ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 10/8 ojú ìwé 4-6
  • Wíwá Ìgbésí Ayé Aláàbò Kiri

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwá Ìgbésí Ayé Aláàbò Kiri
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀kọ́ Gíga
  • Ǹjẹ́ 10,000 Ohun Ìní Tó?
  • Ṣọ́ra!
  • Ẹ Má Yanjú Àmì Ìṣòro Nìkan—Ẹ Yanjú Ìṣòro Pẹ̀lú
  • Ohun Tó Lè Mú Kí Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ Dáa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
  • Ṣó Dájú Pé Ọjọ́ Ọ̀la Ẹnì Kan Á Dáa Tó Bá Kàwé Dáadáa Tó Sì Lówó Rẹpẹtẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
  • Ìgbésí Ayé Tó Ní Ààbò Pípẹ́ Títí
    Jí!—1998
  • Bó O Ṣe Lè Ní Ìfọ̀kànbalẹ̀ Nísinsìnyí àti Títí Ayérayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 10/8 ojú ìwé 4-6

Wíwá Ìgbésí Ayé Aláàbò Kiri

OHUN tí ààbò túmọ̀ sí lójú ẹnì kan yàtọ̀ sí ohun tí ó túmọ̀ sí lójú ẹlòmíràn. Lójú ẹnì kan, ààbò túmọ̀ sí níní iṣẹ́ lọ́wọ́; lójú ẹlòmíràn, ó túmọ̀ sí níní ọrọ̀; lójú ẹnì kẹta, ààbò túmọ̀ sí àìsí ìwà ọ̀daràn láyìíká rẹ̀. Ǹjẹ́ ó túmọ̀ sí ohun mìíràn lójú tìrẹ?

Ohun yòówù kí ó túmọ̀ sí lójú rẹ, ó dájú pé o ń gbé ìgbésẹ̀ láti gbìyànjú láti mú kí ìgbésí ayé rẹ láàbò tó bí o ṣe fẹ́ kí ó ní in. Gbé ohun tí àwọn ènìyàn ń ṣe láti ní ìwọ̀n ààbò díẹ̀ ní Yúróòpù yẹ̀ wò.

Ẹ̀kọ́ Gíga

Gẹ́gẹ́ bí Jacques Santer, ààrẹ Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù, ti sọ, ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ni kò níṣẹ́ lọ́wọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ìbéèrè tí àwọn tí wọ́n wà láàárín ọjọ́ orí yẹn ń béèrè ni pé, Báwo ni mo ṣe máa rí iṣẹ́ tí yóò fi mí lọ́kàn balẹ̀? Ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé ọ̀nà dídára jù lọ tí a lè gbà lé góńgó yìí bá jẹ́ nípa ẹ̀kọ́ gíga, tí ìwé ìròyìn The Sunday Times ti London sọ pé, ó ń fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní “àǹfààní ní ti rírí iṣẹ́.”

Fún àpẹẹrẹ, ní Germany, ìwé ìròyìn Nassauische Neue Presse sọ pé, “ìfẹ́ tí àwọn ènìyàn ní sí ẹ̀kọ́ àti ipò ọ̀mọ̀wé ṣì lágbára gan-an.” Èyí rí bẹ́ẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye tí yóò ná wọ́n, fún gbogbo ìgbà tí wọn óò fi kàwé ní yunifásítì ní orílẹ̀-èdè yẹn, jẹ́ nǹkan bí 55,000 dọ́là ní ìpíndọ́gba.

Ó yẹ kí a gbóríyìn fún àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n fi ọwọ́ gidi mú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí rírí iṣẹ́ tí ó fini lọ́kàn balẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ní òye iṣẹ́, àti àwọn ẹ̀rí ìtóótun sábà máa ń rọ́wọ́ mú nígbà tí ó bá ń wá iṣẹ́. Àmọ́, ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ gíga sábà máa ń jẹ́ kí a rí iṣẹ́ tí ń fini lọ́kan balẹ̀? Akẹ́kọ̀ọ́ kan sọ pé: “Mo mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pé ìlà ẹ̀kọ́ mi kò ní jẹ́ kí n lè rọ́wọ́ yọ bí amọṣẹ́dunjú, kò sì ní fi mí lọ́kàn balẹ̀.” Ọ̀ràn rẹ̀ kò ṣàjèjì. Ní ọdún kan láìpẹ́ yìí, iye àwọn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní yunifásítì, tí wọn kò níṣẹ́ lọ́wọ́ ní Germany, pọ̀ dé ìwọ̀n tí kò tíì dé rí.

