ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 4/15 ojú ìwé 3-4
  • Alaafia Aye Ha Wà Ni Ojutaye Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Alaafia Aye Ha Wà Ni Ojutaye Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ogun Ti A Kò Fiyesi
  • Ireti Fun Alaafia Ha Wa Bi?
  • Àlàáfíà Tòótọ́—Láti Orísun Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ẹ Jẹ Ki “Alaafia Ọlọrun” Maa Daabobo Ọkan-aya Yin
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Nigba Wo ni Alaafia Pipẹtiti Yoo De Niti Gidi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Awọn Ìwéwèé Eniyan Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 4/15 ojú ìwé 3-4

Alaafia Aye Ha Wà Ni Ojutaye Bí?

JALẸJALẸ itan, kò tii si igba ti a kò ṣe awọn iwewee alaafia ati ipolongo alaafia iru kan tabi omiran. O ṣeni laanu pe, bẹẹ gẹlẹ ni ọpọlọpọ ogun ti wà lati sọ wọn di asán. Bi o ba ṣe ti awọn imulẹ adehun ati ipolongo ni, ọpọ julọ awọn eniyan ti kẹkọọ lati maṣe fi igbọkanle pupọ sinu wọn.

Bi o ti wu ki o ri, laaarin iwọnba ọdun diẹ ti o kọja, ọpọlọpọ awọn alakiyesi ati aṣayẹwo irohin ti bẹrẹ sii nimọlara pe ohun kan ti o yatọ ti nṣelẹ. Wọn ti gbé ṣiṣeeṣe naa dide pe, laika awọn iṣoro agbegbe sí, alaafia aye ni a le murasilẹ fun ni akoko yii. Stockholm International Peace Institute wi pe: “Ireti fun fifi alaafia yanju awọn iforigbari ni a fidii rẹ mulẹ daradara ju ọdun eyikeyii miiran lọ lati opin Ogun Agbaye Keji.” Gbajumọ akọrohin kan ni a sún nipa awọn iṣẹlẹ ti nyarakankan ni iha Ila-oorun Europe lati polongo pe: “Alaafia lori Ilẹ Aye dabii pe o ṣeeṣe jù nisinsinyi ju akoko eyikeyii miiran lati igba Ogun Agbaye Keji.” Ani iwe irohin naa The Bulletin of the Atomic Scientists fi imọlara yii han. Ni 1988 o yí agogo ọjọ́ àgbákò iparun rẹ̀ olokiki lati aago mejila òru ku iṣẹju mẹta si aago mejila òru ku iṣẹju mẹfa, ati lẹhin naa ni April 1990 o tún yi i sẹhin si aago mejila òru ku iṣẹju mẹwaa.

Gbogbo eyi ti ru ẹmi nǹkan yoo dara ati itara ayọ̀ pupọpupọ soke ṣaaju ibẹsilẹ ogun ni Aarin Ila-oorun aye. Ṣugbọn lati ìgbà naa paapaa, awọn eniyan kan nsọrọ nipa Ogun Tutu ati sisare le awọn ohun ìjà ogun laaarin awọn alagbara ògbóǹtarìgì gẹgẹ bi eyi ti o ti dopin. Awọn kan ńgbèrò nipa ohun ti a nilati ṣe pẹlu gbogbo owó ti awọn ijọba nreti lati ri kojọ lati inu inawo ologun ti o ti dinku. O ha ṣeeṣe pe akoko naa fun alaafia pipẹtiti ti de niti gidi? Njẹ awọn orilẹ-ede nitootọ ha nkẹkọọ lati “fi idà wọn rọ ohun eelo itulẹ ati ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé bi”? (Aisaya 2:4) Ki ni awọn otitọ fihan?

Awọn Ogun Ti A Kò Fiyesi

“Opin ogun tutu naa ati idẹra laaarin Ila-oorun ati Iwọ-oorun ti tan awọn kan lati gbagbọ pe alaafia ni ohun ti o gbòde,” ni The Economist ti London ṣakiyesi. “Kii ṣe bẹẹ. Nigba ti o bọ́ lọwọ orisun aifararọ titobi, aye ṣì ni ọpọlọpọ aifararọ kekeke.” Ki ni awọn aifararọ, tabi iforigbari “kekeke” wọnyi?

Ile Ayẹwo Iwadii Nipa Alaafia ti Lentz [Lentz Peace Research Laboratory] ti o jẹ eto-ajọ adani kan fun iwadii ni United States, rohin pe titi di September 1990, o keretan awọn ogun mẹẹdogun ni a nja yika ayé. Eyi kò ni yíya tí Iraq yawọ Kuwait ninu, niwọnbi irohin naa ti ka kiki awọn ogun ninu eyi ti a ti pa o keretan ẹgbẹrun eniyan ni ọdun kan titi di akoko yẹn. Diẹ lara awọn ogun wọnyi ti nbaa lọ fun ogún ọdun tabi ju bẹẹ lọ. Lapapọ wọn ti gba iwalaaye 2,900,000, ti ọpọ julọ ninu awọn wọnyi sì jẹ awọn ara ilu. Iye yii ko kan awọn wọnni ti a pa ninu diẹ lara awọn ogun atajẹsilẹ julọ ti o ṣẹṣẹ wa si opin ni ọdun ti o ṣaaju, iru bii ti Uganda, Afghanistan, ati Iran oun Iraq.

