Ṣé Àwọn Àjọ Táwọn Èèyàn Gbé Kalẹ̀ Lè Mú Kí Àlàáfíà Wà Láyé?
Kò sígbà tí ogun àti wàhálà kì í ṣẹlẹ̀ láyé tá a wà yìí. Ìyẹn ti jẹ́ kí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé àtàwọn àjọ míì ṣe ohun táá jẹ́ kí àlàáfíàa wà ní pàtàkì láwọn ibi tí wàhálà ti ń ṣẹlẹ̀ lọ́tùn-ún lósì. Ohun tí wọ́n ń fẹ́ ni pé kí rògbòdìyàn rọlẹ̀ láwọn ibi tí wàhálà ti ń ṣẹlẹ̀ yìí. António Guterres tó jẹ́ Akọ̀wé Àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sọ pé ‘àwọn tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé kí àlàáfíà lè wà ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí àlàáfíà lè wà láyé.’
Látàwọn ọdún yìí wá, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kí àlàáfíà lè wà ti ṣe àwọn àṣeyọrí kan. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n dáàbò bo àwọn ará ìlú, wọ́n dá àwọn tí ogun lé kúrò nílé pa dà sílùú wọn, wọ́n pèsè ohun táwọn èèyàn nílò, wọ́n sì tún àwọn ilé tó bà jẹ́ ṣe. Àmọ́ àwọn ohun kan wà tí ò jẹ́ kí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kí àlàáfíà lè wà yìí lè ṣe gbogbo ohun táwọn èèyàn retí pé kí wọ́n ṣe. Ṣé ohun kan wà tá a lè ṣe táá jẹ́ kí àlàáfíà wà láyé? Kí ni Bíbélì sọ?
Àwọn ohun tí kò jẹ́ kí àlàáfíà wà àti ohun tí Bíbélì sọ
Ohun tó jẹ́ ìṣòro: kò sí ìṣọ̀kan. Kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún àwọn ọmọ ogun àtàwọn míì tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti máa ṣe nǹkan pa pọ̀. Nígbà míì, wọn kì í lè ṣiṣẹ́ pa pọ̀ torí wọn kì í gbọ́ ara wọn yé àti pé ohun tó jẹ kálukú wọn lógún yàtọ̀ síra.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀ . . . ó máa fòpin sí gbogbo wọn [ìjọba èèyàn], òun nìkan ló sì máa dúró títí láé.”—Dáníẹ́lì 2:44.
Láìpẹ́, Ọlọ́run máa fòpin sí ogun, àlàáfíà sì máa wà kárí ayé. (Sáàmù 46:8, 9) Ó máa fi ìjọba ẹ̀ rọ́pò gbogbo ìjọba tó wà láyé báyìí. Torí pé ìjọba kan ṣoṣo tó dáa jù lá máa ṣàkóso gbogbo ayé látọ̀run, a ò ní nílò àwọn táá máa ṣiṣẹ́ kí àlàáfíà lè wà mọ́.
Ohun tó jẹ́ ìṣòro: wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní àwọn ohun tí wọ́n nílò, ó sì níbi tí agbára wọn mọ. Torí pé àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kí àlàáfíà lè wà kì í fi bẹ́ẹ̀ rówó tí wọ́n nílò, tí wọn ò sì láwọn èèyàn tó pọ̀ tó láti bá wọn ṣiṣẹ́ àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n nílò, kò rọrùn fún wọn láti ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ ṣe. Nígbà míì ó lè gba pé kí wọ́n lọ sí agbègbè tí nǹkan ti le gan-an tàbí tó léwu.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ọlọ́run Olúwa wa Jésù Kristi . . . mú [Jésù] jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ní àwọn ibi ọ̀run, tí ó ga ju gbogbo ìjọba àti àṣẹ àti agbára.”—Éfésù 1:17, 20, 21.
