ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 10/8 ojú ìwé 7-10
  • Ìgbésí Ayé Tó Ní Ààbò Pípẹ́ Títí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbésí Ayé Tó Ní Ààbò Pípẹ́ Títí
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Fọwọ́ Rọ́ Ìbẹ̀rẹ̀ Tó Láàbò Dànù
  • Fi Àwọn Ohun Tẹ̀mí Sípò Kìíní
  • “Ẹ Ké Pe Jèhófà, Ọlọ́run Yín”
  • Òdodo, Ìdákẹ́jẹ́ẹ́, àti Ààbò
  • Ààbò Tòótọ́ Nísinsìnyí àti Títí Láé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Wíwá Ìgbésí Ayé Aláàbò Kiri
    Jí!—1998
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé O Kò Já Mọ́ Nǹkan Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Wíwò Rekọja “Alaafia ati Ailewu” Atọwọda Eniyan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 10/8 ojú ìwé 7-10

Ìgbésí Ayé Tó Ní Ààbò Pípẹ́ Títí

BÍ IBÀ bá ń ṣe ọ́, ó ṣeé ṣe kí o wá egbòogi lò kí ẹ̀fọ́rí tí ń ṣe ọ́ lè rọlẹ̀ àti bóyá kí o gbe omi dídì sórí kí ara rẹ lè yé gbóná. Àmọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé egbòogi àti omi dídì náà yóò jẹ́ kí o mú àwọn àmì àrùn náà mọ́ra, wọn kò débi ohun tó fa ibà tí ń ṣe ọ́. Bí àìsàn náà bá sì le, o ní láti rí dókítà kan tí ó mọṣẹ́.

Aráyé wà nínú ìṣòro àìláàbò tí kò dábọ̀. A máa ń gbé ìgbésẹ̀ onígbà kúkúrú láti pẹ̀tù sí àwọn àmì ìṣòro náà, àmọ́, ẹni tí ó lè ṣàlàyé kíkún nípa ìṣòro wa nìkan ni ó lè yanjú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ kò sí ẹni tí ó mọ aráyé dáadáa ju Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, lọ. Ó mọ̀ pé ìwàláàyè wà nínú ewu nítorí àwọn ìṣòro tí a ti fà sórí wa.

A Fọwọ́ Rọ́ Ìbẹ̀rẹ̀ Tó Láàbò Dànù

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàlàyé pé Jèhófà ṣẹ̀dá tọkọtaya àkọ́kọ́ ní pípé, ó sì fi wọ́n sí àyíká tí ó láàbò. Kò sí ohun tí ń dà wọ́n láàmú. Ète Ọlọ́run fún ènìyàn ni pé kí ó máa gbé títí láé nínú párádísè, nínú ààbò pípé. Ibi tí a fi ènìyàn sí lákọ̀ọ́kọ́ ní “olúkúlùkù igi tí ó fani mọ́ra ní wíwò, tí ó sì dára fún oúnjẹ” nínú. Ṣàkíyèsí pé a pèsè fún wọn nípa ti ara àti ìmọ̀lára, níwọ̀n bí a ti ṣàpèjúwe ibi tí wọ́n wà bí èyí tí ó “fani mọ́ra ní wíwò.” Láìsíyèméjì, èyí túmọ̀ sí pé a fi tọkọtaya àkọ́kọ́ náà sí ibi tí ó mú ìgbésí ayé aláàbò, tí kò ti sí ìṣòro dá wọn lójú.—Jẹ́nẹ́sísì 2:9.

Ádámù àti Éfà kọ ìṣàkóso onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run bi ọba aláṣẹ, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ìmọ̀lára àìdájú, ẹ̀rù, ìtìjú, ẹ̀bi, àti àìláàbò wá sínú ayé wọn. Lẹ́yìn tí Ádámù kọ Ọlọ́run, ó jẹ́wọ́ pé ‘àyà fo’ òun. Àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ bo ìhòòhò wọn, wọ́n sì fara pa mọ́ fún Ẹlẹ́dàá wọn onífẹ̀ẹ́, tí wọ́n ti jọ wà nínú ipò ìbátan tímọ́tímọ́, tí ó sì ṣàǹfààní títí di àkókò yẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5, 8-10.

