Kíyè Sí Àwọn Adúróṣinṣin!
“Ta ni kì yoo bẹ̀rù rẹ níti gidi, Jehofa, tí kì yoo sì yin orúkọ rẹ lógo, nitori pé iwọ nìkan ni adúróṣinṣin?”—ÌṢÍPAYÁ 15:4.
1. Ẹ̀rí wo ni J. F. Rutherford fúnni nípa ìdúróṣinṣin ẹni tí ó ṣáájú rẹ̀, C. T. Russell?
JOSEPH F. RUTHERFORD, ẹni tí ó tẹ̀ lé C. T. Russell gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Watch Tower Society ní 1917, bẹ̀rẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ níbi ètò ìsìnkú Russell nípa wíwí pé: “Charles Taze Russell jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọrun, ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Kristi Jesu, ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ìjọba Messia náà. Ó jẹ́ adúróṣinṣin délẹ̀délẹ̀—bẹ́ẹ̀ ni, ó jẹ́ adúróṣinṣin àní títí dé ojú ikú.” Ní tòótọ́, ìyẹ́n jẹ́ ọ̀rọ̀ ìyìn tí a lè sọ nípa ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ sí Jehofa Ọlọrun. Kò sí ọ̀rọ̀ ìyìn tí ó pọ̀ ju èyí lọ tí ènìyàn lè sọ nípa ẹnì kan tí ó yege ìpènijà ìdúróṣinṣin ju pé, ó jẹ́ adúróṣinṣin—adúróṣinṣin délẹ̀délẹ̀.
2, 3. (a) Èé ṣe tí ìdúróṣinṣin fi ní ìpènijà? (b) Àwọn wo ni a tún ṣètò lòdì sí àwọn Kristian tòótọ́ nínú ìsapá wọn láti jẹ́ adúróṣinṣin?
2 Ìdúróṣinṣin máa ń mú ìpènijà wá. Èé ṣe? Nítorí pé ìdúróṣinṣin forí gbárí pẹ̀lú ire ara ẹni. Àwùjọ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù ni aṣíwájú lára àwọn tí wọn jẹ́ aláìdúróṣinṣin sí Ọlọrun. Bákan náà pẹ̀lú, kò tí ì sí irú àìdúróṣinṣin tí ó tí ì gbalégbòde bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú ipò ìbátan ìgbéyàwó lónìí. Panṣágà wà níbi gbogbo. Àìdúróṣinṣin pẹ̀lú gbalégbòde nínú iṣẹ́ okòwò. A sọ fún wa nípa èyí pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́ àti àwọn amọṣẹ́dunjú . . . gbà gbọ́ pé kìkì àwọn ọ̀dẹ̀ àti àwọn òpònú ni wọ́n máa ń jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn ilé iṣẹ́ wọn lónìí.” Àwọn ènìyàn tí “ìdúróṣinṣin” wọ́n “pọ̀ jù” ni a máa ń fojú tẹ́ḿbẹ́lú. Ààrẹ ilé iṣẹ́ àwọn afúnninímọ̀ràn lórí ọ̀ràn okòwò àti ìṣàbójútó ilé iṣẹ́ sọ ọ́ ní ọ̀nà yìí pé: “Ìdúróṣinṣin rẹ àkọ́kọ́ àti ọ̀kan ṣoṣo yẹ kí ó jẹ́ sí ara rẹ.” Láti sọ̀rọ̀ nípa ìdúróṣinṣin nípa ara ẹni túmọ̀ sí bíba ọ̀rọ̀ náà jẹ́. Ó rán wa létí ohun tí a kọ sílẹ̀ nínú Mika 7:2 (NW), pé: “Adúróṣinṣin ti parun kúrò ní ilẹ̀ ayé.”