Jèhófàb Ọlọ́run tó lágbára jù lọ ti yan Jésù láti jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Ó sì ti fún un láwọn ohun tó nílò kó lè ṣàkóso lọ́nà tó tọ́. (Dáníẹ́lì 7:13, 14c) Ọlọ́run ti fún Jésù ní agbára tó pọ̀, ìmọ̀, ọgbọ́n, àti òye tó ju ti àwọn èèyàn èyíkéyìí tó ń ṣàkóso báyìí lọ. (Àìsáyà 11:2) Jésù tún láwọn áńgẹ́lì alágbára tó pọ̀ gan-an tó máa bá a ṣiṣẹ́. (Ìfihàn 19:14) Kò sí ìṣòro tó le jù fún un láti yanjú.
Kì í ṣe pé Jésù máa lo àwọn ohun tí Ọlọ́run fún un láti fòpin sí ogun nìkan, ó máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó máa jẹ́ kí ààbò, ìfọ̀kànbalẹ̀ àti àlàáfíà wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.—Àìsáyà 32:17, 18.
Ohun tó jẹ́ ìṣòro: òfin ò gbà wọ́n láyè láti ṣe àwọn ohun kan. Nígbà míì, àwọn tó ń jà fún àlàáfíà lè má lè ṣe iṣẹ́ wọn bó ṣe yẹ torí àwọn òfin tó lọ́jú pọ̀, tí kò sì yéni tàbí kó jẹ́ pé òfin ò gbà wọ́n láyè láti ṣe àwọn nǹkan kan. Èyí ò sì ní jẹ́ kí wọ́n lè dáàbò bo àwọn èèyàn bó ṣe yẹ, wọn ò sì ní lè ṣe ohun tí wọ́n torí ẹ̀ dá àjọ náà sílẹ̀.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé la ti fún [Jésù].”—Mátíù 28:18.
Ọlọ́run ti sọ fún Jésù pé kó mú kí àlàáfíà wà láyé, ó sì ti fún un lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 5:22) Jésù máa dá ẹjọ́ àwọn èèyàn bó ṣe tọ́, kò sì ní gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. (Àìsáyà 11:3-5) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu bí Bíbélì ṣe pe Jésù ní “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” tó sì sọ pé Ìjọba rẹ̀ máa fìdí múlẹ̀ lórí “ìdájọ́ tí ó tọ́ àti òdodo.”—Àìsáyà 9:6, 7.
Ìjọba Ọlọ́run máa mú àlàáfíà tòótọ́ wá
Àjọ tó ń ṣiṣẹ́ kí àlàáfíà lè wà lè paná ogun ní agbègbè kan kí àlàáfíà díẹ̀ sì wà níbẹ̀. Àmọ́ wọn ò lè mú ohun tó ń fa ogun kúrò, ìyẹn ẹ̀mí ìkórìíra tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn.
“Òótọ́ kan ni pé àjọ yòówù ká gbé kalẹ̀, kò lè sí àlàáfíà táwọn èèyàn bá ṣì kórìíra ara wọn.”—Dennis Jett, aṣojú orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀.
Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú àlàáfíà tòótọ́ wá, torí òun ló máa mú ìkórìíra kúrò lọ́kàn àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, tí wọ́n á sì máa fìfẹ́ hàn:
Jésù tún sọ pé ìfẹ́ la fi máa dá àwọn tó máa wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run mọ̀ torí pé wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó bá kórìíra ọmọnìkejì wọn ò ní wọ Ìjọba Ọlọ́run:
Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa mọ ọ̀nà tó dáa jù láti jẹ́ kí àlàáfíà wà láyé. Ohun táwọn èèyàn ṣe tì, Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe é láṣeyọrí, ó máa mú kí àlàáfíà wà ní gbogbo ayé.
a Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé àti àwọn àjọ míì máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “jẹ́ kí àlàáfíà wà,” “wíwá àlàáfíà,” “ti àlàáfíà lẹ́yìn,” àti “ṣíṣe àwọn ohun táá mú kí àlàáfíà wà.”
b Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”
c Ní Dáníẹ́lì 7:13, 14, ọ̀rọ̀ náà “ọmọ èèyàn” ń tọ́ka sí Jésù Kristi.—Mátíù 25:31; 26:63, 64.