ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 8/22 ojú ìwé 4-8
  • Iye Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi Tí Ń Pọ̀ Sí I

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iye Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi Tí Ń Pọ̀ Sí I
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èé Ṣe Tí Ìṣòro Náà Ń Burú Sí I?
  • Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Ènìyàn Tí A Kò Fẹ́
  • Kí Ló Ń Mú Kí Ọ̀rán Túbọ̀ Máa Dojú Rú?
  • Ìkórìíra àti Ìbẹ̀rù
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Àjèjì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa ‘Fayọ̀ Sin Jèhófà’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Kí Ni Ojútùú Rẹ̀?
    Jí!—1996
  • Ayé Kan Tó Máa Dẹrùn fún Gbogbo Èèyàn
    Jí!—2002
  • Àwọn Èèyàn Tó Ń Wá Ibi Ààbò Kiri
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 8/22 ojú ìwé 4-8

Iye Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi Tí Ń Pọ̀ Sí I

ÈYÍ tó pọ̀ jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn ni ogun, ìyàn, àti inúnibíni ti bà jẹ́. Nítorí èyí, gbogbo ìgbà ni àwọn ènìyàn tí ń fẹ́ ibi ìsádi máa ń wà. Látijọ́, àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ènìyán máa ń pèsè ibi ìsádi fún àwọn tí wọ́n ṣaláìní.

Àwọn ará Aztec, Ásíríà, Gíríìsì, Hébérù, àwọn Mùsùlùmí, àti àwọn mìíràn látijọ́ ṣègbọràn sí àwọn òfin tí ń ṣètìlẹ́yìn fún pípèsè ibi ìsádi. Ọ̀mọ̀ràn ará Gíríìsì náà, Plato, kọ̀wé ní ohun tí ó lé ní ọ̀rúndún 23 sẹ́yìn pé: “Ó yẹ kí àwọn ènìyàn àti àwọn ọlọ́run fi ìfẹ́ ribiribi hàn sí àjèjì tí ó jìnnà réré sí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè àti ìdílé rẹ̀. Nítorí náà, a ní láti ṣọ́ra gidigidi kí a má baà hùwà tí kò dára sí àwọn àjèjì.”

Láàárín ọ̀rúndún ogún, iye àwọn olùwá-ibi-ìsádi ti pọ̀ yamùrá. Nínú ìsapá láti ṣaájò àwọn 1.5 mílíọ̀nù olùwá-ibi-ìsádi tí Ogun Àgbáyé Kejì dà sádàn-ánwò, wọ́n dá Àjọ Àbójútó Ọ̀ràn Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (UNHCR) sílẹ̀ ní 1951. Wọ́n ronú pé àjọ náà yóò wà fún ọdún mẹ́ta, látàri pé kò ní í pẹ́ tí àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí ń bẹ yóò fi di ara àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ tí wọ́n sá di. Wọ́n ronú pé lẹ́yìn náà wọ́n wá lè tú àjọ náà ká.

Bí ó ti wù kí ó rí, ní àwọn ẹ̀wádún tí ó ti kọjá, iye àwọn olùwá-ibi-ìsádi ti pọ̀ lọ súà. Nígbà tí ó fi máa di 1975, iye wọ́n ti di mílíọ̀nù 2.4. Ní 1985, iye wọ́n jẹ́ mílíọ̀nù 10.5. Nígbà tí ó fi máa di 1995, iye àwọn ènìyàn tí àjọ UNHCR ń dáàbò bò, tí ó sì ń pèsè ìrànwọ́ fún, ti fò fẹẹ dóri mílíọ̀nù 27.4!

Ọ̀pọ̀ ènìyán nírètí pé sànmánì ẹ̀yìn Ogun Tútù yóò ṣínà fún yíyanjú ìṣòro wíwá ibi ìsádi tí ó wà yíká ayé; àmọ́ kò yanjú rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ nítorí ti ọ̀rọ̀ ìtàn tàbí ẹ̀yà ìran, tí èyí sì ń yọrí sí ìforígbárí. Bí ogun ti ń jà gùdù, àwọn ènìyán ń sá àsálà, ní mímọ̀ pé àwọn olùṣàkóso wọn kò lè dáàbò bò wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní dáàbò bò wọ́n. Fún àpẹẹrẹ, ní 1991, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méjì àwọn ará Iraq tí wọ́n sá àsálà lọ́pọ̀ yanturu lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè alámùúlégbè wọn. Láti ìgbà náà, 735,000 ni olùwá-ibi-ìsádi tí a fojú díwọ̀n pé wọ́n ti sá àsálà kúrò ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí. Lẹ́yìn náà, ní 1994, ogun abẹ́lé ní Rwanda fipá mú àwọn tí ó lé ní ìdaji lára àwọn mílíọ̀nù 7.3 ènìyàn orílẹ̀-èdè náà láti sá àsálà kúrò ní ilé wọn. Nǹkan bíi mílíọ̀nù 2.1 ará Rwanda ló wá ibi ìsádi lọ sí àwọn orílẹ̀-ède Áfíríkà tí wọ́n wà nítòsí.

