Ǹjẹ́ Ogun Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Ṣì Ń Bọ̀ Wá Jà?
Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní Japan
“Gbogbo ẹni tó bá mọnú rò ló máa ń bẹ̀rù ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé, gbogbo orílẹ̀-èdè tó sì ti gòkè àgbà nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ló máa ń gbára dì fún un. Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé ohun burúkú gbáà logun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé jẹ́, síbẹ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè ló máa ń ṣàwáwí nípa rẹ̀.”—Carl Sagan, tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà.
NÍ ỌJỌ́ kẹfà oṣù kẹjọ ọdún 1945, ọkọ̀ òfuurufú tí ilẹ̀ Amẹ́ríkà fi ń jagun ju àdó olóró kan sí ìlú Hiroshima ní ilẹ̀ Japan, ojú ẹsẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà gba ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àwọn èèyàn, àìmọye dúkìá ló sì ṣòfò. Èyí ni ogun àkọ́kọ́ tí wọ́n ti lo àdó olóró. Ibi tí àdó olóró náà ti ṣọṣẹ́ fẹ̀ tó kìlómítà mẹ́tàlá níbùú àti lóòró, àwọn tó sì ń gbé níbẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlógún àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta. Bí a bá dá ìlú yẹn sí ọ̀nà mẹ́tà, ó ju ọ̀nà méjì lọ tó wó palẹ̀, ó kéré tán, àwọn èèyàn tó pọ̀ tó ẹgbàá márùndínlógójì ló kú, tí àwọn èèyàn tó jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárùn-ún sì fara pa yánnayànna. Ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ju àdó olóró kejì, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ìlú Nagasaki ni wọ́n jù ú sí; ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógójì èèyàn ló bá a rìn, tí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sì fara pa. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì ìlú náà tó pa run tàbí tó bà jẹ́. Wọn ò tíì lo irú ohun ìjà olóró tó lágbára tó bẹ́ẹ̀ rí nínú ìtàn ìran ènìyàn. Ìgbà ti yí pa dà. Ayé ti dayé tí wọ́n ti ń fi bọ́ǹbù jagun. Láàárín ọdún díẹ̀, ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Soviet Union àtijọ́, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ilẹ̀ Faransé àti ilẹ̀ Ṣáínà ti fi afẹ́fẹ́ olóró ṣe àwọn ohun ìjà tó ń ṣekú pani ju àwọn ohun ìjà táráyé ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ lọ.
Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀, ìyẹn ìbánidíje láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó fara mọ́ ètò ìjọba Àjùmọ̀ní àtàwọn tí kò fara mọ́ ọn ló tanná ran èrò ṣíṣe àwọn ohun ìjà olóró tó túbọ̀ lágbára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ àti bí wọ́n ṣe ń yìn wọ́n. Gbogbo ayé lẹ̀rù ń bà látàrí ṣíṣe tí wọ́n ṣe àwọn bọ́ǹbù ICBM, ìyẹn àwọn bọ́ǹbù atamátàsé tó lè la ọ̀pọ̀ ààlà ilẹ̀ orílẹ̀-èdè kọjá. Irú bọ́ǹbù yìí lè lọ ṣe ọṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá dìídì rán an sí, èyí tó lè jìnnà tó ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n kìlómítà, ìyẹn á sì ṣẹlẹ̀ láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀. Àwọn ọkọ̀ abẹ́ omi tí wọ́n fi ń jagun ní àwọn ohun ìjà tó pọ̀ gan-an tí wọ́n lè fi ránṣẹ́ kó sì bú gbàù láwọn ibi tí wọ́n bá rán an sí, àní wọ́n tiẹ̀ lè fi ránṣẹ́ sí ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó tó igba ó dín mẹ́jọ. Nígbà kan, wọ́n fojú bù ú pé àwọn ohun ìjà runlérùnnà táwọn èèyàn tò jọ pelemọ yóò tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta! Nígbà Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn rò pé ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tí yóò jẹ́ òpin ayé, ìyẹn ogun tí kò sí ẹni tí yóò ṣẹ́gun, kò ní pẹ́ jà.
