ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 3/1 ojú ìwé 3-5
  • Awọn Ìwéwèé Eniyan Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Ìwéwèé Eniyan Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwéwèé Titobi Ti Eniyan
  • Ogun Tútù
  • “Sanmani Lẹhin Ogun Tútù”
  • Kí Ló Máa Kẹ́yìn Ogun?
    Jí!—1999
  • Alaafia Aye Ha Wà Ni Ojutaye Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ayé Kan Láìsí Ogun Ha Ṣeé Ṣe Bí?
    Jí!—1996
  • Awọn Ìwéwèé Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede Yoo Ha Kẹ́sẹjárí Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 3/1 ojú ìwé 3-5

Awọn Ìwéwèé Eniyan Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede

“Nigba ti gbogbo eyi bá dopin, a fẹ́ lati jẹ́ olùwonisàn. A fẹ́ lati ṣe ohun ti a lè ṣe lati mú ohun ti mo lè fi ẹmi nǹkan yoo dara pè ni eto ayé titun rọrùn.”—Ààrẹ U.S. George Bush, January 1991, kété lẹhin ibẹrẹ ogun pẹlu Iraq.

“Èròǹgbà Ààrẹ Bush nipa Eto Ayé Titun tẹnumọ ijẹpataki ilana ofin ati igbagbọ pe awọn orilẹ-ede ni ẹru-iṣẹ àjọṣe fun ominira ati idajọ ododo. Pẹlu ìmúwásópin Ogun Tútù naa, sanmani titun kan ni ó ń jẹyọ.”—Ikọ̀ U.S. si Australia, August 1991.

“Ni alẹ́ yii, bi mo ti rí i ti awọn iṣẹlẹ ijọba dẹmọ ń gbèrú yika ayé, boya —boya a ti sunmọ ayé titun yẹn ju ti igbakigba ri lọ.”—Ààrẹ U.S. George Bush, September 1991.

ỌPỌLỌPỌ awọn aṣaaju ayé, bii Ààrẹ Bush, ń sọrọ lọna ẹlẹmii nǹkan yoo dara nipa ọjọ-ọla. Idi rere ha wà fun ẹmi nǹkan yoo dara ti wọn ní bi? Awọn iṣẹlẹ lati igba Ogun Agbaye Keji ha funni ni ipilẹ fun iru ẹmi nǹkan yoo dara bẹẹ bi? Iwọ ha rò pe awọn oṣelu lè mú ailewu jakejado awọn orilẹ-ede wá bi?

Ìwéwèé Titobi Ti Eniyan

“Ni ọdun meji ti o kẹhin ogun agbaye keji,” ni ètò Goodbye War ori tẹlifiṣọn naa ṣalaye, “iye eniyan ti ó ju million kan lọ ni a ń pa loṣooṣu.” Ni akoko naa, awọn orilẹ-ede ni imọlara kanjukanju fun ìwéwèé kan ti yoo ṣediwọ fun iru ogun kan bẹẹ lati maṣe ṣẹlẹ mọ́. Nigba ti ogun naa ṣì ń lọ lọwọ, awọn aṣoju orilẹ-ede 50 mu ìwéwèé titobi julọ tí eniyan tii humọ rẹ̀ rí fun aabo jakejado awọn orilẹ-ede jade: Akọsilẹ Ète idasilẹ Iparapọ Awọn Orilẹ-ede. Ìfáárà sí Akọsilẹ Ète idasilẹ naa sọ ipinnu “lati gba iran ti ń bọ̀ silẹ lọwọ ijiya ti ogun ń fà.” Awọn ti wọn ń fojusọna lati di mẹmba Iparapọ Awọn Orilẹ-ede ni wọn nilati “pa okun [wọn] pọ lati pa alaafia ati ailewu jakejado awọn orilẹ-ede mọ́.”

Ọjọ 41 lẹhin naa, ọkọ ofuurufu kan sọ bọmbu abúgbàù kan sori Hiroshima, Japan. Ó búgbàù saaarin gbungbun ilu naa, ni pipa awọn eniyan ti wọn ju 70,000 lọ. Ìbúgbàù yẹn, ati eyi ti o ṣẹlẹ ni ọjọ mẹta lẹhin naa lori Nagasaki, fi opin si ogun pẹlu Japan lọna gbigbeṣẹ. Niwọn bi Germany alajọṣepọ Japan ti túúbá ni May 7, 1945, Ogun Agbaye Keji tipa bayii wá si opin. Bi o ti wu ki o ri, iyẹn ha ni opin gbogbo ogun bi?

Bẹẹkọ. Lati igba Ogun Agbaye Keji, araye ti ri awọn ogun keekeeke 150 ti o ti gba iwalaaye ti o rekọja 19 million. Ni kedere, ìwéwèé titobi ti UN (Iparapọ Awọn Orilẹ-ede) kò tii mú ailewu jakejado awọn orilẹ-ede wa sibẹ. Láburú wo ni ó ṣẹlẹ?

