ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 5/15 ojú ìwé 4-7
  • Ààbò Tòótọ́ Nísinsìnyí àti Títí Láé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ààbò Tòótọ́ Nísinsìnyí àti Títí Láé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ààbò fún Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọrun
  • Ohun Tí Ọlọrun Ń Ṣe fún Àwọn Ènìyàn Rẹ̀
  • Ààbò Tòótọ́ Yóò Ha Wà fún Gbogbo Ènìyàn Bí?
  • Nígbẹ̀yìngbẹ́yín —Ààbò Tòótọ́ Títí Láé!
  • Iru Ailewu Wo Ni Iwọ Ń Yánhànhàn Fun?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Wíwò Rekọja “Alaafia ati Ailewu” Atọwọda Eniyan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìrètí Tí Ìsìn Tòótọ́ Fúnni
    Jí!—1999
  • Ìgbésí Ayé Tó Ní Ààbò Pípẹ́ Títí
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 5/15 ojú ìwé 4-7

Ààbò Tòótọ́ Nísinsìnyí àti Títí Láé

KÒ SÍ iyè méjì pé Jehofa Ọlọrun lè pèsè ààbò fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Òun ni “Olódùmarè.” (Orin Dafidi 68:14) Orúkọ rẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́ túmọ̀ sí “Ó Mú Kí Ó Wà.” Èyí fi í hàn yàtọ̀ bí Ẹnì kan ṣoṣo lágbàáyé tí ó lè borí ohun ìdènà èyíkéyìí láti lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, kí ó sì ṣàṣeparí ìfẹ́ inú rẹ̀. Ọlọrun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò rí: kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lófo, ṣùgbọ́n yóò ṣe èyí tí ó wù mi, yóò sì máa ṣe rere nínú ohun tí mo rán an.”—Isaiah 55:11.

Ọlọrun ń pèsè ààbò fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé e. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú èyí dáni lójú. Ọlọgbọ́n Ọba Solomoni sọ lábẹ́ ìmísí àtọ̀runwá pé: “Orúkọ Oluwa, ilé ìṣọ́ agbára ni: olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì là.” Ó sọ síwájú sí i pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Oluwa ni a óò gbé lékè.”—Owe 18:10; 29:25.

Ààbò fún Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọrun

Jehofa ti máa ń fìgbà gbogbo pèsè ààbò fún àwọn tí ó gbára lé e. Fún àpẹẹrẹ, wòlíì Jeremiah gbádùn ààbò Ọlọrun. Nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Babiloni dó ti Jerusalemu apẹ̀yìndà, àwọn ènìyàn “jẹ àkàrà nípa ìwọ̀n, àti pẹ̀lú ìtọ́jú.” (Esekieli 4:16) Ipò náà le koko débi tí àwọn obìnrin kan fi se àwọn ọmọ ara wọn jẹ. (Ẹkún Jeremiah 2:20; 4:10) Àní, bí Jeremiah tilẹ̀ wà ní àhámọ́ nígbà náà nítorí ìwàásù rẹ̀ láìbẹ̀rù, Jehofa rí i dájú pé ‘wọ́n ń fún un ní ìṣù àkàrà kọ̀ọ̀kan lójoojúmọ́, láti ìta àwọn alákàrà, títí gbogbo àkàrà fi tán ní ìlú.’—Jeremiah 37:21.

Nígbà tí Jerusalemu ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Babiloni, a kò pa Jeremiah, bẹ́ẹ̀ ni a kò wọ́ ọ lọ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n sí Babiloni. Kàkà bẹ́ẹ̀, “Balógun ìṣọ́ [àwọn ará Babiloni] . . . fún un ní oúnjẹ àti ẹ̀bùn; ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́.”—Jeremiah 40:5.

Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, Jesu Kristi mú un dá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lójú pé: “Ẹ máṣe ṣàníyàn láé kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni awa yoo jẹ?’ tabi, ‘Kí ni awa yoo mu?’ tabi, ‘Kí ni awa yoo wọ̀?’ Nitori gbogbo iwọnyi ni nǹkan tí awọn orílẹ̀-èdè ń lépa pẹlu ìháragàgà. Nitori Baba yín ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọnyi. Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà naa, ní wíwá ìjọba naa ati òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọnyi ni a óò sì fi kún un fún yín.”—Matteu 6:31-33.

