Èé Ṣe Tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kò Fi Nípa Lórí Àwọn Ènìyàn Mọ́?
“Gbogbo àwọn onígbàgbọ́ Stoiki ni Stoiki; ṣùgbọ́n nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù, àwọn Kristian dà?”
RALPH WALDO EMERSON, ÒǸKỌ̀WÉ ÀTI ELÉWÌ ỌMỌ AMERICA NÍ Ọ̀RÙNDÙN KỌKÀNDÍNLÓGÚN.
“Ọ̀ṢỌ́Ọ́RỌ́ abiyamọ kan ṣàlàyé pé: “Ọmọ ìjọ Kátólíìkì ni mi—ṣùgbọ́n kì í ṣe èyí tí ó ń fi ìlànà rẹ̀ ṣèwàhù.” Ọ̀dọ́langba kan fi kún un pé: “Kò sí ohun tó kàn mí nípa ìsìn.” Ohun tí wọ́n sọ jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí ìran àwọn èwe ìwòyí ilẹ̀ Europe ń sọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí wọn—tàbí, kí ó jẹ́ pé àwọn òbí wọn àgbà—ṣì ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì síbẹ̀, ìgbàgbọ́ ìsìn kò tí ì dí àlàfo ìran náà.
Èé ti wá ṣe tí àwọn àṣà ìsìn tí ìrandíran ọmọ ilẹ̀ Europe kà sí pàtàkì nígbà kan rí fi dí ohun tí àwọn ènìyàn kọ̀ sílẹ̀?
Ìbẹ̀rù Kò Tì Wọ́n Mọ́
Fún àìmọye ọ̀rúndún, ìbẹ̀rù iná ọ̀run àpáàdì tàbí pọ́gátórì ti ni ipa alágbára lórí àwọn ara ilẹ̀ Europe. Àwọn ìwàásù gbígbóná janjan àti àwọn àwòrán inú ṣọ́ọ̀ṣì tí ń fi ọ̀run àpáàdì oníná àjóòkú hàn sún àwọn ọmọ ìjọ láti máa ronú pé wíwá sí ṣọ́ọ̀ṣì pẹ̀lú ìtara ìsìn nìkan ló lè gbà wọ́n là lọ́wọ́ ègún. Síwájú sí i, ìwé Catechism of the Catholic Church sọ pé “Ṣọ́ọ̀ṣì mú un lọ́ràn-anyàn fún àwọn onígbàgbọ́ ‘láti lọ́wọ́ nínú Ààtò Ìsìn Mímọ́ lọ́jọ́ Sunday àti ní àwọn ọjọ́ àsè.’”a Ní àwọn agbègbè ìgbèríko, àwọn ènìyàn tún máa ń nípa lórí ẹni dé àyè kan—wọ́n retí kí gbogbo ènìyàn lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ní ọjọ́ Sunday.
Àmọ́ ìgbà ti yí padà. Àwọn ènìyàn ti wà lómìnira láti ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́ nísinsìnyí. Ìbẹ̀rù kò tì wọ́n mọ́. Ọ̀rọ̀ nípa iná ọ̀run àpáàdì tí di ohun tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì ilẹ̀ Europe ni kò kúkú gbà á gbọ́.
Ohun tí ń ṣẹlẹ̀ gan-an ni pé, wọn kò ka “ẹ̀ṣẹ̀” pípa ìsìn Máàsì ọjọ́ Sunday jẹ sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣe bàbàrà mọ́. Tirso Vaquero, àlùfáà Kátólíìkì kan ní Madrid, Spain, gbà pé: “Bí Kristian ọmọ ìjọ [Kátólíìkì] kan kò bá lè wá sí ibi ìsìn Máàsì ní ọjọ́ Sunday, ó bà wá lọ́kàn jẹ́ gan-an nítorí pé ó ti pàdánù àkókò ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Ọlọrun àti àwọn arákùnrin rẹ̀, kì í ṣe nítorí pé ó ti dá ẹ̀ṣẹ̀ kan. Àmọ́ nìyẹn.”
Nítorí náà, ìbẹ̀rù kò ru ìfọkànsìn sókè nínú àwọn ènìyàn mọ́. Agbára ìdarí tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àti àwọn aṣaájú wọn ní lórí ìwà àwọn ènìyàn ńkọ́—wọ́n ha lẹ́tọ̀ọ́ sí ìdúróṣinṣin àwọn agbo wọn bí?
