Òpin Ìsìn Ha Ti Sún Mọ́lé Bí?
“Ayé yóò kún fún ìmọ̀ Oluwa gẹ́gẹ́ bí omi ti bo òkun.”
ISAIAH, WÒLÍÌ ISRAELI TI Ọ̀RÚNDÚN KẸJỌ ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ TIWA.
BẸ́Ẹ̀ ni wòlíì Heberu náà, Isaiah, ṣe sàsọtẹ́lẹ̀ pé ní ọjọ́ kan, gbogbo àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé yóò wà ní ìṣọ̀kan nínú ìjọsìn Ọlọrun Olódùmarè. Bí ó ti wù kí ó rí, lónìí, irú ìfojúsọ́nà bẹ́ẹ̀ lè dà bí èyí tí ó jìnnà gan-an ju bí ó ti yẹ lọ.
Fún àpẹẹrẹ, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, àwọn ẹgbẹ́ alátùn-únṣe Kọ́múníìsì ní Rọ́síà gbà gbọ́ pé pípa ìsìn run jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ó pọn dandan kan láti lè sọ àwọn mẹ̀kúnnù di òmìnira. Wọ́n fi dáni lójú pé, àìgbọlọ́rungbọ́ yóò ‘sọ àwọn tálákà di òmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹrù ìnira ẹ̀tanú àti ìtànjẹ ti ìgbà àtijọ́.’ Nígbà tí yóò fi di ọdún 1939, Stalin ti dín iye ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì tí àwọn ènìyàn ń lọ kù sí 100 ní Soviet Union, tí a bá fi wéra pẹ̀lú ohun tí ó ju 40,000 tí ó wà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ọdún 1917.
Hitler pẹ̀lú wo ìsìn gẹ́gẹ́ bí ìdènà sí ipò gbígba agbára pátápátá rẹ̀. Ó kéde nígbà kan rí pé: “Bí ènìyàn yóò bá jẹ́ Kristian, kí ó jẹ́ Kristian, bí yóò bá sì jẹ́ ọmọ Germany, kí ó jẹ́ ọmọ Germany. Ènìyàn kò lè jẹ́ méjèèjì pa pọ̀.” Èrò ọkàn rẹ̀ ni láti pa gbogbo onírúurú ìjọsìn tí ó wà tí kò lè ṣàkóso run díẹ̀díẹ̀. Láti lè ṣe èyíìnì, ìjọba Nazi dá àdúrà, àjọ̀dún, ìrìbọmi, àti ìsìnkú tiwọn pàápàá, tí ó fara jọ ti ìsìn sílẹ̀. Hitler ni mèsáyà wọn, ilẹ̀ baba wọn sì ni ọlọrun wọn. Wọ́n lè hu ìwà ọ̀dájú èyíkéyìí bí ó bá ṣáà ti jẹ́ ohun tí Hitler fẹ́ nìyẹn.
Ọjọ́ Ìkẹyìn Ìsìn Ha Nìyí Bí?
Kò sí èyí tí ó ṣàṣeyọrí nínú Stalin àti Hitler nínú aáyan wọn láti tẹ ìsìn rì. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ó dà bí ẹni pé àìbìkítà ti gbapò lọ́wọ́ ìwà ìkà. Bí nǹkan ṣe wá rí yìí kò ya àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lẹ́nu. Aposteli Paulu sọ fún Timoteu pé ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn ènìyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọrun.”—2 Timoteu 3:1-4.
Bibeli ha kọ́ni pé “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” tí ìwà ìdágunlá sí ìsìn sàmì sí yìí, yóò jẹ́ àmì ìparun gbogbo ìsìn bí? Rárá. Dípò sísàsọtẹ́lẹ̀ òpin gbogbo ìsìn, Bibeli ṣàlàyé pé ìsìn èké—tí a fún lórúkọ ìṣàpẹẹrẹ náà, Babiloni Ńlá—ni yóò wá sí òpin.a Ìwé Ìṣípayá sọ pé: “Áńgẹ́lì alókunlágbára kan sì gbé òkúta kan tí ó dàbí ọlọ ńlá sókè ó sì fi í sọ̀kò sínú òkun, ó wí pé: ‘Lọ́nà yii pẹlu ìgbésọnù yíyára ni a óò fi Babiloni ìlú-ńlá títóbi naa sọ̀kò sísàlẹ̀, a kì yoo sì tún rí i mọ́ láé.’”—Ìṣípayá 18:21.