Lẹ́yìn Tí Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ Dópin
Ní àwọn ọdún 1970, pákáǹleke Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ dà bíi pé ó lọ sílẹ̀ díẹ̀, ìwé The Encyclopædia Britannica ṣàlàyé nípa èyí, “gẹ́gẹ́ bó ṣe hàn nínú àdéhùn àkọ́kọ́ àti ìkejì tí wọ́n ṣe níbi Ìpàdé Àpérò Lórí Dídín Àwọn Ohun Ìjà Olóró Kù, níbi táwọn ìjọba alágbára ayé ti fi gbèdéke sórí lílo àwọn ohun ìjà tí wọ́n fi ń dènà àwọn bọ́ǹbù atamátàsé àti sórí lílo àwọn ohun ìjà runlérùnnà tí wọ́n máa ń dìídì rán lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń gbéjà koni láti sọ wọ́n di ẹdun arinlẹ̀.” Nígbà tó di apá ìparí àwọn ọdún 1980, Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ nípa tó rinlẹ̀ mọ́, kó tiẹ̀ tó wá di pé wọ́n paná rẹ̀ pátápátá.
Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Àjọ Tó Ń Rí sí Àlàáfíà Láàárín Àwọn Orílẹ̀-Èdè, tí Carnegie gbé kalẹ̀ sọ pé: “Pípa tí wọ́n paná Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ ló jẹ́ káwọn èèyàn nírètí pé ìbánidíje ọlọ́jọ́ pípẹ́ tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè nípa ẹni tó borí nínú títo ohun ìjà olóró jọ pelemọ àti ìjà tó wà láàárín Amẹ́ríkà òun Rọ́ṣíà máa tó dópin.” Látàrí akitiyan láti kó àwọn ohun ìjà olóró dà nù, láìpẹ́ yìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún bọ́ǹbù tí wọ́n ti tò jọ pelemọ tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ti tú palẹ̀. Lọ́dún 1991 Soviet Union àti ilẹ̀ Amẹ́ríkà fọwọ́ sí ìwé Àdéhùn Lórí Dídín Àwọn Ohun Ìjà Olóró Kù, èyí tó sọ ọ́ di dandan fáwọn ìjọba méjèèjì tó ń múpò iwájú nínú ṣíṣe ohun ìjà olóró yìí láti dín àwọn ohun ìjà olóró náà kù. Kì í wá ṣe ìyẹn nìkan, àní fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn, èyí tún mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n dín ohun ìjà olóró tí wọ́n ti kẹ́ sílẹ̀ kù sí ẹgbàata. Ní òpin ọdún 2001, àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí kéde pé àwọn ti mú àdéhùn àwọn ṣẹ nípa dídín ohun ìjà táwọn ti kẹ́ sílẹ̀ náà kù sí iye táwọn ti fẹnu kò lé lórí. Síwájú sí i, ní ọdún 2002, Àdéhùn tí wọ́n fẹnu kò lé lórí ní ìlú Moscow sọ ọ́ di dandan fún wọn láti túbọ̀ dín àwọn ohun ìjà wọ̀nyí kù, àdéhùn yẹn sọ pé kó má ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán sí igba mọ́kànlá lọ ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá tó ń bọ̀.
Àmọ́ ṣá o, láìfi ti àwọn àdéhùn yìí pè, Kofi Annan tó jẹ́ Ọ̀gá Àgbà fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Kì í ṣe àkókò nìyí láti dẹra nù tó bá dọ̀rọ̀ ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tí ń bà wá lẹ́rù.” Ó tún fi kún un pé: “Fífi bọ́ǹbù jagun ṣì ń ṣẹlẹ̀, àti pé ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ń múni wárìrì pàápàá ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkànlélógún.” Ohun tó bani nínú jẹ́ ni pé, ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé àní èyí tó burú ju ti ìlú Hiroshima òun Nagasaki lọ ṣì ń bani lẹ́rù títí dòní olónìí. Àwọn wo gan-an ló ń gbára dì fógun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé? Èyí tó tiẹ̀ ṣe pàtàkì jù ni pé, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé má jà?