Ìwé ìròyìn kan sọ pé, ní ilẹ̀ Faransé, àwọn ọ̀dọ́ ń lọ sí yunifásítì nítorí pé ìwé ẹ̀rí tí wọ́n ń gbà ní ilé ẹ̀kọ́ girama kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì ló mọ̀ pé tí àwọn bá parí ẹ̀kọ́ àwọn, ipò àwọn “kò lè sunwọ̀n sí i bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ti gba páálí.” Ìwé ìròyìn The Independent sọ pé, ní Britain, “àìfararọ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń rí nídìí ìwé kíkà ń fa ìyọnu ńlá fún wọn.” Ìròyìn sọ pé, dípò kí ìwé kíkà ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti kojú àìláàbò tí ó wà nínú ìgbésí ayé wọn, nígbà mìíràn, ìgbésí ayé ní yunifásítì ń fa àwọn ìṣòro bí ìsoríkọ́, àníyàn, àti àìdára-ẹni-lójú.

Lọ́pọ̀ ìgbà, kíkọ́ iṣẹ́ ọwọ́ kan tàbí gbígba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nínú ṣíṣe àwọn ohun kan jáde ń jẹ́ kí ẹnì kan ní iṣẹ́ tí yóò fi í lọ́kàn balẹ̀ ju ìgbà tó bá tó gba oyè yunifásítì.

Ǹjẹ́ 10,000 Ohun Ìní Tó?

Ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé ọrọ̀ ní ń jẹ́ kí a ní ìgbésí ayé aláàbò. Èyí lè jọ ojú ìwòye yíyè kooro láti fi wo ọ̀ràn náà, níwọ̀n bí owó tí ó pọ̀ tó tí a ní ní báńkì ti jẹ́ ohun tí a lè lò lásìkò ìṣòro. Bíbélì ṣàlàyé pé, “owó . . . jẹ́ fún ìdáàbòbò.” (Oníwàásù 7:12) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ àníkún ọrọ̀ sábà máa ń fúnni láàbò sí i?

Kò jọ bẹ́ẹ̀. Gbé bí àwọn ènìyàn ti ń ní àníkún ọrọ̀ tó ní 50 ọdún tó kọjá yẹ̀ wò. Lópin Ogun Àgbáyé Kejì, èyí tí ó pọ̀ jù lára àwọn ará Germany ni kò ní nǹkan kan. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Germany kan sọ pé, lónìí, ará Germany kan tí a lè mú gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ní 10,000 ohun ìní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ipò ọrọ̀ ajé bá ṣe rẹ́gí, àwọn ìran tí ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú yóò ní jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́, ṣé kíkó ọrọ̀ jọ yìí ń mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ láàbò sí i? Rárá. Ìwádìí tí a ṣe ní Germany fi hàn pé ẹni 2 lára àwọn 3 ka ìgbésí ayé sí èyí tí kò láàbò tó bí ó ṣe rí ní 20 ọdún sí 30 ọdún sẹ́yìn. Nípa bẹ́ẹ̀, kíkó ọrọ̀ jọ pelemọ kò mú kí àwọn ènìyàn túbọ̀ láàbò.

A lè lóye èyí nítorí pé bí a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tí ó ṣáájú, ríronú pé a wà láìláàbò jẹ́ wàhálà ìmọ̀lára. A kò sì lè fi ọrọ̀ yọra ẹni nínú wàhálà ìmọ̀lára pátápátá. Dájúdájú, ọrọ̀ dà bí ohun tí ń gbéjà ko ìṣẹ́, ó sì wúlò nígbà tí nǹkan bá le. Ṣùgbọ́n nínú àwọn ipò kan, ìnira tí ó wà nínú níní owó púpọ̀ kò kéré sí ti níní èyí tí kò pọ̀.

Nípa bẹ́ẹ̀, ìṣarasíhùwà tí ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa ọrọ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi sọ́kàn pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọrọ̀ lè jẹ́ ìbùkún, kì í ṣe lájorí ojútùú sí wíwà láàbò nínú ìgbésí ayé. Nígbà tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, ó gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Láti ní ààbò pípé nínú ìgbésí ayé ẹni, ohun tí a nílò ju ọrọ̀ lọ.

Kì í ṣe nítorí bí ohun ìní ṣe níye lórí tó ló ṣe pàtàkì sí àwọn arúgbó, bí kò ṣe nítorí àǹfààní ti ìmọ̀lára tí ó wà nínú ríronú pé a ní wọn. Ohun tó jẹ àwọn àgbàlagbà lógún ju ọrọ̀ lọ ni ewu kíkó sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn.

Ṣọ́ra!

Ìwé pẹlẹbẹ Practical Ways to Crack Crime tí wọ́n ṣe ní Britain sọ pé: “Ìwà ọ̀daràn . . . ti jẹ́ ìṣòro tí ń pelemọ jákèjádò ayé láàárín 30 ọdún tó kọjá.” Àwọn ọlọ́pàá ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó. Báwo ni àwọn ènìyàn kan ṣe ń kojú àwọn ìṣòro wọ̀nyí?

