Fàyàwọ́—Àgbákò Ilẹ̀ Yúróòpù Nínú Àwọn Ọdún 1990
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GERMANY
Ọkọ̀ òkun ayárakánkán kan gbéra láti etíkun Àríwá Áfíríkà, ó forí lé Gibraltar; ọkọ̀ onílégbèé kan gbéra láti Poland, ó ń lọ síhà ìwọ̀ oòrùn; ọkọ̀ akẹ́rù ilẹ̀ Bulgaria kan forí lé àríwá Yúróòpù; ọkọ̀ òfuurufú kan ti Moscow fò lọ sí Munich. Kí ni àwọn ọkọ̀ wọ̀nyí fi bára tan? Wọ́n fi ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kó fàyàwọ́.
FÀYÀWỌ́ la ń pe kíkó ẹrù láti orílẹ̀-èdè kan tàbí ẹkùn ìpínlẹ̀ kan lọ sí òmíràn tàbí kíkó ẹrù wọnú orílẹ̀-èdè kan ní bòókẹ́lẹ́, bóyá láti yẹra fún àwọn aláṣẹ nítorí pé a ti fòfin de àwọn ẹrù náà tàbí láti yẹra fún sísan owó orí tó yẹ lórí wọn. Ó kéré tán, wọ́n ti ń ṣe fàyàwọ́ ní Yúróòpù láti ọ̀rúndún kẹrìnlá. Iṣẹ́ tí kò bófin mu náà ti gbilẹ̀ débi pé ìtàn àtẹnudẹ́nu ni ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ń sọ nípa ìwà akin tí àwọn onífàyàwọ́ kan hù, tí àwọn kan nínú wọn wá di akọni olókìkí.
Fàyàwọ́ kò bófin mu, ó sì léwu púpọ̀—bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ti mú kí àwọn ọjà kan lókìkí. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, wọ́n ṣe fàyàwọ́ àwọn ẹ̀dà apá mélòó kan nínú Bíbélì, tí William Tyndale túmọ̀, wọ ilẹ̀ England tí wọ́n ti fòfin dè wọ́n. Síwájú sí i, ìwé ìròyìn GEO sọ pé, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Germany gba ilẹ̀ Faransé ní 1940, àwọn onífàyàwọ́—tí wọ́n mọ gbogbo ọ̀nà kọ́rọkọ̀rọ ilẹ̀ Normandy—“ló mọ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tí [ilẹ̀ Faransé] lè gbà ja àjàgbara jù.”
Ní báyìí tí a wà ní 50 ọdún lẹ́yìn náà, fàyàwọ́ ń búrẹ́kẹ—ṣùgbọ́n dípò kó jẹ́ ìbùkún, àgbákò ni. Yúróòpù ti wá di ibi tí ìwé ìròyìn Süddeutsche Zeitung ti ilẹ̀ Germany pè ní “párádísè àwọn onífàyàwọ́.” Kí ló fa èyí?
Ìdí kan ni pé, Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ti pọ̀ sí i, àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú rẹ̀ ti pọ̀ sí i láti 6 sí 15 láàárín 40 ọdún.a Bí a ṣe mú òfin nípa àṣẹ ìwọ̀lú rọrùn sí i ti mú kí àwọn ènìyàn lè túbọ̀ ti orílẹ̀-èdè kan wọ òmíràn. Ẹnì kan tí ń gbé Yúróòpù sọ pé: “Ní 30 ọdún sẹ́yìn, àwọn òṣìṣẹ́ máa ń yẹ ìwé àṣẹ ìwọ̀lú wò ní gbogbo ẹnu ibodè. Nísinsìnyí, o lè wakọ̀ kọjá àwọn ẹnu ibodè kan náà láìtilẹ̀ dúró rárá.”
Síwájú sí i, Ìlà Oòrùn Yúróòpù ti ṣí àwọn ibodè rẹ̀. Àwọn ẹnu ibodè kan, bí irú èyí tó wà láàárín ìhà méjèèjì ilẹ̀ Germany tẹ́lẹ̀, kò tilẹ̀ sí mọ́. Gbogbo ìwọ̀nyí túmọ̀ sí pé ó túbọ̀ rọrùn láti ṣòwò kọjá ibodè. Àmọ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ó túbọ̀ rọrùn láti ṣe fàyàwọ́. Ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò sì ti yára ń lo àǹfààní tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí sílẹ̀ náà. Ẹgbẹẹgbẹ́ àwọn ọ̀daràn ní onírúurú ẹrù fàyàwọ́ tí wọ́n gbájú mọ́.
