ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 6/15 ojú ìwé 13-18
  • Ẹ Rin Gẹgẹ Bi Jehofa Ti fun Yin ni Itọni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Rin Gẹgẹ Bi Jehofa Ti fun Yin ni Itọni
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Fun Wọn Ni Itọni Nipa Ẹjẹ
  • Ran Awọn Ẹlomiran Lọwọ Lati di Awọn Ti A Fun Ni Itọni
  • Ẹyin Obi—Ẹ Funni ni Itọni Daradara
  • Fifi Ẹ̀jẹ̀ Gba Ẹmi Là—Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Fi Ojú Pàtàkì Wo Ẹ̀bùn Ìwàláàyè Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 6/15 ojú ìwé 13-18

Ẹ Rin Gẹgẹ Bi Jehofa Ti fun Yin ni Itọni

“Tọ́ mi, Óò Jehofa, nipa ọna rẹ. Emi yoo rin ninu otitọ rẹ. Mu ọkan-aya mi ṣọkan lati bẹru orukọ rẹ.”—SAAMU 86:11, NW.

1, 2. Ki ni o sun awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lati kọ gbigba ifajẹsinilara?

“BOYA awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tọna ni kikọ Ìlò awọn ohun ti a fẹjẹ ṣe, nitori o jẹ otitọ pe iye pataki awọn kokoro arun ni a le ta àtaré rẹ nipasẹ ẹ̀jẹ̀ ti a fà sini lara.”—Iwe irohin ojoojumọ lede Faranse nipa iṣegun Le Quotidien du Médecin, December 15, 1987.

2 Awọn kan ti wọn ka ọrọ yẹn le ti nimọlara pe o wulẹ jẹ èèṣì lasan pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti kọ gbigba ẹ̀jẹ̀ sara tipẹ ṣaaju ki o to di mimọ ni gbogbogboo bi iwọnyi ti le jẹ elewu tó, ani ti o le ṣeku pani paapaa. Ṣugbọn iduro ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti mu lori ẹ̀jẹ̀ kii ṣe nipa èèṣì, bẹẹ si ni kii ṣe ilana ti a hùmọ̀ nipasẹ ẹya isin ajeji kan, iduro kan ti  o jẹyọ lati inu ibẹru pe ẹ̀jẹ̀ ko ṣai lewu. Kaka bẹẹ, awọn Ẹlẹrii kọ ẹ̀jẹ̀ nitori ipinnu wọn lati fi igbọran rin niwaju Atobilọla Olufunni ni Itọni wọn—Ọlọrun.

3. (a) Bawo ni Dafidi ṣe nimọlara nipa gbigbara le Jehofa? (b) Abajade wo ni Dafidi fojusọna fun nitori ninigbẹkẹle ninu Ọlọrun?

3 Ọba Dafidi, ti o nimọlara igbarale Ọlọrun rẹ, pinnu lati di ẹni ti a tọ́ nipasẹ rẹ ati lati ‘rin ninu otitọ rẹ̀.’ (Saamu 86:11) Dafidi ni a fun ni imọran nigba kan ri pe bi oun ba yẹra fun didi ẹni ti o jẹbi ẹ̀jẹ̀ ni oju Ọlọrun, ‘ọkan rẹ ni o le di eyi ti a wé sinu àpò iye pẹlu Jehofa.’ (1 Samuẹli 25:21, 22, 25, 29, NW) Gẹgẹ bi awọn eniyan ti ndi awọn ohun iyebiye pamọ lati daabobo wọn ki wọn si tọju wọn pamọ, bẹẹ ni Ọlọrun ṣe lè daabo bo ẹmi Dafidi ki o si pa a mọ. Ni titẹwọgba imọran olọgbọn naa, Dafidi ko lepa lati gba ẹmi ara rẹ là nipa awọn isapa ara ẹni ṣugbọn o nigbẹkẹle ninu Ẹni naa ti o jẹ ni gbese iwalaaye rẹ: “Iwọ yoo fi ipa ọna iye hàn mi; niwaju rẹ ni ẹ̀kún ayọ wà: ni ọwọ ọtun rẹ ni didun inu wà laelae.”—Saamu 16:11.

