ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 9/1 ojú ìwé 5-6
  • Oju-iwoye Bibeli Nipa Alaafia ati Ailewu

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Oju-iwoye Bibeli Nipa Alaafia ati Ailewu
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Alaafia ati Ailewu—Iṣẹlẹ Akọkọ Kan si Ki Ni?
  • Koko Ti O Niiṣe Pẹlu Akoko Ni A Ṣipaya
  • ‘Kìràkìtà’ Laaarin Awọn Agbara Aye
  • Wíwò Rekọja “Alaafia ati Ailewu” Atọwọda Eniyan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ Ewu Agbára Átọ́míìkì A Ti Fòpin sí I Pátápátá!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ẹ Jẹ Ki “Alaafia Ọlọrun” Maa Daabobo Ọkan-aya Yin
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Awọn Ìwéwèé Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede Yoo Ha Kẹ́sẹjárí Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 9/1 ojú ìwé 5-6

Oju-iwoye Bibeli Nipa Alaafia ati Ailewu

Lóréfèé ọpọlọpọ eniyan nigbagbọ ninu ohun ti o han kedere pe o jẹ itẹsi siha isopọṣọkan aye titobi sii ati alaafia ati ailewu ti eyi le mu wa. Wọn nireti pe iru itẹsiwaju bẹẹ le ṣamọna si aye kan ti o dara ju. Ṣugbọn Bibeli fihan pe ohun pupọ ni o wé mọ́ ọn ju ohun ti o farahan lọ.

KOKO ọrọ alaafia ati ailewu jẹ ohun ti o fa ọkan ifẹ awọn Kristẹni mọra ni pataki nitori ohun ti apọsiteli Pọọlu kọ labẹ imisi si ijọ Kristẹni kan ni ọgọrun un ọdun kìn-ín-ní. Awọn ọrọ rẹ ni a kọsilẹ ninu Bibeli ni 1 Tẹsalonika 5:3: “Nigba ti wọn ba nwi pe, alaafia ati ailewu; nigba naa ni iparun ojiji yoo de si ori wọn gẹgẹ bi irọbi lori obinrin ti o lóyún; wọn ki yoo si le sálà.” Iwe mimọ yii gbé awọn ibeere pataki dide.

Alaafia ati Ailewu—Iṣẹlẹ Akọkọ Kan si Ki Ni?

Bi iwọ ba ka ayika awọn ọrọ Pọọlu ti a fayọ loke yii, iwọ yoo ri pe awọn wọnni ti wọn nsọ pe “alaafia ati ailewu” kii ṣe awọn Kristẹni ti wọn wà lojufo rekete, ṣugbọn, kaka bẹẹ, wọn jẹ awọn ẹni ti wọn ti sùn laimọ ohun ti nṣẹlẹ layiika wọn niti gidi. Wọn wa ni ipo elewu kan ṣugbọn wọn ko mọ nipa rẹ nitori pe wọn ronu pe awọn nǹkan nsunwọn sii. Bi o ti wu ki o ri, nipa awọn Kristẹni, Pọọlu wi pe: “Niti akoko ati igba wọnni, ará, ko tọ ki ẹnikẹni kọwe si yin.” (1 Tẹsalonika 5:1) Bẹẹni, awa nilati mọ nipa itolẹsẹẹsẹ akoko awọn iṣẹlẹ Ọlọrun. Eeṣe? Nitori pe Pọọlu sọ pe akoko iparun ojiji kan, ti a npe ni “ọjọ Oluwa [“Jehofa,” NW],” nbọ “gẹgẹ bi ole ni oru.”—1 Tẹsalonika 5:2.

Ki ni ọrọ nipa alaafia ati ailewu ti a sọtẹlẹ naa yoo ni ninu? Ni kedere, ó gbọdọ ju ọrọ ṣákálá lasan lọ. Awọn eniyan ti nsọrọ nipa alaafia ni ohun ti o fẹrẹẹ pẹ to igba ti wọn ti njagun. Awọn ọrọ Pọọlu gbọdọ tọka si akoko kan nigba ti o jọ bi ẹni pe ọwọ awọn orilẹ-ede ti ntẹ alaafia ni ọna kan ti o tayọ. Ṣugbọn eyi wulẹ jasi kiki ifarahan oréfèé. Ohun kan ti o jọ alaafia ati ailewu ti o ṣamọna si iparun ojiji kii ṣe alaafia gidi tabi ojulowo ailewu ni kedere.

Jesu pẹlu sọrọ nipa iparun ojiji yii. O pe e ni “ipọnju nla . . . , iru eyi ti ko si lati igba ibẹrẹ ọjọ yii wá di isinsinyi, bẹẹkọ, iru rẹ ki yoo sì sí.” Ọgọrọọrun ọdun melookan ṣaaju akoko Jesu, wolii naa Daniẹli tun sọ nipa rẹ, o si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi “akoko wahala . . . , iru eyi ti ko tii si ri, lati igba ti orilẹ-ede ti wa titi fi di igba akoko yii.”—Matiu 24:21; Daniẹli 12:1.

Yala a pe e ni ipọnju nla tabi a pe e ni akoko idaamu—eyikeyii ninu mejeeji, yoo nu gbogbo ipa eto-igbekalẹ ori ilẹ-aye ti Satani nù kuro ni ibamu pẹlu awọn asọtẹlẹ. Dipo titọka si itẹwọgba atọrunwa, ọrọ nipa alaafia ati ailewu ti a sọtẹlẹ naa yọrisi odikeji gan an!—Fiwe Sefanaya 3:8.

