Ẹyin Ọdọ—Ẹyin Yoo Ha Yege Idanwo Iduroṣinṣin Kristian Bi?
“IWỌ ko ka iwa-aimọ si aiduroṣinṣin. Iwọ wulẹ njẹgbadun ni. Lotitọ, iwọ mọ pe bi awọn obi rẹ tabi awọn alagba ba nilati mọ nipa rẹ, yoo fa ibanujẹ ọkan ati awọn ọpọlọpọ iṣoro. Ṣugbọn nigba ti iwọ ba njẹgbadun, iwọ yoo wulẹ pa gbogbo awọn ironu tì sẹgbẹkan.”
Ọdọmọkunrin ti a ṣẹṣẹ mẹnukan tan yii ti yọ́ iwa agbere dá ni abẹlẹ. Oun gbe igbesi-aye meji, ni titan awọn obi rẹ ati ijọ Kristian jẹ. Oun ko mọ nigba yẹn pe oun nkuna idanwo iduroṣinṣin Kristian kan.
Ẹgbẹẹgbẹrun awọn Kristian ọdọ ti kuna iru awọn idanwo iduroṣinṣin bẹẹ. Ko si fi bẹẹ ṣeni ni kayefi! Eeṣe, Satani Eṣu ‘njagun’ pẹlu awọn eniyan Ọlọrun, ni ṣiṣe gbogbo ohun ti o le ṣe lati ba iwatitọ wọn jẹ. (Iṣipaya 12:17) Ni pataki ni oun ti foju sun awọn ewe fun “awọn iṣe arekereke” rẹ. (Efesu 6:11, Kingdom Interlinear) Nitori naa o gba isapa gidigidi ati ipinnu lati pa iduroṣinṣin mọ.
Ani ki tilẹ ni iduroṣinṣin? Ninu Iwe mimọ lede Heberu, ipilẹṣẹ ede ọrọ naa fun “iduroṣinṣin” fi isomọ onifẹẹ kan si eniyan kan pẹlu ete kan lọkan han. (Saamu 18:25) Ko ṣapejuwe ide alailagbara kan ti a le tete já ṣugbọn isomọ kan ti o wà lai yingin titi di igba ti ete rẹ ni isopọ pẹlu onitọhun ba di eyi ti a muṣẹ. Ninu Iwe Mimọ lede Giriiki, ede ọrọ naa ní ipilẹṣẹ fun “iduroṣinṣin” gbe ironu ijẹmimọ, ododo tabi ọwọ nla jade.
Iduroṣinṣin nipa bayii wemọ ipo-ibatan rere kan pẹlu Ọlọrun. Efesu 4:24 (NW) sọ fun wa lati “gbé akopọ animọ iwa titun wọ̀ eyi ti a dá . . . ninu ododo tootọ ati iduroṣinṣin.” Iwọ ha fẹ duro ṣinṣin ti Jehofa bi? Ni igba naa iwọ gbọdọ mu isomọ oniduroṣinṣin kan pẹlu rẹ dagba, ide aláìṣeéjá kan, ipinnu kan lati wu u ni gbogbo awọn ọna rẹ. Iwọ gbọdọ rọmọ awọn ọpa idiwọn ododo ti Jehofa—laika bi o ti le dánniwò tó lati ṣe bamiiran!
Awọn Ikimọlẹ Lati Jẹ́ Alaiduroṣinṣin
Lọna ti o yẹ fun igboriyin, ọpọjulọ awọn ọdọ eniyan laaarin awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wọn ńlàkàkà lati di iduroṣinṣin wọn mu, ti wọn si ntipa bayii gbadun ẹri ọkan mimọ kan. Bi o ti wu ki o ri, apọsteli Pọọlu sọtẹlẹ pe ni “ikẹhin ọjọ,” aiduroṣinṣin yoo jẹ ami animọ awọn eniyan ni gbogbogboo. (2 Timoti 3:1, 2) Lọna ti o ba ni ninu jẹ, awọn ọdọ Kristian kan ti fi aye gba ayé alaiduroṣinṣin yii lati ‘sọ wọn da bi oun ti da.’ (Roomu 12:2, Philips) Bawo ni Satani ti ṣe aṣeyọri yii?
