ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 8/1 ojú ìwé 8-14
  • Fífi Ìdúróṣinṣin Sìn Pẹ̀lú Ètò Àjọ Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Ìdúróṣinṣin Sìn Pẹ̀lú Ètò Àjọ Jèhófà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídarí Àfiyèsí Sórí Àìpé Lè Ba Ìdúróṣinṣin Jẹ́
  • Àìpé Àwa Fúnra Wa
  • Ṣọ́ra fún Oríṣi Àìdúróṣinṣin Tí A Kò Lè Tètè Fura Sí!
  • Fi Ìdúróṣinṣin Kojú Inúnibíni
  • Kíyè Sí Àwọn Adúróṣinṣin!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • “Ìwọ Nìkan Ni Adúróṣinṣin”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Kíkojú Ìpènijà Ìdúróṣinṣin
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ta Ló Yẹ Kó O Jẹ́ Adúróṣinṣin Sí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 8/1 ojú ìwé 8-14

Fífi Ìdúróṣinṣin Sìn Pẹ̀lú Ètò Àjọ Jèhófà

“Ìwọ yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.”—SÁMÚẸ́LÌ KEJÌ 22:26, NW.

1, 2. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin tí gbogbo wá lè rí nínú ìjọ?

NÍ ALẸ́ ọjọ́ kan, alàgbà kan ń múra ọ̀rọ̀ àsọyé sílẹ̀ fún ìpàdé Kristẹni. Ó wù ú láti dáwọ́ dúró, kí ó sì sinmi; kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ, ó ń wá àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ àti àwọn àkàwé tí yóò wọ àwùjọ lọ́kàn, tí yóò sì fún agbo ní ìṣírí. Ní alẹ́ ọjọ́ ìpàdé náà, ó wu àwọn òbí méjì tí ó ti rẹ̀ tẹnutẹnu, tí àwọn àti alàgbà náà jọ ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ kan náà láti gbádùn ìrọ̀lẹ́ wọn nílé; kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fi sùúrù múra fún àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì lọ sí ìpàdé. Lẹ́yìn ìpàdé náà, àwùjọ àwọn Kristẹni kan ń jíròrò ọ̀rọ̀ àsọyé tí alàgbà náà sọ. Ó ń ṣe arábìnrin kan bí ẹni pé kí ó sọ pé arákùnrin kan náà yẹn ti mú kí inú bí òun nígbà kan; kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi ìtara sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan nínú àwọn kókó tí arákùnrin náà sọ. Ìwọ ha rí ànímọ́ kan náà nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí bí?

2 Ànímọ́ náà ni ìdúróṣinṣin. Alàgbà náà fi ìdúróṣinṣin ṣiṣẹ́ láti lè sin agbo Ọlọ́run; àwọn òbí náà fi ìdúróṣinṣin lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ; arábìnrin náà fi ìdúróṣinṣin kọ́wọ́ ti àwọn alàgbà lẹ́yìn. (Hébérù 10:24, 25; 13:17; Pétérù Kíní 5:2) Bẹ́ẹ̀ ni, ní gbogbo apá ìgbésí ayé, a ń rí àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí wọ́n ń pinnu láti fi ìdúróṣinṣin sìn pẹ̀lú ètò àjọ Jèhófà.

3. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì gan-an pé kí a máa bá a lọ ní jíjẹ́ adúróṣinṣin sí ètò àjọ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé?

3 Nígbà tí Jèhófà bojú wo ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí, ìdúróṣinṣin tí ó rí kò tó nǹkan. (Míkà 7:2) Ẹ wo bí inú rẹ̀ yóò ti dùn tó nígbà tí ó ṣàkíyèsí ìdúróṣinṣin àwọn ènìyàn rẹ̀! Bẹ́ẹ̀ ni, ìdúróṣinṣin rẹ ń mú inú rẹ̀ dùn. Ṣùgbọ́n, ó ń mú inú Sátánì, ọlọ̀tẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ru gùdù, ó sì ń fi í hàn gẹ́gẹ́ bí òpùrọ́. (Òwe 27:11; Jòhánù 8:44) Máa retí pé Sátánì yóò gbìyànjú láti bá ìdúróṣinṣin rẹ sí Jèhófà àti sí ètò àjọ Rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé jẹ́. Ẹ jẹ́ kí a gbé díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà tí Sátánì gbà ń ṣe èyí yẹ̀ wò. Nípa bẹ́ẹ̀ a lè túbọ̀ rí bí a ṣe lè dúró ṣinṣin títí dé òpin.—Kọ́ríńtì Kejì 2:11.

Dídarí Àfiyèsí Sórí Àìpé Lè Ba Ìdúróṣinṣin Jẹ́

4. (a) Èé ṣe tí ó fi rọrùn láti ní èrò òdì nípa àwọn tí wọ́n ní ọlá àṣẹ? (b) Báwo ni Kórà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ aláìdúróṣinṣin sí ètò àjọ Jèhófà?

