ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 4/8 ojú ìwé 3-4
  • Àwọn Onígbàgbọ́ Dà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Onígbàgbọ́ Dà?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Iye Àwọn Tí Ń Lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì?
  • Fífi Adùn àti Ìfẹ́ Tara Ẹni Síwájú Ìfọkànsìn
  • Èé Ṣe Tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kò Fi Nípa Lórí Àwọn Ènìyàn Mọ́?
    Jí!—1996
  • Ọwọ́ Wo Làwọn Èèyàn Fi Ń Mú Ìlànà Ẹ̀sìn Lóde Òní?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Òpin Ìsìn Ha Ti Sún Mọ́lé Bí?
    Jí!—1996
Jí!—1996
g96 4/8 ojú ìwé 3-4

Àwọn Onígbàgbọ́ Dà?

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ SPAIN

“Kò sí ohun tó léwu fún ìsìn ju ìdágunlá lọ.”

EDMUND BURKE, AṢAÁJÚ ÒṢÈLÚ ỌMỌ ILẸ̀ BRITAIN NÍ Ọ̀RÚNDÚN KEJÌDÍNLÓGÚN.

LÓRÍ ilẹ̀ títẹ́jú kan tí ìgbì ń gbá kọjá ní agbègbè àríwá Spain ni ìlú kékeré kan tí ń jẹ́ Caleruega wà. Ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé tí a kọ́ ní ọ̀nà ayé ijọ́un ti àwọn ará Romu ni lájorí ilé tí ó wà ní ìlú àtayébáyé náà. Wọ́n kọ́ ọ ní 700 ọdún sẹ́yìn láti fi ṣe àyẹ́sí Domingo de Guzmán, tí ó dá ẹgbẹ́ Dominican sílẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ pé níbẹ̀ ni wọ́n bí i sí. Fún ọ̀rúndún méje, ilé àwọn ajẹjẹ̀ẹ́-anìkàndágbé náà ni àwọn tí wọ́n fẹ́ láti máa gbé ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti láwọn nìkan ti fi ṣelé.

Ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé náà ń jò, ògiri àtayébáyé náà sì ti ń wó. Àmọ́ ohun tí ó jẹ ìyálóde ibẹ̀ lógún jù àwọn nǹkan mìíràn lọ ni ìbàjẹ́ tí ń gbalẹ̀—ìwólulẹ̀ ìsìn fúnra rẹ̀. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wọ ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ní 30 ọdún sẹ́yìn, 40 àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ló wà níhìn-ín. Ní báyìí kìkì àwa 16 la kù. Àwọn ọ̀dọ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé kò sí. Iṣẹ́ ìsìn dà bí ohun tí ó ti di ti ayé àtijọ́.”

Ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní Caleruega ń ṣẹlẹ̀ jákèjádò ọ̀pọ̀ ilẹ̀ Europe. Kì í ṣe ìwà títa ko ìsìn lẹ́ẹ̀kan náà tí ó ní ọ̀pọ̀ ènìyàn nínú ni, àmọ́ fífi tí àwọn ènìyàn ń fi ìsìn sílẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, láìdáwọ́dúró. Àwọn kàtídírà ilẹ̀ Europe lílókìkí wọn wúlò fún àwọn arìnrìn àjò afẹ́, kàkà tí ì bá fi fa àwọn “onígbàgbọ́” àdúgbò mọ́ra. Ṣọ́ọ̀ṣì tí ó ti fìgbà kan rí jẹ́ alágbára ńlá—ì báà jẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì, ì báà jẹ́ Kátólíìkì—ni ẹ̀mí ìdágunlá ti borí. Àwọn nǹkan ti ayé ló gba gbogbo ìgbésí ayé àwọn ènìyàn, kàkà tí ì bá fi jẹ́ àwọn nǹkan ti ẹ̀mí—àṣà ìgbàlódé kan tí àwọn agbẹnusọ ṣọ́ọ̀ṣì pè ní ẹ̀mí nǹkan ti ayé. Ńṣe ló dà bí ẹni pé ìsìn kò já mọ́ nǹkan kan mọ́. Ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí ìsìn ní ilẹ̀ Europe ha lè jẹ́ ìkófìrí ìlọsílẹ̀ kan náà tí yóò ṣẹlẹ̀ jákèjádò apá ibòmíràn ní ayé?

