ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 3/1 ojú ìwé 8-9
  • Iru Ailewu Wo Ni Iwọ Ń Yánhànhàn Fun?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iru Ailewu Wo Ni Iwọ Ń Yánhànhàn Fun?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ààbò Tòótọ́ Nísinsìnyí àti Títí Láé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Wíwò Rekọja “Alaafia ati Ailewu” Atọwọda Eniyan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ Ewu Agbára Átọ́míìkì A Ti Fòpin sí I Pátápátá!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Awọn Ìwéwèé Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede Yoo Ha Kẹ́sẹjárí Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 3/1 ojú ìwé 8-9

Iru Ailewu Wo Ni Iwọ Ń Yánhànhàn Fun?

ORIṢIRIṢI awọn eniyan ní èrò ọtọọtọ nipa ailewu. Awọn kan wò ó gẹgẹ bi ìdúróṣinṣin laaarin awọn agbara ologun ti wọn takora. Fun apẹẹrẹ, awọn alagbara ti wọn jẹgaba lori iran ayé papọ pẹlu awọn alajọṣepọ wọn ni Europe ti fohunṣọkan lori ọpọlọpọ ọna lati dín ìdágbálé ewu naa kù pe awọn iṣẹlẹ kekere yoo fosoke di ogun runlérùnnà yika ayé. Stockholm International Peace Research Institute Yearbook 1990 fi iyalẹnu ńlá han lori aini iharagaga si iru awọn igbesẹ bẹẹ niha ọdọ awọn orilẹ-ede “ni awọn apa miiran ninu ayé.”

Bi o ti wu ki o ri, sí araadọta-ọkẹ ti ń gbé ni awọn orilẹ-ede abòṣì, “ailewu” tumọsi ounjẹ ati itọju ilera. “Nigba ti o ba di ọran rironu nipa ‘alaafia ati ailewu,’” ni onimọ ijinlẹ nipa oṣelu Yash Tandon ṣalaye, “èrò ti a tẹwọgba nipa aṣa ṣiṣepataki julọ ti Iwọ-oorun yoo mókè. . . . ‘Ailewu’ ni a ri gẹgẹ bi ọran ihamọra ogun ati bibọ ihamọra ogun silẹ, ti o jinna si idaniyan fun ailewu ti awọn ti kò ri ounjẹ jẹ ati awọn alainilelori ti wọn jẹ́ ìdá meji ninu mẹta awọn eniyan olùgbé ayé.”

Niti Bibeli, ó ṣeleri pe labẹ Ijọba Ọlọrun kò ni si ogun mọ́. “Ó mu ọ̀tẹ̀ tán dé opin ayé; o ṣẹ́ ọrun, o sì ké ọ̀kọ̀ meji; o sì fi kẹkẹ-ogun jona.” (Saamu 46:9; Aisaya 2:4) Aisan ti ara yoo di ohun ti o ti kọja lọ. “Awọn ará ibẹ̀ ki yoo wi pe, òótù ń pa mi: a o dari aiṣedeedee awọn eniyan ti ń gbé ibẹ̀ jì wọn.”—Aisaya 33:24.

Labẹ Ijọba yẹn, ailewu ti iṣunna owo ki yoo halẹ mọ ẹnikankan mọ́. “Wọn ó sì kọ́ ile, wọn ó sì gbé inu wọn; wọn ó sì gbin ọgbà àjàrà, wọn ó sì jẹ eso wọn. Wọn ki yoo kọ ile fun ẹlomiran gbé, wọn ki yoo gbìn fun ẹlomiran jẹ.”—Aisaya 65:21, 22.

Bi o ti wu ki o ri, eyi ti o tubọ ṣe pataki, Ijọba naa yoo mu okunfa pataki fun aini alaafia ati ailewu kuro. Ta ni o ti wà lẹhin ìtàn gigun ti aiṣaṣeyọri ati awọn ijọba atẹniloriba eniyan? Nigba ti ó jẹ́ pe Ọlọrun, fun idi rere, ti yọnda wọn lati wà, ẹni naa ti o gbọdọ dahun fun un ni Satani, niwọn bi Bibeli ti sọ pe ‘gbogbo ayé ni o wà labẹ agbara rẹ̀.’—1 Johanu 5:19.

Nigba naa, itura wo ni yoo jẹ́, nigba ti labẹ Ijọba Ọlọrun, awọn ọrọ Pọọlu si awọn ara Roomu yoo ni imuṣẹ nikẹhin pe: “Ọlọrun alaafia yoo sì tẹ Satani mọlẹ ni atẹlẹsẹ yin ni lọọlọọ”! (Roomu 16:20) Kiki Ijọba Ọlọrun ti ọrun, labẹ Ọba naa Jesu Kristi, ni o lè ṣaṣepari iru nǹkan bẹẹ. Fun idi yii, kiki labẹ Ijọba yẹn ni ilẹ̀-ayé yoo tó di eyi ti a yipada si paradise.—Jẹnẹsisi 1:28; Luuku 23:43.

Bẹẹni, ailewu ti a ṣeleri ninu Bibeli galọla ju ó sì lọ jinna ju ohunkohun ti eniyan humọ lọ. Họ́wù, a kà pe “ki yoo si iku mọ́, tabi ọ̀fọ̀, tabi ẹkún, bẹẹ ni ki yoo si irora mọ́.” (Iṣipaya 21:4) Njẹ a lè gbẹkẹle iru awọn ileri bẹẹ bi? Bẹẹni, nitori pe wọn pilẹṣẹ pẹlu olodumare Ẹlẹdaa, Jehofa Ọlọrun, ẹni ti ó tun polongo pe: “Ọrọ mi ti o ti ẹnu mi jade . . . ki yoo pada sọdọ mi lofo, ṣugbọn yoo ṣe eyi ti ó wù mí, yoo sì maa ṣe rere ninu ohun ti mo rán an.” (Aisaya 55:11) Aṣeyọrisirere pàtó sami sí awọn igbesẹ ti Jehofa Ọlọrun ń gbé ani nisinsinyi lati mu alaafia, ailewu, ati aasiki ti o tọ́jọ́ ti o sì ń muni layọ wá fun araye, ni dídá ipo ọba-alaṣẹ ayeraye Rẹ̀ lare.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́