4 Nígbà tí arákùnrin kan bá di ẹni tí a fa ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́, àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó rẹ̀ lè túbọ̀ fara hàn. Ẹ wo bí ó ti rọrùn tó láti ṣe lámèyítọ́ ‘ègé koríko tí ń bẹ ní ojú arákùnrin wa nígbà tí a sì ṣá igi ìrólé tí ń bẹ nínú ojú àwa fúnra wa tì’! (Mátíù 7:1-5) Ṣùgbọ́n, ríronú ṣáá lórí ìkù-díẹ̀-káàtó lè yọrí sí àìdúróṣinṣin. Fún àpẹẹrẹ, gbé ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín Kórà àti Dáfídì yẹ̀ wò. Kórà ní ẹrù iṣẹ́ púpọ̀, ó sì ti ṣeé ṣe kí ó jẹ́ adúróṣinṣin fun ọ̀pọ̀ ọdún, ṣùgbọ́n ó di ọ̀kánjúwà. Ó kórìíra níní tí Mósè àti Áárónì, àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n bàbá rẹ̀, ní ọlá àṣẹ. Bí Mósè tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn, ó hàn gbangba pé Kórà ṣe lámèyítọ́ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ó ri àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó lára Mósè. Ṣùgbọ́n, àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó wọ̀nyẹn kò dá Kórà láre fún dídi aláìdúróṣinṣin sí ètò àjọ Jèhófà. A pa á run kúrò nínú ìjọ náà.—Númérì 12:3; 16:11, 31-33.

5. Èé ṣe tí Dáfídì yóò fi fẹ́ láti gbìyànjú dídìtẹ̀ mọ́ Sọ́ọ̀lù?

5 Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Dáfídì ṣiṣẹ́ sìn lábẹ́ Ọba Sọ́ọ̀lù. Sọ́ọ̀lù tí ó jẹ́ ọba rere tẹ́lẹ̀ rí, ti wá di olubi pátápátá. Dáfídì nílò ìgbàgbọ́, ìforítì, àti ọgbọ́n ìhùmọ̀ pàápàá láti lè bọ́ lọ́wọ́ ogun owú jíjẹ Sọ́ọ̀lù. Síbẹ̀, nígbà tí Dáfídì ní àǹfààní láti gbẹ̀san, ó wí pé ‘kò ṣeé ronú kàn, ní ojú ìwòye Jèhófà,’ láti hùwà àìdúróṣinṣin sí ẹni tí Jèhófà ti fòróró yàn.—Sámúẹ́lì Kíní 26:11, NW.

6. Bí a bá tilẹ̀ róye àìlera àti ìkù-díẹ̀-káàtó nínú àwọn alàgbà, kí ni kò yẹ kí a ṣe láé?

6 Nígbà tí ó bá dà bíi pé àwọn kan tí ń mú ipò iwájú láàárín wa ṣàṣìṣe nínú ìdájọ́, tí ó bá dà bíi pé wọ́n sọ̀rọ̀ lọ́nà líle koko, tàbí tí ó bá dà bíi pé wọ́n ń ṣojúsàájú, a óò ha ráhùn nípa wọn bí, bóyá ní dídá ẹ̀mí lámèyítọ́ sílẹ̀ nínú ìjọ? A óò ha ní kí wọ́n fọwọ́ mú ìpàdé Kristẹni wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àtifi ẹ̀hónú wa hàn bí? Dájúdájú a kò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Gẹ́gẹ́ bíi Dáfídì, a kò ní yọ̀ǹda kí ìkù-díẹ̀-káàtó àwọn ẹlòmíràn sún wa di aláìdúróṣinṣin sí Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ láé!—Orin Dáfídì 119:165.

7. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ìwà ìbàjẹ́ tí ó dìde ní ìsopọ̀ pẹ̀lú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù, kí sì ni ìmọ̀lára Jésù sí èyí?

7 Jésù Kristi ni àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin títóbi jù lọ láàárín ẹ̀dá ènìyàn, ẹni tí a ṣàpèjúwe lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ẹni ìdúróṣinṣin” Jèhófà. (Orin Dáfídì 16:10, NW) Àṣìlò tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù ti ní láti mú kí ìdúróṣinṣin jẹ́ ìpèníjà. Jésù mọ̀ pé iṣẹ́ àlùfáà àgbà àti àwọn ìrúbọ ń ṣàpẹẹrẹ iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun fúnra òun àti ikú ìrúbọ òun, ó sì mọ̀ bí ó ti ṣe pàtàkì tó fún àwọn ènìyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn nǹkan wọ̀nyí. Nítorí náà, ó kún fún ìbínú òdodo nígbà tí ó rí i pé tẹ́ńpìlì náà ti di “hòrò àwọn ọlọ́ṣà.” Pẹ̀lú ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fún un, ìgbà méjì ni ó gbé ìgbésẹ̀ láti fọ̀ ọ́ mọ́.a—Mátíù 21:12, 13; Jòhánù 2:15-17.

8. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi ìdúróṣinṣin hàn sí ìṣètò tẹ́ńpìlì? (b) Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a mọrírì jíjọ́sìn Jèhófà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ètò àjọ rẹ̀ mímọ́ tónítóní?

8 Síbẹ̀, Jésù fi ìdúróṣinṣin ti ìṣètò tẹ́ńpìlì lẹ́yìn. Láti kékeré, ó máa ń lọ ṣe àjọyọ̀ nínú tẹ́ńpìlì, ó sì sábà máa ń kọ́ni níbẹ̀. Ó tilẹ̀ san owó orí tẹ́ńpìlì—bí kò tilẹ̀ pọn dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 17:24-27) Jésù gbóríyìn fún òtòṣì opó náà fún sísọ “gbogbo ohun tí ó ní” sínú àpótí ìṣúra tẹ́ńpìlì. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, Jèhófà kọ tẹ́ńpìlì náà sílẹ̀ pátápátá. Ṣùgbọ́n títí di ìgbà yẹn, Jésù jẹ́ adúróṣinṣin sí i. (Máàkù 12:41-44; Mátíù 23:38) Ètò àjọ Ọlọ́run ti orí ilẹ̀ ayé lónìí ga lọ́lá gan-an ju ètò ìgbékalẹ̀ àwọn Júù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀. Òtítọ́ ni pé, ètò àjọ náà kò pé pérépéré; ìdí rẹ̀ nìyẹn tí a fi máa ń ṣe àtúnṣe nígbà míràn. Ṣùgbọ́n a kò fi ìwà ìbàjẹ́ kún inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni Jèhófà Ọlọ́run kò sọ pé òun yóò fi òmíràn rọ́pò rẹ̀ láìpẹ́. Kí a má ṣe yọ̀ǹda fún àìpé èyíkéyìí tí a lè róye nínú rẹ̀ láti mú wa bínú tàbí sún wa láti ní ẹ̀mí lámèyítọ́, ẹ̀mí òdì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a fara wé ìdúróṣinṣin Jésù Kristi.—Pétérù Kíní 2:21.

Àìpé Àwa Fúnra Wa

9, 10. (a) Báwo ni ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan Sátánì ṣe ń lo àìpé wa láti ré wa lọ sínú ìwà àìdúróṣinṣin? (b) Kí ni ó yẹ kí ẹnì kan tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo ṣe?

9 Sátánì tún ń gbìyànjú láti gbé àìdúróṣinṣin lárugẹ nípa lílo àìpé wa. Ètò ìgbékalẹ̀ rẹ̀ ń lo àìlera wa, ní dídán wa wò láti ṣe ohun tí ó lòdì ní ojú Jèhófà. Ó bani nínú jẹ́ pé, lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣubú sínú ìwà pálapàla. Àwọn kan ń dá kún àìdúróṣinṣin yìí nípa gbígbé ìgbésí ayé méjì, ní bíbá híhùwà àìtọ́ nìṣó nígbà tí wọ́n sì ń díbọ́n pé àwọn jẹ́ Kristẹni olùṣòtítọ́. Ní ìdáhùnpadà sí àwọn àpilẹ̀kọ lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí nínú ọ̀wọ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìwé ìròyìn Jí!, ọ̀dọ́bìnrin kan kọ̀wé pé: “Ìtàn ìgbésí ayé mi gan-an ni àwọn àpilẹ̀kọ náà sọ.” Ní bòókẹ́lẹ́, ó ti dọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Kí ni àbájáde rẹ̀? Ó kọ̀wé pé: “Ìgbésí ayé mi bà jẹ́ pátápátá, mo lọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla, a sì bá mi wí. Ipò ìbátan mi pẹ̀lú Jèhófà bà jẹ́, àwọn òbí mi àti àwọn alàgbà kò sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú mi mọ́.”b

10 Ọ̀dọ́bìnrin yìí rí ìrànlọ́wọ́ gbà lọ́dọ̀ àwọn alàgbà, ó sì pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn adúróṣinṣin sí Jèhófà. Ṣùgbọ́n, ó bani nínú jẹ́ pé, àbájáde búburú tí ń dé bá ọ̀pọ̀ tún burú ju ìyẹn lọ, àwọn kan kì í sì í pa dà sínú agbo mọ́. Ẹ wo bí ó ti sàn jù tó láti jẹ́ adúróṣinṣin, kí a sì dènà ìdánwò nínú ayé búburú yìí! Máa kọbi ara sí àwọn ìkìlọ̀ inú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lórí irú àwọn ọ̀ràn bíi kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ayé àti eré ìnàjú tí ń rẹni nípò wálẹ̀. Ǹjẹ́ kí o má ṣe fìgbà kankan ṣubú sínú ìwà àìdúróṣinṣin. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀, má ṣe díbọ́n láé pé o jẹ́ ohun tí o kò jẹ́. (Orin Dáfídì 26:4) Dípò èyí, wá ìrànwọ́. Ohun tí àwọn Kristẹni òbí àti alàgbà wà fún nìyẹn.—Jákọ́bù 5:14.