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Iye Àwọn Tí Ń Lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì?

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kì í ṣe ohun tí ó jẹ́ tuntun ní ìhà àríwá ilẹ̀ Europe. Kìkì ìpín 5 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Scandinavia tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìjọ Luther ló ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé. Ní Britain, kìkì ìpín 3 nínú ọgọ́rùn-ún lásán lára àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní ọmọ ìjọ Anglika ló ń lọ sí ibi ìsìn ní ọjọ́ Sunday. Ṣùgbọ́n ní báyìí, ó dà bí ẹni pé àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì ilẹ̀ Europe tí wọ́n wà ní ìhà gúúsù ti ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn alámùúlégbè wọn ní ìhà àríwá.

Ní ilẹ̀ Faransé, orílẹ̀-èdè tí àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì kún fọ́fọ́, kìkì ìdá mẹ́wàá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè náà ló ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Ní ọdún 25 tí ó kọjá, ìpín ọ̀rún àwọn ará Spain tí wọ́n ka ara wọn sí “Kátólíìkì paraku” ti lọ sílẹ̀ láti orí ìpín 83 nínú ọgọ́rùn-ún sí ìpín 31 nínú ọgọ́rùn-ún. Ní ọdún 1992, bíṣọ́ọ̀bù àgbà ọmọ ilẹ̀ Spain kan, Ramon Torrella, sọ fún ìgbìmọ̀ oníròyìn pé “kò sí ohun tí ń jẹ́ Spain onísìn Kátólíìkì mọ́; àwọn ènìyàn ń lọ sí ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ Ọ̀sẹ̀ Mímọ́ àti Máàsì Kérésìmesì—àmọ́ wọn kì í lọ [sí Máàsì] lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.” Nígbà ìbẹ̀wò kan tí póòpù ṣe sí Madrid ní ọdún 1993, John Paul Kejì kìlọ̀ pé “ó yẹ kí Spain padà sí ìpìlẹ̀ Kristian rẹ̀.”

Ẹ̀mí àìkọbi-ara sí ìsìn ti ran àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ ìjọ bákan náà. Iye àwọn àlùfáà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ fi joyè ní ilẹ̀ Faransé lọ sílẹ̀ láti orí 140 ní ọdún 1988 (ó dín sí ìdajì iye ti ọdún 1970), nígbà tí ó sì jẹ́ pé ní Spain, nǹkan bí 8,000 ló ti pa iṣẹ́ àlùfáà wọn tì láti lè gbéyàwó. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn kan tí wọ́n ń bá a lọ láti máa ṣe òjíṣẹ́ fún àwọn agbo wọn ń ṣiyè méjì nípa ìhìn iṣẹ́ wọn. Kìkì ìpín 24 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn àlùfáà ìjọ Luther ti Sweden ló nímọ̀lára pé àwọ́n lè wàásù nípa ọ̀run rere àti ọ̀run àpáàdì “pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn mímọ́,” nígbà tí ó sì jẹ́ pé àjíǹde Jesu kò dá ìdá mẹ́rin àwọn àlùfáà ọmọ ilẹ̀ Faransé lójú.

Fífi Adùn àti Ìfẹ́ Tara Ẹni Síwájú Ìfọkànsìn

Kí ló ń gba ipò ìsìn? Eré ìtura ti gba ipò ìjọsìn nínú ọ̀pọ̀ ìdílé. Ní ọjọ́ Sunday, àwọn ìdílé máa ń mórí lé etíkun tàbí lé àwọn ibi òkè gíga, dípò kí wọ́n lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Juan, èwe kan tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ bí àwọn èwe Spain ṣe rí, sọ èjìká pé: “Lílọ sí Máàsì máa ń sú ènìyàn.” Àwọn ààtò ìsìn kò lè fagagbága pẹ̀lú eré bọ́ọ̀lù tàbí eré orin lílókìkí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó máa ń wọ́ èrò, tí ó sì máa ń mú kí àwọn ènìyàn kún gbọ̀ngàn ìṣeré fọ́fọ́.

