Ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ Ewu Agbára Átọ́míìkì Ó Ha Ti Dópin Nígbẹ̀yìngbẹ́yín Bí?
“ÀLÀÁFÍÀ lórí Ilẹ̀-Ayé dàbí ohun tí ó ṣeéṣe dáradára nísinsìnyí ju bí ó ti rí nígbà èyíkéyìí láti ìgbà Ogun Àgbáyé II.” Ìfojúdíwọ̀n ẹlẹ́mìí nǹkan-yóò-dára yìí láti ẹnu aṣojúkọ̀ròyìn kan ní ìparí àwọn ọdún 1980 ni a gbékarí òtítọ́ náà pé àwọn àdéhùn ìbọ́ra ogun sílẹ̀ pàtàkì àti àwọn ìrugùdùsókè òṣèlú tí a kò retí tí fòpin sí Ogun Tútù náà nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ewu agbára átọ́míìkì, tí ó fi púpọ̀ jẹ́ ànímọ́ ìkonilójú alágbára ògbóǹtarìgì tẹ́lẹ̀rí náà, ha ti dópin pátápátá pẹ̀lú bí? Ǹjẹ́ níti gidi ni àlàáfíà àti àìléwu pípẹ́títí wà lárọ̀ọ́wọ́tó bí?
Àwọn Ewu Ìgbèrúdipúpọ̀
Nígbà Ogun Tútù náà, nígbà tí ó jẹ́ pé wọ́n gbáralé ìmúdọ́gba ìpayà láti pa àlàáfíà mọ́, àwọn alágbára ògbóǹtarìgì gbà láti fàyègba ìmúgbèrú àpadé-àludé nípa agbára átọ́míìkì nínú ìlépa wọn fún àwọn góńgó alálàáfíà ṣùgbọ́n láti dín ìlò rẹ̀ kù nínú ṣíṣe àwọn ohun ìjà alágbára átọ́míìkì. Ní 1970 Ìmùlẹ̀ Àdéhùn Ìdíwọ̀n Agbára Átọ́míìkì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́; lẹ́yìn náà ni àwọn 140 orílẹ̀-èdè fọwọ́síwèé. Síbẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Argentina, Brazil, India, àti Israel, tí wọ́n lágbára láti ṣe ohun-ìjà alágbára átọ́míìkì ti kọ̀ láti fọwọ́síwèé títí di òní olónìí pàápàá.
Bí ó ti wù kí ó rí, ní 1985, orílẹ̀-èdè mìíràn tí ó lágbára láti ṣe ohun-ìjà alágbára átọ́míìkì, North Korea, fọwọ́síwèé. Nítorí náà nígbà tí ó kéde ìyọwọ́yọsẹ̀ rẹ̀ kúrò nínú ìmùlẹ̀ àdéhùn náà ní March 12, 1993, lọ́nà tí ó bọ́gbọ́nmu aráyé kò fi ara rere gbà á. Ìwé ìròyìn lédè German náà Der Spiegel ròyìn pé: “Ìwé ìyọwọ́yọsẹ̀ kúrò nínú Ìmùlẹ̀ Àdéhùn Ìdíwọ̀n Agbára Átọ́míìkì dá àpẹẹrẹ ìṣáájú kan sílẹ̀: Ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ewu ìfagbára átọ́míìkì báradíje ti wà nísinsìnyí, tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Asia, tí ó sì lè túbọ̀ léwu síi ju ìfi bọ́m̀bù díje láàárín àwọn alágbára ògbóǹtarìgì.”
Bí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ti ń bí àwọn orílẹ̀-èdè titun ní ìwọ̀n kan tí ń ṣeni ní kàyéfì, ó ṣeéṣe kí iye àwọn agbára átọ́míìkì pọ̀ síi. (Wo àpótí.) Akọ̀ròyìn Charles Krauthammer kìlọ̀ pé: “Òpin ìhalẹ̀mọ́ni Soviet kò túmọ̀sí òpin ewu agbára átọ́míìkì. Ewu náà gan-an ni ìgbèrúdipúpọ̀, ìgbèrúdipúpọ̀ sì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni.”
