Kíkojú Ìpènijà Ìdúróṣinṣin
“Gbé àkópọ̀ ìwà titun wọ̀ èyí tí a dá ní ìbámu pẹlu ìfẹ́-inú Ọlọrun ninu òdodo tòótọ́ ati ìdúróṣinṣin.”—EFESU 4:24.
1. Èé ṣe tí a fi jẹ Jehofa Ọlọrun ní gbèsè ìdúróṣinṣin?
KÍKOJÚ ìpènijà ìdúróṣinṣin ní oríṣiríṣi apá. Èyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni kíkojú ìpènijà ìdúróṣinṣin sí Jehofa Ọlọrun. Ní tòótọ́, lójú ìwòye irú ẹni tí Jehofa jẹ́, àti ohun tí ó ṣe fún wa, àti nítorí ìyàsímímọ́ wa sí i, a jẹ ẹ́ ní gbèsè ìdúróṣinṣin. Báwo ni a ṣe ń fi ìdúróṣinṣin sí Jehofa Ọlọrun hàn? Ọ̀nà tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni nípa jíjẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn ìlànà òdodo Jehofa.
2, 3. Ipò ìbátan wo ni ó wà láàárín ìdúróṣinṣin àti òdodo?
2 Láti lè kojú ìpènijà náà, a gbọ́dọ̀ kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a rí nínú 1 Peteru 1:15, 16 pé: “Ní ìbámu pẹlu Ẹni Mímọ́ tí ó pè yín, kí ẹ̀yin fúnra yín pẹlu di mímọ́ ninu gbogbo ìwà yín, nitori a kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nitori tí emi jẹ́ mímọ́.’” Ìdúróṣinṣin sí Jehofa Ọlọrun yóò sún wa láti ṣègbọràn sí i ní gbogbo ìgbà, ní mímú àwọn èrò, ọ̀rọ̀, àti ìṣe wa wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú rẹ̀ mímọ́. Ó túmọ̀ sí pípa ẹ̀rí ọkàn rere mọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ fún wa nínú 1 Timoteu 1:3-5 pé: “Níti gidi ète-ìlépa àṣẹ pàtàkì yii [láti má ṣe fi awọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí ó yàtọ̀ kọ́ni tàbí fiyè sí awọn ìtàn èké] ni ìfẹ́ lati inú ọkàn-àyà tí ó mọ́ ati lati inú ẹ̀rí-ọkàn rere ati lati inú ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè.” Lóòótọ́, kò sí ẹni tí ó pé nínú wa, ṣùgbọ́n a ní láti máa gbìyànjú láti ṣe gbogbo èyí tí a bá lè ṣe, àbí kò yẹ bẹ́ẹ̀?
3 Ìdúróṣinṣin sí Jehofa yóò mú kí a fà sẹ́yìn kúrò nínú fífi ìmọtara ẹni nìkan fi àwọn ìlànà òdodo báni dọ́rẹ̀ẹ́. Ní ti gidi, ìdúróṣinṣin yóò mú kí a fà sẹ́yìn kúrò nínú jíjẹ́ alágàbàgebè. Ìdúróṣinṣin ni ohun tí onipsalmu ní lọ́kàn nígbà tí ó kọrin pé: “Oluwa, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ; èmi óò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ: mú àyà mi ṣọ̀kan láti bẹ̀rù orúkọ rẹ.” (Orin Dafidi 86:11) Ìdúróṣinṣin béèrè fún ohun ti a ṣàpèjúwe dáradára gẹ́gẹ́ bí “ìgbọràn sí àwọn ohun aláìṣeéfipámúniṣe.”
4, 5. Ìdúróṣinṣin yóò mú wa ṣọ́ra, kí a má baà ṣe kí ni?
