ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 3/1 ojú ìwé 5-7
  • Awọn Ìwéwèé Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede Yoo Ha Kẹ́sẹjárí Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Ìwéwèé Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede Yoo Ha Kẹ́sẹjárí Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ki Ni Bibeli Wí?
  • Ailewu Tootọ Lori Ilẹ̀-Ayé
  • Wíwò Rekọja “Alaafia ati Ailewu” Atọwọda Eniyan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Oju-iwoye Bibeli Nipa Alaafia ati Ailewu
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Iru Ailewu Wo Ni Iwọ Ń Yánhànhàn Fun?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Awọn Ìwéwèé Eniyan Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 3/1 ojú ìwé 5-7

Awọn Ìwéwèé Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede Yoo Ha Kẹ́sẹjárí Bi?

“OGUN Tútù naa, ti o ti gbá ayé mú fun ọdun ti o ju 40 lọ, farahan bi eyi ti aanu Ọlọrun ti mú kí ó pari,” ni One World, iwe irohin WCC (World Council of Churches [Igbimọ Awọn Ṣọọṣi Agbaye]) wi. “Awọn iṣẹlẹ jijọniloju ni Aarin ati Ila-oorun Europe . . . jọ bi ami didara fun alaafia ati ailewu ọjọ-ọla ní Europe ati ni iyooku ayé,” ni onkọwe ṣọọṣi Anglican John Pobee ti o jẹ mẹmba Itolẹsẹẹsẹ lori Imọ-ẹkọ Isin ti WCC fikún un.

Awọn aṣoju WCC kò danikan wà ninu siso Ọlọrun pọ mọ awọn ìwéwèé eniyan fun ailewu jakejado orilẹ-ede. Ni April 1991, ni kété lẹhin ogun Persian Gulf, Pope John Paul rán iṣẹ kan si akọwe-agba igba naa ti UN Javier Pérez de Cuéllar ninu eyi ti o ti sọ pe: “Awọn biṣọọbu Ṣọọṣi Katoliki ti Aarin Ila-oorun ati Iwọ-oorun ni igbọkanle ninu iṣẹ Iparapọ Awọn Orilẹ-ede . . . Wọn nireti pe, nipasẹ Iparapọ Awọn Orilẹ-ede ati awọn eto-ajọ rẹ̀ ti wọn yẹ fun eto pàtó kan, awọn wọnni ti ogun ẹnu aipẹ yii ti fi sinu aini titobi gan-an kò ni kuna lati rí ẹmi imọlara ati isowọpọṣọkan jakejado awọn orilẹ-ede.”

Siwaju sii, Vatican jẹ́ ọ̀kan lara awọn Ijọba 35 ti o hùmọ̀ ti o sì fọwọsi Iwe-Adehun Helsinki ti 1975 ati Iwe-Aṣẹ Stockholm ti 1986. Nigba ti Iparapọ Awọn Orilẹ-ede polongo 1986 pé ó jẹ́ “Ọdun Alaafia Agbaye,” pope dahun pada nipa kikesi aṣoju awọn isin ńlá-ńlá inu ayé lati kópa ninu ayẹyẹ “Ọjọ Adura Agbaye Fun Alaafia.” Ni October 1986, awọn aṣoju isin Buddha, Hindu, Islam, Shinto, Anglican, Luther, Ṣọọṣi Greek Orthodox, isin awọn Juu, ati awọn igbagbọ miiran jokoo papọ ni Assisi, Italy, wọn sì gbadura nikọọkan fun alaafia ayé.

Ni ọdun diẹ lẹhin naa, ninu ọrọ iwaasu ti o sọ ni Roomu, Olori Biṣọọbu Anglican ti Canterbury pe iṣẹlẹ ti o wà loke yii wá sí iranti. Ó sọ pe, “Ni Assisi, a ri i pe Biṣọọbu Roomu [pope] lè kó awọn Ṣọọṣi Kristẹni jọ papọ. A lè gbadura papọ, sọrọ papọ ki a sì gbegbeesẹ papọ fun alaafia ati iwa ni alaafia iran eniyan . . . Nibi idanuṣe ti adura fun alaafia ayé yẹn mo nimọlara pe mo wà ni iwaju Ọlọrun ẹni ti o sọ pe ‘Kiyesi i mo ń ṣe ohun titun kan.’”