Àìfararọ Ní ti Ọlá Àṣẹ
Òpin tí ó ti dé bá ìbẹ̀rù tí àwọn ènìyàn ní fún ìsìn ti ṣe kòńgẹ́ pẹ̀lú ìjórẹ̀yìn lílé kenkà nínú ipò ìwà rere ṣọ́ọ̀ṣì. Òpìtàn ọmọ Itali kan, Giordano Bruno Guerri, ṣàròyé pé: “Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni a ti ń ní . . . ọ̀pọ̀ àwọn olùkọ́ ìwà rere, àmọ́ àwọn olùkọ́ oníwà rere kò tó nǹkan.” Àìsí àwọn aṣíwájú rere yìí ni àwọn ogun àgbáyé méjì tí ó fọ́ ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù túútúú fi hàn. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ Europe kò ní agbára tó láti má ṣe jẹ́ kí àwọn onígbàgbọ́ lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ọlọ́gbàrá ẹ̀jẹ̀ náà. Ohun tí ó tilẹ̀ tún wá burú jù lọ ni pé, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì di ẹni tí ó ki ara bọ inú ìjà ogun náà pátápátá—ní ìhà méjèèjì.
Òpìtàn Paul Johnson sọ pé: “Ogun Àgbáyé Kìíní, ogún láàárín àwọn ẹ̀yà ìsìn Kristian, ni ó bẹ̀rẹ̀ sànmánì rúkèrúdò àti ìtìjú fún ìsìn Kristian. Ogun Àgbáyé Kejì tilẹ̀ tún wá gbéjà ko ipò ìwà rere ìsìn Kristian ju Èkíní lọ. Ó túdìí àṣírí àìjámọ́ǹkan kan àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ní Germany, tí ó jẹ́ orírun Ìṣàtúnṣe Ìsìn, àti ojora òun ìmọtara-ẹni-nìkan Ìṣàkóso Póòpù.”
Ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàárín Vatican àti ìjọba Nazi ti Hitler àti àwọn ìjọba Bòńbàtà ti Mussolini ní Itali àti Franco ní Spain tún ba ọlá àṣẹ rere tí ṣọ́ọ̀ṣì ní jẹ́. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ohun tí ìsìn san fún irú ìwà àìronúgbégbèésẹ̀ ti ìṣèlú bẹ́ẹ̀ ni ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ tí àwọn ènìyàn kò ní nínú wọn mọ́.
Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba—Títú Ìdè Náà
Ní ọ̀rúndún ogún yìí, ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Europe ni wọ́n ti wá tú ìdè tí ó so Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba pọ̀. Ní ti tòótọ́, kò sí orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Europe kankan tí ó tún ń ka ìsìn Roman Kátólíìkì sí ìsìn tí a tẹ́wọ́ gbà lábẹ́ òfin mọ́ nísinsìnyí.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn lájorí lára àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ṣì lè jẹ́ èyí tí ìjọba ń tì lẹ́yìn síbẹ̀, wọ́n ti pàdánù agbára ìdarí ìṣèlú tí wọ́n máa ń lò tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ló tí ì gba òtítọ́ yìí. Ògúnná gbòǹgbò kan nínú ìsìn Jesuit, tí ó jẹ́ ará Spain, José María Díez-Alegría, gbà gbọ́ pé “àwọn aṣiwájú ṣọ́ọ̀ṣì [Kátólíìkì]—ọ̀pọ̀ lára wọn fi òtítọ́ inú rò—pé àwọn kò lè ṣe ojúṣe àwọn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn láìjẹ́ pé àwọn ní ìtìlẹyìn ‘ìjọba.’”
Ṣùgbọ́n “ìtìlẹyìn ‘ìjọba’” yìí ti wó lulẹ̀. Spain, tí ó ní ìjọba “orílẹ̀-èdè Kátólíìkì” tẹ́lẹ̀ títí tí ó fi di ọdún 1975, ló lè ṣàpẹẹrẹ ipò yìí. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ìgbìmọ̀ àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Spain ti kó wọnú awuyewuye tí kò dáwọ́ dúró lórí owó tí ń wọlé fún ṣọ́ọ̀ṣì pẹ̀lú àwọn ìjọba Àjùmọ̀ni. Bíṣọ́ọ̀bù ìlú Teruel, Spain, ṣàròyé láìpẹ́ yìí fún àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ pé òún nímọ̀lára pé “wọ́n ń ṣe inúnibíni sí òun gẹ́gẹ́ bíi Kátólíìkì kan” nítorí pé ìjọba Spain kì í fún ṣọ́ọ̀ṣì ní ìtìlẹyìn owó tí ó pọ̀ tó.