3 Ní ọ̀nà tí ó túbọ̀ gbòòrò sí i, Satani àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ni wọ́n kóra jọ lòdì sí wa, pẹ̀lú ìpinnu láti mú wa jẹ́ aláìdúróṣinṣin sí Ọlọrun. Ìdí nìyẹn tí a fi sọ fún àwọn Kristian nínú Efesu 6:12 pé: “Awa ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ ati ẹran-ara, bíkòṣe lòdì sí awọn alákòóso, lòdì sí awọn aláṣẹ, lòdì sí awọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yii, lòdì sí awọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní awọn ibi ọ̀run.” Bẹ́ẹ̀ ni, a ní láti kọbiara sí ìkìlọ̀ náà pé: “Ẹ pa awọn agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyèsára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà lati pa ẹni kan jẹ.”—1 Peteru 5:8.
4. Àwọn ìtẹ̀sí wo ni ó mú kí jíjẹ́ adúróṣinṣin ṣòro púpọ̀?
4 Àwọn ìtẹ̀sí ìmọtara-ẹni-nìkan tí a ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa, tún máa ń mú ìdúróṣinṣin ṣòro, gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nu kàn án nínú Genesisi 8:21 pé: “Ìrò ọkàn ènìyàn ibi ni”—àti onímọtara ẹni nìkan—“láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” Gbogbo wa ni a ní ìṣòro tí aposteli Paulu jẹ́wọ́ pé òún ní pé: “Rere tí mo dàníyàn ni emi kò ṣe, ṣugbọn búburú tí emi kò dàníyàn ni emi fi ń ṣèwàhù.”—Romu 7:19.
Ìdúróṣinṣin Jẹ́ Ohun Àrà Ọ̀tọ̀
5, 6. Kí ni a lè sọ nípa ohun tí ìdúróṣinṣin jẹ́, báwo ni a sì ṣe túmọ̀ rẹ̀?
5 “Ìdúróṣinṣin” jẹ́ ọ̀rọ̀ àrà ọ̀tọ̀ kan. Nípa báyìí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures sọ pé: “Ó dà bíi pé kò sí ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan pàtó tí ó túmọ̀ ọ̀rọ̀ Heberu àti Gíríìkì náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, ṣùgbọ́n ‘ìdúróṣinṣin,’ títí kan èrò ìfọkànsìn àti ìṣòtítọ́, nígbà tí a bá lò ó ní ìbámu pẹ̀lú Ọlọrun àti iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ń ṣiṣẹ́ láti fún un ní ìtumọ̀ tí ó ṣe déédéé, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí gan-an.”a Ní ti “ìdúróṣinṣin” Ilé-Ìṣọ́nà sọ nígbà kan pé: “Ìṣòtítọ́, ẹrù iṣẹ́, ìfẹ́, ojúṣe, àti ìtúúbá onídùúróṣinṣin. Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fi jọra wọn? Wọ́n jẹ́ oríṣiríṣi abala tí ìdúróṣinṣin ní.” Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀pọ̀ ìwà funfun ni ó wà tí ó jẹ́ oríṣiríṣi abala ìdúróṣinṣin. Ní tòótọ́, ó yẹ kí a ṣàkíyèsí bí a ti sábà máa ń so ìdúróṣinṣin pọ̀ mọ́ òdodo nínú Ìwé Mímọ́.
