Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ogun Tí Wọ́n Á Fi Bọ́ǹbù Átọ́míìkì Jà?
Ẹ̀rù ń ba ọ̀pọ̀ èèyàn pé kò sígbà tí ogun tí wọ́n á ti máa ju bọ́ǹbù átọ́míìkì ńlá ò ní wáyé. Ìdí sì ni pé ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ alágbára ló ti tọ́jú ọ̀pọ̀ bọ́ǹbù yìí, ojoojúmọ́ sì ni wọ́n ń ṣe àwọn míì tó túbọ̀ lágbára dípò kí wọ́n máa dín in kù. Ẹ̀rù ń ba àwọn míì pé tí orílẹ̀-èdè kan bá ju bọ́ǹbù átọ́míìkì kékeré kan, ìyẹn lè mú káwọn orílẹ̀-èdè míì náà bẹ̀rẹ̀ sí í ju bọ́ǹbù átọ́míìkì síra wọn títí wọ́n á fi run ayé yìí. Ìwé Bulletin of the Atomic Scientists sọ pé, “tá a bá ń bá a lọ báyìí, kò sígbà tí ogun tí wọ́n á ti máa ju bọ́ǹbù átọ́míìkì ńlá ò ní wáyé.”
Ṣé irú ogun yìí lè wáyé ṣá? Tó bá wáyé, ṣé ayé yìí ò ní pa run? Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa kọ́kàn sókè nípa ogun yìí? Kí ni Bíbélì sọ?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Ṣé Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ogun tí wọ́n á ti máa ju bọ́ǹbù átọ́míìkì máa jà?
Ṣé Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn bọ́ǹbù átọ́míìkì ni wọ́n á fi ja ogun Amágẹ́dọ́nì?
Ṣé ogun tí wọ́n ti ń ju bọ́ǹbù átọ́míìkì ni ìwé Ìfihàn ń sọ?
Ṣé Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ogun tí wọ́n á ti máa ju bọ́ǹbù átọ́míìkì máa jà?
Kò síbì kan ní pàtó tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa ogun tí wọ́n á ti máa ju bọ́ǹbù átọ́míìkì. Àmọ́ Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn nǹkan táá máa ṣẹlẹ̀ àti ìwà táwọn èèyàn á máa hù, ogun sì wà lára ohun tó sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa wáyé.
Ẹ jẹ́ ká fi ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ wéra pẹ̀lú àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé báyìí:
Ẹsẹ Bíbélì: Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bi í pé: “Kí ló sì máa jẹ́ àmì pé o ti wà níhìn-ín àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” Jésù sọ fún wọn pé: “Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.”—Mátíù 24:3, 7.
Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé: Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí kan àwọn tó ti kó bọ́ǹbù átọ́míìkì jọ ló sábà máa ń sọ àwọn nǹkan kékeré di ogun.
“Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ìwà ipá túbọ̀ ń pọ̀ sí i láyé. Ogun lónìí, ìjà lọ́la ò jẹ́ káráyé sinmi.”—The Armed Conflict Location & Event Data Project.
Ẹsẹ Bíbélì: ‘Ní àkókò òpin, ọba gúúsù máa kọ lu [ọba àríwá].’—Dáníẹ́lì 11:40.
Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé: Bí Bíbélì ṣe sọ, ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn alátìlẹyìn wọn ló ń bá ara wọn fà á kí wọ́n lè mọ ẹni tó lágbára jù láàárín wọn. Àwọn orílẹ̀-èdè tó ní bọ́ǹbù átọ́míìkì lọ́wọ́ máa ń gbìyànjú láti yẹra fún ogun, síbẹ̀ wọ́n túbọ̀ ń kó àwọn bọ́ǹbù alágbára yìí jọ.
“Láti nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ọ̀pọ̀ ogun ló ti wáyé láàárín àwọn ẹgbẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè alágbára sì ṣètìlẹyìn fáwọn ẹgbẹ́ yìí.”—The Uppsala Conflict Data Program.
Ẹsẹ Bíbélì: ‘Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira. Torí àwọn èèyàn máa jẹ́ kìígbọ́-kìígbà, abanijẹ́, ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu, ẹni tó burú gan-an.’—2 Tímótì 3:1-3.
Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé: Bó ṣe jẹ́ pé àìgbọ́ra-ẹni-yé sábà máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn, bẹ́ẹ̀ náà ló máa ń wáyé láàárín àwọn alákòóso ayé. Tí àìgbọ́ra-ẹni-yé bá ṣẹlẹ̀ láàárín wọn, dípò kí wọ́n fi sùúrù yanjú ẹ̀, ṣe ni wọ́n máa ń lérí síra wọn. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ sì lè fa ogun tí wọ́n á ti máa ju bọ́ǹbù átọ́míìkì síra wọn.
“Táwọn èèyàn ò bá kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa yanjú ọ̀rọ̀ nítùbí-ìnùbí, kò sí bí ogun ò ṣe ní máa le sí i.”—S. Saran and J. Harman, World Economic Forum.
Ṣé Ọlọ́run máa gbà kí irú ogun yìí jà?
Bíbélì ò sọ. Àmọ́ ó sọ pé “àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù” á máa ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí. (Lúùkù 21:11) Àpẹẹrẹ kan lèyí tó wáyé nígbà Ogun Àgbàyé Kejì nígbà tí wọ́n ju bọ́ǹbù átọ́míìkì. Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gbà á kí ogun máa jà. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo fídíò náà Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà?
Ṣé ayé yìí máa pa run?
