Ìsìn ní Poland Òde Òní
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ POLAND
KÁRÍ ayé, a mọ àwọn ará Poland sí ẹni tí ń káràmáásìkí ọ̀ràn ìsìn. Ní gidi, nǹkan bí ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn ló sọ pé ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì làwọn.
Wọ́n máa ń fọwọ́ gidi mú àwọn ayẹyẹ ìsìn ní orílẹ̀-èdè yìí, wọ́n sì wà lára àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ orílẹ̀-èdè náà. Ní pàtàkì, ní àwọn àrọko, àwọn ayẹyẹ ọdún ìsìn máa ń dùn yùngbà, wọ́n sì máa ń ṣe pọ̀pọ̀ṣìnṣìn, àwọn ọlọ́dún máa ń wọ aṣọ ìbílẹ̀, àwọn ènìyàn sì máa ń ṣe eré ìdárayá.
Àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn sábà máa ń gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ àti àwọn ìrìn àjò sí àwọn ibi mímọ́ ìsìn àti àwọn ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ onísìn jáde. A ń gbé àwọn ayẹyẹ ìgbéyàwó, ayẹyẹ ọjọ́ ẹni mímọ́, batisí, àti Gbígba Ara Olúwa ní ìgbà àkọ́kọ́, tí a bá ṣe ní ṣọ́ọ̀ṣì, lárugẹ bákan náà.
Ní 1978, Karol Wojtyła, láti Poland, di Póòpù John Paul Kejì. Èyí túbọ̀ fún ẹ̀sìn Kátólíìkì níṣìírí ní Poland. Ògìdìgbó ènìyàn tí ń yangàn máa ń lọ kí ọmọ ilẹ̀ wọn káàbọ̀ nígbàkigbà tó bá ṣèbẹ̀wò sí ilẹ̀ ìbí rẹ̀.
Gbogbo ìgbòkègbodò ìsìn wọ̀nyí ń mú kí àwọn tí kì í gbé Poland rò pé ọ̀ràn ìsìn lágbára lọ́dọ̀ àwọn ará Poland, wọ́n sì ń fi hàn ní gbangba. Bí ó ti wù kí ó rí, ní Poland, àwọn aṣáájú Kátólíìkì àti àwọn alákìíyèsí mìíràn ń ṣàníyàn lórí ìyípadà tí ń bá èrò àti àṣà àwọn ọmọ ìjọ tí ń pọ̀ sí i.
Èrò Àwọn Ará Poland
Àwọn gbajúmọ̀ aṣojú àwọn onípò nínú ìjọ Kátólíìkì ilẹ̀ Poland àti àwọn akọ̀ròyìn àti àwọn olùwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ àárín àwùjọ ní èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ipò tí ẹ̀sìn Kátólíìkì wà ní Poland lónìí. Léraléra ni àwọn ènìyàn jàǹkànjàǹkàn ń sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ lórí ìwà ọ̀daràn tí ń burú sí i, ìwà búburú tí ń gbilẹ̀ sí i, àti bí ìfẹ́ tí àwọn ènìyàn ní sí àwọn ẹ̀kọ́ àti ìṣe ìsìn ṣe ń dín kù. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ náà ń dá lórí ìbéèrè náà pé, Ipa wo ni ọ̀nà ìjọsìn Roman Kátólíìkì tó lókìkí náà ń ní lórí ìgbésí ayé ojoojúmọ́ àwọn ènìyàn?
Bí àpẹẹrẹ, Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ilẹ̀ Poland, Józef Glemp, rí i pé àìkàsìnsí ń pọ̀ sí i láàárín àwọn ènìyàn, ó sì sọ̀rọ̀ lórí bí ó ṣe yẹ kí àwọn ènìyàn gbógun ti bí ìgbàgbọ́ àti àṣà kèfèrí ṣe fẹ́ máa gbilẹ̀ ní orílẹ̀-èdè náà. Nínú ìwé ìròyìn Ład, ti Kátólíìkì, òǹkọ̀wé Wojciech Chudy túbọ̀ ṣàlàyé sí i lórí ọ̀ràn náà. Ó wí pé: ‘Ó yẹ kí a ṣàyẹ̀wò ọ̀ràn tó ti ń dààmú àwọn àlùfáà, àwọn onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, àti àwọn afìṣemọ̀rònú nípa ìsìn fún ọ̀pọ̀ ọdún—ìyàtọ̀ gédégbé tó wà láàárín ọ̀nà ìgbésí ayé ti ìsìn àti ti ojoojúmọ́. Àwọn ènìyàn ń jókòó gbọ́ ìwàásù, àmọ́ ní kété tí wọ́n bá ti jáde kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n ti gbàgbé gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ti Ọlọ́run. Wọ́n ti bọ́ sínú ayé mìíràn, ayé ìlépa ọ̀ràn ara ẹni, tí olúkúlùkù ń lo ìgbésí ayé rẹ̀ bí pé Ọlọ́run kò sí rárá.’
Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Henryk Muszyński, tó jẹ́ igbákejì ààrẹ Àjọ Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù, ṣe àfikún yìí pé: “Ìhìnrere kò tíì yí wa padà nínú lọ́hùn-ún. Nígbà tí a bá ń kaye ènìyàn tí ń kún ìjọ nìkan ni àwọn ará Poland ń jẹ́ Kristẹni. Òtítọ́ tí kò ṣeé sẹ́ ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ń ka jíjẹ́ Kristẹni sí àṣà kan ju bí wọ́n ti kà á sí ìsìn tó lọ.”
Ìyípadà Ohun Tí A Kà sí Pàtàkì—Ìyípadà Bí A Ṣe Ń Hùwà
Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn àgbààgbà aṣojú ṣọ́ọ̀ṣì ń dààmú nípa àwọn ìyípadà ńláńlá tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ohun tí àwọn ènìyàn kà sí pàtàkì àti ìhùwà wọn. Ìdí kan ni pé, ó jọ pé àwọn ohun mìíràn ti ń gba àyè ìfọkànsìn onísìn tó wà látijọ́.
Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwádìí kan nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, àwọn ọmọ ilẹ̀ Poland fi ọ̀ràn ìdílé sí àyè ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé, lẹ́yìn náà ni àìlábòsí, àìṣègbè, inúure, àti ìṣeéfọkàntán. Ipò kẹrìndínlógún ni àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ọlọ́run àti ìsìn wà. Ìyọrísí èyí ni pé àwọn tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ń dín kù, láàárín àwọn tí wọ́n tilẹ̀ pe ara wọn ní onígbàgbọ́ pàápàá.
Àwọn àkọsílẹ̀ oníṣirò tí ń fi hàn pé àìka ẹ̀kọ́ ìsìn sí ti gbilẹ̀ gan-an ń da àwọn bíṣọ́ọ̀bù ilẹ̀ Poland pàápàá láàmú. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwádìí kan tí Irena Borowik, láti Yunifásítì Jagielloński, ṣe nípa ọ̀ràn ìsìn, ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún péré lára àwọn tó ṣèwádìí lọ́dọ̀ wọn ló sọ pé àwọn gbà pé ìyè wà lẹ́yìn ikú, ìpín 47 nínú ọgọ́rùn-ún rò pé ó yẹ kí wọ́n gba àwọn àlùfáà láyè láti máa gbéyàwó, ìpín 64 nínú ọgọ́rùn-ún sì fọwọ́ sí ìkọ̀sílẹ̀.
Ìwádìí mìíràn, tí ìwé ìròyìn Wprost gbé jáde, fi hàn pé, “ìpín 69 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Poland dẹ́bi fún bí ṣọ́ọ̀ṣì ṣe ka lílo àwọn oògùn málòóyún léèwọ̀, ìpín 56 nínú ọgọ́rùn-ún kò fara mọ́ òfin tí wọ́n fi de ìṣẹ́yún, ìpín 54 nínú ọgọ́rùn-ún sì fọwọ́ sí ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó.” Àwọn ìṣirò wọ̀nyí fi ìyapa èrò àwọn ènìyàn nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà hàn.
Láàárín ẹ̀wádún méjì tó kọjá, ṣọ́ọ̀ṣì ti gboríyìn nítorí ipa tí ó kó ní lílòdì sí ètò ìjọba Kọ́múníìsì. Bí ó ti wù kí ó rí, ní báyìí, ó jọ pé bí ṣọ́ọ̀ṣì ṣe ń lọ́wọ́ sí àwọn ọ̀ràn ìṣèlú àti ti àwùjọ nìṣó ti ń fa ìbínú, ó tilẹ̀ ti ń yọrí sí àìfohùnṣọ̀kan ńlá láàárín àwọn ọmọ ìjọ àti àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì.