4. Eeṣe ti Dafidi fi fẹ ki a fun oun ni itọni lati ọdọ Jehofa?

4 Pẹlu ẹmi ironu yẹn, Dafidi ko nimọlara pe oun gẹgẹ bi ẹnikan le yan awọn ofin atọrunwa wo ni wọn lẹsẹ nilẹ tabi pọndandan lati ṣegbọran si. Ẹmi ironu rẹ̀ ni: “Tọ́ mi, Óò Jehofa, ni ọna rẹ, ki o si ṣamọna mi ni ipa-ọna ti o duro ṣanṣan.” “Tọ́ mi, Óò Jehofa, nipa ọna rẹ. Emi yoo rin ninu otitọ rẹ. Mu ọkan-aya mi ṣokan lati bẹru orukọ rẹ. Emi yin ọ, Óò Jehofa Ọlọrun mi, pẹlu gbogbo ọkan-aya mi.” (Saamu 27:11; 86:11, 12, NW) Nigba miiran ririn ninu otitọ niwaju Ọlọrun le dabi eyi ti kò báradé tabi o le tumọ si irubọ ńláǹlà, ṣugbọn Dafidi fẹ lati di ẹni ti a tọ́ ni ọna titọ ki o si rin ninu rẹ.

A Fun Wọn Ni Itọni Nipa Ẹjẹ

5. Dafidi yoo ti mọ ki ni nipa iduro Ọlọrun lori ẹ̀jẹ̀?

5 O yẹ fun akiyesi wa pe lati igba ọmọde siwaju, Dafidi ni a ti kọ ni oju-iwoye Ọlọrun nipa ẹ̀jẹ̀, oju-iwoye ti kii ṣe ohun ijinlẹ ti isin. Nigba ti a ka Ofin naa fun awọn eniyan, Dafidi yoo ti gbọ eyi: “Ẹmi ara nbẹ ninu ẹ̀jẹ̀: emi si ti fi fun yin lati maa fi ṣe etutu fun ẹmi yin lori pẹpẹ nì: nitori pe ẹ̀jẹ̀ nii ṣe etutu fun ọkan. Nitori naa ni mo ṣe wi fun awọn ọmọ Isirẹli pe, ọkan kan ninu yin ko gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹẹ ni alejo kan ti nṣe atipo ninu yin ko gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ̀.”—Lefitiku 17:11, 12; Deutaronomi 4:10; 31:11.

6. Eeṣe ti aini ti nbaa lọ fi wa fun awọn iranṣẹ Ọlọrun lati di awọn ti a fun ni itọni nipa ẹ̀jẹ̀?

6 Niwọn bi Ọlọrun ti lo Isirẹli gẹgẹ bi awọn eniyan rẹ ti a kó jọ, awọn wọnni ti wọn nfẹ lati wu u nilo lati gba itọni nipa ẹ̀jẹ̀. Atirandiran awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin Isirẹli ni a tipa bayii fun ni itọni. Ṣugbọn njẹ iru itọni bẹẹ yoo ha maa baa lọ lẹhin ti Ọlọrun ti tẹwọgba ijọ Kristian, ti o sọ wọn di “Isirẹli Ọlọrun”? (Galatia 6:16) Nitootọ, bẹẹni. Oju-iwoye Ọlọrun nipa ẹ̀jẹ̀ ko yipada. (Malaki 3:6) Ipo rẹ ti o ti sọ jade nipa ṣiṣai ṣi ẹ̀jẹ̀ lò wà ṣaaju ki majẹmu Ofin to bẹrẹ si gbeṣẹ, o si nbaa lọ lẹhin ti a ti fopin si Ofin naa.—Jẹnẹsisi 9:3, 4; Iṣe 15:28, 29.