Rárá o. Tí àwọn èèyàn bá tiẹ̀ tún ju bọ́ǹbù átọ́míìkì, Ọlọ́run ò ní jẹ́ kó burú débi tí ayé yìí fi máa pa run. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe pé ayé yìí ò ní pa run nìkan, ṣùgbọ́n àwọn èèyàn á tún máa gbé inú ẹ̀ títí láé.
Àwọn kan rò pé tó bá dọjọ́ iwájú, àwọn èèyàn díẹ̀ ló máa kù láyé, wọ́n á sì máa wá oúnjẹ kiri torí pé bọ́ǹbù átọ́míìkì ti máa ba ayé jẹ́. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa ṣàtúnṣe àjálù yòówù kí ogun ti fà.
Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbé nínú ayé tó rẹwà ká sì máa láyọ̀
Ọlọ́run ti dá ayé yìí lọ́nà tó jẹ́ pé ó máa ń tún ohun táwọn èèyàn bá bà jẹ́ ṣe fúnra ẹ̀. Bákan náà, Ọlọ́run máa lo agbára ẹ̀ láti tún ayé yìí ṣe, á sì jẹ́ ibùgbé tó rẹwà fáwa èèyàn títí láé.—Sáàmù 37:11, 29; Ìfihàn 21:5.
Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa kọ́kàn sókè nípa ogun yìí?
Ẹ̀rù máa ń ba àwọn kan torí ogun yìí àti ohun tó ṣeé ṣe kó tẹ̀yìn ẹ̀ yọ. Àmọ́ àwọn ìlérí àti ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì lè ran àwọn èèyàn yìí lọ́wọ́ kí ọkàn wọn lè balẹ̀. Lọ́nà wo?
Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan dáadáa tí Ọlọ́run máa ṣe fún ayé yìí àtàwọn tó máa gbé inú ẹ̀. Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ yìí, ṣe ló máa dà bí “ìdákọ̀ró fún ẹ̀mí wa,” á sì jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀. (Hébérù 6:19, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Yàtọ̀ síyẹn, ọkàn wa máa balẹ̀ tá ò bá da àníyàn tòní mọ́ tọ̀la, tá ò sì máa da ara wa láàmú nípa àwọn nǹkan tí ò tíì ṣẹlẹ̀. Jésù sọ pé, “wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.”—Mátíù 6:34.
Ká sòótọ́, ó yẹ ká máa tọ́jú ara wa, ká lè máa ronú lọ́nà tó tọ́, kí ọkàn wa sì lè balẹ̀. A sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá ò bá máa tẹ́tí sí ìròyìn àti ìjíròrò nípa ogun àtàwọn bọ́ǹbù átọ́míìkì ní gbogbo ìgbà. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé àá máa díbọ́n bíi pé kò síṣòro? Rárá o, à ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé a fẹ́ gbọ́kàn kúrò lórí àwọn nǹkan tá ò lè yanjú àtàwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó má ṣẹlẹ̀.
Gbọ́kàn ẹ kúrò lórí àwọn ìròyìn burúkú kó o sì pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan dáadáa tó ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé ẹ.
A lè fọkàn tán ohun tí Bíbélì sọ, pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa
Tó o bá túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlérí Ọlọ́run, á jẹ́ kó o ní ìrètí, ayọ̀, ọkàn ẹ á sì túbọ̀ balẹ̀.
Ṣé Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn bọ́ǹbù átọ́míìkì ni wọ́n á fi ja ogun Amágẹ́dọ́nì?
Àwọn kan rò pé ogun Amágẹ́dọ́nì jẹ́ ogun kan tó máa kárí ayé, tó sì jẹ́ pé bọ́ǹbù átọ́míìkì ni wọ́n á fi jagun náà. Wọ́n ń ronú pé tí ogun yẹn bá jà, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló máa bá a lọ, ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì máa bà jẹ́.
Ọ̀rọ̀ náà “Amágẹ́dọ́nì” bá a ṣe lò ó nínú Bíbélì jẹ́ ogun kan tó máa wáyé láàárín “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé,” ìyẹn àwọn ìjọba èèyàn àti Ọlọ́run.a (Ìfihàn 16:14, 16) Amágẹ́dónì kì í ṣe ogun tí wọ́n ti máa ju bọ́ǹbù átọ́míìkì tó máa pààyàn rẹpẹtẹ, tó sì máa ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn burúkú nìkan ni Ọlọ́run máa pa run ní Amágẹ́dọ́nì, èyí sì máa mú kí àlàáfíà àti ààbò wà láyé.—Sáàmù 37:9, 10; Àìsáyà 32:17, 18; Mátíù 6:10.
Kí ni Bíbélì sọ pé ó máa fòpin sí ogun?
Jèhófàb máa lo agbára ẹ̀ láti fòpin sí ogun tó ń jà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, á sì pa àwọn ohun ìjà wọn run. Ó máa ṣe èyí nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀, Ìjọba yìí á máa ṣàkóso láti ọ̀run, á sì máa jọba lórí ayé.—Dáníẹ́lì 2:44.
Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, àwọn èèyàn á kọ́ bí wọ́n á ṣe máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà, wọ́n á sì máa ṣe nǹkan pa pọ̀. Torí pé ìjọba kan lá máa ṣàkóso gbogbo ayé, kò ní sí èdèkòyédè láàárín àwọn orílẹ̀-èdè mọ́. Kódà àwọn èèyàn ò ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́! (Míkà 4:1-3) Báwo layé ṣe máa rí nígbà yẹn? “Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnìkan kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n.”—Míkà 4:4, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.
a Ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì?”
b Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”