11. Èé ṣe tí yóò fi jẹ́ àṣìṣe láti wo ara wa gẹ́gẹ́ bí aláìníláárí, àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo sì ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti tún ojú ìwòye wa ṣe?

11 Àìpé wa lè fi wá sínú ewu ní ọ̀nà míràn. Àwọn kan tí wọ́n hùwà àìdúróṣinṣin ń dẹ́kun gbígbìyànjú láti wu Jèhófà. Rántí pé, Dáfídì dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo. Síbẹ̀, ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ikú Dáfídì, Jèhófà rántí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́. (Hébérù 11:32; 12:1) Èé ṣe? Nítorí pé kò fìgbà kan rí dẹ́kun gbígbìyànjú láti wu Jèhófà. Òwe 24:16 sọ pé: “Olóòótọ́ a ṣubú nígbà méje, a sì tún dìde.” Dájúdájú, bí a bá ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké—àní léraléra pàápàá—nítorí àwọn àìlera kan tí a ń bá jìjàkadì, a ṣì lè jẹ́ olódodo ní ojú Jèhófà bí a bá ń bá a nìṣó láti “dìde”—ìyẹn ni pé, kí a ronú pìwà dà tọkàntọkàn, kí a sì pa dà sí ipa ọ̀nà iṣẹ́ ìsìn àfòtítọ́ṣe.—Fi wé Kọ́ríńtì Kejì 2:7.

Ṣọ́ra fún Oríṣi Àìdúróṣinṣin Tí A Kò Lè Tètè Fura Sí!

12. Ní ti àwọn Farisí, báwo ni ojú ìwòye aláìṣeéyípadà, agbófinrù ṣe yọrí sí àìdúróṣinṣin?

12 Àìdúróṣinsin tún ń wá lọ́nà tí a kò lè tètè fura sí. Ó tilẹ̀ lè fi agọ̀ ìdúróṣinṣin bojú! Fún àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí àwọn Farisí ọjọ́ Jésù rò pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin lọ́nà títayọ lọ́lá.c Ṣùgbọ́n wọ́n kùnà láti rí ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín jíjẹ́ adúróṣinṣin àti jíjẹ́ ẹni tí kò ṣeé tẹ̀ síhìn-ín ṣọ́hùn-ún, tí ń rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ òfin ènìyàn, nítorí wọ́n jẹ́ aláìṣeéyípadà àti alárìíwísí lọ́nà líle koko. (Fi wé Oníwàásù 7:16.) Nínú èyí wọ́n jẹ́ aláìdúróṣinṣin ní ti gidi—sí àwọn ènìyàn tí ó yẹ kí wọ́n máa sìn, sí ẹ̀mí tí ń bẹ lẹ́yìn Òfin tí wọ́n sọ pé àwọn ń fi kọ́ni, àti sí Jèhófà fúnra rẹ̀. Ní òdì kejì, Jésù jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹ̀mí tí ń bẹ lẹ́yìn Òfin, tí a gbé ka ìfẹ́. Nípa báyìí, ó gbé àwọn ènìyàn ró, ó sì fún wọn níṣìírí, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ti sọ.—Aísáyà 42:3; 50:4; 61:1, 2.

13. (a) Báwo ni àwọn òbí Kristẹni ṣe lè jẹ́ aláìdúróṣinṣin? (b) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn òbí yẹra fún jíjẹ́ ẹni tí ó rorò, tí ń ṣe lámèyítọ́, tàbí tí ó le koko ní bíbá àwọn ọmọ wọn wí?

13 Àwọn Kristẹni tí wọ́n ní ọlá àṣẹ díẹ̀ ń jàǹfààní ńlá láti inú àpẹẹrẹ Jésù ní ti èyí. Fún àpẹẹrẹ, àwọn òbí adúróṣinṣin mọ̀ pé àwọn gbọ́dọ̀ bá àwọn ọmọ wọn wí. (Òwe 13:24) Síbẹ̀ wọ́n n rí i dájú pé àwọn kò mú àwọn ògo wẹẹrẹ wọn bínú nípa fífi ìbínú bá wọn wí lọ́nà líle koko tàbí nípa ṣíṣe lámèyítọ́ wọn nígbà gbogbo. Àwọn ọmọ tí wọ́n rò pé àwọn kò lè wu àwọn òbí àwọn láé tàbí tí wọ́n rò pé ìsìn àwọn òbí àwọn ń sọ wọn di ẹni tí ó le koko àti ẹni tí ń ṣe lámèyítọ́ lè sorí kodò, kí wọ́n sì tìtorí èyí di àjèjì sí ìgbàgbọ́ tòótọ́.—Kólósè 3:21.

14. Báwo ni àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn ṣe lè fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin sí agbo tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ sìn?