Èyí ha túmọ̀ sí pé àwọn ìránṣẹ́ Jehofa yóò gbádùn ààbò àtọ̀runwá kúrò lọ́wọ́ gbogbo àjálù òde òní bí? Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀. Àwọn olùṣòtítọ́ kò bọ́ lọ́wọ́ ìpalára. Àwọn Kristian tòótọ́ ń ṣàìsàn, wọ́n ń nírìírí inúnibíni, wọ́n ń hu ìwà ọ̀daràn sí wọn, wọ́n ń kú nínú ìjàm̀bá, wọ́n sì ń jìyà ní àwọn ọ̀nà míràn.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa kò tí ì pèsè ààbò pátápátá kúrò lọ́wọ́ ìpalára, ìròyìn fi hàn pé òún ń lo agbára rẹ̀ láti pèsè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti láti dáàbò bò wọ́n. A tún ń pa àwọn Kristian mọ́ kúrò lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ ìṣòro nítorí pé wọ́n ń fi àwọn ìlàna Bibeli sílò nínú ìgbésí ayé wọn. (Owe 22:3) Síwájú sí i, wọ́n ń gbádùn ààbò ẹgbẹ́ arákùnrin àti arábìnrin onífẹ̀ẹ́ nípa tẹ̀mí kárí ayé, tí wọ́n ń ran ara wọn lọ́wọ́ ní àkókò àìní. (Johannu 13:34, 35; Romu 8:28) Fún àpẹẹrẹ, ní ìdáhùnpadà sí ipò àìnírètí àwọn ará wọn ní Rwanda tí ogun ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Europe yára dá owó àti àwọn ìpèsè jọ, wọ́n sì fi tọ́ọ̀nù 65 aṣọ àti egbòogi, oúnjẹ, àti àwọn ìpèsè míràn tí owó rẹ̀ tó 1,600,000 dọ́là ránṣẹ́.—Fi wé Ìṣe 11:28, 29.

Bí Jehofa tilẹ̀ fàyè gbà àdánwò láti ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristian tòótọ́, wọ́n ní ìdánilójú pé òun yóò fún wọn ní okun, ìtìlẹ́yìn, àti ọgbọ́n láti fara dà. Ní kíkọ̀wé sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, aposteli Paulu sọ pé: “Kò sí ìdẹwò [àdánwò] kankan tí ó ti bá yín bíkòṣe ohun tí ó wọ́pọ̀ fún awọn ènìyàn. Ṣugbọn Ọlọrun jẹ́ olùṣòtítọ́, òun kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ [dán] yín wò rékọjá ohun tí ẹ lè múmọ́ra, ṣugbọn papọ̀ pẹlu ìdẹwò [àdánwò] náà oun yoo tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè faradà á.”—1 Korinti 10:13; The Emphatic Diaglott.

Ohun Tí Ọlọrun Ń Ṣe fún Àwọn Ènìyàn Rẹ̀

Lónìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ní inú dídùn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọrun. A kò fipá mú wọn láti ṣiṣẹ́ sin Ọlọrun; wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé, wọ́n mọ̀ ọ́n, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Nítorí èyí, Jehofa nífẹ̀ẹ́ àwọn adúróṣinṣin ìránṣẹ́ rẹ̀, òun náà tún pète láti yí ilẹ̀ ayé padà sí paradise kan níbi tí aráyé onígbọràn yóò ti gbádùn àlàáfíà, ìlera, àti ààbò títí láé.—Luku 23:43.

Ọlọrun yóò ṣe èyí nípasẹ̀ ìjọba ọ̀run kan, tí yóò ní Ọba tí òún yàn sípò, Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí Aláàkóso rẹ̀. (Danieli 7:13, 14) Bibeli tọ́ka sí ìjọba yìí gẹ́gẹ́ bí “ìjọba Ọlọrun” àti gẹ́gẹ́ bí “ìjọba awọn ọ̀run.” (1 Korinti 15:50; Matteu 13:44) Ìjọba Ọlọrun yóò rọ́pò gbogbo ìjọba ẹ̀dá ènìyàn. Dípo níní ọ̀pọ̀ ìjọba lórí ilẹ̀ ayé, ìjọba kan ṣoṣo ni yóò wà. Yóò ṣàkóso ní òdodo lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.—Orin Dafidi 72:7, 8; Danieli 2:44.