Wọ́n Ń Ṣe Fàyàwọ́ Àwọn Iṣẹ́ Ọnà
Ọ̀pọ̀ ọdún ni ọwọ́ àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn Ayé, tí ń ra ìṣúra iṣẹ́ ọnà, kò fi lè tẹ àwọn ìṣúra iṣẹ́ ọnà ilẹ̀ Rọ́ṣíà títí di ìgbà tí Ìlà Oòrùn Yúróòpù ṣí àwọn ibodè rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé ìròyìn The European sọ pé, ní báyìí, “àjọṣepọ̀ ṣíṣàjèjì láàárín àwọn ibi ìkóṣẹ́-ọnà-sí ti ìhà ìwọ̀ oòrùn Yúróòpù àti àwọn àjọ ìpàǹpá aṣekúpani ti àwọn onífàyàwọ́ ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ń jí” irú àwọn ìṣúra iṣẹ́ ọnà bẹ́ẹ̀ “kó.” Ní gidi, “àwọn ọlọ́pàá gbà pé ṣíṣe fàyàwọ́ àwọn ìṣúra iṣẹ́ ọnà tí a jí kó [ní Yúróòpù] ti di ìwà ọ̀daràn tí ń mérè wá ṣìkẹ́ta lẹ́yìn fàyàwọ́ oògùn olóró àti ohun ìjà tí kò bófin mu.”
Ṣíṣe fàyàwọ́ iṣẹ́ ọnà ń mówó wá gan-an ní Rọ́ṣíà àti níbòmíràn. Ní Ítálì, láàárín ọdún méjì, iye owó àwọn iṣẹ́ ọnà tí wọ́n jí kó lé ní 500 mílíọ̀nù dọ́là. Ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn iṣẹ́ ọnà ilẹ̀ Yúróòpù tí wọ́n jí kó ń gúnlẹ̀ sí London, níbi tí wọ́n ti ń rẹ́ni rà wọ́n. Ní gidi, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n tilẹ̀ “ń jí kó kí wọ́n lè rí òǹrajà tí kò kọ̀kan.” Abájọ ti àwọn tí a ń rí gbà padà fi mọ níwọ̀nba ìpín 15 péré nínú ọgọ́rùn-ún.
Àwọn Èròjà Onímájèlé —Oríṣi Fàyàwọ́ Mìíràn
Ńṣe la ń sanwó fún àwọn ọ̀daràn láti ṣe fàyàwọ́ iṣẹ́ ọnà wọlé sí orílẹ̀-èdè kan, nígbà tí a ń sanwó fún wọn láti ṣe fàyàwọ́ àwọn ohun mìíràn jáde. Àwọn èròjà onímájèlé jẹ́ àpẹẹrẹ kan. Èé ṣe tí a fi ń ṣe wàhálà láti ṣe fàyàwọ́ àwọn èròjà onímájèlé kúrò ní orílẹ̀-èdè kan? Nítorí pé iye tí yóò náni láti palẹ̀ àwọn èròjà onímájèlé mọ́ ti pọ̀ gan-an ní àwọn ilẹ̀ kan. Láfikún sí èyí ni àwọn òfin ìdáàbòbo àyíká tó túbọ̀ le sí i, tó mú kí ó túbọ̀ sàn pé kí a sanwó fún àwọn onífàyàwọ́ láti kó àwọn èròjà onímájèlé tí ń tilé iṣẹ́ ńláńlá wá lọ sílẹ̀ òkèèrè.
Ibo ni wọ́n ń da àwọn èròjà wọ̀nyí sí? Ìwádìí tí Ẹ̀ka Àbójútó Ìwà Ọ̀daràn Lábẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ Ilẹ̀ Germany ṣe fi hàn pé, àwọn àjọ ìpàǹpá ń ṣe fàyàwọ́ àwọn èròjà onímájèlé—bí àlòkù bátìrì ọkọ̀, àwọn èròjà tí ń yòrò, àwọn ọ̀dà, àwọn oògùn apakòkòrò, àti àwọn mẹ́táàlì onímájèlé—láti ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Ayé lọ sí àwọn ilẹ̀ bí Poland, Romania, àti Soviet Union àtijọ́. Lọ́jọ́ iwájú, àwọn nǹkan wọ̀nyí yóò wu ìlera àwọn olùgbé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí léwu.