Ète àkọ́kọ́ tí Jèhófà ní kò yí padà. Bíbélì sọ pé, Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ni Ẹlẹ́dàá wa, ẹni tí yóò jẹ́ kí aráyé onígbọràn yí ilẹ̀ ayé padà sí ipò párádísè láìpẹ́, kí wọ́n sì máa gbé láìséwu títí láé. Ó tẹnu wòlíì Aísáyà ṣèlérí pé: “Èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun; . . . ẹ yọ ayọ̀ ńláǹlà, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú títí láé.” (Aísáyà 65:17, 18) Àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun yìí pé: “Nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò . . . máa gbé.”—2 Pétérù 3:13.

Báwo ni èyí yóò ṣe ṣẹlẹ̀? Nípasẹ̀ ìjọba kan tí Jèhófà yóò gbé kalẹ̀ ni. Ìjọba yìí ni Jésù Kristi wí pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa gbàdúrà fún pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:9, 10.

Ìjọba Ọlọ́run yóò rọ́pò ìṣàkóso ènìyàn, yóò sì fi tìfẹ́tìfẹ́ mú ète Ọlọ́run ṣẹ jákèjádò ayé. (Dáníẹ́lì 2:44) Iyèméjì, ẹ̀rù, ìtìjú, ẹ̀bi, àti àìláàbò tí ó ti ń yọ aráyé lẹ́nu láti ìgbà ayé Ádámù yóò pòórá. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, Ìjọba yẹn ti sún mọ́lé. Nínú ayé àìdánilójú tí a wà yìí pàápàá, àwọn tí wọ́n ń yán hànhàn fún Ìjọba Ọlọ́run ní ààbò dé àyè kan.

Fi Àwọn Ohun Tẹ̀mí Sípò Kìíní

Dáfídì jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ó sì mọ bí ìjayà àti ìdààmú ṣe ń rí lára. Síbẹ̀, Dáfídì kọ ohun tí ó wà nínú Sáàmù 4:8 pé: “Àlàáfíà ni èmi yóò dùbúlẹ̀, tí èmi yóò sì sùn, nítorí pé ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, nìkan ṣoṣo ni ó mú kí n máa gbé nínú ààbò.” Jèhófà mú kí Dáfídì ronú pé òun wà láàbò, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ń ní ìṣòro lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ǹjẹ́ a lè rí nǹkan kọ́ nínú èyí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń gbé inú ayé aláìláàbò, báwo ni a ṣe lè rí ìwọ̀n ààbò díẹ̀?

Gbé ohun tí a kọ sínú Jẹ́nẹ́sísì nípa Ádámù àti Éfà yẹ̀ wò. Ìgbà wo ni wọ́n kò ní èrò pé àwọn ní ààbò mọ́? Gbàrà tí wọ́n kọ ìbátan àárín àwọn àti Ẹlẹ́dàá wọn, tí wọ́n sì kọ̀ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀ fún aráyé. Nítorí náà, bí a bá ṣe òdì kejì ohun tí wọ́n ṣe yẹn nípa níní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, tí a sì ń gbìyànjú láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó ń fẹ́, nísinsìnyí pàápàá, a lè gbádùn ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ láàbò ju bí kò ti lè ṣeé ṣe bí a bá ṣe òdì kejì rẹ̀ lọ.

Mímọ Jèhófà nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ìgbésí ayé túmọ̀ sí. Ìgbà yẹn nìkan ni a lóye irú ẹni tí a jẹ́ àti ìdí tí a fi wà níhìn-ín. Tí a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí a mọ ète rẹ̀ fún aráyé, tí a sì lóye ìdí tí a fi wà níhìn-ín ni a lè gbé ìgbésí ayé tí ó láàbò. Ọkùnrin kan tí ń jẹ́ Paul rídìí ìyẹn ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn.