Bí o ti wù kí ó rí, ìpòórá ìsìn èké kò ní yọrí sí ayé kan tí ó jẹ́ ti aláìwà-bí-Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, Orin Dafidi 22:27 sàsọtẹ́lẹ̀ pé: “Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí, wọn óò sì yí padà sí Oluwa: àti gbogbo ìbátan orílẹ̀-èdè ni yóò wólẹ̀ sìn níwájú rẹ.” Ìwọ náà fojú inú wòye àkókò náà nígbà tí “gbogbo ìbátan orílẹ̀-èdè” yóò wà ní ìṣọ̀kan ní jíjọ́sìn Ọlọrun tòótọ́ kan ṣoṣo náà! Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọrun, ìlérí àgbàyanu yẹn yóò ní ìmúṣẹ ológo. (Matteu 6:10) Nígbà ti àkókò yẹn bá dé, ìsìn—ìsìn tòótọ́—yóò já mọ́ nǹkan gan-an ni. Àmọ́ nísinsìnyí ńkọ́?
Dídí Àlàfo Tẹ̀mí Náà
Àlàfo tẹ̀mí tí ó gbalẹ̀ kan ní ilẹ̀ Europe lónìí bára dọ́gba pẹ̀lú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní Ilẹ̀ Ọba Romu ti ọrúndún kìíní. Òpìtàn Will Durant ṣàpèjúwe bí ìsìn Kristian ọ̀rúndún kìíní ṣe ṣàṣeyọrí ní kíkúnjú àìní tẹ̀mí ìgbà yẹn: “Ó mú ìwà rere tuntun ti ẹgbẹ́ ará, ànímọ́ inú rere, ìwà títọ́, àti àlàáfíà wọ inú ipò àìsí ìwà rere ìsìn ìbọ̀rìṣà, wọ inú itutùringindin ìsìn Stoiki, àti wọ inú ìwà ìbàjẹ́ ìsìn Epikurei, wọ inú ayé kan tí ìwà òǹrorò, ìwà ìkà, ìwà agbonimọ́lẹ̀, àti ìwà ìbálòpọ̀ jákujàku ti gbalẹ̀ kan, wọ inú ilẹ̀ ọba akúrẹtẹ̀ kan tí ó ti dà bí ẹni pé kò nílò ìwà akin àwọn ọkùnrin tàbí àwọn ọlọrun ogun mọ́.”
Ìhìn iṣẹ́ alágbára kan náà tí àwọn Kristian ìgbàanì wàásù rẹ̀ káàkiri Ilẹ̀ Ọba Romu lè dí àlàfo ìwà híhù àti tẹ̀mí tí ó wà nínú ayé àwọn ènìyàn ní àkókò wa. Àwọn tí ó sì ń tẹ́tí sílẹ̀ wà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ará ilẹ̀ Europe fara hàn bí ẹni tí kò fẹ́ràn ìsìn, wọ́n ṣì ń nímọ̀lára pé Ọlọrun ń kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé àwọn. Wọ́n lè má ma lọ sí ibi àwọn ààtò ìsìn tí ṣọ́ọ̀ṣì máa ń ṣe mọ́, síbẹ̀ àwọn kan ti dí àlàfo tẹ̀mí wọn ní ibòmíràn.
Juan José, ọ̀dọ́kùnrin kan tí ó wá láti Palma de Mallorca, Spain, lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Kátólíìkì kan, ó sì sìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìdí pẹpẹ títí tí ó fi pé ọmọ ọdún 13. Ó máa ń lọ sí ibi ìsìn Máàsì ní gbogbo ọjọ́ Sunday pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, àmọ́, ó dáwọ́ lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì dúró nígbà tí ó dí ọ̀dọ́langba. Èé ṣe? Juan José ṣàlàyé pé: “Lákọ̀ọ́kọ́ ná, lílọ sí ibi ìsìn Máàsì sú mi. Mo mọ́ gbogbo àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ààtò ìsìn náà sórí. Gbogbo rẹ̀ dà bí àsọtúnsọ ohun tí mo ti gbọ́ tẹ́lẹ̀. Síwájú sí i, àlùfáà ẹ̀ka wa máa ń rorò mọ́ àwọn ọmọ ìdí pẹpẹ lọ́pọ̀ ìgbà. Mo sì rò pé kò tọ̀nà pé kí ó di dandan fún àwọn tálákà láti sanwó fún àlùfáà kí ó tó lè ṣe ààtò ìsìn ìsìnkú fún wọn.
“Mo ṣì gbà gbọ́ nínú Ọlọrun, àmọ́ mo rò pé mo lè sìn ín fúnra mi, láìsí ní ṣọ́ọ̀sì. Èmi àti àwùjọ àwọn ọ̀rẹ́ mi gbìyànjú láti gbádùn ìgbésí ayé bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ènìyàn tilẹ̀ lè sọ pé eré ìnàjú di ohun àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé mi.