Jehofa ń nawọ́ ìkésíni náà láti wá gbé lábẹ́ Ìjọba náà sí gbogbo ènìyàn. Ọ̀nà kan tí òún gbà ń ṣe èyí jẹ́ nípasẹ̀ ìpínkiri gbígbòòro Bibeli, ìwé náà tí ó ṣàlàyé ohun tí Ìjọba náà yóò ṣe fún ìran ẹ̀dá ènìyàn. Bibeli ni ìwé tí a tí ì pín kiri jù lọ ní ayé, ó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó nísinsìnyí, lódindi tàbí lápá kan, ní àwọn èdè tí ó ju 2,000 lọ.

Jehofa Ọlọrun ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti lóye ohun tí Bibeli fi kọ́ni nípa Ìjọba náà. Ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa dídá àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ àti rírán wọn jáde láti ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Ó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń pòkìkí ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun nísinsìnyí ní èyí tí ó ju 230 orílẹ̀-èdè.

Ààbò Tòótọ́ Yóò Ha Wà fún Gbogbo Ènìyàn Bí?

Gbogbo ènìyàn yóò ha tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà láti di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọrun nípa mímú ara wọn bá ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo rẹ̀ mu bí? Rárá, nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn kò nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọrun. Wọ́n kọ ìsapá láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ìgbésí ayé wọn sunwọ̀n sí i. Ní tòótọ́, wọ́n fi ara wọn hàn bí àwọn tí Jesu sọ nípa wọn pé: “Ọkàn-àyà awọn ènìyàn yii ti sébọ́, wọ́n sì ti fi etí wọn gbọ́ láìsí ìdáhùnpadà, wọ́n sì ti di ojú wọn; kí wọ́n má baà fi ojú wọn rí láé kí wọ́n sì fi etí wọn gbọ́ kí òye rẹ̀ sì yé wọn ninu ọkàn-àyà wọn kí wọ́n sì yípadà, kí n [Ọlọrun] sì mú wọn láradá.”—Matteu 13:15.

Báwo ni ààbò tòótọ́ ṣe lè wà lórí ilẹ̀ ayé láàárín àwọn tí wọ́n kọ̀ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀nà òdodo Ọlọrun? Kò lè sí. Àwọn aláìlọ́lọ́run ń halẹ̀ mọ́ ààbò àwọn tí ń fẹ́ láti ṣiṣẹ́ sin Jehofa.

Ọlọrun kì í fipá mú àwọn ènìyàn láti yí padà, ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fàyè gba ìwà ibi láìlópin. Bí Jehofa tilẹ̀ ń fi sùúrù bá a nìṣó láti rán àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ jáde láti kọ́ àwọn ènìyàn nípa àwọn ọ̀nà àti ète rẹ̀, kì yóò máa bá a lọ láti ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìgbà pípẹ́ mọ́. Jesu Kristi sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A óò sì wàásù ìhìnrere ìjọba yii ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé lati ṣe ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè; nígbà naa ni òpin yoo sì dé.”—Matteu 24:14.

Kí ni “òpin” yóò túmọ̀ sí fún àwọn tí wọ́n kọ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọrun? Yóò túmọ̀ sí ìdájọ́ aláìbáradé àti ìparun wọn. Bibeli sọ̀rọ̀ nípa mímú “ẹ̀san wá sórí awọn wọnnì tí kò mọ Ọlọrun ati awọn wọnnì tí kò ṣègbọràn sí ìhìnrere nipa Jesu Oluwa wa. Awọn wọnyi gan-an yoo faragba ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun.”—2 Tessalonika 1:6-9.

Nígbẹ̀yìngbẹ́yín —Ààbò Tòótọ́ Títí Láé!

