ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 10/8 ojú ìwé 14-17
  • Kí Ló Máa Kẹ́yìn Ogun?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Máa Kẹ́yìn Ogun?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èrò Pé Ogun Ò Dáa
  • Ìsapá Kárí Ayé Láti Mú Àlàáfíà Wá
  • Bí Ogun Ọjọ́ Iwájú Ṣe Máa Rí
  • Kí Ni Ìṣòro Náà?
  • Ta Ló Lè Mú Àlàáfíà Pípẹ́ Títí Wá?
    Jí!—1996
  • Awọn Ìwéwèé Eniyan Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ayé Kan Láìsí Ogun Ha Ṣeé Ṣe Bí?
    Jí!—1996
  • Àlàáfíà Tòótọ́—Láti Orísun Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 10/8 ojú ìwé 14-17

Kí Ló Máa Kẹ́yìn Ogun?

ÒPÌTÀN ogun kan tó ń jẹ́ John Keegan sọ pé: “Láàárín ẹgbàajì [4000] ọdún tí a fi ṣàyẹ̀wò tí a sì ja àjàtúnjà ogun, ó ti wá di àṣà sí wa lọ́rùn.” Ṣé a wá lè já ara wa gbà lọ́wọ́ àṣà náà? Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti ṣòfò nínú ogun. Agbára àrà ọ̀tọ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun àmúṣọrọ̀ la ti fi ṣètìlẹ́yìn fún ogun. Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti fara jin wíwádìí àwọn ọ̀nà tuntun tó tún níkà láti fi pani àti láti fi ba nǹkan jẹ́. Ǹjẹ́ àwọn èèyàn ń fi irú ìtara kan náà hàn tó bá di ọ̀ràn gbígbé àlàáfíà lárugẹ? Ó dájú pé kò rí bẹ́ẹ̀! Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ronú pé àwọn ìdí kan wà tó lè mú ká ní ẹ̀mí pé nǹkan á dára.

Èrò Pé Ogun Ò Dáa

Èrò pé nǹkan á dára náà dá lórí ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn pé àwọn ọ̀làjú èèyàn ò ka ogun sí bí wọ́n ṣe kà á sí nígbà kan rí. Ní ọ̀rúndún kẹtàlá, a gbọ́ pé Genghis Khan tó jẹ́ jagunjagun ará Mongolia sọ pé: “Ohun tó máa ń múnú wa dùn ni pé ká ṣẹ́gun ọ̀tá, ká máa dà wọ́n lọ bí ẹni da màlúù, ká kó wọn lẹ́rù, ká fi wọ́n ṣẹlẹ́yà, ká fipá bá àwọn ìyàwó àti ọmọbìnrin wọn lòpọ̀.”

Èèyàn ò lè ronú pé kí ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ayé sọ irú ọ̀rọ̀ yẹn lóde òní! Ìwé A History of Warfare sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè má ṣeé ṣe níbikíbi lágbàáyé lónìí láti rí èrò tó ṣe gúnmọ́ tó gbe ọ̀rọ̀ náà lẹ́yìn pé àwíjàre wà fún ogun.” Àwọn èèyàn níbi gbogbo ò tún wo ogun bí ohun tó tọ́, tó bá ìwà ẹ̀dá mu, tó jẹ́ àyìnlógo, tàbí èyí tó ń wúni lórí. Ìpakúpa tí ogun ti pa àwọn èèyàn ní ọ̀rúndún ogún yìí ti mú kí aráyé máa bẹ̀rù ogun kí wọ́n sì kórìíra rẹ̀. Òǹkọ̀wé kan sọ pé ìkórìíra tí àwọn èèyàn ní sí ìwà ipá yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè fagi lé fífìyà ikú jẹ́ àwọn ọ̀daràn, ó sì ti mú kí a máa ṣojú àánú sí àwọn tí wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò ológun.

Kì í ṣe kíkórìíra tí àwọn èèyàn kórìíra ìpààyàn nípakúpa nìkan ló yí ìṣarasíhùwà wọn padà. Ọ̀ràn pàtàkì ti dídáàbò bo ẹ̀mí ara ẹni wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Agbára ìpanirun tí àwọn ohun ìjà ìgbàlódé, ìyẹn àwọn tó jẹ́ ọ̀gbálẹ̀gbáràwé àti àwọn tó wọ́pọ̀, ní pọ̀ gan-an débi pé ogunkógun tó bá bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn alágbára ayé pàtàkì lónìí á yọrí sí pípa tọ̀túntòsì run ráúráú. Dídá ogun ńlá sílẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ ìwà wèrè, ìpara-ẹni. Ọ̀pọ̀ èèyàn ṣàlàyé pé èrò tó lágbára yìí ni kò tíì jẹ́ kí ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé bẹ́ sílẹ̀ léyìí tó lé ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn.