Bọ́m̀bù fún Títà
Àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ di alágbára átọ́míìkì ṣì ń háragàgà láti jèrè ipò-iyì àti agbára tí àwọn ohun-ìjà wọ̀nyí ń nawọ́ rẹ̀ síni. Orílẹ̀-èdè kan ni a sọ pé ó ti ra ó kérétán àwọn ṣóńṣó orí àfọ̀njá olóró alágbára átọ́míìkì méjì láti Kazakhstan. Orílẹ̀-èdè aláààrẹ ti Soviet àtijọ́ yìí ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ṣóńṣó orí àfọ̀njá olóró náà lábẹ́ àṣẹ pé wọ́n ti “sọnù.”
Ní October 1992 àwọn ọkùnrin mélòókan ni a fàṣẹ-ọba mú ní Frankfurt, Germany, a sì bá òjé cesium onítànṣán olóró gíga tí ìwọ̀n rẹ̀ tó 200 gíráàmù lọ́wọ́ wọn, èyí tí ó pọ̀ tó láti mú kí ìpèsè omi odidi ìlú-ńlá kan di onímájèlé. Ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, àwọn onífàyàwọ́ méje ni a mú ní Munich tí a sì bá òkúta uranium tí ìwọ̀n rẹ̀ tó 2.2 kìlógíráàmù lọ́wọ́ wọn. Ìṣàwárí àwọn àjọ ìpàǹpá méjì tí ń ṣe fàyàwọ́ agbára átọ́míìkì láàárín ọ̀sẹ̀ méjì ba àwọn aláṣẹ lẹ́rù, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé kìkì márùn-ún irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ni a ròyìn kárí-ayé jálẹ̀ ọdún tí ó kọjá.
Yálà àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ìpètepèrò láti tà wọ́n fún àwọn àwùjọ adáyàfoni tàbí fún àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè ni a kò mọ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ṣíṣeéṣe náà fún ìfagbára átọ́míìkì dáyàfoni ń ga síi. Dókítà David Lowry ti Ibùdó Ìsọfúnni Nípa Ìgbèrúdipúpọ̀ ní Europe ṣàlàyé ewu náà pé: “Gbogbo ohun tí adáyàfoni kan nílò ni láti fi ẹ̀dà òkúta uranium kan tí ó lóró gan-an ráńṣẹ́ sí àwọn aláṣẹ kan tí ó lórúkọ fún àyẹ̀wò, ní sísọ pé a ní èyí tí ó pọ̀ gan-an ẹ̀rí rẹ̀ sì nìyí. Bíi gbọ́mọgbọ́mọ kan tí ó gé etí ẹran-ọdẹ rẹ̀ ráńṣẹ́ ni ó rí.”
“Àwọn Ìfìdùgbẹ̀ Ewu” àti “Ìfẹ̀mí Wewu” Láì Jagun
Nígbà tí 1992 bẹ̀rẹ̀, àwọn 420 ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù agbára átọ́míìkì ni a lò nínú ìlépa tí kò mógun lọ́wọ́ ti pípèsè iná mànàmáná; 76 mìíràn ni a ń ṣe lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, àwọn jàm̀bá ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù agbára átọ́míìkì ti yọrí sí àwọn ìròyìn àmódi tí ń pọ̀ síi, ti ìṣẹ́nú, àti bíbí abirùn ọmọ. Ìròyìn kan sọ pé nígbà tí ó fi máa di ọdún 1967 àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ níbi ilé-iṣẹ́ ìpèsè plutonium kan ní Soviet ti ṣokùnfà àwọn ìtújáde ìtànṣán olóró gíga tí ó fi ìlọ́po mẹ́ta pọ̀ ju ti àjálù Chernobyl lọ.
Àmọ́ ṣáá o, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí ó wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà ní Chernobyl, Ukraine, ní April 1986 ni ó fa àfiyèsí àwọn oníròyìn. Grigori Medwedew, adelé ọ̀gá àwọn onímọ̀ iṣẹ́-ẹ̀rọ alágbára átọ́míìkì ní ilé-iṣẹ́ ìpèsè ní Chernobyl ní àwọn ọdún 1970, ṣàlàyé pé “òkìtì bàm̀bà ìtànṣán olóró gíga wíwàpẹ́títí” tí a tú dà sínú afẹ́fẹ́ “ni a lè fiwé mẹ́wàá irú àwọn bọ́m̀bù tí a tú dà sórí Hiroshima bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìyọrísí onígbà gígùn.”