6 Àwọn ìtumọ̀ tí ó tẹ̀ lé e yìí tún ṣèrànwọ́ pẹ̀lú: ‘Ìdúróṣinṣin lè tọ́ka sí ìṣòtítọ́ àti ìtúúbá onídùúróṣinṣin tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, tí ó ń bá a lọ, tí a pa mọ́ kí ó má baà jù síhìn-ín sọ́hùn-ún tàbí kí a má baà dán an wò.’ ‘Ìdúróṣinṣin dọ́gbọ́n túmọ̀ sí ìṣòtítọ́ sí ẹ̀jẹ́ tí ẹní kan jẹ́ tàbí ìtúúbá onídùúróṣinṣin tí ń bá a lọ sí ètò ìpilẹ̀ tàbí àwọn ìlànà tí ẹnì kan rò pé ó jẹ́ àìgbọdọ̀máṣe; kì í ṣe kìkì dídìrọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ nǹkan ni ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí, ṣùgbọ́n kíkọ̀ láti di ẹni tí a tàn lọ, tí a sì yí lérò padà kúrò nídìí ohun tí ó dìrọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́.’ Nípa báyìí, àwọn ènìyàn tí wọ́n ń bá a lọ láti máa jẹ́ olùṣòtítọ́ láìjẹ́ kí ìdánwò, àtakò, àti inúnibíni fà wọ́n sẹ́yìn yẹ ní ẹni tí a lè pè ní “adúróṣinṣin.”
7. Ìyàtọ̀ wo ni a lè fi hàn láàárín ìdúróṣinṣin àti ìṣòtítọ́?
7 Ṣùgbọ́n ní ti èyí, ó dára láti ṣàpèjúwe ìyàtọ̀ tí ó lè wà láàárín ìdúróṣinṣin àti ìṣòtítọ́. Ní ìwọ̀ oòrùn United States, omi gbígbóná kan máa ń ru jáde ní nǹkan bí wákàtí kọ̀ọ̀kan. Ó ń ṣẹlẹ̀ déédéé débi pé a ń pè é ní Ògbólógbòó Olùṣòtítọ́. Bibeli sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun aláìlẹ́mìí irú bí òṣùpá gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́, ní ti pé ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Orin Dafidi 89:37 sọ̀rọ̀ òṣùpá bí “ẹlẹ́rìí òtítọ́ ní ọ̀run.” Àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni a sọ pé wọ́n jẹ́ òtítọ́. Ìṣípayá 21:5 wí pé: “Ẹni naa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ sì wí pé: ‘Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di titun.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wí pé: ‘Kọ̀wé, nitori pé ọ̀rọ̀ wọnyi ṣeé gbíyèlé wọ́n sì jẹ́ òótọ́.’” Gbogbo ìwọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n ṣe é gbẹ́kẹ̀ lé, ṣùgbọ́n wọn kò lè ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohunkóhun tàbí kí wọ́n ní àwọn ànímọ́ ìwà rere, bí ìdúróṣinṣin.
Jehofa, Adúróṣinṣin Títayọ Lọ́lá
8. Ẹ̀rí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu wo ni ó fi àpẹẹrẹ tí ó dára jù lọ ní ti ìdúróṣinṣin hàn?
8 Láìsí iyè méjì kankan, Jehofa Ọlọrun ni àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin tí ó dára jù lọ. Jehofa jẹ́ adúróṣinṣin sí iran ẹ̀dá ènìyàn, àní ó tilẹ̀ pèsè Ọmọkùnrin rẹ̀ kí ẹ̀dá ènìyàn baà lè rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà. (Johannu 3:16) A kà nínú Jeremiah 3:12 pé: ‘Yí padà ìwọ Israeli, apẹ̀yìndà, ni Oluwa wí, èmi kì yóò jẹ́ kí ojú mi kí ó korò sí ọ; nítorí èmí jẹ́ [adúróṣinṣin, NW].’ Àwọn ọ̀rọ̀ tí a kọ sílẹ̀ nínú Ìṣípayá 16:5 jẹ́rìí síwájú sí i nípa ìdúróṣinṣin Jehofa pé: “Iwọ, Ẹni naa tí ń bẹ tí ó sì ti wà, Ẹni ìdúróṣinṣin, jẹ́ olódodo.” Bákan náà, nínú Orin Dafidi 145:17, a sọ fún wá pé: “Olódodo ni Oluwa ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, àti [adúróṣinṣin, NW] ni iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.” Ní tòótọ́, Jehofa tayọ lọ́lá nínú ìdúróṣinṣin rẹ̀ débi pé Ìṣípayá 15:4 sọ pé: “Ta ni kì yoo bẹ̀rù rẹ níti gidi, Jehofa, tí kì yoo sì yin orúkọ rẹ lógo, nitori pé iwọ nìkan ni adúróṣinṣin?” Jehofa Ọlọrun jẹ́ adúróṣinṣin dé ìwọ̀n àyè tí ó ga jù lọ.