14 Bákan náà, àwọn Kristẹni alàgbà àti àwọn alábòójútó arìnrìn àjò máa ń fún ìṣòro àti ewu tí agbo ń dojú kọ ní àfiyèsí. Gẹ́gẹ́ bí adúróṣinṣin olùṣọ́ àgùntàn, wọ́n ń pèsè ìmọ̀ràn nígbà tí a bá ti nílò rẹ̀, ní rírí i dájú pé lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n mọ gbogbo òkodoro ọ̀rọ̀, wọ́n sì fìsọ́ra gbé ohun tí wọ́n sọ ka Bíbélì àti ìtẹ̀jáde Society. (Orin Dáfídì 119:105; Òwe 18:13) Wọ́n mọ̀ pẹ̀lú pé àwọn àgùntàn ń gbára lé wọn fún ìgbéró nípa tẹ̀mí àti fún oúnjẹ tẹ̀mí. Nítorí náà, wọ́n ń sakun láti fara wé Jésù Kristi, Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà. Wọ́n ń fi ìdúróṣinṣin ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn àgùntàn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nínú ìpàdé Kristẹni—wọn kì í sọ̀rọ̀ tí ń múni rẹ̀wẹ̀sì, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń gbé wọn ró, wọ́n sì ń fún ìgbàgbọ́ wọn lókun.—Mátíù 20:28; Éfésù 4:11, 12; Hébérù 13:20, 21.

15. Báwo ni àwọn kan ní ọ̀rúndún kìíní ṣe fi hàn pé àwọn ní ìdúróṣinṣin tí a gbé gbòdì?

15 Oríṣi àìdúróṣinṣin mìíràn lọ́nà tí a kò lè tètè fura sí ni ìdúróṣinṣin tí a gbé gbòdì. Ìdúróṣinṣin tòótọ́ ní èrò ìtumọ̀ Bíbélì kò yọ̀ǹda fún fífi ìdúróṣinṣin èyíkéyìí ṣáájú ìdúróṣinṣin wa sí Jèhófà Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ Júù ní ọ̀rúndún kìíní rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ Òfin Mósè àti mọ́ ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti àwọn Júù. Síbẹ̀ àkókò Jèhófà ti dé láti mú ìbùkún rẹ̀ kúrò lórí orílẹ̀-èdè ọlọ̀tẹ̀ yẹn, kí ó sì mú un wá sórí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Ní ìfiwéra, kìkì àwọn kéréje ni wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, tí wọ́n sì mú ara wọn bá ìyípadà mánigbàgbé yìí mu. Àní láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ pàápàá, àwọn ẹlẹ́sìn Júù kan rin kinkin mọ́ pípadà sí àwọn ohun “àkọ́bẹ̀rẹ̀ aláìlera àti akúrẹtẹ̀” ti Òfin Mósè, tí a ti mú ṣẹ nínú Kristi.—Gálátíà 4:9; 5:6-12; Fílípì 3:2, 3.

16. Báwo ni àwọn adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe ń hùwà pa dà sí àwọn àtúnṣe?

16 Ní ìyàtọ̀ pátápátá, àwọn ènìyàn Jèhófà ní òde òní ti fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí adúróṣinṣin jálẹ̀ àwọn àkókò ìyípadà. Bí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tí a ṣí payá ṣe túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i, a ṣe àwọn àtúnṣe. (Òwe 4:18) Ní àìpẹ́ yìí, “ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” ràn wá lọ́wọ́ láti tún òye wa ṣe nípa ọ̀rọ̀ náà “ìran” tí a lò nínú Mátíù 24:34 àti nípa àkókò ìdájọ́ “àwọn àgùntàn” àti “àwọn ewúrẹ́” tí a mẹ́nu kàn nínú Mátíù 25:31-46, àti nípa ojú ìwòye wa nípa irú àwọn iṣẹ́ àṣesìnlú kan. (Mátíù 24:45) Kò sí iyè méjì kankan pé inú àwọn apẹ̀yìndà ì bá dùn ká ní Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ òye wọn àtẹ̀yìnwá lórí irú àwọn kókó ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì kọ̀ láti tẹ̀ síwájú. Irú ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀. Èé ṣe? Àwọn ènìyàn Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin.

