Ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ Ewu Agbára Átọ́mí ìkì A Ti Fòpin sí I Pátápátá!
GBÍGBÉ nínú ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì kìí ṣe ohun tí Ọlọrun fẹ́ fún aráyé. Gẹ́gẹ́ bí “Ọlọrun aláyọ̀,” ó fẹ́ kí wọ́n gbádùn àlàáfíà kí wọ́n sì gbé ní àìléwu—ní kúkúrú, kí wọ́n láyọ̀. (1 Timoteu 1:11, NW) Nínú ayé kan tí ó kún fún ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ewu agbára átọ́míìkì, ó ṣe kedere pé èyí kò ṣeéṣe.
“Àlàáfíà àti Àìléwu”—Ayédèrú
Ó yẹ kí ó ṣe kedere pé ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ewu agbára átọ́míìkì kò tíì kásẹ̀ nílẹ̀ rárá. Síbẹ̀, láìka họ́wùhọ́wù ti ìṣèlú, ti ìṣúnná owó, àti ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà sí, ó dàbí ẹni pé àwọn orílẹ̀-èdè ní gbogbogbòò ní ẹ̀mí nǹkan yóò dára. Ìgbìyànjú fífẹsẹ̀múlẹ̀ láti mú ewu náà rọjú ti farahàn kedere láti ìgbà Ọdún Àlàáfíà Àgbáyé ti Àjọ UN ní 1986.
Ìwé ìròyìn The Bulletin of the Atomic Scientists ní ẹ̀wádún tí ó kọjá yí ọwọ́ agogo ọjọ́ ìparun rẹ̀—ọ̀nà tí ó ń gbà mọ̀ bóyá ogun alágbára átọ́míìkì yóò jà—kúrò lórí ìṣẹ́jú 3 ṣáájú ọ̀gànjọ́ òru padà sí ìṣẹ́jú 17 ṣáájú ọ̀gànjọ́ òru. Ní 1989 àjọ Stockholm International Peace Research Institute ròyìn pé “ìrètí fún ìgbèròpinnu ìforígbárí tí kò fa ìjọ̀ngbọ̀n ni a ti fìdíi rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà tí ó túbọ̀ dára ju bí ó ti rí nínú ọdún èyíkéyìí mìíràn láti ìgbà tí Ogun Àgbáyé II ti parí.”
Ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni a ti mú gbaradì láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá nípa àwọn ibi tí wàhálà ti ń jà ranyin lágbàáyé. Àṣeyọrí rẹ̀, nígbà tí kìí ṣe ní gbogbo ọ̀nà, ti tó láti dákún ẹ̀mí nǹkan yóò dára tí gbogbogbòò ní. Ó ṣeéṣe jùlọ kí ọjọ́-ọ̀la mú àfikún àbáyọrí titun wá. Bóyá ó ṣeéṣe kí igbe “àlàáfíà àti àìléwu” túbọ̀ ròkè síi kí ó sì túbọ̀ jẹ́ kíkankíkan síi. Wọ́n tilẹ̀ lè jèrè ìgbọ́kànlé àwọn ènìyàn pàápàá.
Ṣùgbọ́n ṣọ́ra! Bibeli kìlọ̀ pé, “nígbà tí wọ́n bá ń wí pé, àlàáfíà àti àìléwu; nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrọbí lórí obìnrin tí ó lóyún; wọn kì yóò sì lè sálà.” Nípa báyìí, àwọn igbe “àlàáfíà àti àìléwu” yóò sàmì sí àkókò Ọlọrun “láti run àwọn tí ń [tipasẹ̀ ìsọdèérí, ti agbára átọ́míìkì àti ní àwọn ọ̀nà mìíràn] pa ayé run.”—1 Tessalonika 5:3, 4; Ìfihàn 11:18.
