Kí Ni Ojútùú Rẹ̀?
IPÒ àwọn olùwá-ibi-ìsádi náà kì í ṣe èyí tí ó dá gùdẹ̀ pátápátá. Jákèjádò ayé, àwọn àjọ afẹ́dàáfẹ́re ń gbìyànjú láti ran àwọn tí ogun àti àwọn ìṣòro mìíràn ń ṣí nípò padà lọ́wọ́. Lájorí ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbà ṣèrànwọ́ jẹ́ nípa ṣíṣètìlẹ́yìn fún àwọn olùwá-ibi-ìsádi láti darí sí àwọn orílẹ̀-èdè ìbílẹ̀ wọn.
Àwọn olùwá-ibi-ìsádi pa ilé, àdúgbò, àti orílẹ̀-ède wọn tì nítorí pé wọ́n ń bẹ̀rù pé a óò pa wọ́n, dá wọn lóró, fipá bá wọn lò pọ̀, fi wọ́n sẹ́wọ̀n, sọ wọ́n dẹrú, jà wọ́n lólè, tàbí kí a febi pa wọ́n. Nítorí náà, kí àwọn olùwá-ibi-ìsádi tóó lè darí sílé láìséwu, a gbọ́dọ̀ ti yanjú àwọn ìṣòro tó mú kí wọ́n sá lọ. Kódà nígbà tí ìforígbárí ológun bá dópin lẹ́yìn-ọ̀-rẹ́yìn, àìsí òfin àti ìṣètò sábà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ènìyàn láti lọ sílé. Agnes, olùwá-ibi-ìsádi, ará Rwanda kan, tí ó bí ọmọ mẹ́fà sọ pé: “Kíkó wa [padà] sí Rwanda yóò dà bíi kíkó wa lọ sínu sàréè wa.”
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, láti 1989, àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí iye wọ́n lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án ti darí sí ilé wọn. Nǹkan bíi mílíọ̀nù 3.6 lára wọ́n darí sí Afghanistan láti Iran àti Pakistan. Mílíọ̀nù 1.6 àwọn olùwá-ibi-ìsádi mìíràn láti orílẹ̀-èdè mẹ́fà darí sí Mozambique, orílẹ̀-èdè tí ogun abẹ́lé ọlọ́dún 16 ti fọ́ yángá.
Dídarí sílé kò rọrùn. Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn olùwá-ibi-ìsádi máa ń darí sí ti di ahoro—tí àwọn abúlé ti di àwókù àlàpà, àwọn afárá ti bà jẹ́, ọta abúgbàù sì wà káàkiri àwọn ọ̀nà àti pápá oko. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí ń darí sílé ní láti ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe àtúnkọ́ ìgbésí ayé, agbo ilé, ilé ẹ̀kọ́, ilé ìwòsàn, àti ohun gbogbo mìíràn tí wọ́n ní láti ilẹ̀.
Síbẹ̀, kódà tí eruku ìforígbárí bá rọlẹ̀ ní ibì kan, tí èyí sì jẹ́ kí àwọn olùwá-ibi-ìsádi darí sílé, ń ṣe ni wọ́n tún ń bẹ́ sílẹ̀ ní ibòmíràn, tí èyí sì ń mú kí ọ̀wọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi tuntun bẹ̀rẹ̀. Nítorí náà, yíyanjú ìṣòro wíwá ibi ìsádi túmọ̀ sí yíyanjú àwọn ìṣòro ogun, ìtẹ̀mọ́lẹ̀, ìkórìíra, inúnibíni, àti àwọn kókó abájọ mìíràn tí ó tan mọ́ ọn tí ń mú kí àwọn ènìyán sá àsálà nítorí ẹ̀mi wọn.
Àkọsílẹ The State of the World’s Refugees 1995 jẹ́wọ́ pé: “Òtítọ́ ibẹ̀ . . . ni pé níkẹyìn pátápátá, àwọn ojútùú [sí ìṣòro wíwá ibi ìsádi] sinmi lé kókó ọ̀ran ti ìṣèlú, ológun àti ti ètò ọrọ̀ ajé tí ó ré kọjá ìdarí àjọ afẹ́dàáfẹ́re èyíkéyìí.” Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, bákan náà ni àwọn ojútùú rẹ̀ kọjá ohun tí ọwọ́ àjọ èyíkéyìí, yálà ti ìfẹ́dàáfẹ́re tàbí òmíràn lórí ilẹ̀ ayé lè tó.
Ayé Kan Láìsí Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi
Bí ó ti wù kí ó rí, ojútùú kan wà. Bíbélì fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run bìkítà nípa àwọn tí a yà nípá kúrò ní ilé àti lọ́dọ̀ ìdíle wọn. Láìdà bíi ti àwọn alákòóso ayé, òún ní agbára àti ọgbọ́n láti yanjú gbogbo ìṣòro lílọ́jú pọ̀ tí ń dojú kọ ìran aráyé. Òun yóò ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀—ìjọba ọ̀run tí yóò gba ìṣàkóso àwọn àlámọ̀rí ayé láìpẹ́.
Ìjọba Ọlọ́run yóò rọ́po gbogbo ìjọba ènìyàn. Dípo níní ọ̀pọ̀ ìjọba lórí ilẹ̀ ayé, bí a ti ní wọn nísinsìnyí, ìjọba kan ṣoṣo péré ni yóò wà, tí yóò ṣàkóso lórí gbogbo pílánẹ́ẹ̀tì yìí. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀, èyí tí a kì yóò lè parun títí láé: a kì yóò sì fi ìjọba náà lé orílẹ̀-èdè míràn lọ́wọ́, yóò sì fọ́ túútúú, yóò sì pa gbogbo ìjọba wọ̀nyí run, ṣùgbọ́n òun óò dúró títí láéláé.”—Dáníẹ́lì 2:44.
Ó ṣeé ṣe kí o mọ àdúrà àwòṣe tí ó wà nínú Bíbélì ní Mátíù 6:9-13 dunjú. Apá kan àdúrà yẹn sọ pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ inú rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ní ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” Ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà yẹn, Ìjọba Ọlọ́run yóò “dé” láìpẹ́ láti wáá mú ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé ṣẹ.
Lábẹ́ agbára ìṣàkóso onífẹ̀ẹ́ ti Ìjọba Ọlọ́run, àlàáfíà àti ààbò yóò wà jákèjádò ayé. Kì yóò sí ìkórìíra àti ìjà mọ́ láàárín àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè ayé. (Orin Dáfídì 46:9) Kì yóò tún sí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí ń sá àsálà nítorí ẹ̀mi wọn tàbí tí wọ́n ń lálàṣí ní àwọn àgọ́ mọ́.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé Ọba Ìjọba Ọlọ́run, Kristi Jésù, “yóò gba aláìní nígbà tí ó bá ń ké: tálákà pẹ̀lú, àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun óò dá tálákà àti aláìní sí, yóò sì gba ọkàn àwọn aláìní là. Òun óò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ìwà agbára: iyebíye sì ni ẹ̀jẹ wọn ní ojú rẹ̀.”—Orin Dáfídì 72:12-14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Láìpẹ́, gbogbo ènìyàn yóò máa hùwà síra wọn bí arákùnrin àti arábìnrin tòótọ́