4 Ìdúróṣinṣin sí Jehofa Ọlọrun yóò mú kí a fà sẹ́yìn kúrò nínú ṣíṣe ohunkóhun tí yóò mú ẹ̀gàn wá sórí orúkọ àti Ìjọba rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn Kristian méjì kan kó wọnú irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ara wọn débi pé wọ́n wọ́ ara wọn lọ sí ilé ẹjọ́ ayé, èyí tí kò tọ́. Adájọ́ náà béèrè pé, ‘Ṣe Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ẹ̀yin méjèèjì?’ Ó dájú pé, ohun tí wọ́n wá dé ilé ẹjọ́ kò yé e. Ẹ wo irú ẹ̀gàn tí ìyẹ́n jẹ́! Ìdúróṣinṣin sí Jehofa Ọlọrun yẹ kí ó ti sún àwọn arákùnrin wọ̀nyí láti kọbi ara sí ìmọ̀ràn aposteli Paulu pé: “Níti gidi, nígbà naa, gbogbo-ẹ̀ gbògbò-ẹ̀ ó túmọ̀ sí ìpaláyò fún yín pé ẹ̀yin ń pe ara yín lẹ́jọ́ lẹ́nìkínní kejì. Èéṣe tí ẹ kò kúkú jẹ́ kí a ṣe àìtọ́ sí ẹ̀yin fúnra yín? Èéṣe tí ẹ kò kúkú jẹ́ kí a lu ẹ̀yin fúnra yín ní jìbìtì?” (1 Korinti 6:7) Dájúdájú, ipa ọ̀nà ìdúróṣinṣin sí Jehofa Ọlọrun ni láti pàdánù àwọn nǹkan ìní tẹni dípò kíkó ẹ̀gàn bá Jehofa àti ètò àjọ rẹ̀.
5 Ìdúróṣinṣin sí Jehofa Ọlọrun tún kan ṣíṣàìjuwọ́ sílẹ̀ fún ìbẹ̀rù ènìyàn. “Ìbẹ̀rù ènìyàn ní í mú ìkẹkùn wá: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Oluwa ni a óò gbé lékè.” (Owe 29:25) Nípa báyìí, a kò ní juwọ́ sílẹ̀ nígbà tí a bá dojú kọ inúnibíni, ṣùgbọ́n a óò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí, fi lélẹ̀ ní Malawi, ní Etiopia, àti ní ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè míràn.
6. Ìdúróṣinṣin yóò mú wa fà sẹ́yìn kúrò nínú dídára pọ̀ mọ́ àwọn wo?
6 Bí a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jehofa Ọlọrun, a óò yẹra fún bíbá àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá rẹ̀ ṣọ̀rẹ́. Ìdí nìyẹn tí ọmọ ẹ̀yìn náà Jakọbu fi kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin panṣágà obìnrin, ẹ kò ha mọ̀ pé ìṣọ̀rẹ́ pẹlu ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹlu Ọlọrun? Nitori naa, ẹni yòówù tí ó bá fẹ́ lati jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọrun.” (Jakọbu 4:4) A fẹ́ láti ní ìdúróṣinṣin tí Ọba Dafidi fi ẹ̀rí rẹ̀ hàn nígbà tí ó wí pé: “Oluwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tí ó kórìíra rẹ? ǹjẹ́ inú mi kò ha sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ? Èmí kórìíra wọn ní àkótán: èmí kà wọ́n sí ọ̀tá mi.” (Orin Dafidi 139:21, 22) A kò ní láti máa ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tí ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, nítorí a kò fi ohunkóhun jọ wọ́n. Ìdúróṣinṣin sí Ọlọrun kò ha ní mú wa fà sẹ́yìn kúrò nínú ṣíṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn ọ̀tá Jehofa bẹ́ẹ̀ bí, yálà lójúkorojú tàbí nípasẹ̀ tẹlifíṣọ̀n?