7. Eeṣe ti jijẹ ẹni ti a fun ni itọni lati ọdọ Ọlọrun nipa ẹ̀jẹ̀ fi ṣe pataki fun wa?

7 Ọwọ fun ẹ̀jẹ̀ ṣe pataki julọ ninu isin Kristian. ‘Iyẹn kii ha ṣe asọdun bi?’ ni awọn kan le beere. Sibẹ, ki ni o ṣe pataki julọ ninu isin Kristian bi kii ba ṣe irubọ Jesu? Apọsteli Pọọlu si kọwe pe: “Ninu [Jesu] ẹni ti awa ni irapada wa nipa ẹ̀jẹ̀ rẹ, idariji ẹṣẹ wa, gẹgẹ bi ọrọ ore-ọfẹ rẹ.” (Efesu 1:7) The Inspired Letters, ti a tumọ lati ọwọ Frank C. Laubach, tumọ ẹsẹ iwe naa pe: “Ẹjẹ Kristi sanwo fun wa awa si jẹ Tirẹ nisinsinyi.”

8. Bawo ni “ogunlọgọ nla” ṣe gbarale ẹ̀jẹ̀ fun iwalaaye?

8 Gbogbo ẹni ti o ba nireti lati la “ipọnju nla” ti o sunmọle ja ati lati gbadun awọn ibukun Ọlọrun lori paradise ilẹ-aye sinmi le ẹ̀jẹ̀ Jesu ti a ta silẹ. Iṣipaya 7:9-14 ṣapejuwe wọn o si sọ lọna itọka sẹhin si ohun ti wọn ti ṣe pe: “Awọn wọnyi ni o jade lati inu ipọnju nla, wọn si fọ asọ wọn, wọn si sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọdọ Agutan naa.” Ṣakiyesi ede naa nihin-in. Ko sọ pe awọn wọnyi ti a gbala la ipọnju naa já ti ‘gba Jesu’ tabi ‘nigbagbọ ninu rẹ,’ bi o tilẹ jẹ pe iwọnni dajudaju jẹ apa pataki. O tun tẹ̀ siwaju o si wi pe wọn “fọ aṣọ wọn, wọn si sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ [Jesu].” Iyẹn jẹ nitori pe ẹ̀jẹ̀ rẹ ni ìtoye irapada.

9. Eeṣe ti ṣiṣegbọran si Jehofa nipa ẹ̀jẹ̀ fi ṣe pataki tobẹẹ?

9 Imọriri fun itoye yii ran awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọwọ lati pinnu lati maṣe ṣi ẹ̀jẹ̀ lo, ani bi oniṣegun kan ba fi òótọ́ sọ pe ifajẹsinilara ṣe pataki. Oun le gbagbọ pe awọn anfaani ti o ifajẹsinilara ti o ṣeeṣe tẹwọn ju awọn ewu ilera ti ẹ̀jẹ̀ funraarẹ gbé ka iwaju ẹni. Ṣugbọn Kristian ko le ṣáifiyesi ewu ti o tilẹ wuwo ju, ewu pipadanu ojurere Ọlọrun nipa fifohun ṣọkan lati ṣi ẹ̀jẹ̀ lò. Pọọlu sọ nigba kan ri nipa awọn wọnni ti wọn ‘mọọmọ dẹṣẹ lẹhin igba ti wọn ti gba imọ otitọ.’ Eeṣe ti ẹṣẹ eyikeyi iru iyẹn fi wuwo to bẹẹ? Nitori iru eniyan bẹẹ “ti tẹ ọmọ Ọlọrun mọlẹ . . . o si ti ka ẹ̀jẹ̀ majẹmu ti a fi sọ ọ́ di mimọ si ohun aimọ.”—Heberu 9:16-24; 10:26-29.

Ran Awọn Ẹlomiran Lọwọ Lati di Awọn Ti A Fun Ni Itọni

10. Ki ni o wa lẹhin ipinnu wa lati fasẹhin kuro ninu ẹ̀jẹ̀?

10 Awa ti a mọriri ẹbọ irapada Jesu lo iṣọra lati maṣe sọ ẹṣẹ dídá daṣa, ni ṣíṣá itoye ẹ̀jẹ̀ rẹ ti ngbẹmilà tì. Lẹhin rironu jinlẹ lori ọran naa, awa mọ daju pe imoore alailabula si Ọlọrun fun iwalaaye nilati sun wa lati ṣá fifi awọn ofin ododo rẹ bani dọrẹẹ lọnakọna tì, eyi ti a nigbọkanle pe a fi funni pẹlu ire wa didara julọ lọkan—ire wa didara julọ onigba pipẹ. (Deutaronomi 6:24; Owe 14:27; Oniwaasu 8:12) Ṣugbọn, ki ni nipa ti awọn ọmọ wa?