Nǹkan ti o fẹrẹẹ to million mẹta awọn eniyan ni a pa nigba ti a rò pe aye wà ni alaafia! Iyẹn funraarẹ jẹ ọran ibanujẹ. Bi o ti wu ki o ri, ọran ibanujẹ titobi ju naa ni pe, o fẹrẹẹ jẹ pe iyooku araye kò ṣakiyesi pe awọn ogun wọnyi ti nbaa lọ—wọn kò sì kédàárò—nipa rẹ̀. Wọn jẹ ohun ti a lè pè ni awọn ogun ti a kò fiyesi, niwọn bi o ti jẹ pe ọpọ julọ ninu wọn—fifi ipá gba ijọba, ogun abẹle, iyipada tegbòtigaga—ni a ńjà ninu ọkan tabi omiran lara awọn orilẹ-ede ti wọn ṣẹṣẹ ngoke àgbà. Fun ọpọ julọ awọn eniyan ninu orilẹ-ede ọlọ́rọ̀, ti wọn ti gòkè àgbà, ilaji aadọta ọkẹ awọn eniyan ti a pa ni Sudan, tabi ìlàta aadọta ọkẹ ti a pa ni Angola, ni kò dabi pe o fa afiyesi awọn eniyan pupọ. Niti tootọ, awọn kan wà ti wọn njiyan pe aye ti wà ni saa akoko alaafia alailẹgbẹ lati igba Ogun Agbaye Keji nitori pe ko si ogun eyikeyii laaarin awọn orilẹ-ede ti wọn ti gòkè àgbà ati, laika aifararọ ati ikojọ rẹpẹtẹ awọn ohun ija ologun sí, awọn alagbara ògbóǹtarìgì kò tii bẹrẹ ogun lodisi araawọn.

Ireti Fun Alaafia Ha Wa Bi?

Bi alaafia ba tumọ ni ṣakala si aisi ogun àgbá atọmiiki yika aye, nigba naa boya ẹnikan lè jiyan pe awọn orilẹ-ede aye ti ni iwọnba aṣeyọrisi rere bayii ninu awọn isapa wọn fun alaafia. Iwewee nipa Àmúdájú Iparun Tọtuntosi [Mutual Assured Destruction] ni o ti ṣedilọwọ fun awọn alagbara ògbóǹtarìgì titi fi di ìwòyí. Ṣugbọn iyẹn ha jẹ alaafia niti gidi bi? Bawo ni o ṣe le jẹ bẹẹ, nigba ti awọn eniyan ngbe ninu ibẹru igba gbogbo nipa iparun raurau loju ẹsẹ? Bawo ni a ṣe lè sọrọ nipa alaafia nigba ti o jẹ pe, igbesi-aye ọpọlọpọ eniyan ni a ti run patapata yika aye, ọna àtijẹ àtimu wọn ni a ti bẹ́gidí ti a sì ti pa ifojusọna wọn fun iwalaaye ti o ni itumọ ti o sì tẹnilọrun rẹ́ nipasẹ awọn ogun, nla ati kekere?

Olugba ẹ̀bùn Nobel Elie Wiesel kọwe lẹẹkan ri pe: “Lati igba laelae, awọn eniyan ti sọrọ nipa alaafia laifọwọ bà á. Awa ha wulẹ ṣaini iriri ti o pọ̀ to ni bi? Bi o tilẹ jẹ pe a nsọrọ alaafia, ogun ni a nja. Nigba miiran a tilẹ nja ogun ni orukọ alaafia paapaa. . . . Ogun le jẹ apa kan ti o pọ ju lati yọ kuro ninu itan—lae.”

Ati pe laipẹ yii ogun ti a nja ni Aarin Ila-oorun aye tun ti ba ẹ̀tàn alaafia naa jẹ. O ha le jẹ pe araye wulẹ ti nwo orisun ti kò tọna fun alaafia ni bi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

“Iran eniyan yii lori ilẹ aye lè rí dide akoko alaafia alaiṣeeyipada kan ninu itan ọ̀làjú.”—Aarẹ Soviet Mikhail Gorbachev, ni ipade awọn olori orilẹ-ede ni Washington, D.C., U.S.A., May 1990

[Credit Line]

UPI/Bettmann Newsphotos

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

“Aye titun kan ti o jẹ ti ominira wà ni iwaju wa  . . . , aye kan nibi ti alaafia ti wa pẹtiti, nibi ti ètò ìṣòwò ti ni ẹri-ọkan ati nibi ti gbogbo ohun ti o jọ pe o ṣeeṣe ti ṣeeṣe.”—Aarẹ U.S. George Bush, ni ipade eto ìṣòwò ti awọn olori orilẹ-ede ni Houston, Texas, U.S.A., July 1990

[Credit Line]

UPI/Bettmann Newsphotos

“Awọn ògiri ti wọn ti sé awọn eniyan ati èrò ọkàn mọ́ ńwó lulẹ. Awọn ara Europe npinnu kádàrá tiwọn funraawọn. Wọn ńyan ominira. Wọn ńyan idasilẹ ọrọ̀-ajé. Wọn ńyan alaafia.”—Ipolongo lati ẹnu NATO ni ipade awọn olori orilẹ-ede ni London, England, July 1990

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Fọ́tọ̀ ẹ̀yìn ìwé: (àwọn ìràwọ̀) fọ́tò U.S. Naval Observatory; (ayé) fọ́tò NASA.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́