Gbígbèjà Jehofa
7. Kí ni ìdúróṣinṣin yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe nípa Jehofa, báwo sì ni Elihu ti ṣe èyí?
7 Ìdúróṣinṣin yóò sún wa láti gbèjà Jehofa Ọlọrun. Ẹ wo irú àpẹẹrẹ rere tí Elihu jẹ́ fún wa! Jobu 32:2, 3 sọ fún wa pé: ‘Inú bí Elihu . . . ó bínú sí Jobu, nítorí tí ó dá ara rẹ̀ láre kàkà kí ó dá Ọlọrun láre. Inú sì bí i sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nítorí tí wọ́n kò ní ìdáhùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn dá Ọlọrun lẹ́bi.’ Ní Jobu orí 32 dé 37, Elihu gbèjà Jehofa. Fún àpẹẹrẹ, ó wí pé: “Bùn mi láyè díẹ̀, èmi óò sì fi hàn ọ́, nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ni ó kù fún Ọlọrun. . . . Èmi óò sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi. . . . Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo.”—Jobu 36:2-7.
8. Èé ṣe tí a fi ní láti gbèjà Jehofa?
8 Èé ṣe tí a fi ní láti gbèjà Jehofa? Lónìí, a ń sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun wa, Jehofa, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Wọ́n sọ pé Jehofa kò sí, pé ó jẹ́ apá kan Mẹ́talọ́kan, pé ó ń dá ènìyàn lóró gbére nínú hẹ́ẹ̀lì oníná, pé lọ́nà aláìlera, ó ń gbìyànjú láti yí aráyé lọ́kàn padà, pé kò bìkítà nípa aráyé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. A ń fi ìdúróṣinṣin wa hàn nípa gbígbèjà rẹ̀ àti fífi ẹ̀rí hàn pé Jehofa wà; pé ó jẹ́ Ọlọrun tí ó gbọ́n, onídàájọ́ òdodo, alágbára gbogbo, àti onífẹ̀ẹ́; pé ó ní àkókò fún gbogbo nǹkan; àti pé nígbà tí àkókò rẹ̀ bá tó, yóò mú òpin dé bá gbogbo ibi, yóò sì sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di paradise kan. (Oniwasu 3:1) Èyí ń béèrè pé kí a lo gbogbo àǹfààní tí a ní láti jẹ́rìí sí orúkọ Jehofa àti Ìjọba rẹ̀.
Ìdúróṣinṣin sí Ètò Àjọ Jehofa
9. Lórí àwọn ọ̀ràn wo ni àwọn kan ti fi àìdúróṣinṣin wọn hàn?
9 Nísinsìnyí, a dé orí ọ̀ràn jíjẹ́ adúróṣinṣin sí ètò àjọ Jehofa tí ó ṣeé fojú rí. Dájúdájú, a jẹ̀ ẹ́ ní gbèsè ìdúróṣinṣin, títí kan “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú,” nípasẹ̀ èyí tí a ti ń bọ́ ìjọ Kristian nípa tẹ̀mí. (Matteu 24:45-47) Rò ó pé ohun kan jáde nínú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower tí a kò lóye tàbí fara mọ́ ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Kí ni a óò ṣe? Ṣé, kí á bínú kí a sì fi ètò àjọ náà sílẹ̀? Ohun tí àwọn kan ṣe nìyẹn, ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, nígbà tí Ile-Iṣọ Na so májẹ̀mú tuntun náà pọ̀ mọ́ Ìjọba Ẹgbẹ̀rún Ọdún. Àwọn kan bínú sí ohun tí Ilé-Ìṣọ́nà sọ nígbà kan lórí ọ̀ràn àìdásí-tọ̀tún-tòsì. Bí àwọn tí ọ̀ràn wọ̀nyí mú kọsẹ̀ bá ti jẹ́ adúróṣinṣin sí ètò àjọ náà àti àwọn arákùnrin wọn ni, wọn ì bá ti dúró de Jehofa láti yanjú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí, èyí tí ó ṣe nígbà tí ó tó àkókò lójú rẹ̀. Nípa báyìí, ìdúróṣinṣin kan fífi sùúrù dúró títí tí olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú yóò fi tẹ àfikún òye síta.
