Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
“Ohun Ìrántí kan fún Ẹ̀mí Ìfọwọ́sowọ́pọ̀”
NÍTÒSÍ ibi tí ó jẹ́ gúúsù jùlọ ní ilẹ̀ Spain ni òkúta ẹfun ràgàjì kan dúró ṣánṣán sí tí a mọ̀ sí Àpáta Gibraltar. Fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, àpáta yìí ti jẹ́ ẹlẹ́rìí dídákẹ́jẹ́ẹ́ sí àríyànjiyàn olóṣèlú àti àìfohùnṣọ̀kan jákèjádò àgbáyé. Ní ìyàtọ̀ gédégédé sí èyí, Àpáta Gibraltar láìpẹ́ yìí di ògiri tí ó wà lẹ́yìn ìṣàfihàn ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìṣọ̀kan tí a kò fi bẹ́ẹ̀ rí nínú ayé lónìí.
Kìlómítà mẹ́ta péré láti ibi Àpáta náà ni ìlú La Línea, Spain wà. Níbẹ̀ ni kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ti mú ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn òṣìṣẹ́ olùyọ̀ọ̀da ara-ẹni tí wọ́n háragàgà láti yọ̀ọ̀da àkókò àti agbára wọn wà papọ̀. Bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ kára láti kọ́ ibìkan tí o bójúmu fún jíjọ́sìn Ẹlẹ́dàá, Jehofa Ọlọrun, wíwà ọlọ́láńlá ti Àpáta Gibraltar lẹ́yìn rẹ̀ pàápàá kò jámọ́ nǹkankan ní ìfiwéra pẹ̀lú iṣẹ́ takuntakun tí ó wà láti ṣe.
Àwọn olùpòkìkí Ìjọba tí wọ́n wà ní apá ibẹ̀yẹn nínú ayé fi ìròyìn tí ó tẹ̀lé e yìí ránṣẹ́:
“Ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àwọn onítara olùyọ̀ọ̀da ara-ẹni ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sán Friday, September 24, 1993. Nígbà ti yóò fi di agogo méje ìrọ̀lẹ́ Sunday, àmì titun tí ń fi ilé náà hàn gẹ́gẹ́ bí Gbọ̀ngàn Ìjọba ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a ti gbéró, a sì lo ilé titun fífanimọ́ra náà fún ìpàdé rẹ̀ àkọ́kọ́ fún gbogbo ènìyàn.
“Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí láti àgbègbè Gibraltar ni ó la ibodè kọjá láti ran àwọn arákùnrin wọn ará Spain lọ́wọ́. ‘Ìyapa olóṣèlú kò mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹgbẹ́ ará kárí ayé wa,’ ni ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ olùyọ̀ọ̀da ara-ẹni ará Gibraltar kan ṣàlàyé. Ó fikún un pé: ‘Ní ọdún mélòókan sẹ́yìn, àwọn ọ̀rẹ́ láti La Línea wá láti ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ní Gibraltar, nítorí náà nísinsìnyí a láyọ̀ láti san ẹ̀san ojúrere náà padà.’
“Láti ṣàfikún ìsapá aláìláàlà àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jehofa méjì náà àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn olùrànlọ́wọ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ láti àgbègbè Andalusia, ìlú-ńlá La Línea pinnu láti ṣe ìtọrẹ ilẹ̀ tí a nílò. ‘Gẹ́gẹ́ bí àṣà, àwọn aláṣẹ ìbílẹ̀ Spain ti sábà máa ń pèsè ilẹ̀ fún kíkọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki,’ ni olórí ìgbìmọ̀ ìlú-ńlá La Línea ṣàlàyé nígbà ìbẹ̀wò kan sí ibi ìkọ́lé náà. ‘Èéṣe tí a kò ṣe ohun kan náà fún àwọn ẹgbẹ́ onísìn yòókù? Àìmọtara-ẹni-nìkan àwọn olùyọ̀ọ̀da ara-ẹni náà jẹ́ ohun ìwúrí púpọ̀ fún mi, mo sì lérò pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí ìtìlẹ́yìn wa. A nílò púpọ̀ síi irú ẹ̀mí báyìí nínú ayé tí ó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ lónìí.’
“Ó tọ́kasí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí ‘ohun ìrántí kan fún ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀.’ Níti gidi, ohun tí ó wúni lórí jùlọ kìí ṣe ọnà ìkọ́lé náà bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe ìtóbi ilé náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ó wú ọ̀pọ̀ nínú àwọn olùgbé ibẹ̀ lórí ni òtítọ́ náà pé àwọn olùyọ̀ọ̀da ara-ẹni nìkan ni ó kọ́ ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí àti pé wọ́n kọ́ ọ ní wákàtí 48 péré!”
Ẹ̀rí fihàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní La Línea àti àwọn àgbègbè rẹ̀ ń jẹ́rìí òtítọ́ sí ọ̀rọ̀ Galatia 6:10. Níbẹ̀ aposteli Paulu gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú: “Ǹjẹ́ bí a ti rí àkókò, ẹ jẹ́ kí a máa ṣoore fún gbogbo ènìyàn, àti pàápàá fún àwọn tíí ṣe ará ilé ìgbàgbọ́.”