí ó wà nínú ayé bí? Họ́wù, ìwọra ni gbòǹgbò mímọ̀ọ́mọ̀ ba àyíká jẹ́ àti fífi ọrọ̀ ajé nini lára! Dájúdájú, ẹ̀tanú ni ó wà lẹ́yìn gbọ́nmisi-omi-ò-to láàárín ẹ̀yà kan sí èkejì àti àìṣèdájọ́ òdodo láàárín ẹ̀yà ìran kan sí èkejì. Irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ tún ń sún àwọn ènìyàn láti fipá jalè, láti rẹ́ni jẹ, kí wọ́n sì hùwà lọ́nà tí yóò pa àwọn ẹlòmíràn lára.
Kódà àwọn ìsapá tí a ṣe pẹ̀lú ète rere lọ́kàn láti ṣe ìdájọ́ òdodo àti láti fi inú rere hàn sábà máa ń forí ṣánpọ́n nítorí ìsúnniṣe wa láti dẹ́ṣẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ jẹ́wọ́ pé: “Rere tí mo dàníyàn ni èmi kò ṣe, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò dàníyàn ni èmi fi ń ṣèwà hù.” Ó ń bá a nìṣó láti ṣàlàyé ìjàkadì náà, ní sísọ pé: “Ní ti gidi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí nínú àwọn ẹ̀yà ara mi òfin mìíràn tí ń bá òfin èrò inú mi jagun tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.” (Róòmù 7:19-23) Ó ṣeé ṣe pé, àwa lónìí ní irú ìwọ̀yá ìjà bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tí àìṣèdájọ́ òdodo fi ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́.
Ọ̀nà tí ẹ̀dá ènìyàn gbà ń ṣàkóso tún ń dá kún àìṣèdájọ́ òdodo nínú ayé. Ní gbogbo ilẹ̀, òfin ń bẹ, àwọn agbófinró sì wà pẹ̀lú. Dájúdájú, àwọn adájọ́ àti kóòtù náà wà. Òótọ́ ni pé, àwọn ènìyàn onípinnu kan ti gbìyànjú láti gbé ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lárugẹ, kí wọ́n sì rí sí i pé ìdájọ́ òdodo tí kò fì síbì kan wà fún gbogbo ènìyàn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ ìsapá wọn ti forí ṣánpọ́n. Èé ṣe? Nígbà tí ó ń ṣàkópọ̀ àwọn kókó abájọ tí ó wé mọ́ ìkùnà wọn, Jeremáyà 10:23 sọ pé: “Olúwa! èmi mọ̀ pé, ọ̀nà ènìyàn kò sí ní ipa ara rẹ̀: kò sí ní ipa ènìyàn tí ń rìn láti tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀.” Níwọ̀n bí a ti sọ ọ́ dàjèjì sí Ọlọ́run, kò lè ṣeé ṣe fún ènìyàn láti gbé ayé onídàájọ́ òdodo kalẹ̀.—Òwe 14:12; Oníwàásù 8:9.
Ìdènà ńlá fún ìsapá ènìyàn láti gbé ayé onídàájọ́ òdodo kalẹ̀ ni Sátánì Èṣù. Bíbélì sọ kedere pé áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ náà, Sátánì, ni “apànìyàn” àti “òpùrọ́” ìpilẹ̀ṣẹ̀, àti pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (Jòhánù 8:44; Jòhánù Kíní 5:19) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí i gẹ́gẹ́ bí “ọlọ́run ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí.” (Kọ́ríńtì Kejì 4:3, 4) Nítorí tí ó kórìíra òdodo, Sátánì ń jà fitafita láti gbé ìwà ibi lárugẹ. Níwọ̀n bí ó bá ṣì ń darí ayé, àìṣèdájọ́ òdodo onírúurú gbogbo àti àwọn ègbé tí ń tẹ̀yìn rẹ̀ yọ yóò gbé aráyé dè.
Gbogbo èyí ha túmọ̀ sí pé àìṣèdájọ́ òdodo kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ láwùjọ ẹ̀dá ènìyàn bí? Ayé onídàájọ́ òdodo ha jẹ́ àlá tí kò lè ṣẹ bí?
Ayé Onídàájọ́ Òdodo Dájú—Lọ́nà Wo?
