Ayé Kan Láìsí Ogun Ha Ṣeé Ṣe Bí?
FINÚWÒYE kí ènìyàn máà fojú rí tàbí ní ìrírí ìṣẹ̀lẹ̀ amúnifòyà tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà ogun àti lẹ́yìn rẹ̀ mọ́. Finúwòye ṣíṣàìgbọ́ ìró ìbọn tàbí ti bọ́m̀bù mọ́, kí o máà rí àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí ebi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa, tí wọ́n ń fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ mọ́, kí ènìyàn máà máa ronú bóyá òun tàbí olólùfẹ́ kan yóò kú nígbà ìforígbárí oníkà tí kò nídìí mọ́. Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun àgbàyanu tó láti gbé nínú ayé kan láìsí ogun!
Ìwọ́ lè sọ pé, ‘Ìfojúsọ́nà tí kò dájú nìyẹn.’ Síbẹ̀, àwọn ènìyàn fi ìháragàgà ronú nípa ayé alálàáfíà kan lọ́jọ́ iwájú ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn. Ní 1990 àti 1991, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń sọ pé àwọn orílẹ̀-èdè ti wà ní bèbè sànmánì tuntun ti àìléwu àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀. Nígbà tí George Bush, tí ó jẹ́ ààrẹ United States nígbà náà, ń fi bí ipò nǹkan ṣe ń rí hàn, ó sọ lọ́pọ̀ ìgbà nípa “ètò ayé tuntun” kan tí ń yọrí bọ̀.
Kí ló fa ìfojúsọ́nà fún rere náà? Ogun Tútù ti dópin. Fún ohun tí ó lé ní 40 ọdún, ewu ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ti ń fì dùgbẹ̀dùgbẹ̀ bí ẹni máa já sórí ìran aráyé bí idà tí a fi okùn tín-ínrín kan so rọ̀. Àmọ́, pẹ̀lú ìmúkúrò Kọ́múníìsì àti ìpínyà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ Soviet Union, ó jọ pé ewu ìpakúpa rẹpẹtẹ ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kan ti pòórá. Aráyé rímú mí.
Ìdí pàtàkì míràn tún wà tí àwọn ènìyàn fi ń wo ọjọ́ iwájú pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nígbà náà, tí àwọn púpọ̀ sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí síbẹ̀. Fún ẹ̀wádún mẹ́rin, ìbáradíje láàárín Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn ti sọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè di ẹgbẹ́ tí ó wà fún kìkì ṣíṣe àríyànjiyàn. Àmọ́, òpin Ogun Tútù náà sọ àjọ UN dòmìnira láti ṣe ohun tí wọ́n pète rẹ̀ fún—láti ṣiṣẹ́ fún àlàáfíà àti àìléwu àgbáyé.
Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àjọ UN ti fi kún ìsapá rẹ̀ láti má ṣe fún ogun ní ìṣírí. Níwọ̀n bí a ti mú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbaradì pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun láti àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà, ó ń kó wọnú ètò fífìdí àlàáfíà múlẹ̀ sí i ní ọdún 4 tí ó ṣáájú 1994 ju bí ó ti rí ní àwọn ọdún 44 tí ó ṣáájú. Nǹkan bí 70,000 aráàlú àti àwọn òṣìṣẹ́ ológun ṣiṣẹ́ níbi ètò ológun 17 tí ó wà jákèjádò àgbáyé. Ní ọdún méjì péré, ìnáwó lórí fífìdí àlàáfíà múlẹ̀ fi ohun tí ó ju ìlọ́po méjì pọ̀ ju 3.3 bílíọ̀nù dọ́là tí wọ́n ná ní 1994 lọ.
Boutros Boutros-Ghali, akọ̀wé àgbà àjọ UN, kọ̀wé láìpẹ́ yìí pé: “Àwọn àmì wà pé ìlànà ìgbékalẹ̀ ààbò àkọ́wọ́jọṣe tí a gbé kalẹ̀ ní San Francisco ní nǹkan bí 50 ọdún sẹ́yìn [nígbà tí wọ́n dá àjọ UN sílẹ̀] ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí a ti pète rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín . . . A ti wà lójú ọ̀nà àtiṣàṣeparí ìlànà ìgbékalẹ̀ tí ó gbéṣẹ́ jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè.” Láìka àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun yìí sí, ìfojúsọ́nà fún ètò ayé tuntun kan ń yára pòórá. Kí ló ṣẹlẹ̀ tí ó mú kí ìrètí nípa ayé kan láìsí ogun dà bí èyí tí kò dáni lójú? Ìdí ha wà láti gbàgbọ́ pé a óò fojú kan àlàáfíà yíká ayé láé bí? Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò gbé àwọn ìbéèrè yìí yẹ̀ wò.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwọn ọkọ̀ òfuurufú ogun: Fọ́tò USAF
Àwọn ìbọn tí a fi ń já ọkọ̀ òfuurufú: Fọ́tò U.S. National Archives