Èé Ṣe Tí Ìṣòro Náà Ń Burú Sí I?

Àwọn okùnfà bíi mélòó kan wà tí ń pa kún pípọ̀ tí àwọn olùwá-ibi-ìsádi náà ń pọ̀ sí i. Ní àwọn ibì kan, bí Afghanistan àti Somalia, àwọn ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè ti dojú dé. Èyí ti mú kí àṣẹ dé ọwọ́ àwọn ẹgbẹ́ adìhámọ́ra tí ń piyẹ́ agbègbè àrọko láìsí ìdíwọ́, tí èyí sì ń fa ìpayà àti fífẹsẹ̀ fẹ́ ẹ.

Ní àwọn ibòmíràn, ìforígbárí jẹ́ nítorí ìyàtọ̀ ẹ̀yà ìran tàbí ti ìsìn lílọ́jú pọ̀, tí lájorí ète ìlépa àwọn ẹgbẹ́ tí ń gbógun sì jẹ́ láti lé àwọn aráàlú dànù. Nípa ti ogun ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí, aṣojú àjọ UN kan kédàárò ní àárín ọdún 1995 pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò lóye ohun tí ń fa ogun yìí: ẹni tí ń jà, ìdí tí wọ́n fi ń jà. Ọ̀pọ̀ yanturu ènìyàn ló sá kúrò lẹ́yìn ẹgbẹ́ kìíní, lọ́sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ yanturu sì sá kúrò lẹ́yìn ẹgbẹ́ kejì. Ó ṣòro láti lóye, kódà fún àwọn tó yẹ kí wọ́n lóye rẹ̀.”

Àwọn ohun ìjà ogun ìgbàlódé aṣèparun ńláǹlà—àwọn rọ́kẹ́ẹ̀tì àfirọ̀jò ọta tẹ̀lératẹ̀léra, àwọn ọta abúgbàù àrìmọ́lẹ̀, ohun ìjà ràgàjìràgàjì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ—pa kún ìpakúpa rẹpẹtẹ náà, ó sì mú agbègbè ìforígbárí náà tóbi sí i. Àbáyọrí rẹ̀ ni: àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí ń pọ̀ yamùrá láìdábọ̀. Láìpẹ́ yìí, nǹkan bí ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn olùwá-ibi-ìsádi lágbàáyé ti sá àsálà kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè alámùúlégbè wọn tí àwọn pẹ̀lú ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, tí wọn kò sì ní tó láti ṣaájò àwọn tí ń wá ibi ìsádi.

Nínú ọ̀pọ̀ ìforígbárí, àìsí oúnjẹ máa ń dá kún ìṣòro náà. Ó máa ń di ọ̀ràn-anyàn fún àwọn ènìyàn láti ṣí lọ bí ebi bá ń pa wọ́n, bóyá nítorí pé a kò jẹ́ kí àwọn ọkọ̀ tí ń gbé ìpèsè ìrànlọ́wọ́ bọ̀ dé agbègbè tí wọ́n wà. Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé: “Ní àwọn ilẹ̀ kan ní Ibi Ìwo Áfíríkà, àpapọ̀ ọ̀dá àti ogun ti sọ àwọn ilẹ̀ náà di ìdàkudà débi pé kò lè pèsè àwọn ohun amẹ́mìíró mọ́. Ní ti bóyá ebi tàbí ogun ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn tí ń sá àsálà ń sá fún kò ṣe pàtàkì.”

Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Ènìyàn Tí A Kò Fẹ́

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu lásán mú èrò nípa ìsádi ṣẹ, iye tìrìgàngàn àwọn olùwá-ibi-ìsádi ń dáyà fo àwọn orílẹ̀-èdè. Irú ipò kan náà ṣẹlẹ̀ ní Íjíbítì ìgbàanì. Nígbà tí Jékọ́bù àti ìdílé rẹ̀ ń wá ìsádi ní Íjíbítì láti bọ́ lọ́wọ́ ìparun tí ìyàn ọdún méje kan ń ṣe, a gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀. Fáráò fún wọn “nínú ààyò ilẹ̀” tí wọn óò máa gbé.—Jẹ́nẹ́sísì 47:1-6.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí àkókò ti ń lọ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di púpọ̀ gan-an, “ilẹ̀ náà sì kún fún wọn.” Àwọn ará Íjíbítì wáá hùwà padà pẹ̀lú ìkanra, síbẹ̀ “bí [àwọn ọmọ Íjíbítì] sì ti ń pọ́n wọn lójú sí i, bẹ́ẹ̀ ni [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] ń bí sí i, tí wọ́n sì ń pọ̀. Inú wọ́n sì bà jẹ́ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”—Ẹ́kísódù 1:7, 12.

Bákan náà, inú àwọn orílẹ̀-èdè lónìí “ń bà jẹ́” bí iye àwọn olùwá-ibi-ìsádi ti ń di púpọ̀ sí i. Ètò ọrọ̀ ajé ni lájorí okùnfà àníyàn wọn. Ó ń náni ní owó gọbọi láti pèsè oúnjẹ, aṣọ, ilé, kí a sì dáàbò bo àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi. Láàárín 1984 sí 1993, iye owó tí àjọ UNHCR ń ná lọ́dọọdún fò sókè láti mílíọ̀nù 444 dọ́là sí bílíọ̀nù 1.3 dọ́là. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú owó náà jẹ́ ìtọrẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n túbọ̀ lọ́rọ̀, tí àwọn kan lára wọ́n ń bá àwọn ìṣòro ọrọ̀ ajé tiwọn fúnra wọn yí. Àwọn orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ìtọrẹ máa ń ṣàròyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé: ‘A ti sún kan ògiri láti ran àwọn aláìnílé ní orílẹ̀-èdè tiwa fúnra wa lọ́wọ́. Báwo ni a ṣe lè wa ìṣòro àwọn aláìnílé ní gbogbo ayé máyà, pàápàá nígbà tí ó bá jọ pé ìṣòro náà yóò máa pọ̀ sí i dípo kí ó dín kù?’

Kí Ló Ń Mú Kí Ọ̀rán Túbọ̀ Máa Dojú Rú?

Àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí wọ́n wọ orílẹ̀-èdè tí ó lọ́rọ̀ sábà máa ń rí i pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn tí wọ́n wọ orílẹ̀-èdè kan náà nítorí ti ètò ọrọ̀ ajé ń ba ọ̀ràn jẹ́ fún àwọn. Àwọn tí wọ́n wọ̀lú onílùú nítorí ti ètò ọrọ̀ ajé yìí kì í ṣe olùwá-ibi-ìsádi tí ń sá fún ogun tàbí inúnibíni tàbí ìyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n wá ìgbésí ayé tí ó sàn jù wá ni—ìgbésí ayé tí ó bọ́ lọ́wọ́ ipò òṣì. Nítorí pé wọ́n sábà máa ń díbọ́n pé àwọ́n jẹ́ olùwá-ibi-ìsádi, ní dídààmú àwọn àjọ àbójútó ọ̀ran àwọn olùwá-ibi-ìsádi pẹ̀lú irọ́ oríṣiríṣi, wọ́n ń jẹ́ kí ó ṣòro gidigidi fún àwọn ojúlówó olùwá-ibi-ìsádi láti rí àfiyèsí àìṣègbè gbà.a

A ti fi ìrọ́wọlé àwọn olùwá-ibi-ìsádi àti àwọn tí wọ́n wọ̀lú onílùú wé odò méjì tí ń ṣàn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn wọnú orílẹ̀-èdè tí ó lọ́rọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn òfin mímúná púpọ̀ sí i nípa wíwọ̀lú onílùú ti dínà odò ti àwọn tí ń wọ̀lú onílùú nítorí ti ètò ọrọ̀ ajé. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ti di ara odo olùwá-ibi-ìsádi, odò yìí sì ti kún lákùn-ún jù títí ó fi di àkúnya.