“Ṣùgbọ́n nígbà tí mo di ọmọ ọdún 18, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Kí ni ohun tí wọ́n ní láti fún mi tí n kò rí nínú ṣọ́ọ̀ṣì? Ìgbàgbọ́ pọ́nńbélé tí a gbé karí Bibeli dípò kí ó jẹ́ lórí ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ àti ‘àwọn ohun àràmàǹdà’ tí n kò lè lóye láé. Bí ó ti wù kí ó rí, ìgbàgbọ́ mi tuntun túmọ̀ sí ìyípadà ńláǹlà fún mi. Dípò tí ǹ bá fi máa lo gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ lórí ṣíṣètò àríyá ní àwọn ilé ijó dísíkò, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ láti ilé dé ilé kí n lè ṣàjọpín ìgbàgbọ́ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí náà pẹ̀lú àwọn aládùúgbò mi. Dídi ẹni tí ó kara bọ ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ti fún ìgbésí ayé mi ní ìtumọ̀. Fún ọdún méje sẹ́yìn, mo ti jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.”
Kì í ṣe kìkì àwọn ọ̀dọ́ nìkan ló ń wọ́nà láti dí àlàfo ìsìn wọn. Antonia, obìnrin arúgbó kan tí ó wá láti Extremadura, Spain, lo èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀ “ní wíwá Ọlọrun,” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ. Nígbà tí ó ṣì wà ní ọ̀dọ́langba, ó máa ń lọ sí ibi ìsìn Máàsì ní ojoojúmọ́, ó sì di èrò inú ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ìsìn Kátólíìkì kan lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, níwọ̀n bí ó ti gbà gbọ́ “pé bí a kò bá lè rí Ọlọrun nínú ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé, nígbà náà kò tún sí ibi tí a ti lè rí i mọ́.” Ṣùgbọ́n ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ó fi ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé sílẹ̀, ó sì tilẹ̀ wá ní ìdàrú ọkàn àti ìmọ̀lára òfo ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ, nígbà tí ó ti lé dáadáa ní 50 ọdún, ó di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ó ṣàlàyé pé: “Inú mi dùn gan-an nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀ mí wò tí wọ́n sì dáhùn àwọn ìbéèrè mi láti inú Bibeli tèmi fúnra mi. Láti ìgbà tí mo ti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ìgbésí ayé mi ti ní ète. Òtítọ́ ni pé mo ní àwọn ìṣòro tèmi, ṣùgbọ́n, mo lè kojú wọn nítorí pé mo ti rí Ọlọrun tòótọ́ náà nísinsìnyí.”
Àwọn ìrírí méjèèjì yìí kì í ṣe kìkì méjì tí ó wà. Láti lè kọ àwọn àṣà ìsìn tí ó lòde nísinsìnyí sílẹ̀, iye àwọn ènìyàn tí ń pọ̀ sí i ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, wọ́n sì ti rí i pé gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wọn àti wíwàásù nípa rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn ń mú kí ìgbésí ayé wọn ní ìtumọ̀ àti ète.
Ìsìn Tòótọ́ Ń Já Mọ́ Nǹkan Ju Ti Ìgbàkigbà Rí Lọ
Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé à ń gbé ní àkókò tí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ń kọ ìsìn sílẹ̀, yóò jẹ́ ohun tí kò bọ́gbọ́n mu láti ka gbogbo ìsìn sí ohun tí kò já mọ́ pàtàkì. Òtítọ́ ni pé, ní ọ̀rúndún ogún yìí, àwọn ènìyàn ń ṣá àwọn ààtò ìsìn tí kò nítumọ̀, àti àwọn ìlànà ẹ̀kọ́ ìsìn tí kò bá ìgbà mu mọ́, tí kò sì bá Ìwé Mímọ́ mu tì, tí wọ́n sì ń kẹ́gàn ṣọ́ọ̀ṣì lílọ tí ó wulẹ̀ jẹ́ nítorí ṣekárími lásán. Ní ti gidi, Bibeli dámọ̀ràn pé kí á yẹra fún ìsìn alárèékérekè. Aposteli Paulu sàsọtẹ́lẹ̀ pé, ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn ènìyàn kan yóò ‘ní àwòrán-ìrísí ìfọkànsin Ọlọrun ṣugbọn wọn yóò já sí èké níti agbára rẹ̀.’ Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe ojú ayé nínú ọ̀ràn ìsìn, àmọ́, ìwà wọn máa ń sẹ́ ìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ rẹ̀. Báwo ni ó ṣe yẹ kí á hùwà padà sí irú àrékérekè ìsìn bẹ́ẹ̀? Paulu gbà wá nímọ̀ràn pé: “Yà kúrò lọ́dọ̀ awọn wọnyi pẹlu.”—2 Timoteu 3:1, 5.