Lẹ́yìn ìparun àwọn tí wọ́n kọ àwọn ọ̀nà àlàáfíà Jehofa, Ìjọba Ọlọrun yóò mú sànmánì ológo aláàbò wá fún àǹfààní àwọn olódodo lórí ilẹ̀ ayé. (Orin Dafidi 37:10, 11) Ẹ wo bí ayé tuntun yẹn yóò ti yàtọ̀ sí èyí tí a ń gbé inú rẹ̀ lónìí tó!—2 Peteru 3:13.

Ìyàn àti ebi kì yóò sí mọ́. Gbogbo ènìyàn yóò ní púpọ̀ láti jẹ. Bibeli sọ pé ‘gbogbo ènìyàn yóò gbádùn àsè ohun àbọ́pa.’ (Isaiah 25:6) Kí yóò sí àìtó oúnjẹ, nítorí pé “ìkúnwọ́ ọkà ni yóò máa wà lórí ilẹ̀, lórí àwọn òkè ńlá ni èso rẹ̀ yóò máa mì.”—Orin Dafidi 72:16.

Àwọn ènìyàn kì yóò tún máa gbé nínú àwọn ilé jẹ́gẹjẹ̀gẹ tàbí àwọn ìlú onílé ahẹrẹpẹ mọ́. Lábẹ́ Ìjọba Ọlọrun, gbogbo ènìyàn yóò ní ilé mèremère, wọn yóò sì jẹ oúnjẹ tí wọ́n mú jáde lórí ilẹ̀ àwọn tìkára wọn. Bibeli ṣèlérí pé: “Wọn óò sì kọ́ ilé, wọn óò sì gbé inú wọn; wọn óò sì gbin ọgbà àjàrà, wọn óò sì jẹ èso wọn.”—Isaiah 65:21.

Dípò àìríṣẹ́ṣe tí ó tàn kálẹ̀, iṣẹ́ tí ó níláárí yóò wà, àwọn ènìyàn yóò sì rí àbájáde rere láti inú rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé: “Àwọn ìyànfẹ́ mi yóò sì jìfà iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Wọn kì yóò ṣiṣẹ́ lásán.”—Isaiah 65:22, 23.

Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba, àrùn kì yóò kọlu àwọn ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò pa wọ́n. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun mú un dá wa lójú pé: “Àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Otútù ń pa mi.”—Isaiah 33:24.

Nínú Paradise orí ilẹ̀ ayé tí yóò dé láìpẹ́, ìjìyà òun ìrora, ìbànújẹ́ àti ikú, yóò kọjá lọ. Bẹ́ẹ̀ ni, àní ikú pàápàá! Àwọn ènìyàn yóò wà láàyè títí láé nínú Paradise! Bibeli sọ fún wa pé Ọlọrun “yoo sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Awọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.

Lábẹ́ ìṣàkóso Jesu Kristi, “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” náà, ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé yóò láàbò ní tòótọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ní tòótọ́, ààbò kárí ayé yóò wà lábẹ̀ ìṣàkóso òdodo, onífẹ̀ẹ́ ti ìjọba kan—Ìjọba Ọlọrun.—Isaiah 9:6, 7; Ìṣípayá 7:9, 17.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

“Ààbò ẹ̀dá ènìyàn ń tọ́ka sí ìgbọ́kànlé nínú ọjọ́ ọ̀la, . . . [ìgbọ́kànlé nínú] ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ipò òṣèlú àti ti ọrọ̀ ajé.”—Obìnrin kan tí ń gbé ní Asia

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

“Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ohun tí ó mú ọ nímọ̀lára àìláàbò ni ìwà ipá àti ìwà ìbàjẹ́.”—Ọkùnrin kan tí ń gbé ní Gúúsù America

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“N kò nímọ̀lára ààbò nígbà . . . ìkọlù náà. Bí orílẹ̀-èdè kan bá ń jagun, báwo ni a ṣe lè retí pé kí àwọn ènìyàn nímọ̀lára ààbò?”—Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

“Èmi yóò nímọ̀lára ààbò nígbà tí mo bá mọ̀ pé mo lè rìn ní àwọn òpópónà ní alẹ́ láìsí pé a fipá bá mi lò pọ̀.”—Ọmọdébìnrin kan tí ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ní Áfíríkà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́