11-13. Oju-iwoye ti ko tọna wo nipa awọn ọmọ wọn ati ẹ̀jẹ̀ ni awọn Kristian obi kan ni, eesitiṣe?

11 Nigba ti awọn ọmọ wa jẹ ọmọ-ọwọ tabi ti wọn kere ju lati loye, Jehofa le wo wọn gẹgẹ bi ẹni mimọ tonitoni ti wọn si ṣetẹwọgba lori ipilẹ ifọkansin wa. (1 Kọrinti 7:14) Nitori naa otitọ ni pe awọn ìkókó ninu agbo ile Kristian le má tii loye ki wọn si ṣe yiyan nipa ṣiṣe igbọran si ofin Ọlọrun lori ẹ̀jẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, awa ha nṣe ohun ti a le ṣe lati fun wọn ni itọni lori ọran pataki yii bi? Awọn obi Kristian nilati gbé iyẹn yẹwo pẹlu ironu jinlẹ, nitori awọn obi kan jọ bi pe wọn ni ẹmi-ironu ti ko tọna nipa awọn ọmọ wọn ati ẹ̀jẹ̀. O dabi ẹni pe awọn kan nimọlara pe wọn ko fibẹẹ ni akoso niti gidi lori yala awọn ọmọ wọn kekere ni a fa ẹ̀jẹ̀ si lara. Eeṣe ti wọn fi ni oju-iwoye ti ko tọna yii?

12 Ọpọlọpọ ilẹ ní awọn ofin tabi awọn aṣoju ijọba lati daabobo awọn ọmọ ti a patì ti a si nlo nilokulo. Awọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a kò pa tì tabi lò nilokulo nigba ti awọn obi ba pinnu lodi si yiyọnda ki a fun ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn ti wọn fẹran gidigidi ni ẹ̀jẹ̀, ni bibeere lakoko kan naa fun ilo awọn itọju afidipo ti oogun igbalode le pese. Ani lati oju iwoye ti iṣegun paapaa, eyi kii ṣe ìpatì tabi ilo nilokulo, ni gbigbe awọn ewu iwosan ifajẹsinilara ti a jẹwọ rẹ yẹwo. O jẹ lilo ẹtọ lati gbé awọn ewu ti o wémọ́ ọn lori iwọn ati lẹhin naa lati yan itọju iṣegun naa.a Sibẹ, awọn ipese ofin ni awọn oṣiṣẹ iṣegun kan ti mú lò ni wiwa aṣẹ lati fipa fa ẹ̀jẹ̀ ti ẹnikan ko fẹ si i lara.

13 Awọn obi kan, ni mimọ pe o le rọrun fun oṣiṣẹ iṣegun kan lati gba itilẹhin ile-ẹjọ fun fifa ẹ̀jẹ̀ sara ọmọ alaitojuubọ kan, le nimọlara pe ọran ti kọja agbara wọn, pe ko si ohun ti awọn obi le ṣe tabi nilati ṣe. Ẹ wo bi oju-iwoye naa ti ṣaitọna tó!—Owe 22:3.