Nínú ìwé rẹ̀ Tschernobylskaja chronika, Medwedew ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù agbára átọ́míìkì 11 tí ó léwu ní Soviet Union àtijọ́ ní agbedeméjì àwọn ọdún 1980 àti 12 mìíràn ní United States. Èyí tí a mẹ́nukàn gbẹ̀yìn yìí ní àwọn ìjàm̀bá tí ń múnitagìrì nínú ní Erékùṣù Three Mile ní ọdún 1979. Nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn Medwedew mẹ́nukàn án pé: “Òun ni ó kọ́kọ́ ta epo líléwu sí aṣọ àlà agbára átọ́míìkì tí ó sì jádìí ìtànjẹ náà tí ó ti wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn nípa àìléwu àwọn ilé-iṣẹ́ ìpèsè agbára átọ́míìkì—ṣùgbọ́n kìí ṣe lọ́kàn gbogbo ènìyàn ṣáá o.”
Èyí ṣàlàyé ìdí tí àwọn àjálù fi ń wáyé síbẹ̀. Ní ọdún 1992 wọ́n fi èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 20 nínú ọgọ́rùn ún pọ̀ síi ní Russia. Lẹ́yìn ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, nínú oṣù March ní ọdún yẹn ní ibùdó ìpèsè agbára iná mànàmáná ní Sosnovy Bore ní St. Petersburg, Russia, ìpele ìwọ̀n ìtànṣán fi ìpín 50 nínú ọgọ́rùn ún ga síi ní àríwá ìlà-oòrùn England ó sì dé ìlọ́po méjì ìwọ̀n gíga jùlọ tí a gbàláyè ní Estonia àti ní ìhà gúúsù Finland. Ọ̀jọ̀gbọ́n John Urquhart ti Newcastle University gbà pé: “N kò lè fi ẹ̀rí hàn pé Sosnovy Bore ni ó fa ìbísí náà—ṣùgbọ́n bí kìí bá ṣe Sosnovy Bore, kí wá ni?”
Àwọn aláṣẹ kan jẹ́wọ́ pé àwọn ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù agbára átọ́míìkì irú ti Chernobyl ní àléébù nínú ọ̀nà tí a gbà ṣe wọ́n, wọ́n sì wulẹ̀ ti léwu jù láti lò. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, iye tí ó ju dọ́sìnnì kan lọ ni a ṣì ń lò láti ṣèrànwọ́ láti kúnjú ìbéèrè rẹpẹtẹ fún iná mànàmáná. Àwọn olùlo ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù agbára átọ́míìkì kan ni a tilẹ̀ ti dálẹ́bi fún yíyí ètò-ìgbékalẹ̀ ẹ̀rọ tí kìí jẹ́ kí ẹ̀rọ mìíràn ṣiṣẹ́ pa kí wọ́n baà lè mú ìgbéjáde agbára iná mànàmáná pọ̀ síi. Àwọn ìròyìn bí irú èyí dáyàfo àwọn orílẹ̀-èdè bíi France, tí ń lo àwọn ẹ̀rọ alágbára átọ́míìkì láti pèsè ìpín 70 nínú ọgọ́rùn ún iná mànàmáná rẹ̀. Bí irú “Chernobyl” mìíràn bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ ìpèsè ní France ni a lè fipá mú láti kógbáwọlé pátápátá.