Ọ̀kan lára àwọn erékùṣù ìtòsí etíkun Germany ni wọ́n bí Paul sí, tí wọ́n sì tọ́ ọ dàgbà. Nítorí ohun tí àwọn òbí rẹ̀ ti fojú winá rẹ̀ nínú Ogun Àgbáyé Kejì, ìdílé rẹ̀ kò nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn. Paul sọ irú ẹni tí òun yà nígbà tí òun jẹ́ ọ̀dọ́ pé: “N kò gba ohunkóhun gbọ́, n kò sì bọ̀wọ̀ fún ẹnikẹ́ni. Ọtí ni mo máa ń fi pàrònú mi, mo máa ń mutí yó lẹ́ẹ̀mejì tàbí ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀. Kò sí ààbò nínú ayé mi.”

Nígbà tó yá Paul bá ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jíròrò. Paul jiyàn gan-an, àmọ́ ohun kan tí Ẹlẹ́rìí náà sọ mú kí ó ronú. “Ẹ̀ṣẹ́ kì í ṣẹ́ lásán.” Tàbí lédè mìíràn, gbogbo ìṣẹ̀dá tí a ń rí láyìíká wa gbọ́dọ̀ ní Ẹlẹ́dàá.

“Mo ro ọ̀rọ̀ yẹn lọ́pọ̀ ìgbà, mo sì gbà pẹ̀lú rẹ̀.” Èyí ló mú kí Paul gbà pé kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì wá mọ Jèhófà. Ó jẹ́wọ́ pé: “Yàtọ̀ sí àwọn òbí mi, Jèhófà ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó tíì ṣe nǹkan fún mi nínú ìgbésí ayé mi.” Paul ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí ní ọdún 1977, ó sì wí pé: “Nísinsìnyí, mo ti mọ ohun tí ète ìgbésí ayé jẹ́ ní ti gidi. Mo ń gbádùn gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jèhófà ń fẹ́. Mo nímọ̀lára pé mo láàbò, níwọ̀n bí kò ti sí ohunkóhun tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí èmi tàbí ìdílé mi tí Jèhófà kò lè ṣàtúnṣe lọ́jọ́ iwájú.”

Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ nínú ìrírí yìí? Paul borí ipò àìláàbò—wàhálà ti ìmọ̀lára—tí ó wà nípa ṣíṣàìgbájúmọ́ ohun ti ara bí kò ṣe àwọn ohun tẹ̀mí. Ó mú ìbátan tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jàǹfààní wíwà nínú irú ìbátan bẹ́ẹ̀. Èyí ń fún wọn ní okun inú tí ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbójú fo àwọn àǹfààní ara wọn nínú àjọṣepọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Nípa kíkàn sí àwọn ènìyàn ní ilé wọn, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lo àkókò wọn láti ran àwọn ènìyàn mìíràn lọ́wọ́ láti mú kí ìgbésí ayé wọn túbọ̀ láàbò nípa gbígbájú mọ́ àwọn ohun tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìwàásù nìkan ni Àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe.

“Ẹ Ké Pe Jèhófà, Ọlọ́run Yín”

Ní July 1997, nígbà tí omi Odò Oder ya wọ àwọn àdúgbò púpọ̀ ní àríwá Yúróòpù, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Germany gbọ́ nípa ìṣòro tí ń bá àwọn ará Poland, alámùúlégbè wọn, fínra. Kí ni wọ́n lè ṣe? Olúkúlùkù Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń gbé Berlin àti àyíká rẹ̀ fi àgbàyanu ìwà ọ̀làwọ́ hàn nípa fífínnúfíndọ̀ ṣètọrẹ owó tí ó lé ní 116,000 dọ́là láàárín ọjọ́ díẹ̀.

Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n nírìírí nínú iṣẹ́ ìkọ́lé rin ìrìn àjò wákàtí mẹ́fà nínú mọ́tò—lápò ara wọn—láti Berlin dé àwọn àgbègbè Wrocław, Poland. Ní ìlú kékeré kan, ọ̀pọ̀ ilé ló ti bàjẹ́ gan-an. Ilé ìdílé Ẹlẹ́rìí kan wà láàárín omi tí ó kún ju mítà mẹ́fà lọ. Ọmọ bàbá onílé náà ń múra láti ṣègbéyàwó ní oṣù tí ó tẹ̀ lé e, kí òun àti ọkọ rẹ̀ sì fi ibẹ̀ ṣe ilé. Kí ni wọ́n lè ṣe láti tún ilé náà ṣe, kí wọ́n sì ran ìdílé tí gbogbo ohun tí wọ́n ní ti fẹ́rẹ̀ẹ́ run tán náà lọ́wọ́?

Gbàrà tí omi náà fà díẹ̀, aládùúgbò wọn kan ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “Ẹ ò ṣe ké pe Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ sì wò ó bóyá òun yóò ràn yín lọ́wọ́?” Ẹ wo bí ẹnu ṣe ya aládùúgbò wọn náà tó nígbà tí àwọn ọkọ̀ bí mélòó kan dé láti Germany sí ilé ìdílé Ẹlẹ́rìí náà lọ́jọ́ kejì! Àwọn àlejò mélòó kan jáde láti inú àwọn ọkọ̀ náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàtúnṣe ilé náà. Aládùúgbò náà béèrè pé: “Ta ni wọ́n? Ta ni yóò sanwó àwọn ohun tí wọ́n ń lò?” Ìdílé Ẹlẹ́rìí náà ṣàlàyé pé àwọn arákùnrin àwọn nípa tẹ̀mí ni wọ́n, àti pé àwọn àlejò wọ̀nyẹn ni yóò sanwó àwọn ohun tí wọ́n ń lò. Ẹnu ya àwọn ènìyàn ìlú náà bí wọ́n ṣe ń wò ó tí a sọ ilé náà dọ̀tun. Ní gẹ́lẹ́, wọ́n ṣe ìgbéyàwó náà ní ọjọ́ tí wọ́n fi sí gan-an.

Ìdílé náà wá rí i pé kì í ṣe àǹfààní tẹ̀mí nìkan ni wíwà nínú ẹgbẹ́ ará ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń mú wá, àmọ́ ó tún ń fúnni ní ìwọ̀n ààbò díẹ̀ nínú ayé aláìláàbò. Àwọn nìkan kọ́ ni èyí ṣẹlẹ̀ sí. Ní gbogbo àgbègbè tí ìjábá yìí ti ṣẹlẹ̀, a tún àwọn ilé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni a kò gbàgbé àwọn aládùúgbò tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. A ṣe iṣẹ́ ribiribi ní ilé tiwọn náà, wọ́n sì mọrírì rẹ̀ gan-an.

Òdodo, Ìdákẹ́jẹ́ẹ́, àti Ààbò

Bí ara wa bá yá dáadáa, inú wa yóò dùn sí oníṣègùn tó tọ́jú wa gan-an! Bí a bá mú ìṣòro àìláàbò tí ó bo aráyé mọ́lẹ̀ kúrò títí láé—nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run—ọpẹ́ wa yóò ti pọ̀ tó sí Ẹlẹ́dàá wa! Bẹ́ẹ̀ ni, òun ló ń ṣèlérí ìgbésí ayé nínú “òdodo tòótọ́ . . . ; ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti ààbò fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Ẹ wo irú ìfojúsọ́nà àgbàyanu tí èyí jẹ́!—Aísáyà 32:17.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]

A lè dín wàhálà ìmọ̀lára kù nípa ṣíṣàìgbájúmọ́ ohun ti ara bí kò ṣe àwọn ohun tẹ̀mí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Ọlọ́run ṣèlérí ayé tuntun níbi tí gbogbo ènìyàn yóò wà nínú ààbò pípẹ́ títí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́