Ohun mìíràn wà tó ń fà á tí ìrònú àwọn èèyàn kan nípa ọjọ́ iwájú fi yàtọ̀. Kì í ṣe kìkì nítorí pé a lè pàdánù ohun gbogbo làwọn kan fi gbà pé ogun ò dáa, ṣùgbọ́n nítorí pé èyí tí a lè ṣẹ́gun nínú rẹ̀ kò tó nǹkan pẹ̀lú. Ohun tó fi jọ pé ogun ńlá kò lè bẹ́ sílẹ̀, téèyàn bá gbé ọ̀ràn ètò ọrọ̀ ajé yẹ̀ wò nìyí: Àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ àti agbára láyé ń jàǹfààní gan-an nípasẹ̀ àjọṣe ètò ọrọ̀ ajé. Àǹfààní tí àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ń jẹ nígbà tí kò sí ogun ju èyí tí ogun lè mú wá lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, ìdí gúnmọ́ wà tó fi yẹ kí àwọn orílẹ̀-èdè alágbára máa wà lálàáfíà pẹ̀lú ara wọn. Ní àfikún sí i, yóò ṣe wọ́n láǹfààní tí wọ́n bá para pọ̀ láti ṣẹ́pá ogun láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí kò lágbára púpọ̀ tó jẹ́ ewu fún ipò ètò ọrọ̀ ajé wọn.

Ìsapá Kárí Ayé Láti Mú Àlàáfíà Wá

Wọ́n mẹ́nu kan fífẹ́ láti fòpin sí ogun nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìwé tí wọ́n kọ ète Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sí. A kà níbẹ̀ nípa ìpinnu àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ mẹ́ńbà àjọ náà pé, “láti dáàbò bo àwọn ìran ènìyàn tí ń bọ̀ lọ́wọ́ àjálù ogun, tó ti fa ìbànújẹ́ ńlá fún aráyé lẹ́ẹ̀mejì [nínú ogun àgbáyé méjì tó jà] lójú wa kòrókòró.” A sọ nípa ìpinnu láti dáàbò bo àwọn ìran ènìyàn tí ń bọ̀ lọ́wọ́ ogun nínú èròǹgbà ààbò àjọkọ́wọ́tì—ìyẹn èròǹgbà pé kí àwọn orílẹ̀-èdè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti kọ̀yìn sí orílẹ̀-èdè èyíkéyìí tí wọ́n bá rí i pé ó jẹ́ oníjàgídíjàgan. Nípa bẹ́ẹ̀, bí orílẹ̀-èdè èyíkéyìí bá fẹ́ gbógun, yóò rí pípọ́n ojú àwùjọ àgbáyé.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èròǹgbà náà rọrùn, ó sì mọ́gbọ́n dání, títẹ̀lé e ni ohun mìíràn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ààbò àjọkọ́wọ́tì, ní àwọn ọ̀nà tó yàtọ̀ díẹ̀, kó ipa pàtàkì nínú Ẹ̀jẹ́ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, tó sì jẹ́ apá kan Àkọsílẹ̀ Ète Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ó ti kùnà lọ́nà méjèèjì. Níwọ̀n bí àwọn orílẹ̀-èdè kò ti ní ìjọba àgbáyé kan tó dáńgájíá tó lè yanjú ọ̀ràn náà pátápátá, wọn ò tíì fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tó yẹ kí wọ́n kà sí ìwà jàgídíjàgan pọ́ńbélé, wọn ò tíì fi hàn nínú ìṣe wọn pé àwọn tẹ́wọ́ gba ìlànà pé àwọn gbọ́dọ̀ kọ̀yìn sí ìwà jàgídíjàgan láìka ẹni yòówù tó hùwà náà sí, nípa bẹ́ẹ̀, wọn ò tíì ní ikọ̀ ààbò àjọkọ́wọ́tì àgbáyé tí wọ́n finú rò nínú Àkọsílẹ̀ Ète náà.”

Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èrò ti dídá ẹgbẹ́ kan sílẹ̀ tí iṣẹ́ wọ́n jẹ́ láti ṣèrànwọ́ kí àlàáfíà lè wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè jẹ́ ohun tuntun nínú àlámọ̀rí ènìyàn. Èrò ọ̀pọ̀ èèyàn tí ń yán hànhàn fún àlàáfíà ni pé àwọn tí ń rí sí ọ̀ràn àlàáfíà ní àjọ UN, tí wọ́n máa ń dé fìlà aláwọ̀ búlúù, ṣì jẹ́ àmì pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa. Èrò wọ́n dà bíi ti akọ̀ròyìn kan tó gbóríyìn fún “èròǹgbà níní àwọn sójà àlàáfíà, tí a ń rán lọ sí àwọn ibi tí ogun ti ń jà, kì í ṣe láti lọ gbógun, bí kò ṣe láti lọ ṣèrànwọ́ kí àlàáfíà lè wà, kì í ṣe láti lọ bá àwọn ọ̀tá jà, bí kò ṣe láti lọ ran àwọn ọ̀rẹ́ lọ́wọ́.”

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ tó ń jà rànyìn ti pín àjọ UN sí ìsọ̀rí agbára méjì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìtẹ̀sí láti dabarú ohunkóhun tí èkejì bá ní lọ́kàn láti ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé píparí tí Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ náà parí kò mú ogun, àìgbẹ́kẹ̀léni, àti fífura tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fura síra wọn kúrò pátápátá, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé bí ọ̀ràn ìṣèlú ṣe ń lọ ti wá pèsè àǹfààní tí irú rẹ̀ kò sí rí fún àjọ UN láti máa ṣe ohun tí a pète rẹ̀ láti máa ṣe.

Àwọn ohun tuntun mìíràn tó ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún pẹ̀lú ń fún àwọn tó ń yán hànhàn fún àlàáfíà nírètí. Fún àpẹẹrẹ, ète tí wọ́n ṣe ń ṣètò ìjíròrò láàárín àwọn orílẹ̀-èdè jẹ́ nítorí àtiyanjú ogun nítùnbí-ìnùbí. Ṣíṣèrànwọ́ fáwọn tójú ń pọ́n ń ran àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ láti mú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn bọ̀ sípò àti láti ran àwọn tí ogun ti ṣe báṣubàṣu lọ́wọ́. Ṣíṣèrànwọ́ kí àlàáfíà lè wà àti ṣíṣètò àrànṣe tó wà fún ríran ẹ̀dá lọ́wọ́ ti di apá kan ètò nípa ọ̀ràn òkèèrè. A ń dá àwọn tí ń ṣètìlẹ́yìn fún àlàáfíà lọ́lá.

Bí Ogun Ọjọ́ Iwájú Ṣe Máa Rí

Àmọ́, tí a bá ń ronú nípa pé nǹkan yóò dára, a gbọ́dọ̀ retí pé ìṣòro díẹ̀ á wà. Nígbà tí Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ parí ní ọdún 1989, ọ̀pọ̀ èèyàn ló fi ìgbẹ́kẹ̀lé tí wọ́n ní nínú ètò ayé alálàáfíà hàn. Síbẹ̀, ogun ò yé jà. Láàárín ọdún méje tó tẹ̀ lé e, ogun mọ́kànlélọ́gọ́rùn-ún la fojú díwọ̀n pé ó bẹ́ sílẹ̀ ní ibì kan tẹ̀ lé òmíràn. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ogun náà kì í ṣe láàárín orílẹ̀-èdè méjì bí kò ṣe ogun abẹ́lé. Àwùjọ àwọn tí ń ṣòdì síra, tí kò ní ohun ìjà alágbára ló bá ara wọn jà nínú ogun wọ̀nyẹn. Fún àpẹẹrẹ, ní Rwanda, àdá ni wọ́n fi pa àwọn èèyàn jù níbẹ̀.

Lọ́pọ̀ ìgbà, àárín ìlú àti abúlé ló wá di pápá ogun lóde òní, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ láàárín àwọn jagunjagun àti àwọn aráàlú. Michael Harbottle, olùdarí Ibùdó Ètò Àlàáfíà Àgbáyé, kọ̀wé pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, a lè sọ tẹ́lẹ̀ dé àyè kan pé ohun báyìí ló ń fa ogun, àmọ́ lónìí wọ́n túbọ̀ díjú, wọ́n sì túbọ̀ ṣòro láti darí. Ìwọ̀n ìwà ipá tí ń bá wọn rìn jẹ́ ìyàlẹ́nu gbáà, kò sì yéni. Ó ṣeé ṣe kí àwọn aráàlú fara gbọta bíi pé àwọn gan-an ló ń jagun.” Kò sì jọ pé irú àwọn ogun abẹ́lé tí a ti ń lo ohun ìjà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ bẹ́ẹ̀ yóò dáwọ́ dúró.