14. Bawo ni a ṣe fun Dafidi ati Timoti ni itọni ni igba ewe wọn?

14 A ti ṣakiyesi pe Dafidi ni a fun ni itọni ni ọna Ọlọrun lati igba ewe rẹ wá. Iyẹn mura rẹ silẹ lati ka iwalaaye gẹgẹ bi ẹbun lati ọdọ Ọlọrun ati lati mọ pe ẹ̀jẹ̀ duro fun iwalaaye. (Fiwe 2 Samuẹli 23:14-17.) Timoti ni a fun ni itọni ninu ironu Ọlọrun “lati igba ọmode.” (2 Timoti 3:14, 15) Iwọ ko ha gba pe ani nigba ti Dafidi ati Timoti kere si ọjọ ori agbalagba ti o ba ofin mu lonii, wọn ti gbọdọ le ṣalaye araawọn daradara lori awọn ọran ti o wémọ́ ifẹ-inu Ọlọrun? Lọna ti o fara jọra, ṣaaju ki wọn to dagba, awọn Kristian ọdọ lonii ni a nilati fun ni itọni ni ọna Ọlọrun.

15, 16. (a) Oju-iwoye wo ni a ti mu dagba ni awọn ibi kan nipa ẹtọ awọn ọmọ alaitojuubọ? (b) Ki ni o ṣamọna si fifun ti a fun ọmọ alaitojuubọ kan ni ẹ̀jẹ̀?

15 Ni awọn ibi kan ọmọ ti a fẹnu lasan pe ni alaitojuubọ ti o ti mọ ọwọ ọtun yatọ si osi ni a yọnda awọn ẹtọ ti o farajọ ti agbalagba fun. Ni gbigbe e kari ọjọ-ori tabi ironu agba, tabi mejeeji, ewe kan ni a le wo gẹgẹ bi ẹni ti o ti dagba tó lati ṣe awọn ipinnu tirẹ funraarẹ lori itọju iṣegun. Ani nibi ti eyi kii tii ṣe ofin naa, awọn adajọ tabi oṣiṣẹ oloye le gbe iwọn ti o pọ fun awọn idaniyan ewe kan ti o le ṣalaye ipinnu gbọnyingbọnyin rẹ kedere nipa ẹ̀jẹ̀. Ni idakeji, nigba ti ọdọ kan ko ba le ṣalaye igbagbọ rẹ kedere ati lọna ti o fi ironu han, ile-ẹjọ kan le nimọlara pe oun nilati pinnu ohun ti o dabii pe o darajulọ, bi o ti le jẹ fun ọmọ-ọwọ kan.

16 Ọdọmọkunrin kan ti kẹkọọ Bibeli ni ìdákúrekú fun ọpọlọpọ ọdun ṣugbọn ko ṣeribọmi. Laika kiku ọsẹ meje pere fun un lati de ọjọ ori nigba ti oun yoo jere “ẹtọ lati kọ iwosan iṣegun fun ara rẹ,” ile-iwosan kan ti ntọju rẹ fun arun káńsà wá itilẹhin ile-ẹjọ lati fa ẹ̀jẹ̀ sii lara lodi si idaniyan rẹ ati ti awọn obi rẹ. Adajọ naa ti o ni ẹri ọkan beere awọn ibeere lọwọ rẹ nipa awọn igbagbọ rẹ lori ẹ̀jẹ̀ o si beere awọn ibeere ipilẹ, iru bii orukọ awọn iwe marun un akọkọ inu Bibeli. Ọdọmọkunrin na ko le darukọ wọn bẹẹ ni ko si le funni ni ẹri ti o daniloju pe oun mọ idi ti oun fi kọ ẹ̀jẹ̀. Lọna ti o bani ninu jẹ, adajọ naa paṣẹ ifajẹsinilara, ni sisọ pe: “Kikọ rẹ lati fọwọ si ifajẹsinilara ni a ko gbekari oye ti o ba ọgbọn ironu mu ti awọn igbagbọ isin rẹ funraarẹ.”