Níwọ̀n bí àwọn tí ń wọ̀lú onílùú nítorí ti ètò ọrọ̀ ajé ti mọ̀ pé ó lè gba ọdún bíi mélòó kan láti gbé ìbéère wọn fún ibi ìsádi yẹ̀ wò, wọ́n ronú pé àwọ́n wà ní ipò olúborí. Bí a bá tẹ́wọ́ gba ìbéère wọn fún ibi ìsádi, wọ́n borí, níwọ̀n bí wọ́n ti lè máa wà nìṣó ní àyíká ọlọ́rọ̀ ajé tí ó rọ̀ ṣọ̀mù. Bí a bá kọ ìbéère wọn, wọ́n tún borí, nítorí pé wọn yóò ti ní owó díẹ̀, wọn yóò sì ti kọ́ àwọn iṣẹ́ kan tí wọn óò mú relé.

Bí iye àwọn ojúlówó olùwá-ibi-ìsádi, àti àwọn afàwọ̀rajà, tí ń rọ́ wọ̀lú onílùú ṣe ń pọ̀ sí i, ni ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdé ń tilẹ̀kùn àánú wọn mọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi. Àwọn kan ti ẹnubodè wọn mọ́ àwọn tí ń sá àsálà. Àwọn orílẹ̀-èdè míràn ti gbé àwọn òfin àti ìlànà gbígbéṣẹ́ tí ń fi àtiwọ̀lú du àwọn olùwá-ibi-ìsádi dìde. Síbẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè kan ti fipá dá àwọn olùwá-ibi-ìsádi padà sí ilẹ̀ wọn tí wọ́n ti sá kúrò. Ìtẹ̀jáde àjọ UNHCR kan ṣàlàyé pé: “Ìbísí aláìdáwọ́dúró nínú iye—ti àwọn ojúlówó olùwá-ibi-ìsádi àti ti àwọn tí ń wọ̀lú onílùú nítorí ètò ọrọ̀ ajé—ti gbé ìkálọ́wọ́kò líle koko kan dìde sí àṣà rírí ibi ìsádi tí ó ti wà fún 3,500 ọdún, èyí sì ti gbé e dé bèbè ìforíṣánpọ́n.”

Ìkórìíra àti Ìbẹ̀rù

Ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ máfojúkànlejò—ìbẹ̀rù àti ìkórìíra àlejò—ló tún ń dá kún ìṣòro wíwá ibi ìsádi. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn ènìyán gbà gbọ́ pé àwọn ará ìta ń wu ipò ìwàsí orílẹ̀-èdè, ẹgbẹ́ àwùjọ, àti iṣẹ́ wọn léwu. Wọ́n máa ń lo ìwà ipá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti fi irú ẹ̀rù bẹ́ẹ̀ hàn. Ìwé ìròyin Refugees sọ pé: “Kọ́ńtínẹ́ǹti Europe ń nírìírí ìkọlù ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní ìṣẹ́jú mẹ́ta-mẹ́ta—àwọn ibùdó ìgbàlejò àwọn olùwá-ibi-ìsádi ló sì máa ń jẹ́ ibi ìfojúsùn lọ́pọ̀ ìgbà.”

Pátákó ìpolówó ọjà kan ní àárín gbùngbun Europe fi ẹ̀mí ìkóguntini jíjinlẹ̀ hàn, ẹ̀mí ìkóguntini kan tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ayé ń fi hàn léraléra lọ́nà tí ń pọ̀ sí i. Ìhìn iṣẹ́ olóró rẹ̀ ń fojú sun àwọn àjèjì pé: “Wọ́n jẹ́ ìwúlé ọyún akóninírìíra tí ń roni lára fún orílẹ̀-ède wa. Àwùjọ ẹ̀yà ìran tí kò ní ọ̀pá ìdiwọ̀n ti ẹgbẹ́ àwùjọ, ìwà rere tàbí ti ìsìn, alárìnká akóguntini tí ó wulẹ̀ ń lọ́ni lọ́wọ́ gbà, tí ó sì ń jani lólè. Onídọ̀tí, tí iná kún ara rẹ̀, wọ́n wà ní àwọn òpópónà àti ibùdó ọkọ̀ ojú irin. Ẹ jẹ́ kí wọ́n kó àkísà dídọ̀tí wọn, kí wọ́n sì lọ ráúráú!”