Ogun Tútù

Awọn olùwéwèé UN kùnà lati fojusọna fun idije ti o yara gbèrú laaarin awọn alajọṣepọ ninu Ogun Agbaye Keji tẹlẹri. Ọpọlọpọ Ijọba gbè sẹhin ìhà kọọkan ninu ijakadi agbara yii, eyi ti a wá pe ni Ogun Tútù ti o sì jẹ́, ni apa kan, ijakadi laaarin ajọ Kọmunist ati eto oniṣowo bòḿbàtà. Dipo pipa okun wọn pọ̀ ṣọkan lati dá ogun duro, awọn agbo orilẹ-ede mejeeji kín ìhà meji ti o lodi sira lẹhin ninu awọn iforigbari ẹkùn ilẹ kan si omiran ti wọn sì tipa bayii bá a raawọn jà ni Asia, Africa, ati ni awọn ilẹ America.

Ni apa ipari awọn ọdun 1960, Ogun Tútù naa bẹrẹ sii dẹjú. Ìdẹjú naa dé ògógóró ni 1975 nigba ti awọn Ijọba 35 fọwọsi ohun ti a pè ni Adehun Helsinki. Ninu awọn olùkópa naa ni Soviet Union ati United States wà, papọ pẹlu ọkọọkan wọn ni Europe alajọṣepọ. Gbogbo wọn ṣe ileri lati ṣiṣẹ fun “alaafia ati ailewu” ati “lati fà sẹhin . . . kuro ninu ihalẹmọni tabi lilo ipá lodisi ìjọ́kanṣoṣo agbegbe ilẹ tabi ominira oṣelu Ijọba eyikeyii, tabi ni iru ọna eyikeyii miiran ti kò ṣe deedee pẹlu awọn ète Iparapọ Awọn Orilẹ-ede.”

Ṣugbọn awọn èrò wọnyi kò mu eso jade. Ni ibẹrẹ awọn ọdun 1980, ijakadi laaarin awọn alagbara ogbontarigi gbónájanjan lẹẹkan sii. Awọn nǹkan di buburu tobẹẹ gẹẹ ti o fi jẹ pe ni 1982 akọwe-agba fun Iparapọ Awọn Orilẹ-ede ti a ṣẹṣẹ yàn naa, Dr. Javier Pérez de Cuéllar, gba ikuna eto-ajọ rẹ̀ ó sì kilọ nipa “rúgúdù titun jakejado awọn orilẹ-ede.”

Sibẹ, lonii, akọwe-agba UN ati awọn aṣaaju miiran fi ẹmi nǹkan yoo dara han. Awọn irohin tọka si “sanmani lẹhin Ogun Tútù.” Bawo ni iyipada yii ṣe wáyé?

“Sanmani Lẹhin Ogun Tútù”

Okunfa kan ti o yẹ fun afiyesi ni ipade àpérò orilẹ-ede 35 nipa Ailewu ati Ifọwọsowọpọ ni Europe. Ni September 1986 wọn fọwọsi ohun ti wọn pe ní Iwe-Aṣẹ Stockholm, ti ń tún ẹ̀jẹ́ wọn fun Adehun Helsinki ti 1975 polongo.a Iwe-Aṣẹ Stockholm ní ọpọlọpọ ilana lati ṣakoso ṣiṣọ awọn igbokegbodo ologun ninu. “Awọn abayọri ọdun mẹta ti o ti kọja ń funni niṣiiri tí ìwọ̀n ohun ti a ti ṣaṣepari rẹ̀ sì ti bẹrẹ sii tayọ awọn aigbọdọmaṣe ti a kọsilẹ sinu Iwe-Aṣẹ Stockholm,” ni SIPRI (Stockholm International Peace Research Institute [Eto Idasilẹ Iwadii Alaafia Agbaye Ti Stockholm]) rohin ninu Iwe Ọdọọdun 1990 rẹ̀.

Lẹhin naa, ni 1987, awọn alagbara ogbontarigi naa dori adehun pipẹtẹri kan tí ń beere fun bíba gbogbo àfọ̀njá àgbélẹ̀fisọ̀kò tí ìwọ̀n ìlọjìnnà wọn wà laaarin 300 ati 3,400 ibusọ jẹ́. “Biba awọn ohun ìjà ati awọn ibùdó ti a ti ń fi àfọ̀njá ranṣẹ jẹ́ lọna ti o ṣee fojuri ti wà lori itolẹsẹẹsẹ awọn ohun afilelẹ inu adehun naa sì ni ìhà kìn-ín-ní keji ń pamọ gẹgẹ bi o ti yẹ,” ni SIPRI sọ.

Awọn igbesẹ miiran ni a ti gbé lati dín ewu ogun àgbá runlérùnnà kù. Fun apẹẹrẹ, ni 1988 awọn alagbara ogbontarigi fọwọsi adehun kan nipa “afọnja ti a lè fi sọko lọ si ọna jijin ati awọn afọnja ti a lè fi sọko lati abẹ omi.” Ṣaaju fifi iru awọn ohun ìjà bẹẹ sọko, ìhà kọọkan gbọdọ fi tó ekeji leti “ni eyi ti kò din si wakati mẹrinlelogun ṣaaju, ọjọ ti a wéwèé naa, ibi ti a o ti fi ranṣẹ, ati agbegbe ti yoo nipa le lori.” Gẹgẹ bi SIPRI ti wi, iru awọn adehun bẹẹ “fẹrẹẹ mu ṣiṣeeṣe naa pe ki iṣẹlẹ adugbo ti ń gasoke di ogun àgbá runlérùnnà kari ayé kuro patapata.”

Ni akoko yii ná, awọn ìwéwèé lati mu aabo jakejado awọn orilẹ-ede sunwọn sii ń yára kánkán. Ni May 1990, lakooko àpérò awọn alagbara ogbontarigi ni Washington, D.C., ààrẹ Soviet Mikhail Gorbachev nigba naa damọran pe ki awọn agbo mejeeji ti awọn orilẹ-ede Europe fọwọsi iwe adehun alaafia kan. Ni oṣu July, 16 awọn orilẹ-ede ti Iha Iwọ-oorun ti NATO (North Atlantic Treaty Organization) pade ni London. Idahun pada wọn si idamọran Mikhail Gorbachev ni pe ki ìhà mejeeji fọwọsi “ipolongo ajọṣe ninu eyi ti a sọ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pe a kii ṣe ọ̀tá mọ́ ti a sì mú ero ọkàn wa lati fà sẹhin kuro ninu ihalẹmọni tabi lilo ipa dájú.” Àkọlé oju-ewe akọkọ ti iwe irohin Africa kan ṣapejuwe eyi gẹgẹ bi “Ìgbésẹ̀ Ńlá Siha Alaafia Ayé.”

Lẹhin naa, kété ṣaaju àpérò awọn agbara ogbontarigi ni Helsinki, Finland, agbọrọsọ kan fun ijọba U.S. sọ pe “ifojusọna fun ogun [ni Aarin Ila-oorun Ayé] yoo mu ki ìwéwèé awujọ titun kan fun alaafia ayé di eyi ti o wà.” Alaafia ri ilọsẹhin nigba ti Iraq ṣígun lọ bá Kuwait ti Aarin Ila-oorun Ayé si jọ bí eyi ti o wà ninu ewu ìsunjóná ráúráú. Ṣugbọn labẹ aṣẹ Iparapọ Awọn Orilẹ-ede, ẹgbẹ́ ọmọ ogun agbaye kan tí United States ṣiwaju rẹ̀ lé awọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń ṣígun naa pada lọ si orilẹ-ede wọn. Iṣọkan ète jakejado awọn orilẹ-ede ti a fihan ninu ogun yẹn fun awọn kan niṣiiri lati nireti pe ojumọ sanmani ifọwọsowọpọ titun kan ti mọ́.

Lati igba yẹn, awọn iṣẹlẹ ayé ti gbèrú siwaju sii. Ni pataki, irisi ohun ti ó jẹ́ Soviet Union tẹlẹ yipada lọna amunijigiri. Awọn Ijọba Baltic ni a yọnda fun lati polongo ominira tiwọn, awọn orilẹ-ede onijọba àdìbòyàn miiran ni Soviet Union sì tẹle apẹẹrẹ wọn. Idije oniwa-ipa laaarin awujọ ẹ̀yà jẹ jade ni awọn ilẹ ti o ti jọ bi eyi ti ó wà kongbári labẹ akoso gbogbogboo ti Kọmunist. Ni opin ọdun 1991, Soviet Union kò sí mọ́ lọna aṣẹ.

Awọn iyipada patapata wọnyi ninu iran oṣelu ayé ti ṣí ọna anfaani silẹ fun eto-ajọ Iparapọ Awọn Orilẹ-ede. Nipa eyi The New York Times sọ pe: “Mimu awọn aifararọ kárí ayé dẹjú ati ẹmi ifọwọsowọpọ titun laaarin United States ati Soviet Union lè tumọsi ipa titun kan ti o tubọ lagbara sii, ninu awọn àlámọ̀rí jakejado awọn orilẹ-ede fun eto-ajọ ayé.”

Akoko ha ti tó nigbẹhin-gbẹhin fun eto-ajọ ọlọdun 47 yẹn lati fihan pe oun ti tó gbangba sùn lọ́yẹ́ bi? Awa ha ń wọnu ohun ti United States pe ni “ọrundun titun, ati ẹgbẹrundun titun, ti alaafia, ominira ati aasiki bi”?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Adehun yii ni akọkọ ati eyi ti o ṣe pataki julọ ninu awọn ọ̀wọ́ iwe adehun tí Canada, United States, Soviet Union, ati awọn orilẹ-ede 32 miiran, fọwọsi ni Helsinki. Orukọ adehun pataki naa ti a faṣẹ si ni Ofin Ìkẹhìn ti Àpérò lori Ailewu ati Ifọwọsowọpọ ni Europe. Gongo rẹ̀ akọkọ ni lati dín àìfararọ jakejado awọn orilẹ-ede laaarin Ila-oorun ati Iwọ-oorun kù.—World Book Encyclopedia.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́