Ní ọdún 1990, àwọn bíṣọ́ọ̀bù Spain kéde pé “àìfàrarọ tí ó wúwo rinlẹ̀ ní ti ẹ̀rí ọkàn àti ti ìwà rere” ti ń dojú kọ àwùjọ àwọn ènìyàn Spain. Ta ni wọ́n dá lẹ́bi fún ‘àìfararọ ti ìwà rere’ yìí? Àwọn bíṣọ́ọ̀bù sọ pé ọ̀kan lára àwọn lájorí okùnfà rẹ̀ ni “èrò tí ó pẹ̀ka tí àwọn òṣìṣẹ́ ìlú [ìjọba Spain] ń gbé lárugẹ ní gbogbo ìgbà.” Ó ṣe kedere pé àwọn bíṣọ́ọ̀bù máa ń retí kí àwọn ìjọba gbé àwọn àkójọ ìlànà ìsìn Kátólíìkì lárugẹ, kí wọ́n sì máa pèsè owó láti tì wọ́n lẹ́yìn.
Àwọn Àlùfáà Ha Ń Fi Ohun Tí Wọ́n Ń Wàásù Hùwà Bí?
Ọlà jìngbìnnì tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ní sábà máa ń jẹ́ ìtìjú fún àwọn àlùfáà tí ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ẹ̀ka wọn tí ó ti dìdàkudà. Ó tilẹ̀ tún wá tì wọ́n lójú sí i nígbà tí wọ́n ṣàkóbá Ilé Ìfowópamọ́ Vatican pẹ̀lú ohun tí ìwé ìròyìn Time pè ní “ìlowónílòkulò tí ó burú jù lọ ní Itali lẹ́yìn ogun.” Ní ọdún 1987, àwọn adájọ́ Itali pa á láṣẹ pé kí á fàṣẹ ọba mú bíṣọ́ọ̀bù àgbà kan àti àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ Vatican méjì míràn. Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí àkànṣe ipò àṣẹ tí Vatican wà, àwọn ọ̀daràn wọ̀nyí ni a kò fí àṣẹ ọba mú. Ilé Ìfowópamọ́ Vatican yarí kanlẹ̀ pé àwọn kò tí ì ṣe láìfí kankan, ṣùgbọ́n wọn kò mú èrò tí wọ́n ti fi sí àwọn ènìyàn lọ́kàn pé ṣọ́ọ̀ṣì náà kì í fi ohun tí ń wàásù ṣèwà hù kúrò.—Fi wé Matteu 23:3.
Ìwà pálapàla ìbálòpọ̀ takọtabo tí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ń gbé jáde tilẹ̀ ti wá ba orúkọ wọn jẹ́ gan-an. Ní May 1992, bíṣọ́ọ̀bù Ireland kan, tí ó gbajúgbajà fún ṣíṣagbátẹrù wíwà ní ipò àpọ́n, sọ pé kí àwọn ènìyàn ṣọ́ọ̀ṣì òun “forí ji òun” kí wọ́n sì “gbàdúrà fún òun.” Ó di dandan fún un pé kí ó fiṣẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti bọ́ sójútáyé pé òun ni baba ọmọkùnrin ọlọ́dún 17 kan, tí ó sì ti lo owó ṣọ́ọ̀ṣì láti fi rán an lọ sí ilé ẹ̀kọ́. Ní oṣù kan ṣaájú ìyẹn, àlùfáà Kátólíìkì kan fara hàn lórí tẹlifíṣọ̀n Germany pẹ̀lú “ẹnì kejì” rẹ̀ àti àwọn ọmọ wọn méjì. Ó sọ pé òun yóò fẹ́ láti “sọ̀rọ̀” lórí ọ̀ràn àjọṣepọ̀ lọ́kọláyà bòńkẹ́lẹ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn àlùfáà ń ṣe.
Àwọn àpá tí ìbàlórúkọjẹ́ náà ń fi sílẹ̀ kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Òpìtàn Guerri, sọ nínú ìwé rẹ̀, Gli italiani sotto la Chiesa (Àwọn Ará Itali Lábẹ́ Ìsàkóso Sọ́ọ̀ṣì), pé “fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni Ṣọ́ọ̀ṣì ti ń ba ìwà rere àwọn ara Itali jẹ́.” Ó sọ pé, àbájáde rẹ̀ kan ni “àìsí àṣà fífún àwọn àlùfàá ní agbára mọ́ tí ń pọ̀ sí i, àní láàárín àwọn onígbàgbọ́ pàápàá.” Ó lè dà bí ẹni pé kí àwọn Kátólíìkì tí inú ń bí bi àwọn àlùfáà wọn ní ìbéèrè tí aposteli Paulu bi àwọn ará Romu pé: “Fún àpẹẹrẹ, ẹ̀ ń wàásù lòdì sí olè jíjà, àmọ́, ìṣòtítọ́ tiyín fúnra yin ha dá yín lójú bí? Ẹ̀ ń bu ẹnu àtẹ́ lu panṣágà, àmọ́, ìwà àìlabàwọ́n tiyín fúnra yín ha dá yín lójú bí?”—Romu 2:21, 22, Phillips.