10. Kí ni ìdúróṣinṣin yóò fà wá sẹ́yìn láti má ṣe ní ìfẹ́ ìtọpinpin nínú rẹ̀?
10 Ìdúróṣinṣin sí ètò àjọ Jehofa tí ó ṣeé fojú rí tún túmọ̀ sí ṣíṣàìní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú àwọn apẹ̀yìndà. Àwọn Kristian adúróṣinṣin kì yóò ní ìfẹ́ ìtọpinpin nípa ohun tí àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ní láti sọ. Lóòótọ́, àwọn tí Jehofa Ọlọrun ń lò láti darí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé kì í ṣe ẹni pípé. Ṣùgbọ́n kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní kí á ṣe? Ṣé kí a fi ètò àjọ Ọlọrun sílẹ̀ ni? Rárá. Ìfẹ́ni ará yóò jẹ́ kí a jẹ́ adúróṣinṣin sí i, a óò sì máa bá a lọ láti ‘nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kíní-kejì lọ́nà gbígbóná janjan láti inú ọkàn-àyà wá.’—1 Peteru 1:22.
Ìdúróṣinṣin sí Àwọn Alàgbà Adúróṣinṣin
11. Ìrònú òdì wo ni ìdúróṣinṣin yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣọ́ra fún?
11 Nígbà tí a bá sọ tàbí ṣe ohun kan nínú ìjọ, tí ó nira fún wa láti lóye, ìdúróṣinṣin yóò fà wá sẹ́yìn kúrò nínú ṣíṣe ìdájọ́ ohun tí ó fa ìsúnniṣe náà, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìdúró pé bóyá ó jẹ́ ọ̀ràn ṣíṣe iṣẹ́ tí a yàn fún wọn. Kò ha dára jù lọ láti ronú lórí àwọn ànímọ́ rere tí àwọn alàgbà tí a yàn sípò àti àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ní ju kí a máa ronú lórí àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó wọn? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kí a ṣọ́ra fún ìrònú òdì bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó ní í ṣe pẹ̀lú jíjẹ́ aláìdúróṣinṣin! Ìdúróṣinṣin yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sí ìtọ́ni Paulu “lati máṣe sọ̀rọ̀ ẹni kankan lọ́nà ìbàjẹ́.”—Titu 3:1, 2.
12, 13. Àwọn ìpènijà wo ní pàtàkì ni àwọn alàgbà ní láti kojú?
12 Ìdúróṣinṣin ń mú ìpènijà wá fún àwọn alàgbà ní pàtàkì. Ọ̀kan nínú àwọn ìpènijà yìí ni ọ̀ràn pípa ọ̀ràn àṣírí mọ́. Mẹ́ḿbà kan nínú ìjọ lè finú tán alàgbà kan. Ìdúróṣinṣin sí ẹni náà yóò mú kí alàgbà náà fà sẹ́yìn kúrò nínú títẹ ìlànà pípa ọ̀ràn àṣírí mọ́ lójú. Yóò kọbi ara sí ìmọ̀ràn tí ó wà nínú Owe 25:9 pé: “Àṣírí ẹlòmíràn ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi hàn.” Èyí túmọ̀ sí pé kò gbọdọ̀ sọ ọ́ fún ìyàwó rẹ̀ pàápàá!
13 Àwọn alàgbà tún ní àwọn ìdánwò ìdúróṣinṣin mìíràn láti kojú. Wọn yóò ha jẹ́ atẹ́-ènìyàn-lọ́rùn bí, tàbí wọn yóò ha fi ìgboyà àti inú tútù ran àwọn tí wọ́n nílò ìtọ́sọ́nà lọ́wọ́, àní bí wọ́n bá jẹ́ ìbátan tàbí ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́ bí? Ìdúróṣinṣin sí ètò àjọ Jehofa yóò sún àwa tí a jẹ́ alàgbà láti gbìyànjú láti ran ẹni tí ó bá nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí lọ́wọ́. (Galatia 6:1, 2) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a óò jẹ́ onínú rere, ìdúróṣinṣin yóò jẹ́ kí a má ṣe fọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà ẹlẹgbẹ́ wa, gan-an gẹ́gẹ́ bí Paulu kò ti fọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ nígbà tí ó ń bá aposteli Peteru sọ̀rọ̀. (Galatia 2:11-14) Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn alábòójútó ní láti ṣọ́ra, kí wọ́n má baà fi híhùwà pẹ̀lú àìlọ́gbọ́n, tàbí ṣíṣe ojúsàájú, tàbí ṣíṣi ọlá àṣẹ wọn lò ní àwọn ọ̀nà míràn, mú kí ó ṣòro fún àwọn tí wọ́n wà ní ìkáwọ́ wọn láti jẹ́ adúróṣinṣin sí ètò àjọ Ọlọrun.—Filippi 4:5.
