Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Poland
NÍ ÌGBÀ ìkórè ọdún 1989, àwọn àkóso Kọmunist láti Òkun Baltic títí dé Òkun Dúdú bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ sí wẹ́wẹ́. Bí Ìbòjú Irin ṣe ń gé sọnù, àwọn orílẹ̀-èdè ní Eastern Europe bẹ̀rẹ̀ sí wá òmìnira tiwọn. Lára wọn ni Poland wà, orílẹ̀-èdè kan tí àwọn òkè gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, pẹ̀tẹ́lẹ̀ títẹ́jú, àti òkè-ńlá págunpàgun yíká.a
Àwọn ará Poland jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn, Poland sì ni díẹ̀ lára àwọn dókítà àti onímọ̀-ìjìnlẹ̀ tí ó lókìkí ti wá. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí tí ó ju ìyẹn lọ ni pé ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn olùpòkìkí ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun tí ń pọ̀ síi wà níbẹ̀ nísinsìnyí.
Wọn Gbóyà ní Títúdìí Àṣírí Èké
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà ní Poland tí wọn yóò fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láti inú Bibeli. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni àwọn ẹbí àti aládùúgbò wọn ń dílọ́wọ́. Fún àpẹẹrẹ, ní àárín gbùngbùn Wrocław, obìnrin kan tí ó fìfẹ́hàn ṣíwọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nígbà tí àwọn ìdílé àti ọ̀rẹ́ fi ayé ni í lára. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ tí kò tíì pé ogún ọdún ka ọ̀wọ́ àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà tí ń túdìí àṣírí àwọn ìsìn èké. Ìwọ̀nyí tanná ran ọkàn-ìfẹ́ tí ó ní sí òtítọ́.
Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí ó ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ọ̀dọ́ yìí pinnu láti já gbogbo ìdè rẹ̀ pẹ̀lú ìsìn èké. Ó bẹ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ wò láti fi ìpinnu rẹ̀ tó o létí. Àlùfáà náà sọ fún un láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Èmi, K—— P——, jáwọ́ nínú ìgbàgbọ́ Katoliki.”
Ní Sunday tí ó tẹ̀lé e, wọ́n ka gbólóhùn yìí jáde ní ṣọ́ọ̀ṣì. Baba-àgbà ọmọbìnrin náà dákú gbọnran-gandan, ìyá rẹ̀ àgbà pẹ̀lú sì bú sẹ́kún. Bí ó ti wù kí ó rí, ó wú àwọn mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò mìíràn lórí wọ́n sì sọ pé: “Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, ẹnìkan gbóyà tó láti sọ pé ọ̀pọ̀ èké wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì wa.” Ọ̀dọ́langba onígboyà yìí jẹ́ arábìnrin tẹ̀mí tí a ti batisí báyìí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli méje ní abúlé rẹ̀.
“Nípa Èso Wọn”
Ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ Kujawy i Pomorze gbé ìròyìn náà jáde pé “Nípa Èso Wọn Ni Ẹ Óò Fi Mọ̀ Wọ́n.” Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà sọ lápákan pé, àwọn onísìn ní Kristẹndọm “kò fọwọ́ dan-in dan-in mú àwọn ìlànà ìsìn tí wọ́n ti tẹ́wọ́gbà níti gidi. Ìyàtọ̀ gígadabú wà láàárín wọn àti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí wọ́n ń fi ohun tí wọ́n ń wàásù rẹ̀ ṣèwàhù, tí wọ́n sì ń wàásù ohun tí Bibeli paláṣẹ.”
Lẹ́yìn fífi ìrísí àwọn Ẹlẹ́rìí wéra pẹ̀lú ti àwọn Kristian agbórúkọrù, ìròyìn náà ń báa nìṣó pé: “Ó ṣeéṣe jùlọ kí àwọn tí a mẹ́nukàn kẹ́yìn má mọ̀, àti dé ìwọ̀n àyè gíga, kí wọ́n má máa fi àwọn òtítọ́ àti ìlànà ṣíṣekókó nínú ìgbàgbọ́ wọ́n sílò. . . . Nípa ìwà wọn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn, tí wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fihàn pé àwọn kìí ṣe ‘àwọn èké wòlíì,’ kàkà bẹ́ẹ̀, a lè fi èso wọn mọ̀ wọ́n. ‘Àwọn ènìyàn kìí ká èso àjàrà lórí ẹ̀gún ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lórí ẹ̀wọ̀n, àbí wọn a máa ṣe bẹ́ẹ̀?’ (Matteu 7:15-20).”
Obìnrin kan kọ lẹ́tà kan sí ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ náà Przyjaciółka, ní kíkédàárò pé ọmọkùnrin òun fi Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki sílẹ̀ ó sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Kí ni ìmọ̀ràn olóòtú náà? “Bí ọmọkùnrin rẹ bá ń kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí ó kọ́ ìgbàgbọ́ wọn tí ó sì tẹ́wọ́gbà á, ìpinnu tirẹ̀ ni gbogbo rẹ̀ jẹ́, èyí tí ó yẹ kí o mọrírì rẹ̀ kí o sì bọ̀wọ̀ fún. . . . Àwùjọ ìsìn yìí ní ọ̀pọ̀ ànímọ́ dáradára tí ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà máa ń nífẹ̀ẹ́ sí, irú bí ìsowọ́pọ̀ṣọ̀kan àti ìdè jíjinlẹ̀ tí kò wọ́pọ̀ tí ó jẹ́ ti ọmọ-ìyá, ìwà òtítọ́ bíbùáyà àti títẹ̀lé àwọn ìlànà ìgbésí-ayé àwùjọ tí a tẹ́wọ́gbà tímọ́tímọ́, àti paríparì rẹ̀, agbára láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́ wọn, ní fífi àwọn ìwà yíyẹ tí wọ́n jẹ́wọ́ rẹ̀ ṣèwàhù. Àwọn ìwàrere tí ó ṣeyebíye nìwọ̀nyí jẹ́.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àfikún ìsọfúnni, wo 1994 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ NÍPA ORÍLẸ̀-ÈDÈ
Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1993
GÓŃGÓ IYE ÀWỌN TÍ Ń JẸ́RÌÍ: 113,551
ÌṢIRÒ-ÌFIWÉRA: Ẹlẹ́rìí 1 sí 339
ÀWỌN TÍ Ó PÉSẸ̀ SÍBI ÌṢE-ÌRÁNTÍ: 235,642
ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN AKÉDE TÍ WỌ́N JẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ: 7,961
ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BIBELI: 79,131
IYE TÍ A BATISÍ: 8,164
IYE ÀWỌN ÌJỌ: 1,397
Ọ́FÍÌSÌ Ẹ̀KA: Nadarzyn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọ́fíìsì ẹ̀ka Poland ní Lodz ní 1948
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Iṣẹ́ gbígbé àkọlé kọ́rùn, June 1948, ní East Prussia àtijọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Mẹ́ḿbà 72 ti òṣìṣẹ́ Beteli ní Poland, January 1993
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ẹ̀ka titun ní Nadarzyn