17. Báwo ni àwọn olólùfẹ́ wa ṣe lè dán ìdúróṣinṣin wa wò nígbà míràn?

17 Ṣùgbọ́n, ọ̀ràn ìdúróṣinṣin tí a gbé gbòdì lè kàn wá gbọ̀ngbọ̀n. Nígbà tí ọ̀rẹ́ àtàtà kan tàbí mẹ́ńbà ìdílé wa kan bá yan ipa ọ̀nà tí ó tẹ ìlànà Bíbélì lójú, a lè máà mọ ẹni tí ó yẹ kí a jẹ́ adúróṣinṣin sí. Lọ́nà ti ẹ̀dá, a máa ń fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa. Ṣùgbọ́n kò yẹ kí a fi ìdúróṣinṣin wa sí wọn ṣáájú ìdúróṣinṣin wa sí Jèhófà láé! (Fi wé Sámúẹ́lì Kíní 23:16-18.) A kò ní ṣèrànwọ́ fún àwọn oníwà àìtọ́ láti bo ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo mọ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò ní gbè sí wọn lẹ́yìn ní lílòdì sí àwọn alàgbà tí ń gbìyànjú láti ‘tọ́ wọn sọ́nà nínú ẹ̀mí ìwà tútù.’ (Gálátíà 6:1) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò túmọ̀ sí jíjẹ́ aláìdúróṣinṣin sí Jèhófà, sí ètò àjọ rẹ̀, àti sí ẹnì kan tí a fẹ́ràn. Ó ṣe tán, ṣíṣèdíwọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kan láti gba ìbáwí tí ó yẹ fún un túmọ̀ sí dídènà ìfẹ́ tí Jèhófà fẹ́ fi hàn sí i. (Hébérù 12:5-7) Rántí pẹ̀lú pé, “òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́.” (Òwe 27:6) Ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí ó sojú abẹ níkòó tí a gbé karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè mú kí olólùfẹ́ kan tí ó hùwà àìtọ́ sọ iyì tí ó ní fún ara rẹ̀ nù, ṣùgbọ́n ó lè jẹ́ èyí tí yóò gbẹ̀mí rẹ̀ là nígbẹ̀yìngbẹ́yín!

Fi Ìdúróṣinṣin Kojú Inúnibíni

18, 19. (a) Kí ni Áhábù ń fẹ́ kí Nábótì fún òun, èé ṣì ti ṣe tí Nábótì fi kọ̀? (b) Ìdúróṣinṣin Nábótì ha ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi kú nítorí rẹ̀ bí? Ṣàlàyé.

18 Nígbà míràn, ìjà tí Sátánì ń gbé ko ìdúróṣinṣin wa máa ń jẹ́ lọ́nà tààràtà. Gbé ọ̀ràn Nábótì yẹ̀ wò. Nígbà tí Ọba Áhábù fúngun mọ́ ọn láti ta ọgbà àjàrà rẹ̀, ó fèsì pé: “Olúwa máà jẹ́ kí èmi fi ogún àwọn bàbá mi fún ọ.” (Àwọn Ọba Kìíní 21:3) Kì í ṣe pé Nábótì jẹ́ olóríkunkun; ó jẹ́ adúróṣinṣin. Òfin Mósè pàṣẹ pé ọmọ Ísírẹ́lì kankan kò gbọ́dọ̀ ta ilẹ̀ tí ó jogún fún àkókò títí lọ fáàbàdà. (Léfítíkù 25:23-28) Nábótì mọ̀ dájúdájú pé ọba rírorò yí lè pa òun, nítorí Áhábù ti yọ̀ǹda kí aya rẹ̀, Jésébélì, pa ọ̀pọ̀ wòlíì Jèhófà! Síbẹ̀ Nábótì dúró gbọn-in.—Àwọn Ọba Kìíní 18:4.

19 Nígbà míràn ìdúróṣinṣin ń náni ní ohun kan. Jésébélì, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ “àwọn ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun,” yírọ́ mọ́ Nábótì lẹ́sẹ̀ pé ó hùwà ọ̀daràn kan tí òun kò hù. Nítorí èyí, a pa òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. (Àwọn Ọba Kìíní 21:7-16, NW; Àwọn Ọba Kejì 9:26) Ìyẹn ha túmọ̀ sí pé Nábótì gbé ìdúróṣinṣin rẹ̀ gbòdì bí? Rárá o! Nábótì jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin adúróṣinṣin tí ó “wà láàyè” nínú ìrántí Jèhófà títí di ìsinsìnyí, tí wọ́n sùn jẹ́ẹ́jẹ́ nínú ibojì títí di ìgbà àjíǹde.—Lúùkù 20:38; Ìṣe 24:15.

20. Báwo ni ìrètí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti di ìdúróṣinṣin wa mu?

20 Ìlérí kan náà ń fi àwọn adúróṣinṣin sí Jèhófà lọ́kàn balẹ̀ lónìí. A mọ̀ pé ìdúróṣinṣin wa lè ná wa ní ohun ṣíṣeyebíye nínú ayé yìí. Jésù Kristi fi ẹ̀mí rẹ̀ dí ìdúróṣinṣin rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọn yóò ṣe ohun kan náà sí wọn. (Jòhánù 15:20) Bí ìrètí rẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la ti mú un dúró, bẹ́ẹ̀ náà ni tiwa ṣe ń mú wa dúró. (Hébérù 12:2) Nípa báyìí a lè jẹ́ adúróṣinṣin ní kíkojú gbogbo onírúurú inúnibíni.