Ṣàkíyèsí pé Bibeli kò sọ pé ọwọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yóò tẹ “àlàáfíà àti àìléwu.” Ó hàn gbangba pé wọn yóò máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ọ̀nà kan tí kò lẹ́gbẹ́, ní fífi ẹ̀mí nǹkan yóò dára àti ìgbàgbọ́dájú tí a kò tíì nímọ̀lára rẹ̀ títí di ìsinsìnyí hàn nínú ìsọ̀rọ̀ wọn. Àwọn ṣíṣeéṣe náà pé kí ọwọ́ tẹ àlàáfíà àti àìléwu yóò farahàn bí èyí tí ó súnmọ́ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Láìka ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ewu agbára átọ́míìkì tí ń bá a lọ sí, àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó fí ẹ̀tàn mú kí wọ́n nímọ̀lára àìléwu èké.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Kristian tòótọ́ ni a kì yóò tànjẹ. Pẹ̀lú ọkàn-ìfẹ́ mímúhánhán wọn yóò wò rékọjá àlàáfíà àti àìléwu ẹ̀dá ènìyàn sí ohun kan tí ó dára jù!
Àlàáfíà àti Àìléwu—Ojúlówó
Ní ìbámu pẹ̀lú Orin Dafidi 4:8, nínú ìṣètò Jehofa Ọlọrun nìkan ni a ti lè rí àlàáfíà àti àìléwu tòótọ́: “Èmi ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ní àlàáfíà, èmi ó sì sùn; nítorí ìwọ, Oluwa, nìkanṣoṣo ni o ń mú mi jókòó ní àìléwu.” Kìkì ayédèrú ni igbe “àlàáfíà àti àìléwu” èyíkéyìí tí a sọ jáde lẹ́yìn-òde àyíká-ọ̀rọ̀ nípa ìṣètò Ìjọba Jehofa lè jẹ́. Kò lè ṣàṣeyọrí ohunkóhun tí ó ní ìníyelórí títọ́jọ́.
Àwọn ojútùú tí kò lọ jìnnà kò dára tó fún Ìjọba Ọlọrun lábẹ́ Kristi. Àkóso àtọ̀runwá yóò ṣe ju dídín iye àwọn ohun-ìjà alágbára átọ́míìkì kù; yóò mú wọ́n kúrò pátápátá àti gbogbo àwọn ohun-ìjà ogun yòókù. Orin Dafidi 46:9 ṣèlérí pé: “Ó mú [ogun, NW] tán dé òpin ayé; ó ṣẹ́ ọrun, ó sì ké ọ̀kọ̀ méjì; ó sì fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná.”
Bákan náà, ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ewu agbára átọ́míìkì tí ìṣiṣẹ́gbòdì àwọn ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù agbára átọ́míìkì tàbí pàǹtírí ìtànṣán olóró gíga ń mú wá yóò di àwọn nǹkan àtijọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ náà kì yóò jẹ́ òtítọ́ pé: “Wọn óò jókòó olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀; ẹnìkan kì yóò sì dáyàfò wọ́n: nítorí ẹnu Oluwa àwọn ọmọ-ogun ni ó ti sọ ọ́.” Ọlọrun kò lè ṣèké. Kò sí ìdí fún wa láti ṣiyèméjì nípa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Mika 4:4; Titu 1:2.
Ìwọ yóò ha gbádùn níní ìfojúsọ́nà fún gbígbé nínú ayé kan nínú èyí tí a ti fòpin sí ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ewu agbára átọ́míìkì pátápátá bí? Ìwọ lè ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣe ìlàlẹ́sẹẹsẹ àwọn ohun tí a béèrè fún ní kedere. Nípa kíkọ́ nípa wọn àti nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú wọn, ní ọjọ́ kan ìwọ lè ní ayọ̀ ti sísọ pẹ̀lú ìmọ̀lára ìtura pé: “Ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ewu agbára átọ́míìkì—ti dópin nígbẹ̀yìngbẹ́yín!”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àlàáfíà yóò jọba nínú ayé titun Ọlọrun láìsí àwọn ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ewu agbára átọ́míìkì èyíkéyìí
[Credit Line]
M. Thonig/H. Armstrong Roberts
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 6]
Fọ́tò U.S. National Archives