Dájúdájú, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùwá-ibi-ìsádi ni yóò fẹ́ láti “lọ ráúráú.” Wọ́n ń yán hànhàn láti relé. Pẹ̀lú ìrora ọkàn ni wọ́n ń ṣàníyàn láti gbé ìgbésí ayé alálàáfíà, tí ó gún régé pẹ̀lú ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ wọn. Àmọ́ wọn kò ní ilé tí wọn óò lọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní 1993, àwọn ìjọba ní ìhà Ìwọ̀ Oòrun Europe nìkan ná bílíọ̀nù 11.6 dọ́là láti bójú tó ọ̀ràn àwọn tí ń wá ibi ìsádi àti láti gbà wọ́n wọlé.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ipò Ìṣòro Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi

“Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọdé olùwá-ibi-ìsádi ní ń sùn lébi lálaalẹ́? Tàbí pé ọmọdé olùwá-ibi-ìsádi kan ṣoṣo péré nínú àwọn mẹ́jọ ló tí ì tẹ ilé ẹ̀kọ́ rí? Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọdé wọ̀nyí ni kò tí ì lọ ilé sinimá, tàbí ọgbà ìtura rí, kí a má tilẹ̀ wá sọ ti ilé àkójọ ohun ìṣẹ̀m̀báyé. Ọ̀pọ̀ wọn ló dàgbà nínú ibi tí a fi wáyà ẹlẹ́gùn-ún ká mọ́ tàbí ní àwọn àgọ́ àdádó. Wọn kò rí màlúù tàbí ajá rí. Débi tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé olùwá-ibi-ìsádi fi rò pé jíjẹ ni koríko, kì í ṣe ohun tí a ń ṣeré tàbí sáré lóri rẹ̀. Rírí àwọn ọmọdé olùwá-ibi-ìsádi ni apá tí ń bani nínú jẹ́ jù lọ nínú iṣẹ́ mi.”—Sadako Ogata, Kọmíṣọ́nnà Àgbà Àjọ Àbójútó Ọ̀ràn Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.

[Credit Line]

Fọ́tò U.S. Navy

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Jésù Jẹ́ Olùwá-Ibi-Ìsádi Rí

Jósẹ́fù àti Màríà ń gbé ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù pẹ̀lú ọmọkùnrin wọn, Jésù. Àwọn awòràwọ̀ láti ìhà Ìwọ̀ Oòrùn mú ọrẹ wúrà, tùràrí, àti òjíá wá. Lẹ́yìn tí wọ́n lọ, áńgẹ́lì kán fara han Jósẹ́fù, ó wí pé: “Dìde, mú ọmọ kékeré náà àti ìya rẹ̀ kí o sì sá lọ sí Íjíbítì, kí o sì dúró níbẹ̀ títí èmi yóò fi bá ọ sọ̀rọ̀; nítorí Hẹ́rọ́dù ti fẹ́ máa wá ọmọ kékeré náà káàkiri láti pa á run.”—Mátíù 2:13.

Láìjáfara, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wá ibi ìsádi ní orílẹ̀-èdè òkèèrè kan—wọ́n di olùwá-ibi-ìsádi. Inú bí Hẹ́rọ́dù gan-an pé àwọn awòràwọ̀ náà kò wáá sọ ibi tí Ẹni tí a sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò di ọba àwọn Júù náà wà fún un. Nínú ìgbìyànju asán rẹ̀ láti pa Jésù, ó pàṣẹ kí àwọn ìránṣẹ́kùnrin rẹ̀ lọ pa gbogbo ọmọkùnrin kéékèèké tó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti agbègbe rẹ̀.

Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ dúró sí Íjíbítì títí di ìgbà tí áńgẹ́lì Ọlọ́run tóó fara han Jósẹ́fù lẹ́ẹ̀kan sí i nínú àlá. Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Dìde, mú ọmọ kékeré náà àti ìya rẹ̀ kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, nítorí àwọn wọnnì tí wọ́n ń wá ọkàn ọmọ kékeré náà ti kú.”—Mátíù 2:20.

Dájúdájú, Jósẹ́fù ní in lọ́kàn láti tẹ̀dó ní Jùdíà, níbi tí wọ́n ń gbé kí wọ́n tóó sá àsálà lọ sí Íjíbítì. Ṣùgbọ́n a kìlọ̀ fún un nínú àlá pé ewu wà nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù ìwà ipá tún nípa lórí ìgbésí ayé wọn. Jósẹ́fù, Màríà, àti Jésù rìnrìn àjò lọ sí àríwá ní Gálílì, wọ́n sì tẹ̀ dó ní ìlu Násárétì.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi ti sá àsálà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè míràn nítorí ẹ̀mí wọn

[Àwọn Credit Line]

Òkè lápá òsì: Albert Facelly/Sipa Press

Òkè lápá ọ̀tún: Charlie Brown/Sipa Press

Ìsàlẹ̀: Farnood/Sipa Press

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

Ọmọdékùnrin apá òsì: UN PHOTO 159243/J. Isaac

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́