Ikimọlẹ ojugba jẹ irin iṣẹ gbigbeṣẹ kan ti Satani nlo. Ọpọjulọ awọn eniyan ni wọn fẹ ki awọn ẹlomiran ka wọn si ẹni yiyẹ, Satani si mọ bi a ti ṣe le kó ifẹ adanida yi nifa. Ni fifẹ ki a ri wọn gẹgẹ bi ẹni ti o wà deedee, awọn ewe Kristian kan ti lọwọ si ibanisọrọpọ ti ko peye, iwa aimọ, siga mimu, ọti amupara—koda ilokulo oogun—gbogbo rẹ nitori ki awọn ojugba wọn ba le tẹwọgba wọn.
Satani fẹ ki a ‘huwa dari ara wa ni ibamu pẹlu ifẹ ọkan ti ẹran ara, ti a nṣe awọn ohun ti ara fẹ.’ (Efesu 2:3, NW) Oun mọ bi òǹfà ifẹ ibalopọ ṣe maa nlagbara daradara tó laaarin “igba itanna ododo ewe.” (1 Kọrinti 7:36, NW) Oun si fẹ ki o juwọ silẹ fun awọn ifẹkufẹ yẹn. Awọn ewe Kristian kan laifura fi ara wọn lé Satani lọwọ nipa wiwo iwe, ere sinima ati awọn fidio arufẹ iṣekuṣe soke tabi nipa dida nikan huwa ibalopọ. Awọn nǹkan wọnyi saba maa nsunni lọ si awọn iṣe alaiduroṣinṣin ti o wuwo lẹhin naa. Aye Satani ha ti ‘sọ ọ́ dà bi oun ti da’ ninu diẹ lara awọn agbegbe yii bi?
Gbigbe Igbesi-aye Meji
Nigba ti didẹṣẹ buburu jai kan iru bi agbere ti jẹ ọran wiwuwo kan ninu ara rẹ, awọn ewe kan tun nda kun awọn iṣoro wọn. Wọn dabi awọn eniyan “alaiṣotitọ,” ti a sọrọ rẹ ninu Saamu 26:4 (NW), “Ti wọn fi ohun ti wọn jẹ pamọ.” Iru awọn ọdọ bẹẹ ngbé igbesi-aye meji, wọn nhuwa ni ọna kan nigba ti wọn ba wà papọ pẹlu awọn obi wọn tabi awọn Kristian ti wọn dagbadenu ti wọn si nhuwa ni ọna miiran nigba ti wọn ba wa papọ pẹlu awọn ojugba wọn.
Bi o ti wu ki o ri, gbigbe igbesi-aye meji nyọrisi idena aṣeyọri si rere ara-ẹni o si lewu. Awọn iwa aitọ ti a ko ká lọwọ kò fẹrẹ saba maa nsunni si awọn iwa aitọ miiran nigba gbogbo. Nigba ti ẹri ọkan ẹni le dani laamu ni igba akọkọ, bi o ba ti pẹ ti ẹnikan ti ntẹpẹlẹ mọ́ iwa aitọ to, bẹẹ ni ẹri ọkan rẹ yoo ti maa rẹlẹ ni hihuwa pada si iwa aitọ. Ẹni kan niti gidi le ‘ṣiwọ ninimọlara irora’ ni hihuwa aitọ.—Efesu 4:19, Kingdom Interlinear.
Nibi ti ọran dé yii o di ohun ti o nira gidi gan an lati jẹwọ iwa aitọ ẹni ki a si ri iranlọwọ gba. Eyi ri bẹẹ niti gidi bi awọn ewe Kristian miiran ba kopa ninu iwa aitọ naa. Imọlara iduroṣinṣin ti o gbòdì ni o saba maa nbori. Ọdọ ti a mẹnukan ni ibẹrẹ ṣalaye pe: “Iwọ mọ ohun ti iwọ nṣe lẹkun-unrẹrẹ, iwọ mọ pe ko tọna. Nitori ki awọn miiran ti ọran naa kan ma ba ko sinu ijọngbọn, iwọ gbà lati maṣe sọ fun ẹnikẹni.”
Nigba ti ẹnikan le ‘fi ohun ti o jẹ pamọ’ fun awọn obi rẹ̀ tabi ijọ, oun ko le sapamọ fun Jehofa. “Ko sì sí ẹda kan ti ko farahan niwaju rẹ, ṣugbọn ohun gbogbo ni o wa ni ihoho ti a si ṣipaya fun oju rẹ ẹni ti awa nba lò [“ni ijihin fun,” NW].” (Heberu 4:13) Bibeli mu dá wa loju pe: “Ẹni ti o ba bo ẹṣẹ rẹ mọlẹ ki yoo ṣe rere [“aṣeyọrisi rere,” NW].” (Owe 28:13) Iwa aitọ naa ni a o túfo nigba ti o ba ya. Ẹnikan ko wulẹ le gbọn féfé ju Jehofa lọ. Owe 3:7 sọ pe: “Maṣe ọlọgbọn ni oju ara rẹ. Bẹru Oluwa [“Jehofa,” NW] ki o si kuro ninu ibi.” Tun ranti pe, “Oju Oluwa [“Jehofa,” NW] nbẹ ni ibi gbogbo, o nwo awọn ẹni buburu ati ẹni rere.”—Owe 15:3.