Koko Ti O Niiṣe Pẹlu Akoko Ni A Ṣipaya

Njẹ ohun ti o jọ igbesẹ siha isopọṣọkan aye titobi ju lẹnu aipẹ yii ati awọn ireti fun alaafia ati ailewu ti yoo ti inu rẹ jade ha jẹ́ imuṣẹ ikilọ alasọtẹlẹ Pọọlu bi? O dara, gẹgẹ bi iwe irohin yii ti ntọka jade lemọlemọ, lati 1914 a ti rí imuṣẹ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn asọtẹlẹ Bibeli ti wọn tan mọ́ wiwa nihin in Jesu ninu agbara Ijọba ti ọrun. (Matiu, ori 24, 25; 2 Timoti 3:1-5; Iṣipaya 6:1-8) Jesu fihan pe ọjọ Jehofa, nigba ti iparun ojiji yoo wa sori awọn ẹni buburu, yoo dé nigba ti awọn mẹmba iran eniyan ti o ri ibẹrẹ akoko yii ṣì wà laaye.—Luuku 21:29-33.

Apọsiteli Pọọlu tun fi koko ti o niiṣe pẹlu akoko han. O wi pe: “Nigba ti wọn ba nsọrọ nipa alaafia ati ailewu, lairotẹlẹ ni ìjábá yoo dé sori wọn.” Iṣetumọ awọn ọrọ Pọọlu yii ninu The New English Bible fihan ni kedere pe ipọnju nla naa yoo ṣẹlẹ “nigba ti wọn ba nsọrọ.” Bi ole kan ni oru—ti a ko ri tẹlẹ—iparun yoo bẹ́ silẹ nigba ti a ko reti rẹ, nigba ti afiyesi ọpọjulọ awọn eniyan wà lori alaafia ati ailewu wọn ti wọ́n nreti. Fun idi yii, nigba ti awa ko le sọ ni akotan lakooko yii pe ipo alaafia ati ailewu lọwọlọwọ mu awọn ọrọ Pọọlu ṣẹ—tabi dé aye wo ni ọrọ alaafia ati ailewu ṣi nilati gberu—otitọ naa pe iru ọrọ bẹẹ ni a ngbọ dé iwọn ti ko ṣẹlẹ rí nisinsinyi kilọ ewu fun awọn Kristẹni lati wà lojufo ni gbogbo igba.

‘Kìràkìtà’ Laaarin Awọn Agbara Aye

Nigba ti o sọrọ nipa akoko idaamu, wolii naa Daniẹli tun fi koko ti o niiṣe pẹlu akoko han. O fihan pe akoko idaamu yoo ṣẹlẹ ni opin rogbodiyan ti o ti wà tipẹtipẹ laaarin agbo orilẹ-ede alagbara meji, ọkan njẹ “ọba ariwa” ekeji si njẹ, “ọba guusu.” (Daniẹli 11:5-43) Lati opin Ogun Agbaye Keji, agbo orilẹ-ede alagbara wọnyi ni “ọba guusu” ti oniṣowo bòḿbàtà ati “ọba ariwa” ti ijọba ajumọni ti duro fun.

Daniẹli sọtẹlẹ pe ibanidije kikoro laaarin awọn orilẹ-ede mejeeji wọnyi, gẹgẹ bi a ti ṣakiyesi laaarin akoko ọdun 45 ti o kọja yoo jẹ gẹgẹ bii “kìràkìtà kan,” bí awọn ẹlẹ́kẹ meji ti wọn nlakaka fun anfaani kan. Lẹnu aipẹ yii, kìràkìtà naa jọ bii pe o ti dinku. Gẹgẹ bi apẹẹrẹ kan, ni oṣu May ọdun ti o kọja, Minisita Soviet ni ilẹ okeere polongo pe Ogun Tutu ti pari. Ni June, iwe irohin Time tọka si apero awọn olori orilẹ-ede laaarin United States ati Soviet Union o si kọwe pe: “Diẹ lara awọn adehun lori didin awọn ohun ija ogun ku ati didan àgbá atọmiki wò iba ti dabii aṣepari yiyanilẹnu kan ni ọdun diẹ sẹhin. Nisinsinyi, ani ki a tilẹ pa gbogbo adehun naa pọ, wọn dabii ohun ti ko yá ni lórí.”

Yala ohun ti o jọ ibarẹ laaarin awọn alagbara ògbóǹtarìgì yii jẹ́ fun igba diẹ tabi yoo wà titi, akoko ni yoo sọ. Bi o ti wu ki o ri, ohun kan ṣe kedere. Saa akoko ti Jesu mẹnukan ti lọ jinna. Awọn nǹkan ti wọn sì nṣẹlẹ kari aye fihan pe a ti sunmọ awọn iṣẹlẹ ti a sọtẹlẹ nipasẹ apọsiteli Pọọlu ati wolii naa Daniẹli. Bi o tilẹ jẹ pe awọn ohun ti o gbèrú ninu oṣelu lẹnu aipẹ yii jẹ́ nititori agbara idari awọn ṣọọṣi Kristẹndọmu dé iwọn aye kan, wọn ki yoo ṣamọna si alaafia pipẹtiti. Ẹri naa ni pe wọn yoo ṣamọna si odikeji gan an fun awọn orilẹ ede aye yii.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Akoko ni yoo sọ bi ohun ti o jọ ìbárẹ́ laaarin awọn alagbara ògbóǹtarìgì meji naa yoo ti pẹ́ tó

[Credit Line]

USSR Mission to the UN

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́