ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 8/15 ojú ìwé 20-21
  • “Ẹ̀bùn Ńlá” Fáwọn Ará Poland

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ̀bùn Ńlá” Fáwọn Ará Poland
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ọ̀rọ̀ Tó Wọ́pọ̀ Lẹ́nu Àwọn Èèyàn” Ni Wọ́n Fi Túmọ̀ Rẹ̀
  • Ọ̀kan Lára Àwọn Ẹ̀bùn Tó Dára Jù Lọ
  • “Àwọn Ará ní Poland”—Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Ṣenúnibíni sí Wọn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìsìn ní Poland Òde Òní
    Jí!—1998
  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé Fáwọn Tó Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ọ̀kẹ́ Àìmọye Èèyàn Mọyì Rẹ̀ Kárí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 8/15 ojú ìwé 20-21

“Ẹ̀bùn Ńlá” Fáwọn Ará Poland

NÍ ỌJỌ́ kẹfà oṣù July ọdún 1525, Albrecht ti Hohenzollern tó jẹ́ alákòóso ilẹ̀ Ducal Prussia kéde pé ìsìn Luther ni kí àwọn èèyàn ilẹ̀ Ducal Prussia máa ṣe. Bí Ducal Prussia tó wà lábẹ́ ìjọba ilẹ̀ Poland nígbà yẹn ṣe di ibi àkọ́kọ́ tí ìjọba ti fara mọ́ ẹ̀kọ́ Martin Luther ní Yúróòpù nìyẹn.

Alákòóso tó ń jẹ́ Albrecht yìí fẹ́ láti sọ Königsberg tó jẹ́ olú ìlú East Prussia di ojúkò ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Ó kọ́ Yunifásítì kan sílùú náà ó sì gbówó sílẹ̀ pé kí wọ́n máa tẹ àwọn ìwé tí Luther kọ jáde láwọn èdè kan. Lọ́dún 1544, ó tún pàṣẹ pé èdè àwọn ará Poland tó wà lábẹ́ àkóso òun ni kí wọ́n máa fi ka ẹsẹ Bíbélì sétígbọ̀ọ́ kálukú wọn. Àmọ́ kò tíì sí Bíbélì kankan lédè Polish.

“Ọ̀rọ̀ Tó Wọ́pọ̀ Lẹ́nu Àwọn Èèyàn” Ni Wọ́n Fi Túmọ̀ Rẹ̀

Láti lè wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà, Albrecht bẹ̀rẹ̀ sí í wá ẹni tó máa lè rí sí i pé Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì wà lédè Polish. Ní nǹkan bí ọdún 1550, ó fa iṣẹ́ náà lé Jan Seklucjan lọ́wọ́. Ọ̀gbẹ́ni Jan Seklucjan yìí jẹ́ òǹkọ̀wé, ó ń tàwé, ó sì tún ń tẹ̀wé. Ilé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì tó wà ní Leipzig ló lọ, wọ́n sì sọ pé àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ń bínú sí i látàrí bó ṣe ń tan ẹ̀kọ́ ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì kálẹ̀. Àní sísá ló tiẹ̀ sá lọ sí Königsberg tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ kó má bàa jẹ́jọ́ fún títàn tó ń tan ẹ̀kọ́ ìsìn yìí kálẹ̀.

Ọ̀gbẹ́ni Jan Seklucjan ń hára gàgà láti rí i pé Ìwé Mímọ́ wà lédè Polish. Ní nǹkan bí ọdún kan péré lẹ́yìn tí Albrecht gbéṣẹ́ náà lé e lọ́wọ́, wọ́n tú Ìhìn Rere Mátíù tán, wọ́n sì tẹ àwọn ẹ̀dà rẹ̀ àkọ́kọ́. Wọ́n ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ìwé Mátíù àti àlàyé etí ìwé sínú ìtumọ̀ náà, èyí tó jẹ́ kéèyàn lè rí àwọn ọ̀nà míì téèyàn tún lè gbà sọ ohun tó wà nínú àwọn ẹsẹ kan. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí wọ́n fi tẹ ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n ti tú parí pa pọ̀ sọ́nà kan. Ọ̀gbẹ́ni Seklucjan ló sì ṣe kòkárí títẹ̀ rẹ̀. Láàárín ọdún mẹ́ta péré, ó ti tẹ gbogbo Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.

