Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Thailand
“ILẸ̀ àwọn ẹni òmìnira.” Ìyẹn ni ìtumọ̀ orúkọ náà Thailand. Onírúurú èrò ìsìn ni àwọn olùgbé rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, òṣìṣẹ́kára tí wọ́n ju 57,000,000 lọ gbàgbọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsìn Búdà ni ó gbilẹ̀, àwọn ìsìn Kristẹndọm pẹ̀lú ní a tún ń ṣe ní orílẹ̀-èdè tí ó wà ní gúúsù ìlà-oòrùn Asia yìí. Gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí yẹ kí wọ́n gbọ́ ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun.—Matteu 24:14.a
Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi Gbọ́ Ìhìnrere
Ní àwọn ibùdó tí wọ́n wà káàkiri yíká òkè-kékeré Thailand lójú ọ̀nà tí ó lọ sí ààlà ẹnubodè Myanmar, òtítọ́ Bibeli ń fìdímúlẹ̀ láàárín àwọn ọmọ ilẹ̀ Karen tí wọ́n jẹ́ olùwá-ibi-ìsádi tí iye wọn rékọjá 10,000. Àwọn mẹ́ḿbà ìdílé Karen kan tí wọ́n ń gbé ní agbègbè yẹn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa. Wọ́n ti ń tan ìhìnrere náà kálẹ̀ láàárín àwọn olùwá-ibi-ìsádi náà. Báwo ni iṣẹ́ wọn ṣe bẹ̀rẹ̀?
Ní àwọn ọdún mélòókan sẹ́yìn ọ̀dọ́kùnrin kan já ìdè àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀ṣì Anglikan ó sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bí àwọn òjíṣẹ́ wọn ti gbún wọn ní kẹ́ṣẹ́, àwọn ìbátan rẹ̀ takò ó. Bí ó ti wù kí ó rí, ó fi sùúrù lo ìfaradà, àtakò ìdílé rẹ̀ sì wá sópin ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Àwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Anglikan ń bá ìpẹ̀gàn wọn nìṣó títí di nǹkan bí ọdún méjì sẹ́yìn nígbà tí a lé wọn kúrò ní ipò wọn nítorí ìwà pálapàla. Níwọ̀n bí ṣọ́ọ̀ṣì náà sì ti wà láìní olùṣọ́-àgùtàn, ṣìbáṣìbo bá ìdílé àti àwọn ìbátan Ẹlẹ́rìí náà gan-an wọ́n sì di aláìnírànlọ́wọ́. Mọ́kànlá nínú wọn kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀ wọ́n sì ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí tẹ̀síwájú dáradára, pẹ̀lú àwọn olùwá-ibi-ìsádi mìíràn tí wọ́n ń kópa. Òtítọ́ yára tànkálẹ̀, tí èyí sì yọrísí ìrìbọmi àwọn Ẹlẹ́rìí titun 17 nínú odò tí ń ṣàn gba ibùdó àwọn olùwá-ibi-ìsádi náà kọjá. Ẹ wo bí ìran náà ti múniláyọ̀ tó nígbà tí a tẹ ìyá-àgbà kan tí ó jẹ́ ẹni ọdún 88 bọmi pẹ̀lú wọn!
Fídíò Ta Ọkàn-Ìfẹ́ Jí
Ṣíṣeéṣe náà tí ó wà fún ìdàgbàsókè ga láàárín àwọn olùwá-ibi-ìsádi náà. Níbi ayẹyẹ Ìṣe-Ìrántí ní 1993, àwọn ènìyàn 57 ni wọ́n pésẹ̀. Nígbà ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká ní oṣù May nínú ọdún yẹn, àwọn 67 ni wọ́n péjọpọ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé rẹ̀. Nǹkan bíi 250 sì péjọpọ̀ láti wo fídíò Watchtower Society náà Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name.
Aya pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì Baptist kan nínú ibùdó àwọn olùwá-ibi-ìsádi náà lọ síbi ọ̀rọ̀-àsọyé Bibeli kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe onígbọ̀wọ́ fún ó sì kọ àwọn ẹsẹ̀ Bibeli tí a jíròrò sílẹ̀. Ó sọ fún ọkọ rẹ̀ bí àwọn àsọtúnsọ ìwàásù tí òun ń gbọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì àwọn kò ti tẹ́ òun lọ́rùn. Ó takò ó, ní wíwí pé bí ó bá níláti lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, gbogbo àwọn mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì àgbègbè yòókù yóò tẹ̀lé e. Nígbà tí ó tún lọ sí ìpàdé náà, ọkọ rẹ̀ fi ọ̀bẹ lé e káàkiri ó sì sun àwọn àkọsílẹ̀ àti ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀ níná. Láìka ìyẹn sí, nígbà tí a fi fídíò náà hàn, ó tún padà lọ. Lẹ́yìn náà obìnrin yìí sọ ohun tí ó ti rí fún ọkọ rẹ̀. Pẹ̀lú ọkàn-àyà tí ó ti yípadà, ó fẹ́ láti wo fídíò náà ó sì dùn ún pé ó ti sun àwọn àkọsílẹ̀ àti ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ níná.
Bí ó ti jẹ́ nìyẹn tí ó fi di pé àwọn ènìyàn ń gbọ́ ìhìnrere ní Thailand. Wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ jèrè òmìnira tẹ̀mí ní “ilẹ̀ àwọn ẹni òmìnira.”—Johannu 8:32.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun àfikún ìsọfúnni, wo 1994 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ NÍPA ORÍLẸ̀-ÈDÈ Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1993
GÓŃGÓ IYE ÀWỌN TÍ Ń JẸ́RÌÍ: 1,434
ÌṢIRÒ-ÌFIWÉRA: Ẹlẹ́rìí 1 sí 40,299
ÀWỌN TÍ Ó PÉSẸ̀ SÍBI ÌṢE-ÌRÁNTÍ: 3,342
ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN AKÉDE TÍ WỌ́N JẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ: 232
ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BIBELI: 1,489
IYE TÍ Ó ṢÈRÌBỌMI: 92
IYE ÀWỌN ÌJỌ: 39
Ọ́FÍÌSÌ Ẹ̀KA: BANGKOK
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn olùpòkìkí Ìjọba ń fi ìtara wàásù ìhìnrere náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ẹ̀ka ọ́fíìsì àkọ́kọ́, 1947
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ìdílé Beteli níwájú ọ́fíìsì ẹ̀ka titun ní Bangkok, èyí tí a yàsímímọ́ ní February 8, 1992