Kódà ó ṣe kedere pé àwọn ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù agbára átọ́míìkì tí “kò léwu” ń di eléwu bí wọ́n tí ń gbó síi. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1993, lákòókò àyẹ̀wò fún ìdáàbòbò kan tí a ń ṣe déédéé, ó lé ní ibi ọgọ́rùn-ún tí a rí tí ọ̀pá irin gbọọrọ tí ó wà nínú ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù agbára átọ́míìkì tí ó wà ní Brunsbüttel ti sán, ọ̀kan lára èyí tí ó lọ́jọ́lórí jùlọ ní Germany. Irú àwọn sísán bí èyí ni a ti rí nínú àwọn ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù agbára átọ́míìkì ní France àti Switzerland. Ìjàm̀bá líléwu àkọ́kọ́ níbi ẹ̀rọ mànàmáná ilẹ̀ Japan kan wáyé ní 1991, ó ṣeéṣe kí gbígbó tí ó ti gbó jẹ́ kókó abájọ kan. Èyí fihàn pé ó ṣeéṣe kí ìjàm̀bá kan náà ṣẹlẹ̀ ní United States, níbi tí nǹkan bí ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù agbára átọ́míìkì tí a ń gbowó lé lórí ti lé ní ọdún mẹ́wàá.
Àwọn ìjàm̀bá ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù agbára átọ́míìkì lè ṣẹlẹ̀ níbikíbi nígbàkigbà. Bí àwọn ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù agbára átọ́míìkì bá ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ewu náà yóò ti pọ̀ tó; bí ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù agbára átọ́míìkì náà bá ti wà pẹ́ tó, bẹ́ẹ̀ ni ewu náà yóò túbọ̀ pọ̀ síi tó. Ìwé ìròyìn kan kò ṣàdéédéé pè wọ́n ní àwọn ìfìdùgbẹ̀ ewu tí ó ga àti ìtànṣán olóró gíga afẹ̀mí wewu.
Níbo Ni Wọ́n Níláti Da Pàǹtírí Náà Sí?
Ó ya àwọn ènìyàn lẹ́nu ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí láti rí i tí àwọn ọlọ́pàá fi odi sé ibi ìgbafàájì kan tí ó wà lẹ́bàá odò ní French Alps mọ́ tí wọ́n sì ń ṣọ́ ọ. Ìwé ìròyìn náà The European ṣàlàyé pé: “Àyẹ̀wò tí a ń ṣe déédéé èyí tí a pàṣẹ rẹ̀ lẹ́yìn ikú obìnrin àdúgbò kan tí májèlé èròjà beryllium ṣekúpa ní oṣù méjì sẹ́yìn ṣí i payá pé ìwọ̀n ìtànṣán olóró gíga tí ó fi 100 ìgbà pọ̀ ju ti àwọn wọnnì tí ń bẹ ní agbègbè àyíká náà lọ ń bẹ ní ibi ìgbafàájì náà.”
Èròjà beryllium, mẹ́táàlì kan tí ó fúyẹ́ gẹgẹ tí a ń mú jáde ní onírúurú ọ̀nà, ni a ń lò nínú àwọn ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú, nígbà tí a bá sì ti mú un gba abẹ́ ìtànṣán olóró gíga kọjá tán, a ń lò ó ní àwọn ibùdó ìpèsè agbára iná mànàmáná alágbára átọ́míìkì. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ti fihàn, ilé-iṣẹ́ kan tí ń pèsè èròjà beryllium ti da àwọn pàǹtírí tí ó jáde wá láti inú ìmúkọjá lábẹ́ ìtànṣán olóró gíga náà sórí tàbí sẹ́bàá agbègbè ìgbafàájì náà. Ìwé ìròyìn The European ṣàlàyé pé: “Eruku èròjà beryllium, àní nígbà tí kò bá ti inú ìtànṣán olóró gíga wá pàápàá, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn pàǹtírí ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ tí ó lóró jùlọ tí a tíì mọ̀ rí.”
Ní báyìí, láti 30 ọdún sẹ́yìn wá nǹkan bíi 17,000 àwọn àpótí pàǹtírí ìtànṣán olóró gíga ni a ròyìn rẹ̀ pé a ti kó dà sínú odò bèbè-etíkun Novaya Zemlya, tí àwọn Soviet lò gẹ́gẹ́ bí ibi ìṣàyẹ̀wò agbára átọ́míìkì ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950. Ní àfikún, àwọn apá ibi tí èròjà ìtànṣán olóró gíga ń wà lára àwọn ọkọ̀ jagunjagun abẹ́ omi alágbára átọ́míìkì àti ẹ̀yà 12 ó kérétán lára àwọn ẹ̀rọ tí ń díwọ̀n ìbúgbàù agbára átọ́míìkì ni a kó dà sínú ibi ìdalẹ̀sí rírọrùn yìí.