9, 10. Irú àkọsílẹ̀ ìdúróṣinṣin wo ni Jehofa ní nínú ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Israeli?
9 Ìtàn orílẹ̀-èdè Israeli ní pàtàkì ní ọ̀pọ̀ ẹ̀rí nípa ìdúróṣinṣin Jehofa sí àwọn ènìyàn rẹ̀. Ní ọjọ́ àwọn Onídàájọ́, Israeli ṣubú léraléra kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́, ṣùgbọ́n èyí dun Jehofa léraléra, ó sì gbà wọ́n là. (Awọn Onidajọ 2:15-22) Jálẹ̀ ọ̀rúndún márùn-ún tí Israeli fi ní ọba, Jehofa fi ìdúróṣinṣin rẹ̀ sí orílẹ̀-èdè náà hàn.
10 Ìdúróṣinṣin Jehofa sún un láti ní sùúrù pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kíyè sí i nínú 2 Kronika 36:15, 16 pé: “Oluwa Ọlọrun àwọn bàbá wọn sì ránṣẹ́ sí wọn láti ọwọ́ àwọn ońṣẹ́ rẹ̀, ó ń dìde ní kùtùkùtù ó sì ń ránṣẹ́, nítorí tí ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀, àti sí ibùgbé rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n fi àwọn ońṣẹ́ Ọlọrun ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣẹ̀sín, títí ìbínú Oluwa fi ru sí àwọn ènìyàn rẹ̀, tí kò fi sí àtúnṣe.”
11. Ìdánilójú tàbí ìtùnú wo ni ìdúróṣinṣin Jehofa fún wa?
11 Nítorí pé Jehofa jẹ́ adúróṣinṣin ní ọ̀nà tí ó ga lọ́lá, aposteli Paulu lè kọ̀wé, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Romu 8:38, 39 pé: “Mo gbàgbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tabi ìyè tabi awọn áńgẹ́lì tabi awọn ìjọba-àkóso tabi awọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tabi awọn ohun tí ń bọ̀ tabi awọn agbára tabi ibi gíga tabi ibi jíjìn tabi ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yoo lè yà wá kúrò ninu ìfẹ́ Ọlọrun tí ó wà ninu Kristi Jesu Oluwa wa.” Bẹ́ẹ̀ ni, Jehofa fi dá wa lójú pé: “Dájúdájú emi kì yoo fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tabi ṣá ọ tì lọ́nàkọnà.” (Heberu 13:5) Ní tòótọ́, ó tuni nínú láti mọ̀ pé Jehofa Ọlọrun jẹ́ adúróṣinṣin ní gbogbo ìgbà!
Jesu Kristi, Adúróṣinṣin Ọmọkùnrin
12, 13. Ẹ̀rí wo ni a ní, ní ti ìdúróṣinṣin Ọmọkùnrin Ọlọrun?