Ọdọ ti a mẹnukan ni ibẹrẹ pẹlu ọpọlọpọ awọn miiran ti wọn nipa ninu iwa aitọ abẹlẹ naa, ni a tipa bayi ridii rẹ, oun ati awọn alabakẹgbẹ rẹ ni a si nilati lé jade kuro ninu ijọ Kristian. Lẹhin naa wọn jere ipo tẹmi wọn pada a si gbà wọn pada. Sibẹ, ẹ wo ọna lile koko ti o jẹ lati kẹkọọ itumọ iduroṣinṣin!
‘Mimu Awọn Ọran’ Tọ Pẹlu Ọlọrun
Ki ni bi ẹnikan ba ti fi aiduroṣinṣin han ni ọna kan, boya nipa hihuwa aitọ kan? O rọrun lati tan ara ẹni jẹ ki ẹni naa si sẹ́ aini fun atunṣe awọn ọran. Ọdọ kan ti o yọ́lẹ̀ ṣagbere sọ pe: “Mo fi kun iṣẹ isin papa mi, ni riro pe eyi ni ọna kan ṣa yoo bo iwa aitọ naa mọlẹ.” Ni ọna kan naa, orilẹ-ede Isirẹli oniwa wiwọ gbiyanju lati tu Jehofa loju pẹlu awọn irubọ. Ṣugbọn Jehofa kọ iru ifọkansin alagabagebe bẹẹ silẹ. Oun rọ̀ wọn pe: “Ẹ wẹ̀, ki ẹ mọ; mu buburu iṣẹ yin kuro ni iwaju oju mi: dawọ duro lati ṣe buburu.” Jehofa yoo tẹwọgba awọn irubọ wọn kiki lẹhin igba ti wọn ba ti ‘mu awọn koko ọran tọ́ taarata pẹlu rẹ.’ Ohun kan naa ni o jẹ otitọ lonii fun ẹnikẹni ti o ba nipa ninu iwa aitọ.—Aisaya 1:11, 15-18.
Ẹnikan ko le mu awọn koko ọran tọ́ taarata pẹlu Jehofa kiki nipa sisọrọ aṣiri fun ojugba kan. Fun ohun kan, awọn ojugba kii fi igba gbogbo funni ni iranlọwọ ti o dara ju, niwọn bi awọn pẹlu lọpọ igba ko tii fi bẹẹ niriiri igbesi-aye. Lọna ti o ṣe pataki ju, wọn ko le dari ẹṣẹ rẹ ji ọ. Ọlọrun nikan ni o le ṣe iyẹn. Nitori naa “tu ọkan rẹ jade” niwaju rẹ̀ fun ijẹwọ ẹṣẹ. (Saamu 62:8) Bi o tilẹ jẹ pe itiju nla le ba ọ nitori iwa rẹ, jẹ ki o dá ọ loju pe Jehofa ndari ‘jì ni lọpọlọpọ.’—Aisaya 55:7.
Iwọ yoo nilo afikun iranlọwọ. “Jẹ ki awọn obi rẹ mọ, jẹ ki awọn alagba mọ ni kiakia—ni ibẹrẹpẹpẹ,” ni ọdọ Kristian kan ti o jere iru iranlọwọ bẹẹ gbani niyanju. Bẹẹni, o ṣeeṣe ki awọn obi rẹ wa ni ipo ti o dara lati ran ọ lọwọ. “Sọ ohun ti o wa lọkan rẹ” fun wọn, nipa jijẹ ki wọn mọ bi awọn iṣoro rẹ ti gbooro tó. (Owe 23:26) Wọn le ṣeto fun ọ lati gba iranlọwọ sii lati ọdọ awọn alagba ijọ nigba ti iyẹn ba pọndandan.—Jakọbu 5:14, 15.
Fifi Iduroṣinṣin Tootọ Han —Lọna wo?