Yálà ó jẹ́ àmọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe tàbí nípa èèṣì, ìṣọdèérí agbára átọ́míìkì léwu. Nípa ti ọkọ̀ jagunjagun abẹ́ omi kan tí ó rì sí ibìkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìn sí bèbè etíkun Norway ní 1989, ìwé ìròyìn Time kìlọ̀ pé: “Èròjà cesium-137, tí ó jẹ́ èròjà kẹ́míkà kan tí ń fa àrùn jẹjẹrẹ, ti ń jò sílẹ̀ láti inú àwókù náà. Títí di báyìí ìjòdànù náà ni a kà sí èyí tí ó ti kéré jù láti nípa lórí àwọn ohun alààyè inú omi tàbí ìlera ènìyàn. Ṣùgbọ́n ọkọ̀ Komsomolets náà tún gbé àwọn ẹ̀rọ afọ́kọ̀ ojú-omi méjì alágbára átọ́míìkì tí wọ́n ní nínú ìwọn 13 kg [29 pound] èròjà plutonium tí yóò gba 24,000 ọdún kí ó tó jẹra tí ó sì lóró tí ó ga gan-an débi pé ìwọ̀n bín-ín-tín kan lára rẹ̀ lè pani. Àwọn ogbógi ará Russia kìlọ̀ pé èròjà plutonium náà lè fúnká sínú omi kí ó sì yára kó èérí bá omi òkun púpọ̀ salalu ní ọdún 1994.”
Àmọ́ ṣáá o, kíkó pàǹtírí àwọn ìtànṣán olóró dànù kìí ṣe ìṣòro kan tí ó mọ sí ilẹ̀ France àti Russia nìkan. Ìwé ìròyìn Time ròyìn pé: United States ní “òketè pàǹtírí àwọn èròjà ìtànṣán olóró gíga kò sì sí ibi wíwàtítí kan láti tọ́jú rẹ̀ sí.” Ó sọ pé àgbá million kan àwọn èròjà aṣekúpani wà nílẹ̀ ní àwọn ibi ìkẹ́rùsí fún ìgbà kúkúrú pẹ̀lú “ewu ìpàdánù, ìjíkólọ àti ìbàjẹ́ àyíká nítorí àìbójútó wọn lọ́nà yíyẹ” tí ó wà lọ́jọ́ gbogbo.
Àfi bí ẹni pé láti ṣàkàwé ewu yìí, àgbá pàǹtírí alágbára átọ́míìkì kan ní ilé-iṣẹ́ ìpèsè ohun-ìjà tẹ́lẹ̀rí kan ní Tomsk, Siberia, búgbàù ní April 1993, ní ríru ìdíjì ọpọlọ sókè nípa irú ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn kan tí ó farajọ ti Chernobyl.
Lọ́nà tí ó ṣe kedere, igbe àlàáfíà àti àìléwu èyíkéyìí tí a bá ké látàrí ìmúdópin ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ewu agbára átọ́míìkì kò fìdímúlẹ̀. Síbẹ̀ náà àlàáfíà àti àìléwu ṣì súnmọ́tòsí. Báwo ni a ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
ÀWỌN ALÁGBÁRA ÁTỌ́MÍÌKÌ
12 A Sì Tún Ń Kà Síi
TÍ A TI POLONGO tàbí TÍ WỌ́N TI Ń LO AGBÁRA: Belarus, Britain, China, France, India, Israel, Kazakhstan, Pakistan, Russia, South Africa, Ukraine, United States
TÍ WỌ́N LÈ DI ALÁGBÁRA: Algeria, Argentina, Brazil, Iran, Iraq, Libya, North Korea, South Korea, Syria, Taiwan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Lílo agbára átọ́míìkì lọ́nà tí kò níyọnu pàápàá lè léwu
[Credit Line]
Àwòrán àfitẹ́lẹ̀: Fọ́tò U.S. National Archives
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Èpo iwájú ìwé: Stockman/International Stock
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Fọ́tò U.S. National Archives