12 Títí di ìsinsìnyí, Jesu Kristi ń fara wé Jehofa lọ́nà pípé ní kíkojú ìpènijà ìdúróṣinṣin. Lọ́nà tí ó tọ́, aposteli Peteru lè ṣàyọlò Orin Dafidi 16:10 kí ó sì lò ó fún Jesu Kristi nínú Ìṣe 2:27 pé: “Iwọ kì yoo fi ọkàn mi sílẹ̀ ní Hédíìsì, bẹ́ẹ̀ ni iwọ kì yoo yọ̀ǹda kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́.” Lọ́nà ẹ̀tọ́, Jesu Kristi ni a fún ní orúkọ náà “ẹni ìdúróṣinṣin.” Ní gbogbo ọ̀nà, ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Bàbá rẹ̀ àti sí Ìjọba tí Ọlọrun ṣèlérí. Satani kọ́kọ́ gbìyànjú láti mú Jesu sẹ́ ìwà títọ́ rẹ̀ nípa lílo àwọn ìdẹwò, tí ó lè ru ire ara ẹni sókè. Nígbà tí ó kùnà nínú ìyẹn, Èṣù fàbọ̀ sí inúnibíni, ní fífa ikú Jesu lórí òpó igi ìpànìyàn, nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Jesu kò fìgbà kankan yẹsẹ̀ kúrò nínú ìdúróṣinṣin rẹ̀ sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run, Jehofa Ọlọrun.—Matteu 4:1-11.
13 Jesu Kristi jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní mímú ìlérí tí a kọ̀ sílẹ̀ nínú Matteu 28:20 ṣẹ pé: “Wò ó! mo wà pẹlu yín ní gbogbo awọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan.” Ní mímú ìlérí náà ṣẹ, ó ti ń fi ìdúróṣinṣin lo ipò orí lórí ìjọ rẹ̀ láti Pentekosti ọdún 33 Sànmánì Tiwa títí di ìsinsìnyí.
Àwọn Ẹ̀dá Ènìyàn Aláìpé Tí Wọ́n Jẹ́ Adúróṣinṣin
14. Àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin wo ni Jobu fi lélẹ̀?
14 Wàyí o, àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé ń kọ́? Wọ́n ha lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọrun bí? A ní àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá ti Jobu. Satani mú ọ̀ràn náà ṣe kedere nínú ọ̀ràn rẹ̀. Jobu ha jẹ́ adúróṣinṣin sí Jehofa Ọlọrun, bí tàbí ó ha ń jọ́sìn rẹ̀ nítorí kìkì ire ti ara rẹ̀ nìkan bí? Satani lénu pé òún lè yí Jobu lọ́kàn padà kúrò lọ́dọ̀ Jehofa nípa wíwá wàhálà fún Jobu. Nígbà tí Jobu ti pàdánù gbogbo ohun ìní rẹ̀, gbogbo ọmọ rẹ̀, àti ìlera rẹ̀ pàápàá, ìyàwó rẹ̀ rọ̀ ọ́ pé: “Bú Ọlọrun, kí o sì kú.” Ṣùgbọ́n Jobu dúró ṣinṣin, ní ti pé ó wí fún un pé: “Ìwọ́ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan nínú àwọn obìnrin aláìmòye ti í sọ̀rọ̀; kínla! àwa óò ha gba ire lọ́wọ́ Ọlọrun, kí a má sì gba ibi! Nínú gbogbo èyí Jobu kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀.” (Jobu 2:9, 10) Ní tòótọ́ gidi, Jobu sọ fún àwọn tí wọ́n fẹnu lásán jẹ́ olùtùnú rẹ̀ pé: “Bí òun [Ọlọrun] bá pa mí, síbẹ̀ èmi yóò nírètí nínú rẹ̀.” (Jobu 13:15, New International Version) Abájọ tí Jobu fi rí ojú rere Jehofa gbà! Nítorí náà, Jehofa sọ fún Elifasi ará Tema pé: “Mo bínú sí ọ àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjèèjì, nítorí pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀ ní ti èmi, ohun tí ó tọ́ bí Jobu ìránṣẹ́ mi ti sọ.”—Jobu 42:7, 10-16; Jakọbu 5:11.
15. Ẹ̀rí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu wo ni a ní nípa ìdúróṣinṣin ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jehofa Ọlọrun?