Dídáàdòbo ara ẹni ń bẹ̀rẹ̀ láti ilé. Fún àpẹẹrẹ, ní Switzerland, olùyàwòrán ilé kan ń gbájú mọ́ ẹ̀ka ti yíyàwòrán ilé tí ó ní àwọn ohun èlò tí ń dènà ìdigunjalè, kọ́kọ́rọ́ oríṣiríṣi, ilẹ̀kùn onírin ńláńlá, àti fèrèsé tí a kó irin sí dígbadìgba. Ó jọ pé àwọn onílé wọ̀nyẹn gba òwe tí a mọ̀ dáadáa náà to bẹ́ẹ̀ pé: “Ilé mi jẹ́ ibi ìsádi mi.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Focus ṣe sọ, owó ńlá ló gbé àwọn ilé wọ̀nyí dúró, àmọ́ àwọn ènìyàn ń fẹ́ ẹ gan-an.

Kí ààbò ara ẹni lè pọ̀ ní ilé àti lóde, àwọn ará àdúgbò kan ṣètò ṣíṣọ́ àdúgbò. Àwọn tí ń gbé irú àwọn àdúgbò bẹ́ẹ̀ kan tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n máa ń sanwó fún àwọn ilé iṣẹ́ ààbò láti máa rìn kiri àdúgbò wọn ní àwọn àkókò pàtó kan. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ronú pé kò bọ́gbọ́n mu láti rìn nígboro lóru ládùúgbò tí ó dá. Lọ́nà àdánidá, àwọn òbí tí àlámọ̀rí àwọn ọmọ wọn jẹ lọ́kàn lè túbọ̀ ṣọ́ra láti dáàbò bò wọ́n. Ṣàyẹ̀wò àwọn àbá tí ó wà nínú àpótí tó wà lójú ewé yìí.

Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló lágbára àtira ilé tí ó ní ohun èlò tí ń dènà ìdigunjalè. Láfikún sí i, àwọn ètò tí a ṣe ládùúgbò àti ìwọ́de ààbò lè máà dín ìwà ọ̀daràn kù lápapọ̀; wọ́n wulẹ̀ lè tì í sí àwọn àdúgbò tí a kò dáàbò bò. Nípa bẹ́ẹ̀, ìwà ọ̀daràn ṣì jẹ́ ewu ńlá lórí ààbò ara ẹni. Kí a lè láàbò nínú ìgbésí ayé wa, a nílò ohun púpọ̀ sí i ju ìsapá àfìtaraṣe láti ṣẹ́gun ìwà ọ̀daràn.

Ẹ Má Yanjú Àmì Ìṣòro Nìkan—Ẹ Yanjú Ìṣòro Pẹ̀lú

Olúkúlùkù wa ló ní ìfẹ́ àdánidá fún ìgbésí ayé aláàbò, yóò sì dára kí a gbé ìgbésẹ̀ tí ó bọ́gbọ́n mu, tí ó sì wúlò láti ṣàṣeparí góńgó yìí. Àmọ́ ìwà ọ̀daràn, àìríṣẹ́ṣe, àti gbogbo ohun mìíràn tí ń mú kí ìgbésí ayé wa wà nínú ewu wulẹ̀ jẹ́ àmì ìṣòro kan tí ń yọ gbogbo aráyé lẹ́nu ni. Láti yanjú ìṣòro náà, ó pọn dandan láti gbéjà ko okùnfà náà gan-an, kì í ṣe àmì ìṣòro náà lásán.

Kí ni lájorí okùnfà àìláàbò nínú ìgbésí ayé wa? Báwo ni a ṣe lè mú un kúrò, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ mú àìláàbò kúrò nínú ìgbésí ayé títí láé? A óò jíròrò èyí nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé èyí.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Ọ̀nà Tí A Lè Gbà Dáàbò Bo Àwọn Ọmọdé

Nítorí bí bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe, jíjí ọmọ gbé, àti ìpànìyàn ṣe ń ṣe lemọ́lemọ́, ọ̀pọ̀ òbí ti rí i pé àǹfààní wà nínú kíkọ́ àwọn ọmọ wọn láti ṣe àwọn ohun wọ̀nyí:

1. Sọ pé rárá—láìgbagbẹ̀rẹ́—fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbìyànjú láti mú kí ó ṣe ohun tí ó lérò pé kò dára.

2. Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fọwọ́ kan àwọn ẹ̀yà ara ìbímọ rẹ̀ àyàfi—bí ó bá jẹ́ dókítà tàbí nọ́ọ̀sì—tí ọ̀kan lára òbí rẹ̀ bá wà níbẹ̀.

3. Sá lọ, kígbe, lọgun, tàbí ké sí àgbàlagbà tó bá wà nítòsí láti ràn án lọ́wọ́ tí ó bá wà nínú ewu.

4. Sọ fún àwọn òbí nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ tàbí ìjíròrò tí kò mú kí ara rọ ọmọ náà.

5. Má fi àṣírí pa mọ́ fún àwọn òbí.

Kókó tí ó gbẹ̀yìn ni pé, yóò dára bí àwọn òbí bá lo ìṣọ́ra nípa ẹni tí wọn óò yàn láti fi ọmọ wọn tì.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Kí ìgbésí ayé wa lè láàbò, a nílò ju ẹ̀kọ́, ọrọ̀, tàbí ìsapá onítara láti ṣẹ́gun ìwà ọ̀daràn lọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́