Dajudaju, yoo jẹ ohun ti o dara julọ lati maṣe ko sinu iwa aiduroṣinṣin rara. Saamu 18:25 sọ fun wa pe: “Fun alaanu ni iwọ [Jehofa] yoo fi ara rẹ han ni alaanu; fun ẹni ti o duro ṣinṣin ni iwọ yoo fi ara rẹ han ni diduroṣinṣin.” Jehofa nbukun awọn wọnni ti wọn fi iduroṣinṣin pa awọn ọpa idiwọn giga ti iwa mọ lọpọlọpọ.
Bi o ti wu ki o ri, awọn ọna miiran wa ninu eyi ti a le gba dan iduroṣinṣin rẹ wo. Fun apẹẹre, ki a sọ pe ọrẹ rẹ kan ti dawọ le ipa ọna oniwa wiwọ kan. Iwọ yoo ha jẹ ki iduroṣinṣin rẹ ti o ṣì gbé fun ọrẹ yẹn ṣijibo iduroṣinṣin rẹ ti Jehofa bi? Ohun ti o ba ifẹ mu lati ṣe ni lati tọ ọrẹ yẹn lọ ki o si rọ̀ ọ́ lati sọ ọrọ naa fun awọn obi rẹ̀ tabi awọn alagba. Sọ fun ọrẹ rẹ pe bi oun ko ba ṣe bẹẹ laaarin iwọn akoko ti o bojumu kan, iwọ yoo nilati ṣe bẹẹ funraarẹ. Owe 27:5 wipe: “Ibawi ni gbangba san ju ifẹ ti o farasin lọ.” Nipa ṣiṣeranlọwọ fun ọrẹ rẹ ni ọna yii, kii wulẹ ṣe pe iwọ nfi ojulowo ibadọrẹẹ rẹ han nikan ni, ṣugbọn iwọ tun nfi bi iduroṣinṣin rẹ ti Jehofa ti jinlẹ to han.
Ohun yoowu ki idanwo naa le jẹ, okun lati le fi iduroṣinṣin han njẹyọ jade lati inu nini ibatan timọtimọ ti o lagbara kan pẹlu Jehofa. Adura onitumọ ati idakẹkọọ alaapọn funra ẹni ṣe pataki bi a ba nilati gbadun iru ibatan kan bẹẹ. Lọna ti o dun mọni ninu, gbogbo awọn ewe ti wọn ṣaṣiṣe ti a mẹnukan siwaju gba pe awọn adura wọn ati awọn iṣe aṣa idakẹkọọ funra ẹni wọn ti di alafaraṣe mafọkanṣe—ti wọn ko si ṣe mọ nigba ti o ya. Jehofa ko jẹ gidi si wọn mọ, iwa aimọ si tẹle e laipẹ. Iwọ, nipa adura ati idakẹkọọ funra ẹni, ha nfun ibatan rẹ pẹlu Jehofa lokun ki o ba le di iduroṣinṣin rẹ mu bi?
Nitootọ, nigba miiran iwọ le ṣekayefi boya iwọ npadanu igbadun ara ẹni. “Ni awọn igba miiran, o maa njọ bi ẹni pe awọn eniyan aye njẹgbadun,” ni ọdọbinrin kan sọ. “Ṣugbọn nigba ti a ba kẹ́kùn mu ọ ninu ọran kan, iwọ le ri pe kii ṣe igbadun rara.” Oun sọrọ lati inu iriri, ni lilọwọ ninu iwa aimọ takọtabo, ti o yọrisi oyun ati iṣẹyun. “Wiwa ninu otitọ jẹ idaabobo kan,” ni oun wa sọ nisinsinyi—ẹkọ kan ti oun kọ́ lọna ti o le koko. Saamu 119:165 ran wa leti pe “awọn ti o fẹ ofin [Ọlọrun] ni alaafia pupọ.”
Nitori naa, ṣe gbogbo ohun ti o le ṣe lati di iduroṣinṣin mu. Ṣiṣẹ lori nini ipo-ibatan ti o wà pẹ́ titi kan pẹlu Jehofa. Koriira ohun tii ṣe buburu ki o si rọ mọ ohun tii ṣe rere. (Roomu 12:9) Saamu 97:10 sọ fun wa pe: “Ẹyin ti o fẹ Oluwa [“Jehofa,” NW] ẹ koriira ibi. O pa ọkan awọn eniyan mimọ rẹ mọ; o gba wọn ni ọwọ awọn eniyan buburu.” Bẹẹni, gẹgẹ bi ọdọ Kristian kan, iwọ yoo janfaani lati inu idaabobo Jehofa iwọ yoo si gbadun iye ayeraye bi iwọ ba yege idanwo iduroṣinṣin Kristian naa.