Ọ̀gbun Tí Ó Wà Láàárín Àwọn Àlùfáà àti Àwọn Ọmọ Ìjọ
Ìṣòro kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ hàn síta, ṣùgbọ́n tí ń sọ ìsìn di aláìlágbára ni ọ̀gbun tí ó wà láàárín àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ ìjọ. Ó dà bí ẹni pé àwọn lẹ́tà ìtọ́jú agbo tí àwọn bíṣọ́ọ̀bù ń kọ ń bí àwọn ọmọ ìjọ nínú dípò kí ó máa fún wọn ní ìtọ́ni. Nínú ìwádìí kan tí a ṣe ní Spain, kìkì ìpín 28 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí a fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló “gbà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àwọn bíṣọ́ọ̀bù.” Iye àwọn ènìyàn kan náà “ni kò tilẹ̀ kọbi ara sí wọn,” ìpín 18 nínú ọgọ́rùn-ún sì sọ pé àwọn “kò lóye ohun tí wọ́n [àwọn bíṣọ́ọ̀bù] ń sọ.” Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Ubeda ti Majorca, Spain, sọ pé: “Àwa bíṣọ́ọ̀bù náà gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba ẹ̀bi wa nínú ọ̀ràn fífa ọwọ́ àwọn ènìyàn sẹ́yìn nínú jíjẹ́ Kristian—èyí tí ó jẹ́ òtítọ́ pọ́ńbélé.”
Àìsí ìhìn iṣẹ́ tí ó ṣe kedere láti inú Ìwé Mímọ́ ni ó tún mú kí àwọn ọmọ ìjọ máa fi wọ́n dágunlá. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Catholic Herald ṣe sọ, “ọ̀pọ̀ àwọn àlùfáà [ní ilẹ̀ Faransé] ti yíjú sí ọ̀ràn ìṣèlú kí wọ́n baà lè jẹ́ ‘ènìyàn pàtàkì,’” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ọmọ ìjọ wọn yóò fẹ́ kí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí. Àlùfáà Itali kan tí ó tún jẹ́ onímọ̀ nípa àjọṣepọ̀ ẹ̀dá, Silvano Burgalassi, sọ pé: “Bóyá nítorí àpẹẹrẹ wa tí kò dára ni wọ́n [àwọn ọ̀dọ́] fi ń sá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun. A ti fún wọn ní ‘àgbo’ ìdàpọ̀ atinilójú, ìsìn àti ìṣòwò, ìmọtara-ẹni-nìkan àti àdàlúpọ̀ mu.” Kò yani lẹ́nu pé àwọn àlùfáà tí ń pàdánù ipò tí wọ́n ní láwùjọ. Ohun tí a sábà máa ń gbọ́ láti ẹnu àwọn Kátólíìkì ti Spain ni, “Kátólíìkì ni mí, ṣùgbọ́n n kò gbà gbọ́ nínú àwọn àlùfáà.”
Ó ṣòro fún àwọn Kátólíìkì kan láti fọ̀rọ̀ pa mọ́ sí àwọn àlùfáà lọ́wọ́, àwọn mìíràn sì ń ṣiyè méjì lọ́nà tí ó lágbára nípa àwọn ìlànà ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ṣọ́ọ̀ṣì—pàápàá jù lọ, nípa àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n kà sí èyí tí kò mọ́gbọ́n dání tàbí tí kò wúlò.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìgbàgbọ́ Tí Kò Ṣeé Lóye
Àpẹẹrẹ kan tí ó burú jáì ni ẹ̀kọ́ nípa iná ọ̀run àpáàdì tí a fàṣẹ sí tí àwọn Kátólíìkì ń kọ́ni. Ìwé Catechism of the Catholic Church sọ pé: “Ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì náà tẹnu mọ́ ọn pé iná ọ̀run àpáàdì àti ìwàpẹ́títí rẹ̀ wà.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí fi hàn pé kìkì ìdá mẹ́rin lára àwọn Kátólíìkì Faransé àti ìdá mẹ́ta àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn ní Spain ló gbà gbọ́ pé iná ọ̀run àpáàdì wà.