Kí Ni Ojútùú Gidi Náà?
Ṣáájú àwọn ìyípadà mánigbàgbé nínú ìṣèlú tó wáyé ní 1989, ìjọba ti gbé àwọn ìlànà ìwà híhù pàtó kan kalẹ̀. Púpọ̀ nínú ìwọ̀nyẹn kò sí mọ́ báyìí. Ètò ìṣèlú tuntun ti mú ìjọba tiwa-n-tiwa wá pẹ̀lú òmìnira ara ẹni, bákan náà ló sì fa ìgbìyànjú láti rọ́wọ́ mú nínú ètò ọrọ̀ ajé ìbánidíje tí olúkúlùkù ti ń ṣe bó ti fẹ́. Ọ̀pọ̀ ènìyàn lérò pé àwùjọ ilẹ̀ Poland kò múra sílẹ̀ fún irú ìyípadà tegbòtigaga bẹ́ẹ̀. Kí la nílò?
Láti rọ́wọ́ mú ní ti ìwàrere àti ipò tẹ̀mí nínú ayé òde òní gba ìgbàgbọ́ tí a gbé karí ohun kan to lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ju àṣà tàbí ayẹyẹ ìsìn lọ. Ẹnì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ gidi nínú ìmọ̀ àti òye tí a ní fúnra ẹni nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì.
Póòpù John Paul Kejì fúnra rẹ̀ sọ láìpẹ́ yìí pé ó yẹ kí àwọn Kristẹni máa ka Ìwé Mímọ́ déédéé. Ó ké sí àwọn ènìyàn “láti túbọ̀ sọ lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run léraléra, lọ́nà tó jinlẹ̀, di àṣà.” Ó fi kún un pé: “Kíkọ́ láti ka Ìwé Mímọ́ jẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe fún onígbàgbọ́: òun ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú àtẹ̀gùn kan, tí ń bá a lọ pẹ̀lú ṣíṣe àṣàrò, àti nípa bẹ́ẹ̀, gbígbàdúrà tọkàntara.” Póòpù rọni pé, “kí ẹnikẹ́ni tó bá ń wá òtítọ́ . . . máa fi oúnjẹ Ọ̀rọ̀ Ìyè bọ́ ara rẹ̀ lójoojúmọ́.”
Ní ọ̀rúndún mọ́kàndínlógún sẹ́yìn, kí ìgbésí ayé tó di kàráǹgídá, tí kò sì dúró sójú kan, bó ṣe rí nísinsìnyí, Jésù Kristi bẹ Ọlọ́run pé kí ó dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lọ́wọ́ àwọn ipá tí ń sọni di aláàárẹ̀ nípa tẹ̀mí tó yí wọn ká. Ó gbàdúrà pé: “Sọ wọ́n di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Ìdí tí Bíbélì sì fi ‘jẹ́ òtítọ́’ ni pé, ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe ti ènìyàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ kan pé: “Nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—1 Tẹsalóníkà 2:13.
Bíbélì lè fún wa ní ohun tí a nílò láti dáàbò bo ara wa nínú ayé aláìlẹ́mìí-ìsìn yìí nítorí pé ó jẹ́ “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” ó sì ‘jẹ́ òtítọ́.’ Bíbélì sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tímótì 3:16, 17.
Ọ̀pọ̀ ènìyàn tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn àti olóye ní Poland àti kárí ayé ń rí i pé kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra ẹni ń pèsè ìpìlẹ̀ tó lágbára fún ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti ète rẹ̀. Irú ìgbàgbọ́ yìí ní ń fún wọn lókun láti gbé ojúlówó ìgbésí ayé Kristẹni nínú ayé òde òní tí ó túbọ̀ ń di aláìlẹ́mìí-ìsìn.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 16]
“Nígbà tí a bá ń kaye ènìyàn tí ń kún ìjọ nìkan ni àwọn ará Poland ń jẹ́ Kristẹni.”—Bíṣọ́ọ̀bù àgbà kan ní Poland
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]
Àìka ẹ̀kọ́ ìsìn sí ti gbilẹ̀ gan-an
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
POLAND