14, 15. Àwọn kókó abájọ wo ni ó lè fi ìdúróṣinṣin àwọn mẹ́ḿbà ìjọ sábẹ́ àdánwò?
14 Àwọn apá mìíràn wà tí ó ní í ṣe pẹ̀lú kíkojú ìpènijà ìdúróṣinṣin sí ìjọ àti àwọn alàgbà rẹ̀. Bí ohun tí ó dà bí ipò ìṣòro bá wà nínú ìjọ, èyí ń fún wa ní àǹfààní láti fi ìdúróṣinṣin wa sí Jehofa àti àwọn tí ń ṣojú fún un hàn. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà, June 15, 1987, ojú ìwé 15 sí 17.) Nígbà tí a bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, ìdúróṣinṣin béèrè pé kí a ti àwọn alàgbà lẹ́yìn, kì í ṣe gbígbìyànjú láti ronú àwọn ọ̀nà tí wọn ì bá ti gbà bí ìdí tí ó tó bá wà fún irú ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé.
15 Ìdúróṣinṣin sí ìjọ tún béèrè pé kí a ṣètìlẹyìn fún àwọn ìpàdé márùn-ún ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ dé ìwọ̀n tí agbára wa àti ipò wa bá mọ. Kì í ṣe pípésẹ̀ síbẹ̀ déédéé nìkan ni ìdúróṣinṣin ń béèrè, ṣùgbọ́n mímúra wọn sílẹ̀, kí a sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìlóhùnsí tí ń gbéni ró bí àǹfààní bá ti ṣí sílẹ̀ tó.—Heberu 10:24, 25.
Ìdúróṣinṣin Nínú Ìgbéyàwó
16, 17. Àwọn ìpènijà wo ní ti ìdúróṣinṣin ni àwọn Kristian tí wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó ní láti dojú kọ?
16 Ta tún ni a jẹ ní gbèsè ìdúróṣinṣin? Bí a bá ti ṣe ìgbéyàwó, ní ojú ìwòye àwọn ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wa, a ní láti kojú ìpènijà jíjẹ́ adúróṣinṣin sí ẹnì kejì wa nínú ìgbéyàwó. Ìdúróṣinṣin sí ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó yóò mú kí a yẹra fún ṣíṣe àṣìṣe ti jíjẹ́ ẹni rere sí àwọn obìnrin tàbí ọkùnrin mìíràn ju bí a ṣe jẹ́ sí ọkọ tàbí aya wa lọ. Ìdúróṣinṣin sí ẹnì kejì wa nínú ìgbéyàwó tún ń béèrè pé kí a má ṣe ṣí àwọn àléébù àti ìkùdíẹ̀-káàtó ẹnì kejì wa nínú ìgbéyàwó payá fún àwọn ará ìta. Ó rọrùn láti ráhùn fún àwọn ẹlòmíràn ju bí ó ti rí láti ṣiṣẹ́ kára láti ṣí ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ẹnì kejì wa nínú ìgbéyàwó lọ, èyí tí ó yẹ kí a ṣe ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Oníwúrà. (Matteu 7:12) Ní tòótọ́, ipò ìgbéyàwó ń mú ìpènijà gidi wá fún ìdúróṣinṣin Kristian wa.