Síbẹ̀ náà, àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ láyé kàn ń ṣe àwọn ohun ìjà atamátàsé lọ ni yàà. Àwọn ẹ̀rọ tí a fi ń wo nǹkan—yálà èyí tí a gbé sínú afẹ́fẹ́, sínú gbalasa òfuurufú, sínú òkun, tàbí sórí ilẹ̀—ń jẹ́ kí jagunjagun ìgbàlódé kan tètè rí nǹkan kedere ju ti tẹ́lẹ̀ rí lọ, kódà ní àwọn ibi tó ṣòro láti wọ̀ bí inú igbó. Gbàrà tí àwọn ẹ̀rọ tí a fi ń wo nǹkan bá ti fojú sun ibì kan, àwọn bọ́ǹbù atamátàsé, àwọn ọkọ̀ ogun tí ń fọ́ ọkọ̀ yángá, tàbí àwọn bọ́ǹbù onítànṣán olóró lè lọ fọ́ ibẹ̀—lọ́pọ̀ ìgbà láìtàsé. Bí a ti ń mú àwọn ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tuntun sunwọ̀n sí i tí a sì ń ṣàkójọ wọn, “ogun àtọ̀nà-jíjìn-jà” ń di èyí tó ṣeé ṣe, ó ń jẹ́ kí jagunjagun kan lè rí ohun gbogbo, kó rọ̀jò ọta lu ohun gbogbo, kó sì ba ohun púpọ̀ tó jẹ́ ti ọ̀tá jẹ́.

Bí a bá ń gbé ọ̀rọ̀ nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ogun lọ́jọ́ iwájú yẹ̀ wò, kò yẹ ká gbàgbé ewu ti ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé. Ìwé ìròyìn The Futurist sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Pípọ̀ tí àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ń pọ̀ sí i ń mú kó túbọ̀ jọ pé ogun átọ́míìkì kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lè ṣẹlẹ̀ láàárín ọgbọ̀n ọdún tó ń bọ̀. Ní àfikún sí i, àwọn akópayàbáni pẹ̀lú lè lo ohun ìjà átọ́míìkì.”

Kí Ni Ìṣòro Náà?

Kí ló ń dọwọ́ àwọn èèyàn tí ń gbìyànjú láti mú kí àlàáfíà wà kárí ayé délẹ̀? Kókó kan tó hàn gbangba ni pé aráyé ò ṣọ̀kan. Aráyé pínra wọn sí orílẹ̀-èdè àti àṣà ìbílẹ̀ tí kò gbẹ́kẹ̀ lé ara wọn, tó kórìíra ara wọn, tó sì ń bẹ̀rù ara wọn. Àwọn ìlànà, èròǹgbà, àti góńgó kan wà tí kò bára dọ́gba. Síwájú sí i, láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni a ti ń wo lílo agbára ogun bí ojúlówó ọ̀nà láti gbà lépa ire orílẹ̀-èdè ẹni. Lẹ́yìn tí ìròyìn kan láti Ẹ̀ka Ìwéwèé Ogun ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ológun ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà jẹ́rìí sí bí ipò nǹkan ṣe rí yìí, ó sọ pé: “Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, èyí fi hàn pé kìkì nípasẹ̀ ìjọba àgbáyé ni àlàáfíà yóò ti wá.”

Àwọn kan tí lérò pé ó lè jẹ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni ìjọba yẹn. Ṣùgbọ́n a kò pète àjọ UN láti jẹ́ ìjọba àgbáyé tó ní agbára ré kọjá ti àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀. Bí àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀ bá ṣe jẹ́ kó lágbára tó ló máa ní in. Ìfura àti àìfohùnṣọ̀kan kò yé ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn, agbára tí wọ́n sì ń fún àjọ UN ní ààlà. Nítorí náà, dípò kí àjọ UN máa darí ètò àgbáyé, ńṣe ló kàn jẹ́ àwòrán rẹ̀ lásán.

Bó ti wù kó rí, ó dájú pé àlàáfíà yóò wà jákèjádò ayé. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí fi bó ṣe máa ṣẹlẹ̀ hàn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]

“ARÁYÉ GBỌ́DỌ̀ RẸ́YÌN OGUN, BÍ BẸ́Ẹ̀ KỌ́ OGUN Á RẸ́YÌN ARÁYÉ.” —JOHN F. KENNEDY

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àjọ UN kò tíì di ìjọba àgbáyé

[Credit Line]

Fọ́tò UN

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́