ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 9/15 ojú ìwé 24-25
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—India

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—India
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdúró Gbọn-in-Gbọn-in fún Ìjọsìn Mímọ́ Gaara ní Ilé-Ẹ̀kọ́
  • A San Èrè fún Ìgbọràn sí Òfin Ọlọrun Lórí Ẹ̀jẹ̀
  • “Èmi Ti Pa Ìgbàgbọ́ Mọ́”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • “Láti Ẹnu Àwọn Ìkókó”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Mo Fara Mọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀
    Jí!—2003
  • Ẹ Rin Gẹgẹ Bi Jehofa Ti fun Yin ni Itọni
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 9/15 ojú ìwé 24-25

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—India

INDIA! Àgbáálá ilẹ̀ kékeré tí ó tẹ́ rẹrẹ yìí jẹ́ ilé fún 1 nínú 6 iye gbogbo ẹ̀dá ènìyàn tí ń gbé orí pílánẹ́ẹ̀tì yìí. Lápapọ̀, nǹkan tí ó lé ní 1,000 èdè àti èdè àdúgbò ni a ń sọ ní ilẹ̀ olónírúurú yìí. Èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn ènìyàn náà, ìpín 83 nínú ọgọ́rùn-ún wọn, jẹ́ onísìn Hindu, nígbà tí ìpín 11 nínú ọgọ́rùn-ún jẹ́ Musulumi, tí àwọn onísìn Sikh, Buddha, Jain, àti àwọn Kristian aláfẹnujẹ́ sì kó apá tí ó ṣẹ́ kù.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń gbádùn àṣeyọrí títayọ lọ́lá ní India ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Wọ́n ti rí àwọn ẹni-bí-àgùtàn tí wọ́n ti ṣe tán láti mú ìdúró wọn gbọn-in-gbọn-in sí ìhà ọ̀dọ̀ Ìjọba Jehofa, láìka oríṣiríṣi ìkìmọ́lẹ̀ àti àtakò sí.

Fún àpẹẹrẹ, ọmọbìnrin kan nínú ìdílé onísìn Hindu tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tẹ́wọ́ gbà ni àrùn rọpárọsẹ̀ ti sọ di arọ láti ìgbà ọmọdé. Ìyà tí ó jẹ ẹ́ mú kí ó ronú nípa Ọlọrun àti ète ìgbésí-ayé. Ó wo inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsìn fún ìdáhùn, ṣùgbọ́n kò rí ìtùnú kankan. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ó sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú ìsìn nù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sọ ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun nù.

Ní àsìkò yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì pàdé ọmọbìnrin yìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé wọn. Ó rántí pé: “Ẹkún gbọ̀n mí nígbà tí mo gbọ́ tí wọ́n ka Ìṣípayá 21:4.” Ó tẹ́wọ́ gba ọ̀pọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society, ó sì gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé láìka àtakò ìyá rẹ̀ sí. Ọmọbìnrin náà ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ó fi ìgboyà kojú àtakò láti ọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí, ó sì di Ẹlẹ́rìí tí a batisí. Ó sọ pé: “Mo ti tẹ̀ síwájú púpọ̀, ó sì ti jẹ́ ohun tí ó ṣòro gan-an. Ṣùgbọ́n Jehofa Ọlọrun ti máa ń fìgbà gbogbo wà pẹ̀lú mi, ó sì ti fún mi ní ọ̀pọ̀ àlááfíà àti ìdùnnú.”

Ìdúró Gbọn-in-Gbọn-in fún Ìjọsìn Mímọ́ Gaara ní Ilé-Ẹ̀kọ́

Ọmọbìnrin kékeré kan ni olùkọ́ rẹ̀ sọ fún pé kí ó bá àwọn yòókù ní kíláàsì lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki. Arábìnrin náà fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kọ̀, ní sísọ pé òun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, òun kì yóò sì jọ́sìn ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun, yàtọ̀ sí Jehofa. Olùkọ́ náà sọ pé, nígbà tí gbogbo àwọn yòókù bá lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, òun pẹ̀lú ní láti lọ. Ṣùgbọ́n arábìnrin náà dúró gbọn-in-gbọn-in, ó sì sọ pé níwọ̀n bí àwọn tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kì yóò ti gbàdúrà sí Jehofa, òun kò rí bí òun ṣe lè pésẹ̀ síbẹ̀.