21. Kí ni Jèhófà fi dá àwọn adúróṣinṣin rẹ̀ lójú?

21 Lóòótọ́, ìwọ̀nba kéréje lára wa ni a ń gbéjà ko ìdúróṣinṣin wọn lọ́nà tààràtà. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn Ọlọ́run lè dojú kọ inúnibíni púpọ̀ sí i kí òpin tó dé. Báwo ni a ṣe lè ní ìdánilójú pé a óò di ìdúróṣinṣin wa mú? Nípa pípa ìdúróṣinṣin wa mọ́ nísinsìnyí. Jèhófà ti gbé iṣẹ́ ńlá kan lé wa lọ́wọ́—wíwàásù àti kíkọ́ni nípa Ìjọba rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a máa fi ìdúróṣinṣin bá iṣẹ́ pàtàkì yí lọ. (Kọ́ríńtì Kíní 15:58) Bí a kò bá yọ̀ǹda láti jẹ́ kí àìpé ẹ̀dá ènìyàn ba ìdúróṣinṣin wa sí ètò àjọ Jèhófà jẹ́, bí a bá sì dènà irú àìdúróṣinṣin tí a kò lè tètè fura sí bẹ́ẹ̀ irú bí ìdúróṣinṣin tí a gbé gbòdì, nígbà náà, bí a bá tilẹ̀ dán ìdúróṣinṣin wa wò gan-an, a óò ti gbára dì dáradára. Bí ó ti wù kí ó rí, a lè ní ìdálójú nígbà gbogbo pé Jèhófà ń fi ìdúróṣinṣin aláìkùsíbìkan hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin. (Sámúẹ́lì Kejì 22:26) Bẹ́ẹ̀ ni, òun yóò dáàbò bo àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀!—Orin Dáfídì 97:10.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Jésù fi ìgboyà gbéjà ko irú ètò okòwò tí ń mówó wọlé bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn kan ti sọ, ẹyọ owó àwọn Júù ìgbàanì kan pàtó ni a gbọ́dọ̀ fi san owó orí tẹ́ńpìlì. Nítorí náà, ó máa ń pọn dandan fún ọ̀pọ̀ àwọn olùbẹ̀wò sí tẹ́ńpìlì láti pààrọ̀ owó wọn kí wọ́n baà lè san owó orí. A yọ̀ǹda fún àwọn olùpààrọ̀ owó láti pààrọ̀ owó náà sí iye kan pàtó, èyí sì mú owó gọbọi wọlé.

b Wo Jí! December 22, 1993; January 8, 1994; àti January 22, 1994.

c Ẹgbẹ́ wọ́n ya láti inú ẹgbẹ́ Hásídì, ẹgbẹ́ kan tí ó dìde ní àwọn ọ̀rúndún ṣáájú láti ṣẹ́pá agbára ìdarí Gíríìkì. Àwọn Hásídì mú orúkọ wọn láti inú ọ̀rọ̀ Hébérù náà chasi·dhimʹ, tí ó túmọ̀ sí “àwọn ẹni ìdúróṣinṣin” tàbí “àwọn onítara ìsìn.” Bóyá wọ́n rò pé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó mẹ́nu kan “àwọn ẹni ìdúróṣinṣin” Jèhófà tọ́ka sí wọn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. (Orin Dáfídì 50:5) Àwọn, pẹ̀lú àwọn Farisí tí ó dìde lẹ́yìn wọn, jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn, àwọn tí wọ́n yan ara wọn sípò olùgbèjà ọ̀rọ̀ Òfin.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Báwo ni a ṣe lè yẹra fún jíjẹ́ kí àìpé àwọn ẹlòmíràn sún wa sí jíjẹ́ aláìdúróṣinṣin?

◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni àìpé tiwa fúnra wa fi lè sún wa sínú ìwà àìdúróṣinṣin?

◻ Báwo ni a ṣe lè dènà ìtẹ̀sí náà láti gbé ìdúróṣinṣin wa gbòdì?

◻ Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti pa ìdúróṣinṣin wa mọ́ àní ní àwọn àkókò inúnibíni pàápàá?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

Fífi Ìdúróṣinṣin Sìn Ní Bẹ́tẹ́lì

“Kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà bíbójúmu àti nípa ìṣètò.” Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé rẹ̀ nìyẹn. (Kọ́ríńtì Kíní 14:40) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé kí ìjọ kan tó lè mú ète tí a fi dá a sílẹ̀ ṣẹ, “ìṣètò” kí nǹkan lè lọ létòlétò pọn dandan. Bákan náà lónìí, àwọn alàgbà ní láti ṣe ìpinnu lórí àwọn ọ̀ràn pàtàkì kan, irú bíi yíyan àwọn mẹ́ńbà ìjọ sí onírúurú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ, ṣíṣètò ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, àti yíyẹ bí a ṣe ń kárí ìpínlẹ̀ wa wò. Nígbà míràn, irú ìṣètò bẹ́ẹ̀ lè gbé ìdánwò ìdúróṣinṣin dìde. A kò pa àṣẹ wọ̀nyí láti ọ̀run, wọn kò sì lè bá ìfẹ́ ọkàn gbogbo ènìyàn mu.