Awọn isin yooku, bi o tilẹ jẹ pe a kò ṣoju fun wọn ni Assisi, tun ni ẹmi nǹkan yoo dara nipa awọn ìwéwèé eniyan fun ailewu jakejado awọn orilẹ-ede. Ọrọ olootu kan ninu Die Kerkbode, iwe irohin ti a faṣẹ si kan ti Dutch Reformed Church ni South Africa, sọ pe: “A ń niriiri ìrésọdá sinu eto ayé titun kan. Ohun ti o farajọ ohun ti kò ṣee finuro ni iwọnba ọdun diẹ sẹhin ń ṣẹlẹ ni oju wa kòrókòró. Ìlàjà ti ń ṣẹlẹ ninu iran ayé ti o tubọ tobi sii laaarin Soviet Union ati Iwọ-oorun ní ijẹpataki gbigbooro ni ẹkùn ilẹ pupọ. Ni apa ọdọ wa ni ayé, awọn eniyan ti o ti jẹ aṣa wọn lati maa tako araawọn ti wọn sì jẹ́ ọ̀tá paraku ń jumọsọrọpọ, oofa atinuwa fun ‘alaafia’ ń yọju nibi gbogbo . . . Lati inu oju-iwoye Kristẹni kan, gbogbo awọn isapa wa lati mu alaafia wà laaarin awọn eniyan ni a gbọdọ fi ayọ gbà. A lè gbadura fun alaafia ni akoko wa.”

Ọlọrun ha ń bukun awọn ìwéwèé eniyan fun ailewu jakejado awọn orilẹ-ede bi?

Ki Ni Bibeli Wí?

Nigba ti o ba di ọran gbigbarale awọn isapa eniyan, Bibeli pese ikilọ ti o ṣe taarata pe: “Ẹ maṣe gbẹkẹ yin lé awọn ọmọ-alade, tabi lé ọmọ eniyan, lọwọ ẹni ti kò si iranlọwọ. Ẹmi rẹ̀ jade lọ, o pada si erupẹ rẹ̀; ni ọjọ naa gan-an, iro inu rẹ̀ run.” (Saamu 146:3, 4) Itẹsiwaju siha alaafia ti ode oni lè jọ eyi ti ń funni ni iṣiri. Ṣugbọn a gbọdọ fi ìlọ́gbọ́n-nínú han. Agbara eniyan mọniwọn. Niye igba, awọn iṣẹlẹ maa ń tobi ju wọn lọ. Agbara káká ni wọn fi lè loye awọn imọlara abẹ́nú, awọn ipá ti o farasin, ti ń dojú awọn ìwéwèé wọn ti wọn ti ronu rẹ̀ daradara dé.

Ni 700 ọdun ṣaaju akoko Jesu, ní awọn ọjọ wolii Aisaya, aṣaaju awọn Juu ń wéwèé fun ailewu jakejado awọn orilẹ-ede nipasẹ awọn adehun pẹlu awọn orilẹ-ede ti o wà layiika ni ọna ti o ṣee fiwera pẹlu ohun ti ń ṣẹlẹ lonii. Ni awọn ọjọ wọnni pẹlu, awọn aṣaaju isin ti ohun tí awọn oṣelu ń ṣe lẹhin. Ṣugbọn Aisaya kilọ pe: “Ẹ gbimọ pọ̀ yoo sì di asan; ẹ sọrọ naa, ki yoo sì duro.” (Aisaya 8:10) Ìhùmọ̀ wọn yọrisi ikuna onijaaba. Ohun kan naa ha lè ṣẹlẹ lonii bi?

Bẹẹni, ó lè ṣẹlẹ, niwọn bi Ọlọrun ti kéde, nipasẹ wolii kan naa yẹn pe Oun ní ọna ti Oun lati mú ailewu wa si ilẹ-aye. Yoo jẹ́, kii ṣe nipasẹ eto-ajọ eniyan eyikeyii, bikoṣe nipasẹ atọmọdọmọ ọba Isirẹli naa Dafidi. (Aisaya 9:6, 7) Ajogun Ọba Dafidi yii ni Jesu Kristi, ẹni ti, nigba ti Pọntu Pilatu bi i leere, gbà pe oun jẹ́ Ọba kan ṣugbọn ti o sọ pe: “Ijọba mi kii ṣe ti ayé yii.” (Johanu 18:36; Luuku 1:32) Ni tootọ, Ijọba Jesu ni yoo jẹ́ ti ọrun. Oun—kii ṣe Iparapọ Awọn Orilẹ-ede tabi orilẹ-ede oṣelu ti ilẹ-aye eyikeyii miiran—ni yoo sì mú alaafia pipẹtiti, ailewu ti o ṣee gbarale wá si ilẹ-aye yii.—Daniẹli 2:44.

Jesu Kristi sọtẹlẹ ṣaaju pe Ijọba oun yoo bẹrẹ iṣakoso lati ọrun wá ni akoko ti ‘ìró ogun ati idagiri ogun,’ yoo wà ti “orilẹ-ede yoo dide si orilẹ-ede, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba.” Imuṣẹ asọtẹlẹ sami si 1914 gẹgẹ bi akoko naa nigba ti iyẹn ṣẹlẹ ó sì fi awọn ọdun lati igba yẹn han gẹgẹ bi “ipari eto igbekalẹ awọn nǹkan.”—Matiu 24:3, 6-8, New World Translation (Gẹẹsi).

Ki ni eyi tumọ si? Pe akoko ti ó ṣẹku fun eto ayé isinsinyi mọniwọn, ati pe laipẹ yoo tán. Iyẹn ha jẹ́ idi fun aniyan tabi ibanujẹ bi? Kii ṣe bi a bá ranti iwa ìkà, aiṣedajọ ododo, itẹloriba, ìjà-ogun, ati gbogbo inira ti o ti sami si eto awọn nǹkan yii. Ó daju pe itura ni yoo jẹ́ lati wà labẹ oluṣakoso kan nipa ẹni ti Ọrọ Ọlọrun, Bibeli wi pe: “Ẹmi Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo sì bà lé e, ẹmi ọgbọn ati òye, ẹmi igbimọ ati agbara, ẹmi imọran ati ibẹru Oluwa [“Jehofa,” NW].”—Aisaya 11:2.

Ailewu Tootọ Lori Ilẹ̀-Ayé

Ni otitọ, ki yoo sí ailewu gidi lori ilẹ-aye titi fi di ìgbà tí, labẹ Ijọba Ọlọrun, a o mú asọtẹlẹ Aisaya ṣẹ kárí ayé: “Emi dá awọn ọrun titun ati ayé titun: a kì yoo sì ranti awọn ti iṣaaju, bẹẹ ni wọn ki yoo wá si àyà.” (Aisaya 65:17) Laika bi o ti wu ki adura ti awọn aṣaaju isin ń gbà nititori ayé yii ti pọ̀ tó sí, awọn ìwéwèé eniyan fun ailewu jakejado awọn orilẹ-ede kò lè rọpo ọna Ọlọrun fun mimu alaafia ati ailewu wá.

Ailewu wíwàpẹtiti, kari ayé ti Ijọba Ọlọrun ń mú wọlé bọ̀ wá yoo jẹ́ ologo. Ọ̀kan ṣaa niyii lara awọn apejuwe ti a ri ninu Bibeli: “Wọn o fi idà wọn rọ ohun eelo itulẹ, wọn o sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ doje: orilẹ-ede ki yoo gbe idà soke si orilẹ-ede, bẹẹ ni wọn ki yoo kọ́ ogun jija mọ. Ṣugbọn wọn o jokoo olukuluku labẹ àjàrà rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ rẹ̀; ẹnikan ki yoo sì daya fò wọn: nitori ẹnu Oluwa [“Jehofa,” NW] awọn ọmọ-ogun ni o ti sọ ọ́.”—Mika 4:3, 4.

Kiki ailewu ti Ọlọrun funraarẹ nikan yọọda ni o lè wà pẹtiti ti o sì ṣee gbarale. Fun idi yii, dipo fifi igbẹkẹle rẹ sinu awọn ọ̀tọ̀kùlú, eeṣe ti o kò fi fi igbẹkẹle rẹ sinu rẹ̀? Nigba naa ni iwọ yoo ri pe awọn ọrọ onisaamu naa jẹ́ otitọ pe: “Ayọ ni fun ẹni ti o ni Ọlọrun Jakọbu fun iranlọwọ rẹ̀, ireti ẹni ti ń bẹ lọdọ Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun rẹ̀: ẹni ti o dá ọrun oun ayé, okun ati ohun ti o wà ninu wọn: ẹni ti o pa otitọ mọ́ titi ayé.”—Saamu 146:5, 6.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Ṣọọṣi Katoliki ati Iṣelu Agbaye

“Bi o tilẹ jẹ pe Kristi sọ pe Ijọba oun ‘kii ṣe ti ayé yii,’ awọn alufaa-ṣọọṣi ti wọn wà ni ipo gigagiga ati ipo poopu gẹgẹ bi idasilẹ kan ti lọwọ ninu ijakadi oṣelu agbaye ati ti orilẹ-ede lọna mimuna lati akoko Constantine.”—The Catholic Church in World Politics, lati ọwọ Ọjọgbọn Eric Hanson ti Jesuit Santa Clara University.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́