17. Ipo wo ni ọmọbinrin ọlọdun mẹrinla kan dimu nipa fifun un ni ẹ̀jẹ̀, pẹlu iyọrisi wo?

17 Awọn ọran le jẹ jade lọna ti o yatọ fun ọmọ alaitojubọ kan ti a fun ni itọni daradara ninu awọn ọna Ọlọrun ti o si nrin taapọntaapọn ninu otitọ Rẹ. Kristian kan ti o tubọ kere ní iru káńsà kan naa ti o ṣọwọn. Ọmọbinrin naa ati awọn obi rẹ loye wọn si tẹwọ gba iwosan egboogi ti a palojuda fẹẹrẹfẹ lọwọ ògbógi oniṣegun ni ile iwosan ti a mọ dunju kan. Sibẹ, ọran naa ni a gbe lọ si ile-ẹjọ. Adajọ naa kọwe pe: “D.P. jẹrii pe oun yoo dena ifajẹsinilara ni ọna eyikeyi ti oun le gbà. O ka ifajẹsinilara si fífín ara rẹ níràn o si fiwe ifipábánilòpọ̀. O beere lọwọ Ile-ẹjọ naa lati bọwọ fun yíyàn oun ki wọn si yọnda oun lati wa ni [ile-iwosan naa] niṣo laijẹ pe Ile-ẹjọ paṣẹ ifajẹsinilara.” Itọni Kristian ti oun ti gba wa si iranlọwọ rẹ ni akoko iṣoro yii.—Wo apoti.

18. (a) Ọmọbinrin kan ti a pọnloju mu iduro gbọnyingbọnyin wo nipa gbigba ẹ̀jẹ̀? (b) Ki ni adajọ naa pinnu nipa itọju rẹ?

18 Ọmọbinrin ọlọdun mejila kan ni a ntọju fun arun leukemia. Aṣoju ire-alaafia ọmọde kan gbe ọran naa lọ si ile-ẹjọ ki a ba le fipa fun ọmọ naa ni ẹ̀jẹ̀. Adajọ naa pari ero pe: “L. ti sọ fun ile-ẹjọ yii ni kedere ati ni bi ọrọ ti ri gan an pe, bi a ba gbiyanju lati fa ẹ̀jẹ̀ si oun lara, oun yoo ba ifajẹsinilara naa jà pẹlu gbogbo ipa ti oun ba le sà. O sọ, mo si gba a gbọ, pe yoo figbeta yoo si jà fitafita ati pe yoo fa ohun eelo ifa nǹkan sinu ara naa jade kuro ni apa rẹ yoo si gbiyanju lati jo ẹ̀jẹ̀ ti o wa ninu apo loke ibusun rẹ. Mo kọ lati pa aṣẹ eyikeyi ti yoo mu ki ọmọ yii la iru iriri buruku bẹẹ ja . . . Pẹlu alaisan yii, itọju iṣegun ti a damọran nipasẹ ile-iwosan naa bojuto arun naa kiki nipa ti ara. O kuna lati bojuto awọn aini ti imọlara rẹ ati awọn igbagbọ isin rẹ.”

Ẹyin Obi—Ẹ Funni ni Itọni Daradara

19. Iṣẹ aigbọdọmaṣe akanṣe wo ni awọn obi nilati muṣẹ si iha-ọdọ awọn ọmọ wọn?

19 Iru awọn iriiri bẹẹ gbe ihin-iṣẹ alagbara ru fun awọn obi ti wọn fọkan fẹ pe ki gbogbo awọn ti wọn wa ninu idile wọn gbé ni ibamu pẹlu ofin Ọlọrun lori ẹ̀jẹ̀. Idi kan ti Aburahamu fi jẹ ọrẹ Ọlọrun ni pe Oun mọ pe olori idile naa yoo “fi aṣẹ fun awọn ọmọ rẹ ati fun awọn ara ile rẹ lẹhin rẹ, ki wọn ki o maa pa ọna Oluwa [“Jehofa,” NW] mọ lati ṣe ododo.” (Jẹnẹsisi 18:19) Eyi ko ha yẹ ki o jẹ otitọ nipa awọn obi Kristian lonii bi? Bi iwọ ba jẹ obi kan, iwọ ha ntọ awọn ọmọ rẹ ọwọn lati rin ni ọna Jehofa ki wọn ba le wa ‘ni imuratan nigba gbogbo lati dá olukuluku lohun ti o nbeere idi ireti ti o nbẹ ninu wọn, ṣugbọn pẹlu ọkan tutu ati ibẹru’?—1 Peteru 3:15.