Bákan náà, nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn ìwà rere, àwọn ara ilẹ̀ Europe jẹ́ “àwọn Kristian ṣe-é-bí-o-ṣe-fẹ́.” Mimmi, ọ̀dọ́ ọmọ ìjọ Luther kan láti Sweden, gbà gbọ́ pé ọ̀ran ìwà rere, irú bíi bíbí ọmọ láìgbéyàwó, jẹ́ “ohun tí oníkálukú gbọ́dọ̀ pinnu fúnra rẹ̀.” Ọ̀pọ̀ àwọn Kátólíìkì Faransé ni yóò gbà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí 80 ìpín nínú ọgọ́rùn-ún lára wọ́n bá dojú kọ àwọn ìpinnu tí ó ṣe kókó nínú ìgbésí ayé, wọ́n sọ pé àwọn yóò tẹ̀lé ohun tí ẹ̀rí ọkàn àwọ́n bá sọ, dípò ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì bá sọ.
Ní ayé àtijọ́, agbára tí ṣọ́ọ̀ṣì ní ti tó láti pa ẹni yòówù tí ó bá ń gbó wọn lẹ́nu mọ́. Ní ojú ìwòye Vatican, ohun tí ó yí padà kò pọ̀. Ìwé Catechism fi tagbáratagbára sọ pé “gbogbo ohun tí wọ́n ti sọ nípa ọ̀nà ìgbàtúmọ̀ Ìwé Mímọ́ sinmi lórí èrò inú Ṣọ́ọ̀ṣì pátápátá.” Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ènìyàn kò fara mọ́ ọ̀nà oníjẹgàba tí wọ́n fi ń ṣe é náà. Antonio Elorza, ọmọ Spain, tí ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ẹ̀kọ́ ọ̀ràn ìṣèlú, ṣàròyé pé: “Iyàn lórí ẹni tí ó yẹ kí ó ni ọlá àṣẹ kò dáwọ́ dúró. Ṣọ́ọ̀ṣì náà ń fẹ́ láti mọ odi kan yí ara rẹ̀ ká, èyí tí yóò sọ ìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ rẹ̀ dí aláìṣeéyípadà bí ọdún ti ń gorí ọdún.” Níta “odi” náà, agbára ìdarí àti ọlá àṣẹ tí ṣọ́ọ̀ṣì ní ń lọ sílẹ̀.
Yàtọ̀ sí ìjórẹ̀yìn nǹkan tẹ̀mí, àwọn nǹkan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwùjọ ènìyàn tún jẹ́ kókó abájọ pàtàkì kan nípa ìdágunlá sí ìsìn. Àwọn òǹṣọ̀wọ́ káràkátà pèsè ọ̀pọ̀ yanturu àwọn nǹkan ìnàjú àti ìtura—ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará ilẹ̀ Europe ló sì ní ìfẹ́ láti gbádùn wọn, tí wọ́n sì rí ọ̀nà àtigbádùn wọn. Tí a bá fi wéra, lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì dà bí ọ̀nà tí kì í mórí yá kan láti lo òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ó jọ bíi pé àwọn ààtò ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì kì í kájú àìní àwọn ènìyàn nípa tẹ̀mí.
Bóyá ni yóò fi lè ṣeé ṣe pé kí ìsìn ìṣẹ̀m̀báyé tún ní ìdarí lórí àwọn agbo ọmọ ilẹ̀ Europe mọ́. Ìsìn ha jẹ́ agbára ayé àtijọ́—tí ó di dandan pé kí ó re ibi àgbà ń rè bí?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wọ́n kọ́kọ́ tẹ ìwé Catechism of the Catholic Church jáde ní ọdún 1992, èrò ọkàn wọn sì ni pé kí ó jẹ́ àkójọ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí a fọwọ́ sí fún àwọn Kátólíìkì káàkiri gbogbo àgbáyé. Nínú ọ̀rọ̀ ìfáárà rẹ̀, Póòpù John Paul Kejì ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìwé ìtọ́ka tí ó dájú tí ó sì ṣeé gbẹ́mìí lé kan láti máa fi kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ìsìn Kátólíìkì.” Ìgbà tí ó kẹ́yìn tí wọ́n gbé irú àkójọ ìlànà ìsìn Kátólíìkì bẹ́ẹ̀ jáde ni ọdún 1566.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Pańpẹ́ ìgbafẹ́ ti mú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù lọ́rùn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Nígbà tí ó bá di ọ̀ràn bóyá kí wọ́n lọ sí ibi ìwàásù kan tàbí kí wọ́n lọ yáàrùn, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará ilẹ̀ Europe yóò yàn láti lọ sí etíkun láìlọ́tìkọ̀