Nítorí ìdúró gbọn-in-gbọn-in ọmọbìnrin náà, olùkọ́ rẹ̀ fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i. Nítorí náà, ní ọjọ́ kejì, arábìnrin náà fún un ní ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà kan lórí ìjọsìn Jehofa. Ohun tí ó kà wú u lórí púpọ̀, nígbà náà ni olùkọ́ náà yọ̀ọ̀da rẹ̀ láti má ṣe lọ́wọ́ nínú gbogbo àwọn ìgbòkègbodò ìsìn ní ilé ẹ̀kọ́. Arábìnrin náà fi ìwé ìròyìn mẹ́wàá sóde lọ́dọ̀ rẹ̀ àti àwọn olùkọ́ yòókù.

A San Èrè fún Ìgbọràn sí Òfin Ọlọrun Lórí Ẹ̀jẹ̀

Láìpẹ́ yìí, àrànkálẹ̀ àrùn ibà tí fáírọ́ọ̀sì ń fà bẹ́ sílẹ̀ ní àwọn apá ibì kan ní ìpínlẹ̀ Kerala. Òkùnrùn yìí máa ń ba kíndìnrín jẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì ń yọrí sí ṣíṣe àwọn ìyàsọ́tọ̀ kan nínú ara. Ìfàjẹ̀sínilára ni a sábà máa ń lò. Ní ìlú ńlá kan, àwọn ènìyàn 14 ni a dá dúró sí ilé-ìwòsàn nítorí òkùnrùn yìí. Ọ̀kan lára àwọn aláìsàn yìí jẹ́ Ẹlẹ́rìí, alàgbà kan nínú ìjọ àdúgbò. Wọ́n sọ fún un pé ìgbẹ̀jẹ̀sára nìkan ni ìtọ́jú tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Alàgbà náà ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ̀ tí a gbé karí Ìwé Mímọ́, ó sì fi ìdúró gbọn-in-gbọn-in kọ ẹ̀jẹ̀. (Ìṣe 15:28, 29) Lẹ́yìn ìjiyàn púpọ̀, àwọn dókítà náà sọ pé yóò kú nítorí kíkọ̀ tí ó kọ ìfàjẹ̀sínilára.

Àwọn aláìsàn 13 yòókù gba ẹ̀jẹ̀. Ó bani nínú jẹ́ pé, gbogbo wọn kú láàárín ọjọ́ díẹ̀. Arákùnrin náà nìkan ni ó là á já! Ó ya àwọn aláṣẹ ilé-ìwòsàn náà lẹ́nu púpọ̀. Ìbẹ̀wò àtìgbàdégbà tí àwọn mẹ́ḿbà ìjọ ṣe wú àwọn òṣìṣẹ́ oníṣègùn náà lórí púpọ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n tí dá a sílẹ̀ kúrò ní ilé-ìwòsàn, arákùnrin náà lọ dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn dókítà náà, ṣùgbọ́n wọ́n wí pé: “Èé ṣe tí o fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wa? Dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun rẹ, Jehofa. Oun ni Ẹni tí ó gbà ọ́ là. Jọ̀wọ́ bá àwa náà gbàdúrà sí Ọlọrun rẹ, Jehofa.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ NÍPA ORÍLẸ̀ ÈDÈ

Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1994

GÓŃGÓ IYE ÀWỌN TÍ Ń JẸ́RÌÍ: 14,271

ÌṢIRÒ ÌFIWÉRA: Ẹlẹ́rìí 1 sí 65,266

ÀWỌN TÍ Ó PÉSẸ̀ SÍBI ÌṢE ÌRÁNTÍ: 38,192

ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN AKÉDE TÍ WỌ́N JẸ́ AṢÁÁJÚ Ọ̀NÀ: 1,780

ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BIBELI: 12,453

IYE TÍ Ó ṢE BATISÍ: 1,312

IYE ÀWỌN ÌJỌ: 410

Ọ́FÍÌSÌ Ẹ̀KA: LONAVLA

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ọ́fíìsì ẹ̀ka, Lonavla

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Jíjẹ́rìí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àpéjọpọ̀ “Ìhìnrere Àìnípẹ̀kun” ní 1963

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Wíwàásù fún atàwéèròyìn kan ní ẹ̀yìn òde Red Fort ní Delhi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́