Dídín tí iye àwọn tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ń dín kù nìkan kọ́ ní ẹ̀rí tí a ní pé ìsìn ń lọ sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Europe fẹ́ láti yan àwọn èrò ìsìn tí wọ́n bá fẹ́, kí wọ́n sì ta èyí tí wọn kò bá fẹ́ nù. Ní òde òní, àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì tí a mọ̀ lábẹ́ òfin ni kò fi bẹ́ẹ̀ jọra pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n pe ara wọn ní ẹlẹ́sìn yẹn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Europe—wọn ì báà jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì, wọn ì báà jẹ́ ọmọ ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì—kò gbà gbọ́ nínú ìwàláàyè lẹ́yìn ikú mọ́, nígbà tí ó sì jẹ́ pé ohun tí ó ju 50 ìpín nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ Faransé, Itali, àti Spain tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì ni kò gbà gbọ́ nínú iṣẹ́ ìyanu bí tí í wù kí ó rí.

Ó dà bí ẹni pé agbo àwọn aṣaájú àlùfáà kò lágbára tó láti dáwọ́ bí àwọn ènìyàn ṣe ń kọ̀yìn sí ìlànà ṣọ́ọ̀ṣì lọ́nà tí ó yára kánkán yìí dúró. Ibi tí èyí tilẹ̀ ti hàn gbangba jù lọ ni ibi ìwọ́de tí póòpù ṣe lòdì sí fífètò sọ́mọ bíbí. Ní ọdún 1990, Póòpù John Paul Kejì rọ àwọn Kátólíìkì apòògùn pé kí wọ́n má ṣe ta oògùn fètò-sọ́mọ-bíbí. Ó sọ pé àwọn oògùn yìí “lòdì sí àwọn òfin ìṣẹ̀dá, wọ́n sì ń ba iyì ènìyàn jẹ́.” Bákan náà, ìwé Catechism of the Catholic Church tẹnu mọ́ ọn pé “ìfẹ́ lọ́kọláyà tí ó máa ń wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin yóò tipa báyìí wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe alábala méjì ti ìṣòtítọ́ àti ìbímọ.”

Láìka àṣẹ tí ó lágbára wọ̀nyí sí, àwọn tọkọtaya ọmọ ìjọ Kátólíìkì kan tí a lè mú gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ń ṣe tiwọn lọ ni láìbìkítà. Àwọn ìdílé tí ó ní ọmọ tí ó ju méjì lọ kò pọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè ọmọ ìjọ Kátólíìkì ti ìhà gúúsù ilẹ̀ Europe. Ní Spain, kọ́ńdọ́ọ̀mù—tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọjà tí wọn ń tà lábẹ́lẹ̀ ní ẹ̀wádún méjì sẹ́yìn—ni wọ́n ń polówó déédéé lórí tẹlifiṣọ̀n lónìí, kìkì ìpín 3 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin ọmọ Faransé tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì ló sì sọ pé àwọn rọ̀ mọ́ òfin Kátólíìkì tí a fọwọ́ sí lábẹ́ òfin náà lórí ìfètòsọ́mọbíbí.

Ó ṣe kedere pé, àwọn ará ilẹ̀ Europe ti ń kọ ẹ̀yìn sí ṣọ́ọ̀ṣì àti ẹ̀kọ́ wọn. Bíṣọ́ọ̀bù àgbà Anglika ti Canterbury, George Carey, ṣàpèjúwe ipò tí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ wà ní kedere nípa sísọ pé: “À ti ń kú lọ, ìyẹn sì jẹ́ ọ̀ràn pàjáwìrì kan tí ó yẹ kí a kojú.”

Àfi ìgbà tí ó di àkókò rúkèrúdò Ìṣàtúnṣe Ìsìn ni gbàgede kíkàmàmà ti ìsìn ilẹ̀ Europe tó di ahẹrẹpẹ. Èé ṣe ti ọ̀pọ̀ àwọn ara ilẹ̀ Europe kò fi kọbi ara sí ìsìn mọ́? Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ìsìn ní ọjọ́ ọ̀la?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́