Kí ìrètí ayé onídàájọ́ òdodo baà lè dájú, aráyé ní láti yíjú sí orísun kan tí ó lè mú àwọn okùnfà àìṣèdájọ́ òdodo kúrò. Ṣùgbọ́n ta ní lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, kí ó sì mú Sátánì àti ìṣàkóso rẹ̀ kúrò pátápátá? Ní kedere, kò sí ẹ̀dá ènìyàn tàbí àjọ èyíkéyìí tí ẹ̀dá ènìyàn gbé kalẹ̀, tí ó lè ṣe irú iṣẹ́ tí ń páni láyà bẹ́ẹ̀. Jèhófà Ọlọ́run nìkan ni ó lè ṣe é! Nípa rẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:4, NW) Nítorí pé ó jẹ́ “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo,” Jèhófà fẹ́ kí aráyé gbádùn ìyè nínú ayé onídàájọ́ òdodo.—Orin Dáfídì 37:28, NW.
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣètò Ọlọ́run láti mú ayé onídàájọ́ òdodo wá, àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun kan wà tí àwa ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú àwọn wọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (Pétérù Kejì 3:13) “Àwọn ọ̀run tuntun” wọ̀nyí kì í ṣe ọ̀run tí a lè fojú rí. Ọlọ́run dá ọ̀run tí a lè fojú rí lọ́nà pípé, wọ́n sì ń mú ògo wá fún un. (Orin Dáfídì 8:3; 19:1, 2) “Àwọn ọ̀run tuntun” náà jẹ́ ìṣàkóso tuntun lórí ayé. “Àwọn ọ̀run” ti ìsinsìnyí ní àwọn ìṣàkóso tí ènìyàn gbé kalẹ̀ nínú. Láìpẹ́, nígbà ogun Ọlọ́run ti Amágẹ́dọ́nì, ìwọ̀nyí yóò fi àyè sílẹ̀ fún “àwọn ọ̀run tuntun”—Ìjọba rẹ̀, tàbí ìṣàkóso rẹ̀ ti ọ̀run. (Ìṣípayá 16:14-16) Jésù Kristi ni Ọba Ìjọba náà. Ní mímú òpin pátápátá dé bá ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn, ìjọba yìí yóò ṣàkóso títí ayérayé.—Dáníẹ́lì 2:44.
Nígbà náà, kí ni “ilẹ̀ ayé tuntun”? Kì í ṣe pílánẹ́ẹ̀tì tuntun, nítorí Ọlọ́run dá ilẹ̀ ayé lọ́nà tí ó pegedé fún ẹ̀dá ènìyàn láti gbé, ìfẹ́ rẹ̀ sì ni pé kí ó wà títí láé. (Orin Dáfídì 104:5) “Ilẹ̀ ayé tuntun” náà ń tọ́ka sí àwùjọ tuntun ti àwọn ènìyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1; Orin Dáfídì 96:1) “Ilẹ̀ ayé” tí a óò pa run ní àwọn ènìyàn tí wọ́n sọ ara wọn di apá kan ètò ìgbékalẹ̀ búburú ti àwọn nǹkan yìí nínú. (Pétérù Kejì 3:7) “Ilẹ̀ ayé tuntun” tí ó rọ́pò wọn yóò jẹ́ àpapọ̀ àwọn ìránṣẹ́ tòótọ́ ti Ọlọ́run, tí wọ́n kórìíra ìwà ibi, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo. (Orin Dáfídì 37:10, 11) Nípa báyìí, ayé Sátánì yóò kọjá lọ.
Ṣùgbọ́n kí ni ó wà ní ìpamọ́ fún Sátánì? Àpọ́sítélì Jòhánù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ó [Kristi Jésù] . . . gbá dírágónì náà mú, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí í ṣe Èṣù àti Sátánì, ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Ó sì fi í sọ̀kò sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà ó sì tì í ó sì fi èdìdì dí i lórí rẹ̀, kí ó má baà ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́.” (Ìṣípayá 20:1-3) Sátánì tí a fi ọ̀gbàrà ẹ̀wọ̀n dè kì yóò ní ipa kankan lórí aráyé gẹ́gẹ́ bíi ti ẹlẹ́wọ̀n kan tí a jù sí àjàalẹ̀. Ẹ wo irú ìtura tí èyí yóò jẹ́ fún aráyé, ní wíwá gẹ́gẹ́ bí òléwájú fún ayé onídàájọ́ òdodo! Ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún, a óò pa Sátánì run pátápátá.—Ìṣípayá 20:7-10.