Àwọn Sìgá Tí A Fòfin Dè
Àwọn àwùjọ ọ̀daràn mìíràn gbájú mọ́ kíkó àwọn sìgá tí a fòfin dè. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ti fi ọkọ̀ òkun ayárakánkán kó irú àwọn sìgá bẹ́ẹ̀ láti Àríwá Áfíríkà lọ síbi Ìyawọlẹ̀ Omi Iberian tàbí kí wọ́n fi mọ́tò kó wọn láti Poland lọ sí Germany. Owó rẹpẹtẹ ló ń náni. Òwò fàyàwọ́ sìgá tí a kò sanwó orí rẹ̀ ń ná Ìjọba Germany ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mílíọ̀nù owó mark (674 mílíọ̀nù dọ́là, U.S.) tí à bá san bí owó orí lọ́dọọdún.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Die Welt ṣe sọ, ní àwọn pópó Berlin, nǹkan bí 10,000 òǹtajà—tí a tún ń pè ní agbóògùn-olóró—ń ta àwọn sìgá tí a ti fòfin dè lówó pọ́ọ́kú.
Kíkó Ènìyàn Wọ̀lú Láìbófinmu
Oríṣi ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò mìíràn—èyí tó burú jù—ni kíkó ènìyàn wọ̀lú láìbófinmu. Owó gọbọi ni wọ́n ń pa bí wọ́n bá lè kó ènìyàn—bóyá nínú ọkọ̀ akérò bi irú èyí tí a mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí—wọ Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù láìbófinmu. Ní gidi, Ibùdó Àgbékalẹ̀ Ìlànà Ìṣíkiri Lágbàáyé, ní Vienna, fojú díwọ̀n pé, owó tí wọ́n ń pa lọ́dọọdún lórí kíkó ènìyàn wọ̀lú láìbófinmu lé ní 1.1 bílíọ̀nù dọ́là.
Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn tí ń ṣí wọ̀lú láìbófinmu ń wá láti àwọn ilẹ̀ tí kò lọ́rọ̀, nítorí náà, díẹ̀ lára wọn ló lè rówó san fún àwọn onífàyàwọ́ náà ṣáájú. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá gúnlẹ̀ sí Yúróòpù, wọ́n ń mú kí wọn san gbèsè náà tipátipá nípa ṣíṣiṣẹ́ fún àwọn onífàyàwọ́ náà àti àwọn tí wọ́n jọ ń hùwà ọ̀daràn náà. Àwọn aṣíwọ̀lú tí kò lólùrànlọ́wọ́ náà ń tipa bẹ́ẹ̀ bá ara wọn nínú ìdè ìsìnrú òde òní, tí a ń rẹ́ wọn jẹ, tí a ń fipá mú wọn ṣe nǹkan, tí a ń jà wọ́n lólè, tí a sì ń fipá bá wọn lò pọ̀. Níkẹyìn, àwọn kan ń di òṣìṣẹ́ fún àwọn tí ìwé ìròyìn Die Welt pè ní àjọ ìpàǹpá onísìgá; àwọn mìíràn ń di aṣẹ́wó.
Kì í ṣe iye owó orí tí a kò san nìkan ni orílẹ̀-èdè tí wọ́n kó wọ̀ náà ń pàdánù. Àwọn àjọ ìpàǹpá tí ń bára wọn díje ń bẹ̀rẹ̀ ohun tí ìwé ìròyìn Süddeutsche Zeitung pè ní “ìwà ìkà aláìlẹ́gbẹ́.” Àwọn àkọsílẹ̀ tó wà jẹ́ ẹ̀rí fúnra wọn: Níbi tí a ń pè ní Ìlà Oòrùn Germany tẹ́lẹ̀, àwọn àjọ ìpàǹpá pa ènìyàn 74 láàárín ọdún mẹ́rin.
Èyí Tó Bani Lẹ́rù Jù
Ìwé ìròyìn kan sọ pé: “Nínú gbogbo ohun ti a kò rò tẹ́lẹ̀ tí àìsí ilẹ̀ Soviet Union mọ́ fà, ó ṣeé ṣe kó máà sí ọ̀kan tó bani lẹ́rù ju fàyàwọ́ ohun ìjà olóró lọ.” Ó jọ pé wọ́n ti ṣe fàyàwọ́ àwọn nǹkan onítànṣán olóró láti Rọ́ṣíà lọ sí Germany, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ìtúkiri oníjàǹbá yìí di “ìṣòro àgbáyé, ní pàtàkì, ìṣòro ilẹ̀ Germany.”