15 A lè sọ̀rọ̀ gbogbo àwọn ọkùnrin àti obìnrin ìgbàgbọ́ tí a ṣàpèjúwe wọn nínú Heberu orí 11 gẹ́gẹ́ bí ẹni ìdúróṣinṣin. Kì í ṣe pé wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún jẹ́ adúróṣinṣin lójú ìkìmọ́lẹ̀. Nítorí náà, a kà nípa “awọn ẹni tí ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ . . . wọ́n dí ẹnu awọn kìnnìún, wọ́n dá ipá iná dúró, wọ́n yèbọ́ lọ́wọ́ ojú idà . . . Bẹ́ẹ̀ ni, awọn mìíràn rí àdánwò wọn gbà nipa ìfiṣẹlẹ́yà ati ìnàlọ́rẹ́, nítòótọ́, ju èyíinì lọ, nipa awọn ìdè ati ẹ̀wọ̀n. A sọ wọ́n ní òkúta, a dán wọn wò, a fi ayùn rẹ́ wọn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n kú nipa fífi idà pa wọ́n, wọ́n lọ káàkiri ninu awọ àgùtàn, ninu awọ ewúrẹ́, nígbà tí wọ́n wà ninu àìní, ninu ìpọ́njú, lábẹ́ ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́.”—Heberu 11:33-37.
16. Irú àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin wo ni aposteli Paulu pèsè?
16 Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Gíríìkì tún pèsè àpẹẹrẹ tí ó gba àfiyèsí nípa aposteli Paulu. Ó lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ bá àwọn Kristian ní Tessalonika sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí, Ọlọrun jẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹlu, bí a ti jẹ́ adúróṣinṣin ati olódodo ati aláìṣeédálẹ́bi sí ẹ̀yin onígbàgbọ́.” (1 Tessalonika 2:10) A ní ẹ̀rí síwájú sí i nípa ìdúróṣinṣin Paulu nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀ nínú 2 Korinti 6:4, 5, níbi tí a ti kà pé: “Ní ọ̀nà gbogbo awa ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọrun, nipa ìfaradà púpọ̀, nipa awọn ìpọ́njú, nipa awọn ọ̀ràn àìní, nipa awọn ìṣòro, nipa lílù, nipa ẹ̀wọ̀n, nipa rúgúdù, nipa òpò, nipa awọn òru àìlèsùn, nipa awọn àkókò àìsí oúnjẹ.” Gbogbo èyí jẹ́rìí sí i pé aposteli Paulu ní ọ̀wọ̀ ara ẹni nítorí ó jẹ́ adúróṣinṣin.
Àwọn Adúróṣinṣin ní Òde Òní
17. Àwọn ọ̀rọ̀ J. F. Rutherford wo ni ó fi ìpinnu rẹ̀ láti jẹ́ adúróṣinṣin hàn?
17 Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa òde òní, a ní àpẹẹrẹ àtàtà tí a ti mẹ́nu kàn nínú ìfáárà wa. Ṣàkíyèsí ohun tí ó wà nínú ìwé náà, Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia,” ojú ìwé 146 lábẹ́ ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ náà “Iduroṣinṣin Nigba Akoko Ifisẹwọn.” A sọ níbẹ̀ pé: “Ni ṣiṣafihan iduroṣinṣin si ètò-àjọ Jehofa nigba akoko [ìfisẹ́wọ̀n] rẹ̀, aarẹ Watch Tower Society, Joseph F. Rutherford, ní December 25, 1918, kọ awọn ọ̀rọ̀ ti ó tẹ̀lé e yii: ‘Nitori pe mo kọ̀ lati fohunṣọkan pẹlu Babiloni, ṣugbọn ti mo fi pẹlu iṣotitọ gbiyanju lati ṣiṣẹsin Oluwa mi, mo wà lẹwọn, mo si dupẹ fun eyi. . . . Emi yoo fẹ itẹwọgba ati ẹrin musẹ Rẹ̀ ki [n] si wà lẹwọn, ju ki n fohunṣọkan tabi gbọ ti Ẹranko naa ki n si wà lominira ki n si gba oriyin gbogbo aye.’”b
18, 19. Àwọn àpẹẹrẹ títuninínú délẹ̀délẹ̀ ní ti ìdúróṣinṣin wo ni a ní lóde òní?