Ṣùgbọ́n Paulu tún sọ bákan náà pé “ìsìn máa ń mú èrè yanturu wá.” (1 Timoteu 6:6, New English Bible) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa ìsìn èyíkéyìí lásán ni Paulu ń sọ. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a túmọ̀ níhìn-ín sí “ìsìn” ni eu·seʹbei·a, tí ó túmọ̀ sí “ìfọkànsìn tàbí ìbọlá fún Ọlọrun.” Ìsìn tòótọ́, ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀, “ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí ati ti èyíinì tí ń bọ̀.”—1 Timoteu 4:8.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn àpẹẹrẹ tí a mẹ́nu kàn lókè yìí tí fi hàn, ìsìn tòótọ́ lè mú kí ìgbésí ayé wa ní ìtumọ̀, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro pẹ̀lú ìgboyà ọkàn. Ju èyíinì lọ, ìsìn tòótọ́ máa ń mú ọjọ́ ọ̀la ayérayé dáni lójú. Irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ yẹ ní ohun tí ènìyàn ń lépa, níwọ̀n bí a ti mú un dá wa lójú pé bópẹ́bóyá yóò ‘kún ayé.’b (Isaiah 11:9; 1 Timoteu 6:11) Kò sí iyè méjì nípa rẹ̀ pé, ìsinsìnyí ní àkókò tí ìsìn tòótọ́ já mọ́ nǹkan ju ti ìgbàkigbà rí lọ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bibeli lo ìlú ńlá Babiloni ìgbàanì gẹ́gẹ́ bí àmì ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, nítorí pé ní ìlú yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn ìgbàgbọ́ ìsìn tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ti pilẹ̀ṣẹ̀. Jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, àwọn èrò ìgbàgbọ́ Babiloni yìí wá di èyí tí ó ràn wọnú gbogbo àwọn ìsìn kàǹkàkàǹkà inú ayé.
b Fún ìjíròrò lórí bí o ṣe lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀, wo orí 5, “Ìjọsìn Ta Ni Ọlọrun Tẹ́wọ́gbà?” tí ó wà nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde ní ọdún 1995.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìtàn Àwọn Ilé Méjì
Àwọn ilé ìsìn kún Spain fọ́fọ́, àmọ́ ó dà bí ẹni pé ìmọ̀lára gbígbóná tí ó ń jẹ́ kí wọ́n máa kọ́ àwọn kàtídírà olówó gọbọi nígbà kan ti pòórá. Fún àpẹẹrẹ, ní Mejorada del Campo, ní ẹ̀yìn odi Madrid, wọ́n ń kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fífani mọ́ra kan lọ́wọ́. Justo Gallego Martínez, tí ó jẹ́ àlùfáà Benedictine tẹ́lẹ̀, ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé náà ní nǹkan bí 20 ọdún sẹ́yìn. Àmọ́ gbagudu ni ilé náà ṣì wà. Martínez, tí ó ń dá ilé náà kọ́, ti lé ní ọmọ 60 ọdún báyìí, nítorí náà ó dà bí ẹni pé bóyá ni wọ́n yóò fi kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì náà parí láé. Bí ó ti wù kí ó rí, ní 300 kìlómítà sí ìhà gúúsù, nǹkan mìíràn ṣẹlẹ̀.
Ìwé agbéròyìnjáde àdúgbò kan ṣàpèjúwe iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí wọ́n fi ọjọ́ méjì ṣe ní Martos, Jaén, Spain, nípa sísọ pé: “Ìgbàgbọ́ Ń Ṣí Àwọn Òkè Nídìí.” Ìwé agbéròyìnjáde àdúgbò náà bèèrè pé: “Báwo ni ó ṣe ṣeé ṣe pé nínú ayé òde òní tí a gbé karí ìmọtara-ẹni-nìkan, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni láti onírúurú ẹkùn [ní Spain] fi àìmọtara-ẹni-nìkan rìnrìn àjò lọ sí Martos, kí wọ́n baà lè kọ́ ilé kan tí a kò tí ì ní irú àkọsílẹ̀ rẹ̀ ṣáájú ni ti bí ó ti yá tó, bí ó ṣe dára tó, àti bí a ti ṣètò rẹ̀ tó, rí?” Láti lè dáhùn ìbéèrè yìí, ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ náà fa ọ̀rọ̀ ọ̀kan lára àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà yọ tí ó sọ pé: “Ohun tí ó mú kí ó yàtọ̀ ni pé àwá jẹ́ ènìyàn tí Jehofa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.”
[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Mejorada del Campo
Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó wà ní Martos