Nígbà míràn, ó ha máa ń jẹ́ ìpèníjà fún ọ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn ìṣètò pàtàkì kan tí a ṣe nínú ìjọ Kristẹni bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Bẹ́tẹ́lì lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Orúkọ náà Bẹ́tẹ́lì, ọ̀rọ̀ èdè Hébérù kan tí ó túmọ̀ sí “Ilé Ọlọ́run,” ni a ń pe gbogbo ẹ̀ka 104 ti Watch Tower Society, títí kan orílé iṣẹ́ ní United States. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ń gbé ní Bẹ́tẹ́lì, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ń fẹ́ kí àwọn ibi wọ̀nyí fi ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù fún Jèhófà hàn. Èyí ń béèrè ìdúróṣinṣin níhà ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.

Àwọn olùṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìwàlétòlétò àti ìmọ́tótó tí wọ́n rí níbẹ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ wà létòlétò, wọ́n sì jẹ́ aláyọ̀; ọ̀rọ̀ wọn àti ìwà wọn àti ìrísí wọn pàápàá fi hàn pé wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn Kristẹni tí ó dàgbà dénú tí a ti fi Bíbélì dá lẹ́kọ̀ọ́. Gbogbo mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì pátá jẹ́ adúróṣinṣin sí ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Ní àfikún sí i, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso pèsè ìwé pẹlẹbẹ kan fún wọn, tí a pè ní Dwelling Together in Unity, tí ó fi inú rere la àwọn ìṣètò pàtàkì tí wọ́n nílò fún irú ìdílé ńlá bẹ́ẹ̀ láti ṣiṣẹ́ pa pọ̀ dáradára lẹ́sẹẹsẹ. (Orin Dáfídì 133:1) Fún àpẹẹrẹ, ó sọ̀rọ̀ lórí iyàrá, oúnjẹ, ìmọ́tótó, ìmúra àti ìwọṣọ, àti irú àwọn ọ̀ràn tí ó fara pẹ́ ẹ. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ń fi ìdúróṣinṣin kọ́wọ́ ti irú ìṣètò bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn, wọ́n sì ń rọ̀ mọ́ ọn, àní nígbà tí ìfẹ́ ọkàn wọn gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan lè fẹ́ láti ṣe ohun tí ó yàtọ̀. Wọ́n wo ìwé pẹlẹbẹ yìí, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ìlànà tí ó ṣeé mú lò tí a wéwèé láti gbé ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ lárugẹ, kì í ṣe òfin àti àṣẹ rẹpẹtẹ tí kò báradé. Àwọn alábòójútó jẹ́ adúróṣinṣin nínú rírọ̀ mọ́ àwọn ìlànà wọ̀nyí tí a gbé ka Bíbélì, wọ́n sì ń lò wọ́n lọ́nà rere láti gbé ìdílé Bẹ́tẹ́lì ró àti láti fún wọn níṣìírí láti lépa iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì.

* Àwọn ilé ìtẹ̀wé, ọ́fíìsì, àti ilé gbígbé wọ̀nyí kò dúró fún tẹ́ńpìlì, tàbí ilé ńlá ti Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. Ìṣètò Ọlọ́run fún ìjọsìn mímọ́ gaara ni tẹ́ńpìlì Rẹ̀ nípa tẹ̀mí. (Míkà 4:1) Nítorí náà, a kò fi mọ sórí ilé kan tí a gbé kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn Adúróṣinṣin àti Àwọn Agbófinrù

Nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní ọdún 1916, ìwé Encyclopædia of Religion and Ethics sọ pé “a lè rí ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín àwọn adúróṣinṣin àti àwọn agbófinrù ní gbogbo ìgbà àti ní ibi gbogbo.” Ó ṣàlàyé pé: “Agbófinrù máa ń ṣe ohun tí a bá sọ pé kí ó ṣe, kì í rúfin kankan; ó máa ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ tí a kọ sílẹ̀, tí a sì lè rí kà. Adúróṣinṣin ń ṣe èyí pẹ̀lú ṣùgbọ́n . . . ó tilẹ̀ ń ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó ń fi gbogbo ọkàn rẹ̀ ṣeṣẹ́ rẹ̀, ó ń gbé ìṣarasíhùwà rẹ̀ karí ẹ̀mí tí ń bẹ lẹ́yìn ète iṣẹ́ tí ó fẹ́ ṣe.” Níwájú, ìwé kan náà yí sọ pé: “Láti jẹ́ adúróṣinṣin ní nínú ju jíjẹ́ ẹni tí ń pa òfin mọ́ lọ. . . . Ohun tí a fi ń dá adúróṣinṣin mọ̀ yàtọ̀ sí apòfinmọ́ ni pé adúróṣinṣin máa ń fi gbogbo ọkàn àti èrò inú ṣiṣẹ́ . . . Kì í yọ̀ǹda kí òun fúnra rẹ̀ ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá, kí ó fi ohun tí ó tọ́ sílẹ̀ láìṣe, tàbí kí ó ṣàìka nǹkan sí.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́