18 A ní àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá ti àwọn Kristian míràn tí wọ́n fara da inúnibíni. Lára àwọn ẹni adúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí fún Jehofa tí wọ́n jẹ́ ará Germany nígbà ìṣàkóso Nazi, gẹ́gẹ́ bí fídíò Purple Triangles, tí a pín káàkiri rẹpẹtẹ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, ti gbé e yọ. Ọ̀pọ̀ àwọn adúróṣinṣin, Ẹlẹ́rìí fún Jehofa, tí wọ́n jẹ́ ará Áfíríkà, irú bí àwọn tí wọ́n wà ní Malawi tún yẹ fún àfiyèsí. Níbẹ̀, ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n kan jẹ́rìí sí ìdúróṣinṣin àwọn Ẹlẹ́rìí, ní sísọ pé: “Wọn kì yóò juwọ́ sílẹ̀ láé. Wọ́n wulẹ̀ ń pọ̀ sí i ni.”
19 Bí ènìyàn bá ka àwọn ìwé Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ti àìpẹ́ yìí, ìdúróṣinṣin tí àwọn Kristian tòótọ́ fi hàn yóò wú u lórí, irú bíi ti àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Gíríìkì, Mozambique, àti Poland. Ọ̀pọ̀ nínú wọn jìyà ìdálóró aronigógó; a ṣekú pa àwọn mìíràn. Ìwé 1992 Yearbook, ojú ìwé 177 fi àwòrán àwọn Kristian ọkùnrin mẹ́sàn-án ní Etiopia hàn, tí wọ́n dojú kọ ìpènijà ìdúróṣinṣin dé ojú ikú. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa, a kò ha láyọ̀ láti ní àwọn àpẹẹrẹ àtàtà púpọ̀ bẹ́ẹ̀ láti sún wa láti kojú ìpènijà ìdúróṣinṣin bí?
20. Kí ni àbájáde jíjẹ́ adúróṣinṣin?
20 Nípa kíkọ àwọn ìdánwò àti ìkìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìdúróṣinṣin, a ń gbé ọ̀wọ̀ ara ẹni wa ró. Nítorí náà, ìhà ọ̀dọ̀ ta ni o fẹ́ láti wà nínú ọ̀ràn ìdúróṣinṣin nígbà náà? Nípa kíkojú ìpènijà ìdúróṣinṣin, a wà níhà ọ̀dọ̀ Jehofa Ọlọrun lórí ọ̀ràn náà, a sì ń fi Satani Eṣu hàn bí òpùrọ́ paraku tí ó burú jáì, èyí tí òún jẹ́! A tipa báyìí jèrè ojú rere Aṣẹ̀dá wa, Jehofa Ọlọrun, àti èrè ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayọ̀. (Orin Dafidi 37:29; 144:15b) Ohun tí kíkojú ìpènijà ìdúróṣinṣin ń béèrè ni a óò gbé yẹ̀ wò tẹ̀ lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Bibeli, onídìpọ̀ méjì, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
b Tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èé ṣe tí jíjẹ́ adúróṣinṣin fi mú ìpènijà wá?
◻ Èé ṣe tí a fi lè sọ pé “ìdúróṣinṣin” jẹ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì kan?
◻ Àwọn àpẹẹrẹ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu wo ni a ní ní ti àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin?
◻ Àwọn àpẹẹrẹ òde òní wo ni a ní ní ti ìdúróṣinṣin?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Charles Taze Russell
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Lóòótọ́, Jesu jẹ́ “ẹni ìdúróṣinṣin” si Jehofa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Bí Jobu tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọrun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Paulu fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ ní ti ìdúróṣinṣin sí Jehofa