Fi ọkọ̀ òfuurufú tó lọ láti Moscow tí a mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣàpẹẹrẹ. Nígbà tó gúnlẹ̀ sí Munich, wọ́n rí èrò kan tó di èròjà plutonium, èròjà onítànṣán olóró kan, sínú ìfàlọ́wọ́ rẹ̀. Nítorí pé èròjà plutonium jẹ́ májèlé eléwu ńlá gan-an, tí ó sì lè fa jẹjẹrẹ, ìtújáde rẹ̀ ì bá ṣèparun fún Munich àti àwọn olùgbé rẹ̀.
Níbẹ̀rẹ̀ 1996, wọ́n mú onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ohun àdánidá kan tó jẹ́ ará Rọ́ṣíà, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn án pé ó ṣe fàyàwọ́ èròjà onítànṣán olóró tó lé ní kìlógíráàmù kan, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Süddeutsche Zeitung sì ṣe sọ, “ó wúlò láti fi ṣe bọ́ǹbù eléròjà átọ̀mù.” Ó tọ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn máa ṣàníyàn. Níbi ìpàdé àwọn lọ́gàálọ́gàá ìjọba kan ní Moscow, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Times ti London ṣe wí, àwọn òṣèlú láti àwọn orílẹ̀-èdè oníléeṣẹ́ ẹ̀rọ ńláńlá pohùn pọ̀ lórí ètò kan láti gbìyànjú “láti dènà ṣíṣe fàyàwọ́ àwọn èròjà ohun ìjà olóró láti Soviet Union àtijọ́ lọ fún àwọn akópayàbáni tàbí ‘àwọn orílẹ̀-èdè tí ń fàjọ̀ngbọ̀n lẹ́sẹ̀.’”
Nítorí irú ewu bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń rí, wọ́n ń bi ara wọn pé: Ǹjẹ́ àdéhùn àjùmọ̀ṣe láàárín àwọn orílẹ̀-èdè lè dènà fàyàwọ́? Bí àwọn ìjọba bá tilẹ̀ ń ṣòótọ́, tí wọ́n sì lérò rere, ǹjẹ́ wọ́n lè dẹ́kun ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò? Ṣe fàyàwọ́ yóò tẹ̀ síwájú láti ipò jíjẹ́ àgbákò ní àwọn ọdún 1990 sí jíjẹ́ àjálù àjàkálẹ̀ ní ẹgbẹ̀rúndún tuntun ni? Tàbí ìdí wà láti retí pé iṣẹ́ yóò tán mọ́ àwọn onífàyàwọ́ lọ́wọ́ láìpẹ́?
Fàyàwọ́—Òwò Tí Ẹ̀mí Rẹ̀ Kò Gùn Mọ́
A nídìí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti gbà gbọ́ pé fàyàwọ́ yóò di nǹkan àtijọ́ láìpẹ́. Ìdí ni pé àwọn ohun tó mú kí fàyàwọ́ ṣeé ṣe, kó sì fa àwọn ènìyàn kan mọ́ra, yóò parẹ́ láìpẹ́. Àwọn nǹkan wo ni?
Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ètò ọrọ̀ ajé òde òní tí ń dẹ́rù pani, tó sì jẹ́ ti àìṣòdodo, ti yọrí sí àìdọ́gba nínú pípín ọrọ̀. Nígbà tí àwọn ènìyàn ń gbádùn ní àwọn ilẹ̀ kan, àwọn ènìyàn tí ń gbé gẹ́rẹ́ lódìkejì ẹnu ibodè ilẹ̀ náà lè tòṣì tàbí kí wọ́n máà ní tó. Àwọn ipò wọ̀nyí ló mú kí fàyàwọ́ máa mówó wọlé. Ṣùgbọ́n Ẹlẹ́dàá wa ti ṣèlérí nínú Ìwé Mímọ́ pé òun yóò gbé ètò àwọn nǹkan kan kalẹ̀ láìpẹ́, nínú èyí tí “òdodo yóò . . . máa gbé.” Àwọn ètò ọrọ̀ ajé tí ń dẹ́rù pani, tó sì jẹ́ ti àìṣòdodo, kò ní sí mọ́.—2 Pétérù 3:13.
Síwájú sí i, a ó pa àwọn ààlà ilẹ̀ rẹ́, nítorí pé lábẹ́ ìjọba Ọba ọ̀run náà, Jésù Kristi, aráyé yóò di àwùjọ kan ṣoṣo. Nígbà tí irú ẹgbẹ́ ará bẹ́ẹ̀ bá ń gbé gbogbo orí ilẹ̀ ayé, kò ní sí àwọn tí ń ṣí wọ̀lú láìbófinmu mọ́. Níwọ̀n bí ẹnikẹ́ni kò sì ti ní jagun mọ́, kò ní sí ewu fífi ìtànṣán olóró bàyíká jẹ́ nípasẹ̀ ogun oníbọ́ǹbù. Nínú ètò àwọn nǹkan tuntun, aráyé yóò kọ́ láti lo àyíká bó ti yẹ.—Sáàmù 46:8, 9.