Ẹni tó túmọ̀ Bíbélì náà lọ wo àwọn Bíbélì tó wà lédè Gíríìkì kó bàa lè ṣe ìtumọ̀ tó péye. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀rọ̀ ìṣáájú tó wà nínú Bíbélì èdè Polish tí wọ́n tẹ̀ lọ́dún 1551 sọ pé “ó tún lọ wo” àwọn Bíbélì tó wà lédè Latin “àtàwọn èdè míì.” Ìwé kan tí ọ̀gbẹ́ni Stanisław Rospond kọ, tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Studies on the Polish Language of the 16th Century, sọ pé “èdè tó dùn tó sì lọ geere” ni wọ́n fi túmọ̀ Bíbélì èdè Polish yìí. Ọ̀gbẹ́ni Rospond sọ pé ẹni tó túmọ̀ rẹ̀ ò lo àwọn “ọ̀rọ̀ ńlá ńlá” táwọn tí kì í ṣe ọ̀mọ̀wé ò lè mọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbìyànjú láti lo “àwọn ọ̀rọ̀ tó wọ́pọ̀ lẹ́nu àwọn èèyàn” tó ń sọ èdè Polish.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Seklucjan ló ṣe kòkárí iṣẹ́ ìtumọ̀ yìí, ẹ̀rí fi hàn pé òun gan-an kọ́ ló túmọ̀ rẹ̀. Ta wá ni ògbóǹkangí olùtumọ̀ yìí? Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Stanisław Murzynowski ni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé díẹ̀ ló fi lé lọ́mọ ogún ọdún nígbà tí Seklucjan gbé iṣẹ́ bàǹtà-banta náà lé e lọ́wọ́.

Abúlé ni wọ́n bí Murzynowski sí, àmọ́ nígbà tó tó iléèwé lọ, bàbá rẹ̀ ní kó lọ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Gíríìkì àti Hébérù nílùú Königsberg. Nígbà tó ṣe tán níbẹ̀, ó wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì tó wà nílùú Wittenberg lórílẹ̀-èdè Jámánì, ó sì ṣeé ṣe kó rí Martin Luther níbẹ̀. Ọ̀dọ́kùnrin Murzynowski kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ olùkọ́ kan tó ń jẹ́ Philipp Melanchthon, ó sì dájú pé olùkọ́ yìí kọ́ ọ lédè Gíríìkì àti Hébérù débi tó fi mọ̀ ọ́n dáadáa. Nígbà tó ṣe, Murzynowski lọ kàwé sí i ní Ítálì. Lẹ́yìn náà, ó padà sí Königsberg ó sì ń ṣiṣẹ́ fún Albrecht alákòóso Ducal Prussia.

Nínú ìwé tí Maria Kossowska kọ, tó pe orúkọ rẹ̀ ní The Bible in the Polish Language, ó ní: “Murzynowski tẹra mọ́ iṣẹ́ náà, iṣẹ́ rẹ̀ sì péye. Àmọ́ kò polongo ara rẹ̀, kò wá ipò ńlá, kò sì sọ pé kí wọ́n kọ orúkọ òun sí ojú ewé tí wọ́n kọ àkọlé Bíbélì náà sí.” Àní ọ̀dọ́kùnrin yìí tiẹ̀ sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Mi ò mọ èdè Látìn kọ dáadáa, bẹ́ẹ̀ náà sì ni èdè Polish.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò dá ara rẹ̀ lójú, iṣẹ́ ńlá tó ṣe mú kí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà lédè Polish. Ọ̀gbẹ́ni Seklucjan tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ sọ pé Bíbélì náà jẹ́ “ẹ̀bùn ńlá” fáwọn ará Poland.

Ọ̀kan Lára Àwọn Ẹ̀bùn Tó Dára Jù Lọ

Látìgbà tí wọ́n ti parí iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì àkọ́kọ́ lédè Polish, ọ̀pọ̀ Bíbélì ni wọ́n ti tún túmọ̀ sédè náà. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1994, wọ́n mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè yẹn. Nígbà tó sì di ọdún 1997, wọ́n mú odindi Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè náà. Àwọn tó túmọ̀ Bíbélì yìí kò polongo ara wọn, wọ́n sì rí i dájú pé àwọn túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó péye tó sì bá ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà sọ̀rọ̀ lóde òní mu, kì í ṣe lọ́nà táwọn èèyàn ń gbà sọ̀rọ̀ ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún.

Lónìí, apá kan Bíbélì tàbí odindi rẹ̀ wà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ó lé irínwó [2,400] èdè. Tó o bá ní Bíbélì lédè rẹ, tó sì jẹ́ èyí tí wọ́n túmọ̀ lọ́nà tó péye, ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn dídára jù lọ tó o lè rí gbà lo ní yẹn o. Ó jẹ́ ẹ̀bùn tí Jèhófà Ọlọ́run fún ọ kó lè máa tọ́ ọ sọ́nà.—2 Tímótì 3:15-17.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Òkúta tí wọ́n fi ń rántí Stanisław Murzynowski tó túmọ̀ “Májẹ̀mú Tuntun” sédè Polish

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Orí kẹta ìwé Mátíù tí Stanisław Murzynowski túmọ̀

[Credit Line]

Dzięki uprzejmości Towarzystwa Naukowego Płockiego

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́