17 Láti lè kojú ìpènijà ìdúróṣinṣin yìí, kì í ṣe kìkì pé a ní láti yẹra fún jíjẹ̀bi ìwà àìtọ́ bíburú lé kenkà nìkan ni, ṣùgbọ́n a tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ èrò àti ìmọ̀lára wa gidigidi. (Orin Dafidi 19:14) Fún àpẹẹrẹ, bí ọkàn-àyà wa ẹlẹ́tàn bá ní ìwọra fún ìgbádùn àti mùkẹ́ẹ̀kẹ̀, ó rọrùn fún wa láti fi ìmọtara ẹni lọ láti orí nínífẹ̀ẹ́ ohun náà di fífẹ́ ẹ. Nígbà tí ó ń rọ̀ wọ́n láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ìgbéyàwó, Ọba Solomoni fún àwọn ọkọ nímọ̀ràn láti ‘mu omi’ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ‘láti inú kùdu wọn.’ (Owe 5:15) Jesu sì wí pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan lati ní ìfẹ́ onígbòónára sí i ti ṣe panṣágà pẹlu rẹ̀ ná ninu ọkàn-àyà rẹ̀.” (Matteu 5:28) Àwọn ọkọ tí wọ́n bá ń kó wọnú wíwò tàbí kíka ìwé tí a pète láti ru ìbálòpọ̀ takọtabo sókè ni ó ṣeé ṣe kí a dẹ wò lọ sínú ṣíṣe panṣágà, kí wọ́n sì tipa báyìí rẹ́ àwọn ìyàwó wọn jẹ, kí wọ́n sì di aláìdúróṣinṣin sí wọn. Nítorí ìdí kan náà, aya kan tí eré orí tẹlifíṣọ̀n tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àgbèrè ti gbà lọ́kàn, ni a lè dán wò láti di aláìdúróṣinṣin sí ọkọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, nípa jíjẹ́ adúróṣinṣin ní tòótọ́ sí ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó, a ń fún ìdè ìgbéyàwó lókun sí i, a sì ń ran ara wa lọ́wọ́ lẹ́nì kíní-kejì nínú ìsapá wa láti wu Jehofa Ọlọrun.
Àwọn Ìrànwọ́ Láti Máa Bá A Lọ ní Jíjẹ́ Adúróṣinṣin
18. Mímọrírì kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin?
18 Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìpènijà ìdúróṣinṣin ní àwọn ọ̀nà mẹ́rin wọ̀nyí: ìdúróṣinṣin sí Jehofa, sí ètò àjọ rẹ̀, sí ìjọ, àti sí ẹnì kejì wa nínú ìgbéyàwó? Ìrànlọ́wọ́ kan ni mímọ̀ pé kíkojú ìpènijà ìdúróṣinṣin ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ìdáláre ipò ọba aláṣẹ Jehofa. Bẹ́ẹ̀ ni, nípa dídúró gẹ́gẹ́ bí adúróṣinṣin, a ń fi hàn pé a ń wo Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Àgbáyé. Nípa báyìí, a tún lè ní ọ̀wọ̀ ara ẹni àti ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun ti Jehofa. A lè ran ara wa lọ́wọ́ láti dúró gẹ́gẹ́ bí adúróṣinṣin nípa gbígbé àwọn àpẹẹrẹ àtàtà ti ìdúróṣinṣin wò, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jehofa títí dórí àwọn tí a mẹ́nu kàn nínú Bibeli àti nínú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower, títí kan àwọn àkọsílẹ̀ Yearbook.
19. Ipa wo ni ìgbàgbọ́ ń kó nínú jíjẹ́ adúróṣinṣin?
19 Ìgbàgbọ́ tí ó lágbára nínú Jehofa Ọlọrun àti ìbẹ̀rù ṣíṣe ohun tí kò wù ú yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìpènijà ìdúróṣinṣin. A ń fún ìgbàgbọ́ wa nínú Jehofa lókun, a sì ń bẹ̀rù rẹ̀ nípa fífi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti nípa lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Paulu tí a kọ sílẹ̀ nínú Efesu 4:23, 24 pé: “Ẹ di titun ninu ipá tí ń mú èrò-inú yín ṣiṣẹ́, kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà titun wọ̀ èyí tí a dá ní ìbámu pẹlu ìfẹ́-inú Ọlọrun ninu òdodo tòótọ́ ati ìdúróṣinṣin.”
20. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ànímọ́ wo ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jehofa, àti sí gbogbo àwọn mìíràn tí a jẹ ní gbèsè ìdúróṣinṣin?
20 Mímọrírì àwọn ànímọ́ Jehofa ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìfẹ́ aláìmọtara ẹni nìkan fún Bàbá wa ọ̀run àti ọpẹ́ fún gbogbo ohun tí ó ṣe fún wa, nínífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa, ọkàn àti èrò-inú àti okun wa, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Síwájú sí i, níní ìfẹ́ tí Jesu sọ pé yóò jẹ́ àmì ìdánimọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí gbogbo Kristian nínú ìjọ àti nínú ìdílé wa. Ní èdè míràn, ní ti gidi, ó jẹ́ ọ̀ràn mímọ tara ẹni nìkan tàbí ṣíṣàìmọ tara ẹni nìkan. Àìdúróṣinṣin túmọ̀ sí jíjẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. Ìdúróṣinṣin túmọ̀ sí jíjẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan.—Marku 12:30, 31; Johannu 13:34, 35.
21. Báwo ni a ṣe lè sọ ọ̀rọ̀ kíkojú ìpènijà ìdúróṣinṣin ní àkópọ̀?
21 Ní àkópọ̀: Ìdúróṣinṣin ni ànímọ́ gíga lọ́lá tí Jehofa Ọlọrun fi hàn, nípasẹ̀ Jesu Kristi, àti nípasẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ tòótọ́ ti Jehofa. Láti ní ipò ìbátan rere pẹ̀lú Jehofa Ọlọrun, a ní láti kojú ìpènijà ìdúróṣinṣin sí i, nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àbéèrèfún rẹ̀ tí ó jẹ́ òdodo, nípa ṣíṣàìní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti nípa gbígbèjà Jehofa nínú jíjẹ́rìí gẹ́gẹ́ bí àṣà àti láìjẹ́-bí-àṣà. A tún ní láti kojú ìpènijà jíjẹ́ adúróṣinṣin sí ètò àjọ Jehofa tí ó ṣeé fojú rí. A ní láti jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn ìjọ wa, àti sí àwọn ẹnì kejì wa nínú ìgbéyàwó. Nípa kíkojú ìpènijà ìdúróṣinṣin pẹ̀lú àṣeyọrí, a óò máa nípìn-ín nínú dídá ipò ọba aláṣẹ Jehofa láre, a óò sì máa wà níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú ọ̀ràn náà. Nípa báyìí, a óò jèrè ojú rere rẹ̀, a óò sì gba èrè ìyè àìnípẹ̀kun. Ohun tí aposteli Paulu sọ nípa ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run ni a lè sọ nípa kíkojú ìpènijà ìdúróṣinṣin tiwa náà pẹ̀lú. Ó ṣàǹfààní fún ìwàláàyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.—Orin Dafidi 18:25; 1 Timoteu 4:8.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà kojú ìpènijà ìdúróṣinṣin sí Ọlọrun?
◻ Kí ni ìdúróṣinṣin sí ètò àjọ Jehofa ń bèèrè lọ́wọ́ wa?
◻ Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè kojú ìpènijà ìdúróṣinṣin?
◻ Ìpènijà tí ó kan ìdúróṣinṣin wo ni àwọn Kristian tí wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó ní láti kojú?
◻ Àwọn ànímọ́ wo ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìpènijà ìdúróṣinṣin?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ìdúróṣinṣin sí àwọn mẹ́ḿbà ìjọ yóò mú kí àwọn alàgbà yẹra fún títú ọ̀ràn àṣírí síta
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ìdúróṣinṣin sí ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó ń fún ìdè ìgbéyàwó lókun