20. Ki ni awa nfẹ ni pataki pe ki awọn ọmọ wa mọ̀ ki wọn si gbagbọ nipa ẹ̀jẹ̀? (Daniẹli 1:3-14)

20 Bi o tilẹ jẹ pe yoo dara fun awọn ọmọ wa lati mọ nipa awọn ewu aisan ati awọn ewu miiran ti ifajẹsinilara, fiifun awọn ọmọ wa ni itọni ninu ofin pipe ti Ọlọrun lori ẹ̀jẹ̀ ko tumọ ni pataki si gbigbiyanju lati tẹ ibẹru ẹ̀jẹ̀ mọ wọn lọkan. Fun apẹẹrẹ, bi adajọ kan ba beere lọwọ ọmọbinrin kan idi ti oun ko fi fẹ ki a fun un ni ẹ̀jẹ̀ ti idahun rẹ si jẹ ni pataki pe oun ronu pe ẹ̀jẹ̀ lewu tabi pe o ndẹru bani, ki ni yoo jẹ iyọrisi naa? Adajọ naa le pari ero pe oun ko wulẹ dagba denu o si nbẹru ju, gan an gẹgẹ bi oun ti le bẹru nitori iṣẹ abẹ appendectomy ti oun yoo si kigbe lati dena iṣẹ abẹ yii ti awọn obi rẹ paapaa nimọlara pe yoo ṣanfaani fun un. Ju bẹẹ lọ, a ti ṣakiyesi ṣaaju pe idi ipilẹ naa ti Kristian fi tako ifajẹsinilara kii ṣe pe ẹ̀jẹ̀ naa ni a ti sọ deeri ṣugbọn pe o ṣeyebiye si Ọlọrun ati Olufunni ni Iye wa. Awọn ọmọ wa nilati mọ iyẹn, ati pẹlu pe ewu iṣegun ti o ṣeeṣe ti ẹ̀jẹ̀ tubọ mu ki ipo wa nipa ti isin tẹwọn sii.

21. (a) Awọn obi nilati mọ ki ni nipa awọn ọmọ wọn ati oju-iwoye Bibeli niti ẹ̀jẹ̀? (b) Bawo ni awọn obi ṣe le ran awọn ọmọ wọn lọwọ nipa ọran ẹ̀jẹ̀?

21 Bi iwọ ba ni awọn ọmọ, o ha dá ọ loju pe wọn fohunṣọkan pẹlu wọn si le ṣalaye iduro ti a gbekari Bibeli lori ifajẹsinilara bi? Wọn ha gba iduro yii gbọ nitootọ lati jẹ ifẹ-inu Ọlọrun bi? O ha dá wọn loju pe lati ré ofin Ọlọrun kọja yoo lewu to bẹẹ debi pe o le fi ifojusọna Kristian kan fun iye ainipẹkun sinu ewu? Awọn ọlọgbọn obi yoo ṣatunyẹwo awọn ọran wọnyii pẹlu awọn ọmọ wọn, yala wọn kere gan an tabi wọn fẹrẹ to agba. Awọn obi le ni awọn akoko ifidanrawo ninu eyi ti ọdọ kọọkan dojukọ awọn ibeere ti adajọ kan tabi oṣiṣẹ oloye ile-iwosan kan le gbeka iwaju wọn. Gongo ti a nlepa naa kii ṣe lati mu ki ọdọ kan tún awọn otitọ tabi idahun ti a ṣàyàn sọ lati ori. O ṣe pataki pe ki wọn mọ ohun ti wọn gbagbọ, ati idi rẹ. Dajudaju, ni igbẹjọ kan, awọn obi naa tabi awọn ẹlomiran le pese isọfunni nipa awọn ewu ẹ̀jẹ̀ ati iwalarọọwọto awọn itọju afidipo. Ṣugbọn ohun ti o ṣeeṣe pe ki adajọ kan tabi oṣiṣẹ-oloye kan wa ọna lati mọ lati inu biba awọn ọmọ wa sọrọ ni boya wọn loye ipo wọn ati ohun ti wọn yan lọna ti o fi ironu agba han ati boya wọn tun ni awọn ọpa idiwọn ati idaniloju gbọnyingbọnyin tiwọn funraawọn.—Fiwe 2 Ọba 5:1-4.