Ṣùgbọ́n, ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti jogún ńkọ́? Jèhófà ti pèsè ìpìlẹ̀ fún mímú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò tẹ́lẹ̀. “Ọmọkùnrin ènìyàn [Jésù Kristi] ti wá, . . . kí ó . . . fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà kan ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Ọ̀rọ̀ náà “ìràpadà” dúró fún iye owó tí a béèrè fún ríra àwọn tí ó wà nígbèkùn pa dà. Jésù fi ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ san iye owó náà gẹ́gẹ́ bí ìràpadà láti dá aráyé nídè.—Kọ́ríńtì Kejì 5:14; Pétérù Kíní 1:18, 19.
Ẹbọ ìràpadà Jésù lè ṣàǹfààní fún wa nísinsìnyí pàápàá. Nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, a lè gbádùn ìdúró mímọ́ níwájú Ọlọ́run. (Ìṣe 10:43; Kọ́ríńtì Kíní 6:11) Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, ìràpadà yóò mú kí bíbọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá ṣeé ṣe fún aráyé. Ìwé tí ó gbẹ̀yìn nínú Bíbélì ṣàpèjúwe “odò omi ìyè” ìṣàpẹẹrẹ kan, tí ń ṣàn jáde láti orí ìtẹ́ Ọlọ́run, tí àwọn igi eléso ìṣàpẹẹrẹ tí ó ní ewé tí ó wà “fún wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn” sì wà ní bèbè rẹ̀. (Ìṣípayá 22:1, 2) Ohun tí Bíbélì gbé yọ níhìn-ín dúró fún ìpèsè àgbàyanu tí Ẹlẹ́dàá ṣe fún mímú kí aráyé bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù. Lílo ìpèsè yí dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́ yóò sọ àwọn ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.
Ìgbésí Ayé Nínú Ayé Onídàájọ́ Òdodo
Ronú nípa bí ìgbésí ayé yóò ṣe rí lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba. Ìwà ipá àti ìwà ọ̀daràn yóò di ohun àtijọ́. (Òwe 2:21, 22) Àìṣèdájọ́ òdodo ní ti ọrọ̀ ajé yóò kọjá lọ. (Orin Dáfídì 37:6; 72:12, 13; Aísáyà 65:21-23) Gbogbo àmì àìbánilò lọ́gbọọgba láwùjọ, ẹ̀yà ìran, ẹ̀yà èdè ni a óò pa rẹ́ pátápátá. (Ìṣe 10:34, 35) Ogun àti ohun ìjà ogun kì yóò sí mọ́. (Orin Dáfídì 46:9) A óò jí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn òkú dìde sí ìyè nínú ayé kan tí ó bọ́ lọ́wọ́ àìṣèdájọ́ òdodo. (Ìṣe 24:15) Olúkúlùkù yóò gbádùn ìlera pípé, tí ó sì jí pépé. (Jóòbù 33:25; Ìṣípayá 21:3, 4) “Nínú òótọ́,” ni Bíbélì mú un dá wa lójú pé, “òun [Jésù Kristi] yóò mú ìdájọ́ òdodo wá.”—Aísáyà 42:3, NW.
Ní báyìí ná, a lè nírìírí àìṣèdájọ́ òdodo, ṣùgbọ́n kí a má ṣe jẹ́ aláìṣèdájọ́ òdodo nígbà tí a bá hùwà pa dà. (Míkà 6:8) Àní nígbà tí a bá ní láti fara da àìṣèdájọ́ òdodo, ǹjẹ́ kí a máa bá a lọ láti ní ẹ̀mí ìfojúsọ́nà fún rere. Ayé onídàájọ́ òdodo tí a ṣèlérí yóò dé láìpẹ́. (Tímótì Kejì 3:1-5; Pétérù Kejì 3:11-13) Ọlọ́run Olódùmarè ti sọ ọ́, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì “rí.” (Aísáyà 55:10, 11) Ìsinsìnyí ni àkókò náà láti múra sílẹ̀ fún ìgbésí ayé nínú ayé onídàájọ́ òdodo náà nípa kíkọ́ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa.—Jòhánù 17:3; Tímótì Kejì 3:16, 17.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
A óò pa gbogbo àmì àìṣèdájọ́ òdodo rẹ́ pátápátá nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí