ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 9/1 ojú ìwé 7-8
  • Wíwò Rekọja “Alaafia ati Ailewu” Atọwọda Eniyan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwò Rekọja “Alaafia ati Ailewu” Atọwọda Eniyan
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Alaafia ati Ailewu Nisinsinyi!
  • Alaafia ati Ailewu Yika Aye
  • Oju-iwoye Bibeli Nipa Alaafia ati Ailewu
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ẹ Jẹ Ki “Alaafia Ọlọrun” Maa Daabobo Ọkan-aya Yin
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Iru Ailewu Wo Ni Iwọ Ń Yánhànhàn Fun?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ Ewu Agbára Átọ́míìkì A Ti Fòpin sí I Pátápátá!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 9/1 ojú ìwé 7-8

Wíwò Rekọja “Alaafia ati Ailewu” Atọwọda Eniyan

Otitọ naa ni pe, eniyan kò le mu alaafia gidi, tí ó wà pẹtiti wá lae. Eetiṣe? Nitori pe awọn eniyan gan an kọ́ ni oluba alaafia jẹ́, bi o tilẹ jẹ pe wọn ṣajọpin ninu ẹ̀bi nitori itan wọn ti o kún fun abaawọn ẹjẹ. Oluba alaafia jẹ́ tootọ lagbara ju eniyan lọ. Kii ṣe ẹlomiran bikoṣe Satani Eṣu, ẹni ti a ṣapejuwe ninu Bibeli gẹgẹ bi ẹni ti “ntan gbogbo aye jẹ.”—Iṣipaya 12:9.

BIBELI wi pe: “Gbogbo aye ni o wà labẹ agbara ẹni buburu nì [Satani].” (1 Johanu 5:19) Fun idi yii, jijere alaafia tootọ ati ailewu pipẹtiti gbọdọ wémọ́ mimu Satani kuro ninu iran naa papọ pẹlu eto-igbekalẹ aye tí oun ti kọ́ tí ó sì han kedere pe oun nṣakoso. (Fiwe Aisaya 48:22; Roomu 16:20.) Awọn eniyan ko le ṣe eyi.

Bawo, nigba naa, ni ọwọ ṣe le tẹ alaafia ati ailewu? Nipa agbara Ẹni naa ti o lagbara ju Satani lọ fíìfíì. Ọlọrun Olodumare ti diwọn akoko kan fun igbokegbodo Satani laaarin araye. Nigba ti idiwọn akoko yẹn ba dé, “iparun ojiji” yoo wá sori aye naa ti o wa labẹ agbara Satani. (1 Tẹsalonika 5:3-7) Gbogbo ẹ̀rí ṣamọna si ipari ero naa pe eyi yoo ṣẹlẹ laipẹ.

Alaafia ati Ailewu Nisinsinyi!

Bi o ti wu ki o ri, ki ni nipa ti isinsinyi? Iwọn alaafia tootọ ati ailewu kan ni o ṣeeṣe ani lonii paapaa. Bawo? Kii ṣe gẹgẹ bi ọpọlọpọ awọn aṣaaju isin ti gbiyanju rẹ, nipa kikowọnu oṣelu aye yii, ṣugbọn kaka bẹẹ, nipa titẹle awọn aṣẹ ati imọran Ọlọrun.

Njẹ iru ipa ọna kan bẹẹ ha nmu alaafia tootọ wa bi? Bẹẹni, o nṣe bẹẹ. Fun apẹẹrẹ, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti gbidanwo rẹ̀ wọn sì ti rí i pe o ṣeeṣe nitootọ lati gbadun ojulowo alaafia ati iwọn ailewu de aye kan pẹlu. Titẹle awọn aṣẹ Ọlọrun gẹgẹ bi a ti ṣí i payá ninu Bibeli ti mu ki o ṣeeṣe fun wọn lati wà papọ gẹgẹ bi eto-ajọ jakejado awọn orilẹ-ede ninu alaafia tootọ, laika iran, orilẹ-ede, tabi ede wọn sí.—Saamu 133:1.

Ni igbọran si ofin atọrunwa, wọn ti ‘fi ọ̀kọ̀ rọ doje wọn ko si kọ́ ogun mọ́’ lọna iṣapẹẹrẹ. (Aisaya 2:2-4) Wọn nimọlara aabo ninu ifẹ Ọlọrun wọn si ni igbọkanle pe awọn arakunrin wọn tẹmi daniyan fun wọn. (Roomu 8:28, 35-39; Filipi 4:7) Bi iwọ ba nṣiyemeji yala eyi jẹ otitọ, a ké si ọ lati bẹ̀ wọ́n wò ninu ọkan lara awọn Gbọngan Ijọba wọn ki o si ri i funraarẹ.

Alaafia ati Ailewu Yika Aye

Bi o ti wu ki o ri, eyi kii ṣe ipari imuṣẹ ileri Bibeli nipa alaafia ati ailewu tootọ. Ki a má ri! O wulẹ jẹ ikofiri bi aye yii yoo ti rí bi gbogbo eniyan ba tẹle awọn ofin Ọlọrun ni. Laipẹ ikofiri yẹn yoo di otitọ gan an.

Apọsiteli Pọọlu wi pe: “Nigba ti wọn [awọn wọnni ti wọn ko jọsin Ọlọrun] ba nwi pe, Alafia ati ailewu; [ni rironu pe wọn ti mu alaafia ati ailewu wá ni ọna tiwọn funraawọn]; nigba naa ni iparun ojiji yoo de sori wọn.” (1 Tẹsalonika 5:3) Ọlọrun yoo pinnu pe Satani ti ṣi araye lọna tó. Akoko yoo ti tó nigba naa lati mu un kuro loju ọpọ́n, papọ pẹlu eto-igbekalẹ aye idibajẹ ti o wà labẹ agbara rẹ̀. Nigba naa ni akoko yoo tó fun imuṣẹ asọtẹlẹ Daniẹli pe: “Ni ọjọ awọn ọba wọnyi ni Ọlọrun ọrun yoo gbe ijọba kan kalẹ, eyi ti a ki yoo le parun titi lae: a ki yoo si fi ijọba naa lé orilẹ-ede miiran lọwọ, yoo si fọ́ gbogbo ijọba wọnyi tuutuu, yoo si pa wọn run; ṣugbọn oun yoo duro titi laelae.”—Daniẹli 2:44.

Eyi yoo ha jẹ iṣe ti ko ba idajọ ododo mu ni iha ọdọ Ọlọrun bi? Bẹẹkọ rara. Iparun ojiji yoo dé sori kiki awọn wọnni ti wọn lẹtọọ si i ni ibamu pẹlu idajọ Ọlọrun, awọn ọpa idiwọn Ọlọrun. Iwọ ha nigbẹkẹle ninu Ẹlẹdaa lati pinnu lọna ti o ba idajọ ododo mu ninu ọran yii bi? Dajudaju awa le fi ọran naa silẹ laisewu si ọwọ rẹ̀! Ki ni yoo sì jẹ iyọrisi iṣẹ idajọ rẹ̀? Owe naa wi pe: “Nitori pe ẹni iduroṣinṣin ni yoo jokoo ni ilẹ naa, awọn ti o pe yoo si maa wà ninu rẹ̀. Ṣugbọn awọn eniyan buburu ni a o ké kuro ni ilẹ-aye.” (Owe 2:21, 22) Ẹnikẹni yoo ha ni irobinujẹ ọkan fun pipadanu awọn ẹni buburu bi?

Bi a ti mu awọn oluba alaafia jẹ́ kuro ni ori ilẹ-aye, ojulowo alaafia ati ailewu yoo jẹ́ ìní araye yika aye labẹ iṣakoso oloore ti Ijọba Ọlọrun. “Wọn ki yoo panilara, bẹẹ ni wọn ki yoo panirun ni gbogbo oke mimọ mi: nitori aye yoo kun fun imọ Oluwa [“Jehofa,” NW] gẹgẹ bi omi ti bo okun.” (Aisaya 11:9) Iwọ ha gba ileri Bibeli yii gbọ́ bi? Iwọ ha ni idaniloju pe awọn nǹkan wọnyi yoo ṣẹlẹ laipẹ bi? Bi iwọ ba ni iyemeji eyikeyii, a gbà ọ́ niyanju lati ṣayẹwo ọran naa siwaju. Niti tootọ, ọna Ọlọrun ni ọna kanṣoṣo ti ọwọ eniyan le gbà tẹ gongo alaafia tootọ ati ojulowo ailewu ti wọn ńyánhànhàn fun.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Awọn eniyan Jehofa ngbadun alaafia tootọ ati iwọn ailewu pupọ lonii

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́