22. Ki ni o le jẹ iyọrisi ti o wa titi lọ ti jijẹ awọn ẹni ti a tọ́ lati ọdọ Jehofa nipa ẹ̀jẹ̀?

22 Gbogbo wa nilati mọrírì ki a si gberopinnu lati di oju-iwoye Ọlọrun mu lori ẹ̀jẹ̀. Iṣipaya 1:5 ṣapejuwe Kristi gẹgẹ bi ẹni naa ti “o fẹ wa, ti o si wẹ wa ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ kuro ninu ẹṣẹ wa.” Kiki nipa titẹwọ gba itoye ẹ̀jẹ̀ Jesu ni a fi le jere idariji awọn ẹṣẹ wa ni kikun ati titi laelae. Roomu 5:9 sọ ni kedere pe: “Melomelo si ni, ti a dá wa lare nisinsinyi nipa ẹ̀jẹ̀ rẹ, ni a o gbà wa là kuro ninu ibinu nipasẹ rẹ.” Nigba naa, bawo ni o ti ba ọgbọn mu to fun wa ati fun awọn ọmọ wa lati di awọn ti a tọ lati ọdọ Jehofa lori ọran yii ati lati jẹ onipinnu lati rin ni ọna rẹ titi lae!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo How Can Blood Save Your Life?, ti a tẹ̀jade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., oju-iwe 21 si 22, 28 si 31.

Awọn Koko Pataki Itọni

◻ Oju-iwoye wo ni a nilati ni nipa jijẹ awọn ẹni ti a tọ lati ọdọ Jehofa?

◻ Eeṣe ti ṣiṣegbọran si ofin Ọlọrun lori ẹ̀jẹ̀ fi ṣe pataki tobẹẹ?

◻ Eeṣe ti o fi ṣe pataki pe ki awọn ọdọ le ṣalaye ni kedere ati ni gbọnyingbọnyin idaniloju wọn nipa ẹ̀jẹ̀?

◻ Bawo ni awọn obi Kristian ṣe le ran awọn ọmọ wọn lọwọ lati ni itọni daradara ninu ofin Jehofa lori ẹ̀jẹ̀?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

A MU ORI ILE ẸJỌ WÚ

Ki ni ipinnu ile-ẹjọ sọ nipa D.P. ti a mẹnukan ni ipinrọ 17?

“Ile-ẹjọ naa ni a wú lori gidigidi pẹlu òye, isẹraro, iyì, ati itẹnumọ ọdọ ọlọdun 14-1\2 yii. Mimọ pe oun ni iru káńsà aṣekupani kan ti le bo ọkan rẹ mọlẹ . . . Laika eyiini si, ọdọ kan ti o gbó ṣáṣá ni o wa si Ile-ẹjọ lati jẹrii. O jọ pe o ti ko afiyesi jọ ni kedere sori iṣẹ ṣiṣoro ti o doju kọ ọ́. Oun ti lọ si gbogbo awọn ijokoo igbani nimọran, fọwọsi iṣeto iwosan kan, mu ọgbọn ironu jinlẹ ti o ṣee loye dagba lori bi oun gẹgẹ bi eniyan kan yoo ṣe dojukọ ipenija iṣegun yii, o si wa si Ile-ẹjọ pẹlu ibeere ti o wọni lọkan naa: ẹ bọwọ fun ipinnu mi . . .

“Ni afikun si idagbadenu rẹ, D.P. ti sọ awọn idi ti o tẹrun jade fun ipinnu rẹ fun Ile-ẹjọ naa lati bọwọ fun un. Nipa tẹmi, nipa ti ọgbọn ero-ori, niti iwa rere, ati niti imọlara a le pa á lara nipasẹ iṣeto iwosan kan ti o ni ifajẹsinilara ninu. Ile-ẹjọ naa yoo bọwọ fun iwewee itọju ti oun yan.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Adajọ kan tabi adari ile-iwosan kan le fẹ mọ ohun ti ọdọ Kristian kan gbagbọ niti gidi, ati idi rẹ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́