Àwọn lájorí ohun tí ń fa fàyàwọ́ lóde òní ni ìwọra, àìṣòótọ́, àti àìnífẹ̀ẹ́ ẹlòmíràn. Ti pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ní irú ìwà báwọ̀nyí lónìí jẹ́ ẹ̀rí pé a ń gbé ní àkókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1-5) Ètò tuntun òdodo tí Jèhófà yóò gbé kalẹ̀ ti dé tán. Ìdí wà fún gbogbo wa láti fìgbọ́kànlé wo ọjọ́ iwájú fún ètò tuntun ti Jèhófà, kì í ṣe fún àwọn ìjọba ènìyàn tàbí ètò ìṣúnná wọn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ni Austria, Belgium, Britain, Denmark, Finland, Faransé, Germany, Gíríìsì, Ireland, Ítálì, Luxembourg, Netherlands, ilẹ̀ Potogí, Sípéènì, àti Sweden.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
Àwọn Ẹrù Òfin Mìíràn
Àwọn ẹranko tó ṣọ̀wọ́n: Wọ́n mú ọkùnrin kan tí ń kó ìjàpá ṣíṣọ̀wọ́n láti Serbia lọ sí Germany. Ó jẹ́wọ́ pé òun ti ṣe fàyàwọ́ 3,000 irú ẹranko bẹ́ẹ̀ láàárín ọdún márùn-ún, tí owó tí òun pa sì jẹ́ ìlàjì mílíọ̀nù owó mark (300,000 dọ́là, U.S.). Ṣíṣe fàyàwọ́ àwọn ẹranko tó ṣọ̀wọ́n wà lọ́wọ́ àwọn tí ń fi ọ̀ràn dídá ṣiṣẹ́ ṣe, ó sì ń pọ̀ sí i. Òṣìṣẹ́ ibodè kan sọ pé: “Òwò fàyàwọ́ náà ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. Àwọn kan tí ń rà wọ́n ń sanwó gọbọi lórí wọn.”
Àwọn ayédèrú ọjà olórúkọ lílókìkí: Láàárín oṣù mẹ́fà, àwọn aṣọ́bodè níbùdókọ̀ òfuurufú Frankfurt, ní Germany, gbẹ́sẹ̀ lé ẹrù tó lé ní 50,000 tó ní orúkọ lílókìkí. Àwọn ẹrù ọ̀hún—bí aago, àwọn èlò kọ̀ǹpútà, àwọn èlò eré ìdárayá, àti àwọn ìgò ojú—jẹ́ àgbélẹ̀rọ.
Àwọn ọkọ̀: Gbajúmọ̀ ilé iṣẹ́ kan tí ń fi ọkọ̀ háyà ní Yúróòpù sọ pé jíjí ọkọ̀ gbé pọ̀ sí i ní ìpín 130 nínú ọgọ́rùn-ún láàárín ọdún márùn-ún. Ìwé ìròyìn kan sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọgbọ́n tí “àwọn olè ojú pópó òde òní” ń lò. Wọn yóò háyà ọkọ̀, wọn yóò padà sọ pé olè ti já a gbà lọ́wọ́ àwọn, wọn yóò wá ṣe fàyàwọ́ àwọn ọkọ̀ náà kúrò lórílẹ̀-èdè náà.
Àwọn mẹ́táàlì oníyebíye: Cobalt, nickel, bàbà, ruthenium, àti germanium wà lárọ̀ọ́wọ́tó—lówó pọ́ọ́kú—ní Estonia, tó ti wá di ọ̀kan lára àwọn olú ìlú ẹrù fàyàwọ́ lágbàáyé.
Epo mọ́tò: Àwọn onífàyàwọ́ tí ń fi ọkọ̀ ojú omi gbé epo mọ́tò kọjá lórí Odò Danube láàárín Romania àti Serbia ń pa owó tó pọ̀ tó 2,500 dọ́là lóru ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Ní àgbègbè yìí, ìpíndọ́gba owó tí òṣìṣẹ́ kan ń gbà lóṣù jẹ́ nǹkan bí 80 dọ́là!